ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/15 ojú ìwé 3-5
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ara Láìsí Ẹ̀mí Jẹ́ Òkú’
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ẹ̀mí Nígbà Téèyàn Bá Kú?
  • Ohun Tí Ẹ̀mí Jẹ́
  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ọkàn
    Jí!—2016
  • Kí Ni Ọkàn?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/15 ojú ìwé 3-5

Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?

Ṣé ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara òun ẹ̀jẹ̀ lásán ni wá? Àbí a tún ní ohun míì tó ju ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ lọ? Ṣé tá a bá ti gbé láyé fúngbà díẹ̀ tá a sì kú, ó parí náà nìyẹn? Àbí ohun kan tí ò ṣeé fojú rí wà nínú wa tó máa ń lọ gbé níbòmíì nígbà tá a bá kú?

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé onírúurú ẹ̀kọ́ tó lọ́jú pọ̀ ni ìsìn fi ń kọ́ni lórí ìgbàgbọ́ pé èèyàn máa ń ṣípò padà tó bá kú, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló gbà gbọ́ pé ohun kan wà nínú èèyàn tí kì í kú, pé ńṣe lohun náà máa ń lọ gbé níbòmíì lẹ́yìn téèyàn bá kú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé ẹ̀mí èèyàn lohun tí wọ́n sọ pé kì í kú yìí. Kí lèrò tìẹ? Kí ni ẹ̀mí jẹ́ gan-an? Ṣé ẹ̀mí èèyàn máa ń jáde lọ téèyàn bá kú? Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí yìí?

‘Ara Láìsí Ẹ̀mí Jẹ́ Òkú’

Nínú Bíbélì, ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n pè ní “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ní tààràtà ni “èémí” tàbí “afẹ́fẹ́.” Àmọ́, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” ju kéèyàn wulẹ̀ mí sínú tàbi kó mí síta lọ. Àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Bíbélì sọ pé: ‘Ara láìsí ẹ̀mí jẹ́ òkú.’ (Jákọ́bù 2:26) Nítorí náà, ẹ̀mí lohun tó ń mú kí ara wà láàyè.

Tá a bá tún wo ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbàrà tẹ́nì kan ò bá mí mọ́, ó máa túbọ̀ yé wa pé ẹ̀mí tó ń mú kí ara wà láàyè kì í wulẹ̀ ṣe èémí tàbí afẹ́fẹ́ tó máa ń gba inú ẹ̀dọ̀fóró kọjá. Ẹni náà lè jí padà bó bá rẹni tó lè sapá gan-an láti mí sí i lẹ́nu láìpẹ́ sígbà tí ò mí mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀mí ṣì wà nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara ẹni náà. Tí ẹ̀mí yẹn ò bá sí nínú ara rẹ̀ mọ́ rárá, kò sí bí ìsapá ọ̀hún ṣe lè pọ̀ tó, kò ní mí mọ́. Kódà kí wọ́n rọ gbogbo afẹ́fẹ́ ayé yìí sínú rẹ̀, ìyẹn o lè mú káwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà lára rẹ̀ padà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí ni ohun tó ń mú kí sẹ́ẹ̀lì inú ara máa ṣiṣẹ́ tó sì ń mú kéèyàn wà láàyè. Ara bàbá àti ìyá lẹ̀mí yìí ti máa ń dé ara ọmọ ní gbàrà tí ìyá bá fẹ́ra kù. Mímí téèyàn ń mí ló sì máa ń mú kí ẹ̀mí náà máa wà nìṣó nínú ara.—Jóòbù 34:14, 15.

Ǹjẹ́ ẹ̀mí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú wa ní? Àbí ẹ̀mí kan náà ló wà nínú gbogbo èèyàn? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí láìfi igbá kan bọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n ọba fi hàn pé ẹ̀mí kan náà ló wà nínú gbogbo ohun alààyè, ó ní: “Nítorí pé àtúbọ̀tán kan ni ó wà ní ti àwọn ọmọ aráyé àti àtúbọ̀tán kan ní ti ẹranko, àtúbọ̀tán kan náà sì ni wọ́n ní. Bí èkíní ti ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan ṣoṣo sì ni gbogbo wọ́n ní. . . . Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru. Ta ní ń bẹ tí ó mọ ẹ̀mí àwọn ọmọ aráyé, bóyá ó ń gòkè lọ sókè; àti ẹ̀mí ẹranko, bóyá ó ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sísàlẹ̀ ilẹ̀?” (Oníwàásù 3:19-21) Dájúdájú, ẹ̀mí kan náà lèèyàn àtẹranko ní.

A lè fi ẹ̀mí tó wà nínú èèyàn wé agbára iná mànàmáná tó máa ń mú nǹkan ṣiṣẹ́. Agbára iná mànàmáná téèyàn ò lè fojú rí yìí lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, ó sinmi lórí ohun èèlò téèyàn bá lò ó fún. Bí àpẹẹrẹ, ó lè tan gílóòbù, ó lè mú kí fáànù yí, ó lè mú kí rédíò sọ̀rọ̀, ó lè mú kí tẹlifíṣọ̀n ṣiṣẹ́ tá a fi máa rí àwòrán nínú rẹ̀, ó sì lè mú kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, agbára iná mànàmáná ò lè fúnra rẹ̀ ṣe èyíkéyìí lára nǹkan táwọn ohun èèlò wọ̀nyẹn ń ṣe. Tiẹ̀ ni pé kó sáà ti mú kí wọ́n ṣiṣẹ́. Agbára iná mànàmáná ni, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ẹ̀mí ṣe rí gan-an nìyẹn. Ẹ̀mí ò lè fúnra rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan tára ń ṣe. Ẹ̀mí kì í ṣe ẹ̀dá kan lọ́tọ̀ nínú ara bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè ronú. Ó wulẹ̀ jẹ́ ohun tó ń mú kí ara wà láàyè ni. Ẹ̀mí kan náà sì lèèyàn àtẹranko ní. Nítorí náà, téèyàn bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ kì í lọ gbé níbòmíì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá kan lọ́tọ̀ tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí.

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ẹ̀mí Nígbà Téèyàn Bá Kú?

Oníwàásù 12:7 sọ pé nígbà téèyàn bá kú, “ekuru yóò padà sí ilẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀, àní ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.” Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé ńṣe ni ẹ̀mí ń jáde kúrò lára táá wá mú ọ̀nà ọ̀run pọ̀n láti lọ bá Ọlọ́run o. Ìwọ wo àpẹẹrẹ kan ná. Jèhófà gbẹnu wòlíì Málákì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.” (Málákì 3:7) Ohun tí gbólóhùn yìí, “padà” sọ́dọ̀ Jèhófà túmọ̀ sí ni pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn jáwọ́ nínú ìwàkiwà, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa òfin òdodo Ọlọ́run mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Pípadà tí Jèhófà sì máa “padà” sọ́dọ̀ wọn túmọ̀ sí pé á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣojú rere sí wọn bíi tàtẹ̀yìnwá. Kì í ṣe pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á lọ bá Jèhófà lọ́run tàbí pé Jèhófà á wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé. Èyí fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ibi tí Bíbélì ti lo ọ̀rọ̀ náà “padà” ló ti túmọ̀ sí pé kéèyàn kúrò níbì kan lọ síbòmíì.

Bákan náà, téèyàn bá kú, pé ‘ẹ̀mí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fi í fúnni’ wúlẹ̀ túmọ̀ sí pé, tí ẹ̀mí yẹn bá ti lè jáde kúrò lára, Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ló lè dá ẹ̀mí náà padà. Òun ló kúkú fi í fún ẹni náà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kẹ́ni náà padà wà láàyè lọ́jọ́ iwájú.

Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Ìhìn Rere Lúùkù sọ nípa ikú Jésù Kristi. Ó ní: “Jésù sì fi ohùn rara kígbe, ó sì wí pé: ‘Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.’ Nígbà tí ó ti sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.” (Lúùkù 23:46) Nígbà tí Jésù kú, pé ẹ̀mí rẹ̀ jáde kúrò lára rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ lókè ọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n sin ín sínú sàréè. Aláìsí ni títí tí Ọlọ́run fi jí i dìde lọ́jọ́ kẹta. (Oníwàásù 9:5, 10) Kódà, kì í ṣe gbàrà tí Jésù jíǹde ló ti lọ sókè ọ̀run. Kó tó lọ, “ó fi ara rẹ̀ hàn . . . láàyè” fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “jálẹ̀jálẹ̀ ogójì ọjọ́,” ẹ̀yìn náà ló wá lọ “sókè” ọ̀run. (Ìṣe 1:3, 9) Nígbà tí Jésù kú, pé ó ‘fi ẹ̀mí rẹ̀ lé ọwọ́ Bàbá rẹ’ túmọ̀ sí pé ó dá a lójú pé Jèhófà yóò jí òun dìde.

Ohun Tí Ẹ̀mí Jẹ́

Kò sí àní-àní pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí ẹ̀mí jẹ́. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí gbọ́dọ̀ wà lára èèyàn kéèyàn tó lè wà láàyè. Èémí tàbí afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú ló sì ń mú kí ẹ̀mí yẹn máa wà nínú ara nìṣó. Nítorí náà, kò sí nǹkan kan lára èèyàn tó máa ń lọ gbé níbòmíì nígbà téèyàn bá kú.

Pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí jẹ́ yìí, bí àwọn tó ti kú yóò bá padà wà láàyè, àfi kí Ọlọ́run jí wọn dìde. Bíbélì ṣèlérí pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Ìlérí tó dájú yìí pé àjíǹde máa wáyé ni ìrètí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ táwọn òkú ní, kì í ṣe ìgbàgbọ́ pé ẹ̀mí kì í kú táwọn ìsìn fi ń kọ́ni.

Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kéèyàn ní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí àjíǹde jẹ́ àti àǹfààní tó máa ṣe fáráyé! Bákan náà, ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti Kristi ṣe pàtàkì. (Jòhánù 17:3) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ìmọ̀ tó o ní nípa Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìlérí Rẹ̀ lè pọ̀ sí i. Jọ̀wọ́, kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní

[Credit Line]

Ewúrẹ́: CNPC—Centro Nacional de Pesquisa de Caprinos (Sobral, CE, Brasil)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́