ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 15-20
  • Dúró Sí “Ìlú Ààbò” Kí O Sì Wà Láàyè!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dúró Sí “Ìlú Ààbò” Kí O Sì Wà Láàyè!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ha Jẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ Ní Tòótọ́ Bí?
  • Ipa Iṣẹ́ Pàtàkì ti Jesu
  • Ìlú Ààbò Lónìí
  • A Dá Wa Sílẹ̀ Lómìnira Kúrò Nínú Ìlú Ààbò Náà
  • Ẹ̀kọ́ Ṣíṣeyebíye fún Wa
  • Àwọn Ìlú Ààbò—Ìpèsè Aláàánú Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé Ò Ń Sá Di Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Sá Di Orúkọ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Fi Jèhófà Ṣe Ibi Ààbò Rẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 15-20

Dúró Sí “Ìlú Ààbò” Kí O Sì Wà Láàyè!

“Òun ì bá jókòó nínú ìlú ààbò rẹ̀ títí di ìgbà ikú [àlùfáà àgbà, NW].”—NUMERI 35:28.

1. Ta ni Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ náà, ìgbésẹ̀ wo ni yóò sì gbé láìpẹ́?

AGBẸ̀SAN ẹ̀jẹ̀ ti Jehofa, Jesu Kristi, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjà. Pẹ̀lú agbo ọmọ ogun áńgẹ́lì rẹ̀, Agbẹ̀san yìí yóò gbé ìgbésẹ̀ láìpẹ́, lòdì sí gbogbo àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà. Bẹ́ẹ̀ ni, Jesu yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ Ọlọrun nígbà “ìpọ́njú ńlá” náà tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. (Matteu 24:21‚ 22; Isaiah 26:21) Aráyé kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn.

2. Ibo ni ibi tòótọ́ kan ṣoṣo fún ààbò, àwọn ìbéèrè wo ni ó sì ń fẹ́ ìdáhùn?

2 Ọ̀nà láti wà láìléwu ni láti bọ́ sí ojú ọ̀nà ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà, kí a sì sá àsálà fún ẹ̀mí wa! Bí a bá gbà á sí ìlú náà, olùwá ibi ìsádi ní láti dúró síbẹ̀, nítorí pé ibẹ̀ nìkan ni ibi ààbò tòótọ́. Ṣùgbọ́n o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa kò tí ì pànìyàn rí, a ha jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ní tòótọ́ bí? Èé ṣe tí Jesu fi jẹ́ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀? Kí ni ìlú ààbò òde òní náà? Ẹnì kan ha lè kúrò níbẹ̀ láìséwu bí?’

A Ha Jẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ Ní Tòótọ́ Bí?

3. Apá wo nínú Òfin Mose ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn nípìn-ín nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?

3 Apá kan lára Òfin Mose yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n nípìn-ín nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ọlọrun gbé jíjíhìn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ karí àwọn ọmọ Israeli lápapọ̀. Bí a bá rí òkú ènìyàn, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á, àwọn onídàájọ́ yóò wọn bí àwọn ìlú tí ó sún mọ́ ibẹ̀ ti jìnnà tó láti lè mọ ìlú tí ó sún mọ́ ibẹ̀ jù lọ. Láti lè mú ẹ̀bi náà kúrò, àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú tí ó dájú pé ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà, ní láti yí ẹgbọrọ màlúù kan, tí a kò tí ì fi ṣiṣẹ́ lọ́rùn, ní àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn tí a kò dáko sí. A óò ṣe èyí níṣojú àwọn àlùfáà Lefi ‘nítorí pé àwọn ni Jehofa yàn láti máa yanjú ọ̀rọ̀ iyàn.’ Àwọn alàgbà ìlú náà yóò fọ ọwọ́ wọn sórí màlúù náà, wọn yóò sì sọ pé: “Ọwọ́ wa kò [ta] ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ojú wa kò rí i. OLUWA, dárí ji Israeli àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ tí rà padà, kí o má sì ṣe [ka] ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí ọrùn Israeli àwọn ènìyàn rẹ.” (Deuteronomi 21:1-9) Jehofa Ọlọrun kò fẹ́ kí a fi ẹ̀jẹ̀ ba ilẹ̀ Israeli jẹ́, tàbí kí àwọn ènìyàn rẹ ru ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lápapọ̀.

4. Àkọsílẹ̀ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wo ni Babiloni Ńlá ní?

4 Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí a ń pè ní ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lápapọ̀, tàbí fún àwùjọ wà. Ṣàkíyèsí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹpẹtẹ tí ó wà lórí Babiloni Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Èé ṣe, ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa yó! (Ìṣípayá 17:5‚ 6; 18:24) Àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ń jẹ́wọ́ pé àwọn ń tẹ̀ lé Ọmọ Aládé Àlááfíà, ṣùgbọ́n ogun, ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ ìsìn, àti àwọn ogun ìsìn aṣekúpani ti mú un jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ níwájú Ọlọrun. (Isaiah 9:6; Jeremiah 2:34) Ní tòótọ́, ó ní láti ru ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn nínú àwọn ogun àgbáyé méjèèjì ti ọ̀rúndún yìí. Nítorí náà, àwọn alágbàwí ìsìn èké, bákan náà ni àwọn alátìlẹyìn àti àwọn akópa nínú ogun ẹ̀dá ènìyàn jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ níwájú Ọlọrun.

5. Báwo ni àwọn ènìyàn kan ṣe dà bí àwọn tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn ní Israeli?

5 Àwọn ènìyàn kan ti mọ̀ọ́mọ̀ tàbí fi àìbìkítà pànìyàn. Àwọn mìíràn ti lọ́wọ́ nínú ìdáwọ́jọ pànìyàn, bóyá èyí tí àwọn aṣáájú ìsìn sún wọn ṣe, ní sísọ pé èyí jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọrun. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ti ṣenúnibíni, wọ́n sì ti pa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Bí a kò bá tilẹ̀ tí ì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, a ń nípìn-ín nínú jíjíhìn, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ, fún òfò ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn, nítorí pé a kò mọ òfin àti ìfẹ́ inú Ọlọrun. A dà bí ẹnì kan tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn, ‘tí ó ṣèèṣì pa ẹnì kejì rẹ̀, tí òun kò kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.’ (Deuteronomi 19:4) Ó yẹ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọrun, kí wọ́n sì sá lọ sínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò kàgbákò lọ́dọ̀ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.

Ipa Iṣẹ́ Pàtàkì ti Jesu

6. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jesu ni ìbátan tí ó súnmọ́ aráyé jù lọ?

6 Ní Israeli, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ni ìbátan tí ó sún mọ́ òjìyà náà jù lọ. Láti gbẹ̀san gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé, àti ní pàtàkì àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí a pa, Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ òde òní ní láti jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ gbogbo aráyé jù lọ. Ipa yìí ni Jesu Kristi ti kó. A bí i gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé. Jesu fi ìwàláàyè rẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ lélẹ̀ nínú ikú gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà, àti lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ sí ọ̀run, ó pèsè ìtóye rẹ̀ fún Ọlọrun nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹni kíkú, àtìrandíran Adamu. Nípa báyìí, Kristi di Olùgbàlà aráyé, ìbátan tí ó sún mọ́ wa jù lọ—ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ jíjẹ́ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. (Romu 5:12; 6:23; Heberu 10:12) A fi Jesu hàn gẹ́gẹ́ bí arákùnrin àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn tí ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀. (Matteu 25:40‚ 45; Heberu 2:11-17) Gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run, ó di “Baba Ayérayé” fún àwọn tí yóò jàǹfààní láti inú ẹbọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí yóò wà láàyè títí láé. (Isaiah 9:6, 7) Nítorí náà, lọ́nà tí ó bá a mu gẹ́ẹ́, Jehofa ti yan Ìbátan tí ó sún mọ́ aráyé jù lọ gẹ́gẹ́ bí Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.

7. Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá, kí ni Jesu ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn?

7 Jesu tún jẹ́ Àlùfáà Àgbà aláìlẹ́ṣẹ̀, tí a ti dán wò, tí ó sì jẹ́ abánikẹ́dùn. (Heberu 4:15) Nítorí ipò yìí, ó ń lo àǹfààní ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún aráyé. A dá àwọn ìlú ààbò sílẹ̀ “fún àwọn ọmọ Israeli, àti fún [àlejò olùgbé, NW] àti fún àtìpó láàárín wọn.” (Numeri 35:15) Nítorí náà, Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá náà kọ́kọ́ lo àǹfààní ẹbọ rẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró, “àwọn ọmọ Israeli.” Nísinsìnyí, a ti ń lò ó fún ‘àwọn àlejò olùgbé’ àti ‘àwọn àtìpó’ nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà. Àwọn “àgùtàn mìíràn” ti Jesu Kristi Oluwa ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Johannu 10:16; Orin Dafidi 37:29‚ 34.

Ìlú Ààbò Lónìí

8. Kí ni ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ?

8 Kí ni ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà? Kì í ṣe ọ̀gangan ibì kan bíi ti Hebroni, ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò àwọn ọmọ Lefi, tí ó sì tún jẹ́ ilé àlùfáà àgbà Israeli. Ìlú ààbò lónìí, ni ìpèsè tí Ọlọrun ṣe fún dídáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ikú nítorí rírú òfin ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. (Genesisi 9:6) Gbogbo ẹni tí ó bá rú òfin náà, yálà ó mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kò mọ̀ọ́mọ̀, gbọ́dọ̀ wá ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìfagilé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Àlùfáà Àgbà náà, Jesu Kristi. Àwọn Kristian ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run àti àwọn “àgùtàn mìíràn” tí ń wọ̀nà fún ìwàláàyè orí ilẹ̀ ayé, ti mú ara wọn bá àǹfààní ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ Jesu mu, wọ́n sì wà nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà.—Ìṣípayá 7:9‚ 14; 1 Johannu 1:7; 2:1‚ 2.

9. Báwo ni Saulu ará Tarsu ṣe rú òfin Ọlọrun nípa ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe yí ìwà rẹ̀ padà?

9 Kí ó tó di Kristian, aposteli Paulu ti tàpá sí àṣẹ nípa ẹ̀jẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Saulu ará Tarsu, ó ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu, ó tilẹ̀ fọwọ́ sí pípa wọ́n. Paulu sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, nitori tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ pẹlu àìnígbàgbọ́.” (1 Timoteu 1:13; Ìṣe 9:1-19) Saulu ní ìṣarasíhùwà onírònúpìwàdà, èyí tí ó fẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìgbàgbọ́ tí ó ṣe lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n ó ń béèrè ju ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà lọ, kí á baà lè wọnú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà.

10. Báwo ni ó ti ṣeé ṣe láti ní ẹ̀rí ọkàn dídára, kí sì ni a ní láti ṣe láti máa ní in nìṣó?

10 Ẹnì kan tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn lè dúró sínú ọ̀kan nínú àwọn ìlú ààbò ní Israeli, kìkì bí ó bá fi ẹ̀rí hàn pé òun ní ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀. Láti lè ní ẹ̀rí ọkàn rere, a ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jesu, kí a ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí a sì yí ọ̀nà wa padà. A ní láti bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn rere nínú àdúrà ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi, kí a sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. (1 Peteru 3:20‚ 21) Ẹ̀rí ọkàn dídára yìí mú kí a lè jèrè ìbátan mímọ́ tónítóní pẹ̀lú Jehofa. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti máa bá a lọ láti ní ẹ̀rí ọkàn rere ni láti máa mú ara wa bá àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè fún mu, kí a sì máa ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wa, nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà, àní bí àwọn olùwá ibi ìsádi ní àwọn ìlú ààbò ìgbàanì pàápàá ti ní láti ṣègbọràn sí Òfin, kí wọ́n sí ṣe iṣẹ́ àyànfúnni wọn. Olórí iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn Jehofa ní lónìí ni pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà. (Matteu 24:14; 28:19, 20) Ṣíṣe iṣẹ́ náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùgbé tí ó wúlò ní ìlú ààbò òde òní.

11. Kí ni a ní láti yẹra fún, bí a bá ní láti máa bá a lọ ní wíwà láìséwu nínú ìlú ààbò tòní?

11 Fífi ìlú ààbò òde òní sílẹ̀ yóò túmọ̀ sí fífi ara wa fún ìparun, nítorí pé Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí gbogbo àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ láìpẹ́. Ìsinsìnyí kì í ṣe àsìkò láti jẹ́ kí a ká wa mọ́ ìta ìlú ààbò náà tàbí mọ́ inú àgbègbè eléwu ní bèbè àgbègbè rẹ̀. Bí a bá sọ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ Àlùfáà Àgbà náà nu, a óò bá ara wa ní ẹ̀yìn òde ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà. (Heberu 2:1; 6:4-6) Bákan náà ni a kì yóò gbà wá là bí a bá mú àwọn ọ̀nà ayé lò, tí a bá dúró sí gẹ́gẹ́rẹ́ etí ètò àjọ Jehofa, tàbí tí a yà bàrá kúrò nínú ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Bàbá wa ọ̀run.—1 Korinti 4:4.

A Dá Wa Sílẹ̀ Lómìnira Kúrò Nínú Ìlú Ààbò Náà

12. Báwo ni àwọn tí wọ́n ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ṣe gbọ́dọ̀ pẹ́ tó nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ?

12 Ẹni náà, tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn ní Israeli ní láti dúró sí ìlú ààbò “títí di ìgbà ikú [àlùfáà àgbà, NW].” (Numeri 35:28) Nítorí náà, báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí náà gbọ́dọ̀ dúró sí ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà? Títí di ìgbà tí wọn kò bá nílò ìrànlọ́wọ́ Àlùfáà Àgbà náà, Jesu Kristi, mọ́. Paulu sọ pé: “Ó lè gba awọn wọnnì tí wọ́n ń tọ Ọlọrun wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹlu.” (Heberu 7:25) Níwọ̀n bí àbàwọ́n èyíkéyìí tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àtẹ̀yìnwá bá ṣì ń báa lọ, a ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ Àlùfáà Àgbà, náà kí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé baà lè ní ìdúró rere pẹ̀lú Ọlọrun.

13. Àwọn wo ni “àwọn ọmọ Israeli” òde òní, báwo sì ni wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ pẹ́ tó nínú “ìlú ààbò”?

13 Rántí pé a dá àwọn ìlú ààbò ìgbàanì sílẹ̀ fún “àwọn ọmọ Israeli,” àwọn àlejò olùgbé, àti àwọn àtìpó. “Awọn ọmọ Israeli” jẹ́ ọmọ Israeli nípa tẹ̀mí. (Galatia 6:16) Wọ́n ní láti dúró sí ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà níwọ̀n bí wọ́n bá ṣì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n ṣì wà nínú ẹran ara aláìpé, nítorí náà wọ́n nílò àǹfààní ètùtù Àlùfáà Àgbà wọn láti ọ̀run. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn Kristian ẹni àmì òróró wọ̀nyí bá kú, tí a sì jí wọn dìde sí ìwàláàyè tẹ̀mí ní ọ̀run, wọn kì yóò nílò ìrànlọ́wọ́ ètùtù Àlùfáà Àgbà náà mọ́; wọn yóò ti fi ẹran ara àti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí ó wé mọ́ ọn sílẹ̀ títí ayérayé. Fún àwọn ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ tí a jí dìde, Àlùfáà Àgbà ti ní láti kú ikú ètùtù, ní ọ̀nà tí ó lè dáàbò bò wọ́n.

14. Ohun mìíràn wo ni ó béèrè pé kí àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run dúró sí ìlú ààbò òde òní?

14 Irú ẹ̀dá tí ènìyàn jẹ́ béèrè pé, kí àwọn tí yóò jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹlu Kristi” ní ọ̀run dúró sí ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà títí tí wọn yóò fi fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí wọ́n bá kú, wọn yóò fi ìwà ẹ̀dá ènìyàn rúbọ títí láé. (Romu 8:17; Ìṣípayá 2:10) Ẹbọ Jesu ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ìwà ẹ̀dá ènìyàn. Nípa báyìí, Àlùfáà Àgbà kú fún àwọn Israeli nípa tẹ̀mí nígbà tí a bá jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí yóò gbé títí láé ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí “alájọpín ìwà ẹ̀dá ti ọ̀run.”—2 Peteru 1:4.

15. Àwọn wo ni ‘àwọn àlejò olùgbé’ àti ‘àwọn àtìpó’ òde òní, kí sì ni Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá náà yóò ṣe fún wọn?

15 Nígbà wo ni Àlùfáà Àgbà yóò “kú” fún ‘àwọn àlejò olùgbé’ àti ‘àwọn àtìpó’ òde òní, tí yóò sì fún wọn ní àǹfààní láti kúrò ní ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà? Àwọn mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ ńlá kò lè jáde kúrò lọ́gán nínú ìlú ààbò náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá náà. Èé ti ṣe? Nítorí pé wọn yóò ṣì tún wà nínú ẹran ara aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wọn, wọn yóò sì ní láti wà níbẹ̀ lábẹ́ ààbò Àlùfáà Àgbà náà. Nípa mímú ara wọn bá ìrànlọ́wọ́ ètùtù rẹ̀ nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ipò ọba àti ipò àlùfáà rẹ̀ mu, wọn yóò dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn. Nígbà náà, Jesu yóò fà wọ́n lé Ọlọrun lọ́wọ́ fún ìdánwò onípinnu tí ó kẹ́yìn fún ìdúróṣinṣin wọn, nípa títú Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sílẹ̀ fún sáà díẹ̀. Ní ti pé wọ́n yege nínú ìdánwò yìí pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá, Jehofa yóò kà wọ́n sí olódodo. Nípa báyìí, wọn yóò dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn pátápátá.—1 Korinti 15:28; Ìṣípayá 20:7-10.a

16. Nígbà wo ni àwọn olùla ìpọ́njú ńlá já kì yóò nílò ìrànlọ́wọ́ iṣẹ́ ètùtù Àlùfáà Àgbà náà síwájú sí i mọ́?

16 Nígbà náà, àwọn olùla ìpọ́njú ńlá já yóò ní láti máa bá a lọ ní níní ẹ̀rí ọkàn rere nípa dídúró sí ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà títí di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn tí a sọ di pípé, wọn kì yóò nílò ìrànlọ́wọ́ ètùtù Àlùfáà Àgbà mọ́, wọ́n yóò sì bọ́ lọ́wọ́ ààbò rẹ̀. Nígbà náà ni Jesu yóò kú gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà wọn, nítorí pé òun kì yóò ní láti ṣiṣẹ́ nítorí wọn pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ mọ́. Ní àkókò náà ni wọn yóò kúrò ní ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà.

17. Èé ṣe tí kì yóò fi pọn dandan fún àwọn tí a jí dìde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi láti wọ inú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ, kí wọ́n sì dúró síbẹ̀?

17 Àwọn tí a jí dìde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jesu ha gbọ́dọ̀ wọ ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà lọ, kí wọ́n sì máa bá a lọ ní wíwà níbẹ̀ títí di ìgbà ikú àlùfáà àgbà bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé kíkú tí wọ́n kú ti tán ọ̀ràn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Romu 6:7; Heberu 9:27) Síbẹ̀síbẹ̀, Àlùfáà Àgbà náà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dé ìjẹ́pípé. Bí wọ́n bá yege nínú ìdánwò ìkẹyìn lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rúndún náà, Ọlọrun yóò tún kéde wọn bí olódodo pẹ̀lú ìdánilójú ìwàláàyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ṣáá o, kíkọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ohun àbéèrèfún Ọlọrun yóò mú ìdájọ́ ẹ̀bi àti ìparun wá sórí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí kò bá yege nínú ìdánwò ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwà títọ́ mọ́.

18. Ní ti ipò ọba àti ti àlùfáà Jesu, kí ni yóò wà pẹ̀lú aráyé títí láé?

18 Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àlùfáà àgbà Israeli kú. Ṣùgbọ́n Jesu “ti di àlùfáà àgbà ní ìbámu pẹlu irú-ọ̀nà ti Melkisedeki títí láé.” (Heberu 6:19‚ 20; 7:3) Nítorí náà, àìsí Jesu nípò mọ́ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, tí ń ṣalárinà fún aráyé kò fopin sí ìwàláàyè rẹ̀. Àbájáde iṣẹ́ ìsìn rere rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà yóò wà pẹ̀lú aráyé títí láé, ẹ̀dá ènìyàn yóò sì jẹ ẹ́ ní gbèsè títí láé fún ṣíṣiṣẹ́sìn ní ipò yìí. Ní àfikún sí i, títí ayérayé, Jesu yóò máa mú ipò iwájú nínú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa.—Filippi 2:5-11.

Ẹ̀kọ́ Ṣíṣeyebíye fún Wa

19. Ẹ̀kọ́ wo nípa ìkórìíra àti ìfẹ́ ni a lè rí kọ́ láti inú ìpèsè àwọn ìlú ààbò?

19 A lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ láti inú ìpèsè àwọn ìlú ààbò. Fún àpẹẹrẹ, kò sí apànìyàn kankan tí ìkórìíra sún láti pànìyàn tí a yọ̀ọ̀da fún láti gbé ní ìlú ààbò. (Numeri 35:20‚ 21) Nítorí náà, báwo ni ẹnì kan tí ó wà ní ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà ṣe lè yọ̀ọ̀da kí ìkórìíra fún arákùnrin rẹ̀ dàgbà nínú ọkàn rẹ̀? Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró ninu rẹ̀.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa “bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nìkínní kejì, nitori pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìfẹ́ ti wá.”—1 Johannu 3:15; 4:7.

20. Fún ààbò kúrò lọ́wọ́ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí ni àwọn tí wọ́n wà ní ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ gbọ́dọ̀ ṣe?

20 Fún ààbò kúrò lọ́wọ́ agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, ẹni náà tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn ní láti dúró sí ìlú ààbò, kí ó má sì rìn gbéregbère kọjá bèbè pápá oko náà. Kí ni nípa ti àwọn tí wọ́n wà ní ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà? Fún ààbò kúrò lọ́wọ́ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ kúrò ní ìlú náà. Ní ti gidi, kí a sọ ọ́ ní ọ̀nà àpẹẹrẹ, wọ́n ní láti ṣọ́ra kí a má ṣe dẹ wọ́n lọ kọjá bèbè àgbègbè náà. Wọ́n ní láti ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ fún ayé Satani dàgbà nínú ọkàn wọn. Èyí lè béèrè fún àdúrà àti ìsapá, ṣùgbọ́n ìwàláàyè wọn sinmi lé e.—1 Johannu 2:15-17; 5:19.

21. Iṣẹ́ amérèwá wo ni àwọn tí wọ́n wà ní ìlú ààbò lónìí ń ṣe?

21 Ẹni náà tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn tí ó wà ní àwọn ìlú ààbò ìgbàanì ní láti jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ó wúlò. Lọ́nà kan náà, àwọn ẹni àmì òróró “ọmọ Israeli” ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìkórè àti olùpòkìkí Ìjọba. (Matteu 9:37‚ 38; Marku 13:10) Gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn àlejò olùgbé’ àti ‘àwọn àtìpó’ ní ìlú ààbò lónìí, àwọn Kristian tí ń wọ̀nà fún ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ wo irú iṣẹ́ amérèwá tí èyí jẹ́! Àwọn tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà yóò bọ́ lọ́wọ́ ikú ayérayé láti ọwọ́ Agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. Dípò èyí, wọn yóò rí àǹfààní ayérayé gbà láti inú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá ti Ọlọrun. Ìwọ yóò ha dúró sí ìlú ààbò náà kí o sì wà láàyè títí láé bí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1991, ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 15, 16.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù lórí ilẹ̀ ayé jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?

◻ Ipa iṣẹ́ wo ni Jesu Kristi ń kó fún aráyé?

◻ Kí ni ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà, báwo sì ni ẹnì kan ṣe ń wọ ibẹ̀?

◻ Nígbà wo ni a óò dá àwọn ènìyàn sílẹ̀ lómìnira nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ náà?

◻ Ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye wo ni a lè rí kọ́ láti inú ìpèsè àwọn ìlú ààbò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìwọ ha mọ àwọn ipa pàtàkì tí Jesu Kristi kó bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́