ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 13 ojú ìwé 153-162
  • Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè Àtitúká

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè Àtitúká
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • NÍ OJÚ ÌWÒYE TÒÓTỌ́
  • Ẹ JÍRÒRÒ AÁWỌ̀ YÍN
  • FÍFI Ẹ̀TỌ́ ÌGBÉYÀWÓ FÚNNI
  • ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ TÍ BIBELI FỌWỌ́ SÍ FÚN ÌKỌ̀SÍLẸ̀
  • ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ FÚN ÌPÍNYÀ
  • BÍ A ṢE GBA ÌGBÉYÀWÓ TÍ Ó TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ TÚKÁ LÀ
  • Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ka Ìgbéyàwó Sí Ohun Mímọ́?
    Jí!—2004
  • Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 13 ojú ìwé 153-162

ORÍ KẸTÀLÁ

Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè Àtitúká

1, 2. Nígbà tí ìgbéyàwó bá wà lábẹ́ másùnmáwo, ìbéèrè wo ni ó yẹ kí á béèrè?

NÍ 1988, obìnrin ará Itali kan, tí ń jẹ́ Lucia, soríkọ́ gidigidi.a Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, ìgbéyàwó rẹ̀ forílé àtiforíṣánpọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ti gbìyànjú láti parí ìjà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n òtúbáńtẹ́ ló ń já sí. Nítorí náà, ó pínyà, nítorí àìbára-ẹni-mu, ó sì wá dojú kọ dídánìkan gbọ́ bùkátà lórí àwọn ọmọbìnrin méjì. Ní wíwẹ̀yìn padà sí àkókò yẹn, Lucia rántí pé: “Mo ní ìdánilójú, nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé, kò sí ohun tí ó lè gba ìgbéyàwó wa là.”

2 Bí o bá ń dojú kọ ìṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti lóye ìmọ̀lára Lucia. Ìgbéyàwó rẹ lè kún fún ìṣòro, kí o sì máa ṣe kàyéfì bí ohunkóhun bá lè gbà á là. Bí ó bá jẹ́ bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn, yóò ṣàǹfààní fún ọ láti gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò: Mo ha ti tẹ̀ lé gbogbo ìmọ̀ràn rere tí Ọlọrun fi fúnni nínú Bibeli láti ran ìgbéyàwó lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí?​—Orin Dafidi 119:105.

3. Bí ìkọ̀sílẹ̀ tilẹ̀ wọ́pọ̀, ìhùwàpadà wo ni a ròyìn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ó ti ṣèkọ̀sílẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn?

3 Nígbà tí pákáǹleke bá ga láàárín ọkọ àti aya, títú ìgbéyàwó náà ká lè dà bí ìgbésẹ̀ tí ó rọrùn jù lọ láti gbé. Ṣùgbọ́n, bí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń rí ìbísí kíkàmàmà nínú ìdílé tí ń tú ká, ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti ṣèkọ̀sílẹ̀ ní ń kábàámọ̀ ìtúká náà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń jìyà ìṣòro ìlera, ti ara àti ti ọpọlọ, ju àwọn tí kò tú ìgbéyàwó wọn ká. Ìdàrú ọkàn àti àìláyọ̀ àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ti kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń pẹ́ kí ó tó san. Àwọn òbí àti àwọn ọ̀rẹ́ ìdílé títúká ń jìyà pẹ̀lú. Ojú tí Ọlọrun, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, fi ń wo ipò náà ńkọ́?

4. Báwo ni ó ṣe yẹ kí á bójú tó àwọn ìṣòro nínú ìgbéyàwó?

4 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àwọn orí tí ó ṣáájú, Ọlọrun pète pé kí ìgbéyàwó jẹ́ ìdè wíwà pẹ́ títí. (Genesisi 2:24) Nígbà náà, kí ni ìdí tí ọ̀pọ̀ jaburata ìgbéyàwó fi ń forí ṣánpọ́n? Ó lè má ṣẹlẹ̀ lójijì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àmì ìkìlọ̀ máa ń wà ṣáájú. Àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ìgbéyàwó lè gbèrú di ńlá títí tí wọn yóò fi dà bí èyí tí kò ṣeé yanjú. Ṣùgbọ́n, bí a bá tètè bójú tó àwọn ìṣòro wọ̀nyí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bibeli, kò ní sí ìdí fún ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó láti tú ká.

NÍ OJÚ ÌWÒYE TÒÓTỌ́

5. Ipò jíjóòótọ́ wo ni ó yẹ kí a dojú kọ nínú ìgbéyàwó èyíkéyìí?

5 Ohun kan tí ó sábà ń ṣamọ̀nà sí ìṣòro ni ìfojúsọ́nà tí kò jóòótọ́ tí alábàáṣègbéyàwó kan tàbí àwọn méjèèjì ní. Àwọn ìwé ìtàn eléré ìfẹ́, àwọn ìwé ìròyìn gbígbajúmọ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn sinimá lè ru ìrètí àti àlá asán, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé sókè. Nígbà tí àwọn àlá wọ̀nyí kò bá ṣẹ, ẹnì kan lè ronú pé a ti rẹ́ òun jẹ, a kò tẹ́ òun lọ́rùn, ó sì lè ní ìkorò ọkàn pẹ̀lú. Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni àwọn aláìpé méjì ṣe lè rí ayọ̀ nínú ìgbéyàwó? Ó ń béèrè ìsapá kí ọwọ́ tó lè tẹ ìbátan aláṣeyọrí.

6. (a) Ojú ìwòye wíwà déédéé wo nípa ìgbéyàwó ni Bibeli fúnni? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí ń fa àìfohùnṣọ̀kan nínú ìgbéyàwó?

6 Bibeli gbéṣẹ́. Ó sọ nípa ìdùnnú tí ń bẹ nínú ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n, ó tún kìlọ̀ pé, àwọn tí ó ṣègbéyàwó “yoo ní ìpọ́njú ninu ẹran-ara wọn.” (1 Korinti 7:28) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìṣáájú, tọkọtaya náà jẹ́ aláìpé, wọ́n sì lè dẹ́ṣẹ̀. Èrò orí, èrò ìmọ̀lára àti ìgbésí ayé àtilẹ̀wá àwọn méjèèjì yàtọ̀ síra. Àwọn tọkọtaya nígbà míràn kì í fohùn ṣọ̀kan nípa owó, ọmọ, àti àwọn àna. Àìsí àkókò tó láti jọ ṣe nǹkan pọ̀ àti àwọn ìṣòro ìbálòpọ̀ takọtabo tún lè jẹ́ orísun ìforígbárí.b Ó ń gba àkókò láti bójú tó irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n, mọ́kàn le! Ọ̀pọ̀ jù lọ tọkọtaya ni ó ti ṣeé ṣe fún láti kojú irú ìṣòro wọ̀nyí, wọ́n sì ti pèsè ojútùú tí àwọn méjèèjì fara mọ́.

Ẹ JÍRÒRÒ AÁWỌ̀ YÍN

7, 8. Bí ìmúbínú tàbí èdè àìyedè bá wà láàárín tọkọtaya, ọ̀nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó yẹ kí a gbà yanjú wọn?

7 Ó máa ń nira fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti sinmẹ̀dọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ ohun tí ó bí wọn nínú, èdè àìyedè, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ wọ́n. Kàkà kí ó sọ ní tààràtà pé: “O ṣì mí lóye,” alábàáṣègbéyàwó kan lè bínú, kí ó sì fẹ ìṣòro náà lójú ju bí ó ti yẹ lọ. Ọ̀pọ̀ yóò wí pé: “Ti ara rẹ nìkan ni o mọ̀,” tàbí, “O kò nífẹ̀ẹ́ mi.” Láìfẹ́ kó wọnú àríyànjiyàn, ẹnì kejì rẹ̀ lè kọ̀ láti fèsì.

8 Ọ̀nà tí ó dára jù láti tẹ̀ lé jẹ́ láti fetí sí ìmọ̀ràn Bibeli náà pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ máṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín ninu ipò ìtánnísùúrù.” (Efesu 4:26) A bi tọkọtaya kan, tí ń ṣe ayẹyẹ ọgọ́ta ọdún ìgbéyàwó wọn, ní àṣírí ìgbéyàwó wọn aláṣeyọrí. Ọkọ náà sọ pé: “A kọ́ láti má ṣe lọ sùn láìyanjú àwọn aáwọ̀ wa, láìka bí wọ́n ti lè kéré tó sí.”

9. (a) Kí ni Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó jẹ́ apá ṣíṣe kókó kan nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀? (b) Kí ni tọkọtaya ní láti ṣe lọ́pọ̀ ìgbà, bí èyí tilẹ̀ ń béèrè ìgboyà àti ìrẹ̀lẹ̀?

9 Nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀ láàárín tọkọtaya kan, olúkúlùkù wọ́n ní láti “yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nipa ìrunú.” (Jakọbu 1:19) Lẹ́yìn fífetí sílẹ̀ kínníkínní, àwọn méjèèjì lè rí ìdí láti tọrọ àforíjì. (Jakọbu 5:16) Fífi tinútinú sọ pé, “Máà bínú fún ìpalára tí mo ṣe fún ọ,” ń béèrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà. Ṣùgbọ́n, yíyanjú aáwọ̀ lọ́nà yìí yóò gbéṣẹ́ gidigidi ní ríran tọkọtaya lọ́wọ́, kì í ṣe láti yanjú ìṣòro wọn nìkan, ṣùgbọ́n láti mú ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí, tí yóò mú kí wọ́n túbọ̀ gbádùn ìbáṣepọ̀ wọn dáradára sí i, dàgbà.

FÍFI Ẹ̀TỌ́ ÌGBÉYÀWÓ FÚNNI

10. Ààbò wo tí Paulu dámọ̀ràn fún àwọn Kristian ní Korinti ni ó lè kan Kristian lónìí?

10 Nígbà tí aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Korinti, ó dámọ̀ràn ìgbéyàwó “nitori ìgbòdekan àgbèrè.” (1 Korinti 7:2) Ayé òde òní burú bíi Korinti ìgbàanì, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Àwọn ọ̀rọ̀ oníwà pálapàla tí àwọn ènìyàn ayé ń sọ ní gbangba, ọ̀nà tí kò bójú mu tí wọ́n ń gbà múra, àwọn ìtàn ìṣekúṣe tí a ń gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé mìíràn, lórí tẹlifíṣọ̀n, àti nínú sinimá, gbogbo wọ́n ń para pọ̀ láti ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè. Fún àwọn ará Korinti tí ń gbé nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, aposteli Paulu sọ pé: “Ó sàn lati gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara-ẹni gbiná.”​—1 Korinti 7:9.

11, 12. (a) Gbèsè kí ni ọkọ àti aya jẹ ara wọn, irú ẹ̀mí wo ni ó sì yẹ kí wọ́n fi san án fún ara wọn? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí á bójú tó ipò náà, bí a óò bá du ara wa ní ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún ìgbà kúkúrú?

11 Nítorí náà, Bibeli pàṣẹ fún àwọn tọkọtaya Kristian pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣugbọn kí aya pẹlu ṣe bákan naa fún ọkọ rẹ̀.” (1 Korinti 7:3) Kíyè sí i pé orí fífúnni ni ìtẹnumọ́ náà wà​—kì í ṣe orí fífagbára béèrè. Ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí nínú ìgbéyàwó ń tẹ́ni lọ́rùn ní tòótọ́, kìkì bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìgbéyàwó bá ń ṣàníyàn nípa ire ẹnì kejì rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli pàṣẹ fún ọkọ láti bá ìyàwó rẹ̀ lò “ní ìbámu pẹlu ìmọ̀.” (1 Peteru 3:7) Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nínú fífúnni àti gbígba ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó. Bí a kò bá fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá aya kan lò, ó lè ṣòro fún un láti gbádùn ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí yìí nínú ìgbéyàwó.

12 Àwọn ìgbà kán máa ń wà tí àwọn tọkọtaya lè ní láti fi ohun ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó du ara wọn. Èyí lè jẹ́ òtítọ́ nípa aya ní àwọn àkókò kan láàárín oṣù tàbí nígbà tí ó bá rẹ̀ ẹ́ gan-an. (Fi wé Lefitiku 18:19.) Ó lè jẹ́ òtítọ́ nípa ọkọ nígbà tí ó bá ń dojú kọ ìṣòro ńlá kan níbi iṣẹ́, tí èrò ìmọ̀lára rẹ̀ sì ti fàro. Irú fífi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó duni fún ìgbà kúkúrú bẹ́ẹ̀, ní a lè bójú tó dáradára jù lọ bí àwọn méjèèjì bá jọ jíròrò ipò náà, láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan nípasẹ “ìjọ́hẹn tọ̀túntòsì.” (1 Korinti 7:5) Èyí yóò ṣèdènà fún èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì láti dórí ìpinnu tí kò tọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí aya kan bá mọ̀-ọ́nmọ̀ fi du ọkọ rẹ̀, tàbí bí ọkọ kan bá dìídì kùnà láti fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún aya rẹ̀ ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, ó lè ṣí ẹnì kejì rẹ̀ payá sí ìdẹwò. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìṣòro lè jẹ yọ nínú ìgbéyàwó.

13. Báwo ni àwọn Kristian ṣe lè ṣiṣẹ́ láti pa ìrònú wọn mọ́ ní mímọ́ tónítóní?

13 Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo Kristian, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tí ó lè ru ìfẹ́ ọkàn tí kò mọ́, tí kò sì bá ti ẹ̀dá mu sókè. (Kolosse 3:5) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ èrò àti ìwà wọn nígbà tí wọ́n bá ń bá gbogbo mẹ́ḿbà ẹ̀yà kejì lò. Jesu kìlọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan lati ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹlu rẹ̀ ná ninu ọkàn-àyà rẹ̀.” (Matteu 5:28) Nípa fífi ìmọ̀ràn Bibeli lórí ìbálòpọ̀ takọtabo sílò, ó yẹ kí ó ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti yẹra fún kíkó sínú ìdánwò, àti ṣíṣe panṣágà. Wọ́n lè máa bá a lọ láti gbádùn ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí dídùn mọ́ni nínú ìgbéyàwó tí a ti ka ìbálòpọ̀ takọtabo sí ẹ̀bùn gbígbámúṣé láti ọ̀dọ Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, Jehofa.​—Owe 5:15-19.

ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ TÍ BIBELI FỌWỌ́ SÍ FÚN ÌKỌ̀SÍLẸ̀

14. Ipò bíbani nínú jẹ́ wo ni ó máa ń jẹ yọ nígbà míràn? Èé ṣe?

14 Lọ́nà tí ń múni láyọ̀, nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbéyàwó Kristian, a lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí ó bá yọjú. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, ọ̀ràn kì í rí bẹ́ẹ̀. Nítorí aláìpé ni wá, tí a sì ń gbé nínú ayé ẹlẹ́ṣẹ̀, tí ó wà lábẹ́ ìdarí Satani, àwọn ìgbéyàwó kan máa ń dé bèbè àtitúká. (1 Johannu 5:19) Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn Kristian bójú tó irú ipò dídánniwò bẹ́ẹ̀?

15. (a) Kí ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fúnni fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn? (b) Èé ṣe tí àwọn kan fi yàn láti má ṣe kọ alábàáṣègbéyàwó wọn aláìṣòótọ́ sílẹ̀?

15 Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú Orí 2 ìwé yìí, àgbèrè nìkan ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fúnni fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn.c (Matteu 19:9) Bí o bá ní ẹ̀rí gúnmọ́ pé ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó ti hùwà àìṣòótọ́, nígbà náà, o dojú kọ ìpinnu nínira. Ìwọ yóò ha máa bá ìgbéyàwó náà lọ tàbí ìwọ yóò ṣèkọ̀sílẹ̀? Kò sí òfin kan tí ó dè é. Àwọn Kristian kan ti forí ji ẹnì kejì wọn tí ó ronú pìwà dà tinútinú, tí ìgbéyàwó tí a pa mọ́ náà sì yọrí sí rere. Àwọn mìíràn kò ṣèkọ̀sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ.

16. (a) Kí ni díẹ̀ lára ìdí tí ó sún àwọn kan láti kọ alábàáṣègbéyàwó wọn tí ó ṣẹ̀ sílẹ̀? (b) Nígbà tí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú ìgbéyàwó bá pinnu láti ṣèkọ̀sílẹ̀ tàbí láti má ṣèkọ̀sílẹ̀, èé ṣe tí kò fi yẹ kí ẹnikẹ́ni ṣe lámèyítọ́ ìpinnu ẹni náà?

16 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ náà ti lè yọrí sí oyún tàbí àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré. Tàbí bóyá a ní láti dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ òbí tí ń bọ́mọ ṣèṣekúṣe. Ní kedere, a ní láti gbé ohun púpọ̀ yẹ̀ wò kí a tó ṣèpinnu. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá gbọ́ nípa àìṣòtítọ́ ẹnì kejì rẹ, tí o sì ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn náà, o tipa báyìí fi hàn pé o ti forí ji alábàáṣègbéyàwó rẹ, o sì fẹ́ máa bá ìgbéyàwó náà lọ. Ìpìlẹ̀ fún ìkọ̀sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn, lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, kò sí níbẹ̀ mọ́. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọjúràn, kí ó sì gbìyànjú láti nípa lórí ìpinnu rẹ, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ ṣe lámèyítọ́ ìpinnu tí o bá ṣe. Ìwọ yóò ní láti tẹ́wọ́ gba àbájáde ìpinnu tí o ṣe. “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.”​—Galatia 6:5.

ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ FÚN ÌPÍNYÀ

17. Bí kò bá sí àgbèrè, ìkálọ́wọ́kò wo ni Ìwé Mímọ́ gbé ka ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀?

17 Àwọn ipò kan ha wà tí ó lè mú kí ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá, kúrò lọ́dọ̀ alábàáṣègbéyàwó ẹní tọ̀nà, àní bí ẹni tọ̀hún kò bá ṣàgbèrè pàápàá? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, Kristian kan kò lómìnira láti bá ẹlòmíràn dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ète fífẹ́ ẹ. (Matteu 5:32) Bí Bibeli tilẹ̀ yọ̀ǹda fún irú ìpínyà bẹ́ẹ̀, ó fi lélẹ̀ pàtó pé ẹni tí ń pínyà náà ní láti “wà láìlọ́kọ [tàbí láìláya] bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹlu ọkọ [tàbí aya] rẹ̀.” (1 Korinti 7:11) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò lílégbákan tí ó lè mú kí ìpínyà dà bí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu?

18, 19. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò lílé kenkà tí ó lè sún alábàáṣègbéyàwó kan láti gbé àǹfààní tí ń bẹ nínú ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ tí ó bófin mu yẹ̀ wò, bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn?

18 Ó dára, ìdílé lè di aláìní nítorí ìwà ọ̀lẹ paraku àti àwọn àṣà burúkú ọkọ.d Ó lè máa náwó ìdílé dànù sórí tẹ́tẹ́ tàbí kí ó máa ná an sórí ìlòkulò oògùn tàbí ìmukúmu ọtí. Bibeli sọ pé: “Bí ẹni kan kò bá pèsè fún . . . awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 5:8) Bí irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ bá kùnà láti yí ọ̀nà rẹ̀ padà, bóyá kí ó tilẹ̀ máa mú lára owó aya rẹ̀ láti ná sórí àwọn àṣà burúkú rẹ̀, aya náà lè yàn láti dáàbò bo ire rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa pípínyà lọ́nà òfin.

19 A tún lè gbé irú ìgbésẹ̀ tí ó bófin mu bẹ́ẹ̀ bí alábàáṣègbéyàwó kan bá jẹ́ ẹni tí ń hùwà ipá sí ẹnì kejì rẹ̀, bóyá ó máa ń lu ẹni tọ̀hún débi pé ìlera àti ẹ̀mí rẹ̀ pàápàá wà nínú ewu. Ní àfikún sí i, bí alábàáṣègbéyàwó kan bá ń gbìyànjú ní gbogbo ìgbà láti fipá mú ẹnì kejì rẹ̀ rú òfin Ọlọrun ní ọ̀nà kan, ẹni tí a ń halẹ̀ mọ́ náà lè ronú nípa pípínyà, pàápàá bí ọ̀ràn bá dórí ibi tí a ti fi ìwàláàyè rẹ̀ nípa tẹ̀mí sínú ewu. Alábàáṣègbéyàwó tí ó wà nínú ewu náà lè dórí ìpinnu pé, ọ̀nà kan ṣoṣo láti “ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn” jẹ́ láti pínyà lábẹ́ òfin.​—Ìṣe 5:29.

20. (a) Nínú ọ̀ràn ìwólulẹ̀ ìdílé, kí ni àwọn ọ̀rẹ́ tí ó dàgbà dénú àti àwọn alàgbà lè fi fúnni, kí sì ni kò yẹ kí wọ́n fi fúnni? (b) Àwọn tọkọtaya kò gbọdọ̀ lo àwọn ìtọ́ka Bibeli sí ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti ṣe kí ni?

20 Nínú gbogbo ọ̀ràn ìwà oníkà lílé kenkà ti alábàáṣègbéyàwó kan, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fagbára mú aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú ìgbéyàwó náà yálà láti pínyà tàbí láti dúró ti ẹnì kejì rẹ̀. Bí àwọn ọ̀rẹ́ tí ó dàgbà dénú àti àwọn alàgbà tilẹ̀ lè fúnni ní ìtìlẹ́yìn àti ìmọ̀ràn tí a gbé karí Bibeli, àwọn wọ̀nyí kò lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ń lọ láàárín ọkọ àti aya. Jehofa nìkan ṣoṣo ni ó lè rí èyí. Àmọ́ ṣáá o, Kristian aya kò bọlá fún ètò ìgbéyàwó tí Ọlọrun ṣe, bí ó bá ń lo àwọn àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ipò líléwu gidi kan bá ń bá a lọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ bí ó bá yàn láti pínyà. A lè sọ ohun kan náà nípa Kristian ọkọ kan tí ó fẹ́ pínyà. “Gbogbo wa ni yoo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọrun.”​—Romu 14:10.

BÍ A ṢE GBA ÌGBÉYÀWÓ TÍ Ó TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ TÚKÁ LÀ

21. Ìrírí wo ni ó fi hàn pé ìmọ̀ràn Bibeli lórí ìgbéyàwó ń múná dóko?

21 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí Lucia, tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú, pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ó ṣalábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn. Ó ṣàlàyé pé: “Sí ìyàlẹ́nu mi gíga jù lọ, Bibeli pèsè àwọn ojútùú gbígbéṣẹ́ sí ìṣòro mi. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan péré tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́, mo hára gàgà láti bá ọkọ mi làjà. Lónìí, mo lè sọ pé, Jehofa mọ bí a ti ń gba àwọn ìgbéyàwó tí ó wà nínú yánpọnyánrin sílẹ̀, nítorí pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń ṣèrànwọ́ fún tọkọtaya láti mọ bí wọ́n ṣe ní láti buyì fún ara wọn. Kì í ṣe òótọ́, bí àwọn kan ti ń sọ, pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pín ìdílé níyà. Nínú ọ̀ràn tèmi, òdì kejì ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Lucia kọ́ láti lo ìlànà Bibeli nínú ìgbésí ayé rẹ̀.

22. Nínú kí ni ó yẹ kí gbogbo tọkọtaya ní ìgbọkànlé?

22 Ọ̀ràn Lucia kì í ṣe àrà ọ̀tọ̀. Ó yẹ kí ìgbéyàwó jẹ́ ìbùkún, kì í ṣe ẹrù ìnira. Nítorí ìdí yìí, Jehofa ti pèsè orísun ìmọ̀ràn ìgbéyàwó dídára jù lọ tí a tíì kọ rí​—Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣíṣeyebíye. Bibeli lè sọ “òpè di ọlọgbọ́n.” (Orin Dafidi 19:​7-11) Ó ti gba ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tí ó wà ní bèbè àtitúká là, ó sì ti mú ọ̀pọ̀ míràn, tí ó ní ìṣòro wíwúwo rinlẹ̀, sunwọ̀n sí i. Ǹjẹ́ kí gbogbo tọkọtaya ní ìgbọkànlé kíkún nínú ìmọ̀ràn ìgbéyàwó tí Jehofa Ọlọrun ń pèsè. Ó ń ṣiṣẹ́ gan-an!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ padà.

b A ti mójú tó díẹ̀ lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí nínú àwọn orí tí ó ṣáájú.

c Ọ̀rọ̀ Bibeli náà tí a tú sí “àgbèrè,” kan panṣágà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbẹ́ranko-lòpọ̀, àti àwọn ìwà àìbófinmu mìíràn, tí a mọ̀-ọ́nmọ̀ hù, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú lílo àwọn ẹ̀yà ìbímọ.

d Èyí kò kan àwọn ipò nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún ọkọ, bí òún tilẹ̀ ní ète rere lọ́kàn, láti pèsè fún ìdílé rẹ̀ nítorí àwọn ìdí tí ó ré kọjá agbára rẹ̀, irú bí àìsàn tàbí àìníṣẹ́lọ́wọ́.

BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ . . . LÁTI YẸRA FÚN ÌWÓLULẸ̀ ÌGBÉYÀWÓ?

Ìgbéyàwó jẹ́ orísun ìdùnnú àti ìpọ́njú.​—Owe 5:​18, 19; 1 Korinti 7:28.

A gbọ́dọ̀ bójú tó aáwọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.​—Efesu 4:26.

Nínú ìjíròrò, sísọ̀rọ̀ kò ṣe pàtàkì ju fífetí sílẹ̀.​—Jakọbu 1:19.

A gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.​—1 Korinti 7:​3-5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 154]

Ẹ tètè yanjú àwọn ìṣòro yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìtánnísùúrù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́