ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/15 ojú ìwé 4-7
  • Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Nìkan Kò Fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Nìkan Kò Fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Kò fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró
  • Ìtumọ̀ Ìgbàgbọ́ Tòótọ́
  • Gbígbàgbọ́ Bí A Kò Tilẹ̀ Rí I
  • Ṣé Òótọ́ Ni Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ǹjẹ́ A Lè Gbà Pé Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jesu—Ìtàn Tàbí Àròsọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/15 ojú ìwé 4-7

Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Nìkan Kò Fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró

OHUN a rí là ń gbà gbọ́. Ojú ìwòye ọ̀pọ̀lọpọ̀ nìyẹn. Àwọn kan sọ pé, àwọn yóò gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run bí ó bá lè ṣí ara rẹ̀ payá fún wọn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu. Bóyá ìyẹn lè rí bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n, irú ìgbàgbọ́ yẹn yóò ha yọrí sí ojúlówó ìgbàgbọ́ bí?

Gbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà yẹ̀ wò, Kórà, Dátánì, àti Ábírámù. Bíbélì fi hàn pé, wọ́n fojú rí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, láti ọwọ́ Ọlọ́run: ìyọnu mẹ́wàá lórí Íjíbítì, àsálà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì la Òkun Pupa já, àti ìparun Fáráò ará Íjíbítì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. (Ẹ́kísódù 7:19–11:10; 12:29-32; Orin Dáfídì 136:15) Kórà, Dátánì, àti Ábírámù tún gbọ́ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá lórí Òkè Sínáì. (Diutarónómì 4:11, 12) Síbẹ̀, kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, àwọn ọkùnrin mẹ́ta náà pilẹ̀ ọ̀tẹ̀ sí Jèhófà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó yàn sípò.—Númérì 16:1-35; Orin Dáfídì 106:16-18.

Ní nǹkan bí 40 ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Báláámù pẹ̀lú fojú rí iṣẹ́ ìyanu kan. Àní lílo áńgẹ́lì kan láti dá sí ọ̀ràn náà pàápàá kò mú kí ó dẹ́kun gbígbè sẹ́yìn àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, àwọn ará Móábù. Láìka iṣẹ́ ìyanu yẹn sí, Báláámù pàpà gbégbèésẹ̀ lòdì sí Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ̀. (Númérì 22:1-35; Pétérù Kejì 2:15, 16) Ṣùgbọ́n, àìnígbàgbọ́ Báláámù kò tó nǹkan bí a bá fi wé ti Júdásì Ísíkáríótù. Láìka níní tí ó ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù sí, tí ó sì fojú rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ iṣẹ́ ìyanu àràmàǹdà, Júdásì da Kristi fún ọgbọ̀n owó fàdákà.—Mátíù 26:14-16, 47-50; 27:3-5.

Àwọn aṣáájú ìsìn Júù pẹ̀lú rí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Lẹ́yìn tí ó jí Lásárù dìde, wọ́n tilẹ̀ sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì.” Ṣùgbọ́n, rírí tí wọ́n rí Lásárù tí ó wà láàyè nísinsìnyí ha pẹ̀tù sí ọkàn àyà wọn, kí ó sì fún wọn ní ìgbàgbọ́ bí? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù àti Lásárù!—Jòhánù 11:47-53; 12:10.

Àní dídá tí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà ní tààràtà pàápàá kò mú kí àwọn ọkùnrin búburú wọ̀nyẹn ní ìgbàgbọ́. Nígbà kan tí Jésù wà ní àgbègbè tẹ́ńpìlì, ó gbàdúrà sókè pé: “Bàbá, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Jèhófà fèsì pẹ̀lú ohùn kan láti ọ̀run wá pé: “Èmi ti ṣe é lógo èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” Síbẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ yíyanilẹ́nu yìí kò mú kí àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú ọkàn àyà wọn. Bíbélì sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.”—Jòhánù 12:28-30, 37; fi wé Éfésù 3:17.

Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Kò fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró

Báwo ni irú àìnígbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe lè wà láìka ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe sí? Kíkọ̀ tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù kọ Jésù dà bí èyí tí ó rúni lójú, ní pàtàkì, nígbà tí o bá ronú nípa rẹ̀ pé, ní àkókò tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gan-an, àwọn Júù lódindi wà “nínú ìfojúsọ́nà” fún “Kristi,” tàbí Mèsáyà náà. (Lúùkù 3:15) Ṣùgbọ́n, ìṣòro náà wà nínú ohun tí àwọn ìfojúsọ́nà wọ̀nyẹn jẹ́. Òǹṣèwé atúmọ̀ èdè, W. E. Vine, ṣàyọlò ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bíbélì, tí a mọ̀ bí ẹní mowó, tí ó sọ pé, èrò nípa Mèsáyà kan tí yóò fún wọn ní “ìjagunmólú ti ayé” àti “aásìkí nípa ti ara” ni ó gba àwọn Júù lọ́kàn. Nítorí náà, wọn kò múra tán fún Jésù ará Násárétì, onírẹ̀lẹ̀, tí kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, tí ó fara hàn ní àárín wọn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tòótọ́ náà ní ọdún 29 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àwọn aṣáájú ìsìn náà tún bẹ̀rù pé, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù yóò da ipò nǹkan rú, yóò sì fi ipò títayọ lọ́lá wọn sínú ewu. (Jòhánù 11:48) Àwọn èrò tí wọ́n ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀ àti ìmọtara-ẹni-nìkan wọn kò jẹ́ kí wọ́n rí ìtumọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù.

Àwọn aṣáájú ìsìn Júù àti àwọn mìíràn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kọ ẹ̀rí iṣẹ́ ìyanu náà pé, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbádùn ojú rere àtọ̀runwá. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wo ọkùnrin kan tí ó ti yarọ láti ìgbà tí a ti bí i sàn, àwọn onínú fùfù tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà kóòtù gíga ti àwọn Júù béèrè pé: “Kí ni kí a ti ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Nítorí, ní ti tòótọ́, iṣẹ́ àmì tí ó yẹ fún àfiyèsí ti ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wọn, ọ̀kan tí ó fara hàn kedere fún gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù; a kò sì lè sẹ́ ẹ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí a má baà tàn án káàkiri síwájú sí i láàárín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a sọ fún wọn pẹ̀lú ìhalẹ̀mọ́ni pé kí wọ́n má ṣe bá ènìyàn kankan sọ̀rọ̀ mọ́ lórí ìpìlẹ̀ orúkọ yìí.” (Ìṣe 3:1-8; 4:13-17) Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ ìyanu àràmàǹdà yí kò tí ì gbé ìgbàgbọ́ ró tàbí kí ó mú un gbilẹ̀ nínú ọkàn àyà àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn.

Ìlépa òkìkí, ìgbéraga, àti ìwọra jẹ́ àwọn kókó abájọ tí ó ti sún ọ̀pọ̀ láti sé ọkàn àyà wọn pa. Ó dà bí ẹni pé bí ọ̀ràn ṣe rí nìyẹn pẹ̀lú Kórà, Dátánì, àti Ábírámù, tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú. Owú, ìbẹ̀rù, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìṣarasíhùwà míràn tí ń ṣèpalára, ti jin àwọn ẹlòmíràn lẹ́sẹ̀. A tún rán wa létí nípa àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn, àwọn ẹ̀mí èṣù, tí wọ́n ní àǹfààní nígbà kan láti wo ojú Ọlọ́run gan-an. (Mátíù 18:10) Wọn kò ṣiyè méjì nípa pé Ọlọ́run ń bẹ. Ní tòótọ́, “àwọn ẹ̀mí èṣù . . . gbà gbọ́ wọ́n sì gbọ̀n jìnnìjìnnì.” (Jákọ́bù 2:19) Síbẹ̀, wọn kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

Ìtumọ̀ Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

Ìgbàgbọ́ ní nínú ju wíwulẹ̀ gba nǹkan gbọ́ lásán lọ. Ó tún ní nínú ju ìhùwàpadà elérò ìmọ̀lára fún sáà díẹ̀ sí iṣẹ́ ìyanu kan lọ. Hébérù 11:1 sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà pẹ̀lú ìdánilójú fún àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Ẹnì kan tí ó bá ní ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú nínú ọkàn àyà rẹ̀ pé, ohun gbogbo tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí dà bíi pé ó ti ní ìmúṣẹ. Ní àfikún sí i, ẹ̀rí tí kò ṣeé sẹ́ ní ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tòótọ́ tí a kò rí lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi lè sọ pé ìgbàgbọ́ fúnra rẹ̀ bá ẹ̀rí yẹn dọ́gba. Bẹ́ẹ̀ ni, a gbé ìgbàgbọ́ karí ẹ̀rí. Nígbà àtijọ́, iṣẹ́ ìyanu kó ipa nínú ìdàgbàsókè ìgbàgbọ́ tàbí nínú gbígbé e ró. Àwọn iṣẹ́ àmì tí Jésù ṣe mú kí àwọn ẹlòmíràn gbà gbọ́ dájú pé òun ni Mèsáyà náà tí a ṣèlérí. (Mátíù 8:16, 17; Hébérù 2:2-4) Bákan náà, irú ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́, Ọlọ́run bẹ́ẹ̀, bí ìwòsàn lọ́nà ìyanu àti fífi èdè fọ̀, fẹ̀rí hàn pé, àwọn Júù kò ní ojú rere Jèhófà mọ́, ṣùgbọ́n pé, ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ nísinsìnyí sinmi lórí ìjọ Kristẹni, tí Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, dá sílẹ̀.—Kọ́ríńtì Kíní 12:7-11.

Agbára láti sàsọtẹ́lẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn ìyanu ti ẹ̀mí. Nígbà tí àwọn aláìgbàgbọ́ kíyè sí iṣẹ́ ìyanu yìí, a sún àwọn kan láti jọ́sìn Jèhófà, ní pípolongo pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 14:22-25) Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà Ọlọ́run kò pète pé kí iṣẹ́ ìyanu di apá wíwà pẹ́ títí nínú ìjọsìn Kristẹni. Nítorí náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:8) Ó hàn gbangba pé, àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí wá sí òpin nígbà tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn tí wọ́n rí irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ gbà lọ́wọ́ wọn kú.

A óò ha fi àwọn ènìyàn sílẹ̀ láìní ìpìlẹ̀ fún ìgbàgbọ́ bí? Rárá o, nítorí Pọ́ọ̀lù wí pé: “[Ọlọ́run] kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ ati ìmóríyágágá kún ọkàn àyà yín dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Ní tòótọ́, lójú àwọn aláìlábòsí ọkàn tí wọ́n múra tán láti ṣí ìrònú àti ọkàn àyà wọn payá sí ẹ̀rí tí ó yí wa ká, “àwọn ànímọ́” Jèhófà Ọlọ́run “tí a kò lè rí ní a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti Jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n [àwọn tí wọ́n sẹ́ Ọlọ́run] kò ní àwíjàre.”—Róòmù 1:20.

A nílò ju gbígbàgbọ́ lásán pé Ọlọ́run ń bẹ lọ. Pọ́ọ̀lù rọni pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) A lè ṣe èyí nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, irú bí ìwé ìròyìn yí. Ìgbàgbọ́ tí a gbé karí ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, kì í ṣe ahẹrẹpẹ tàbí oréfèé. Àwọn tí wọ́n ti fòye mọ ìfẹ́ inú Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi ìgbàgbọ́ ṣe é, ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run.—Róòmù 12:1.

Gbígbàgbọ́ Bí A Kò Tilẹ̀ Rí I

Àpọ́sítélì Tómásì ní ìṣòro gbígbàgbọ́ pé a ti jí Jésù dìde nínú ikú. Tómásì polongo pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá awọn ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀ kí n sì ki ìka mi bọ àpá àwọn ìṣó náà kí n sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ, dájúdájú èmi kì yóò gbà gbọ́.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí Jésù gbé ẹran ara kan wọ̀ tí ó ní ọgbẹ́ kíkàn tí a kàn án mọ́ igi, Tómásì dáhùn pa dà lọ́nà rere sí iṣẹ́ ìyanu yìí. Ṣùgbọ́n, Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí kò rí síbẹ̀ tí wọ́n sì gbà gbọ́.”—Jòhánù 20:25-29.

Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘ń rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí wọ́n rí.’ (Kọ́ríńtì Kejì 5:7) Bí wọn kò tilẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a kọ sílẹ̀ nínú Bíbélì, wọ́n gbà gbọ́ dájú pé ìwọ̀nyí ṣẹlẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àti ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ta yọ jù lọ—ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. (Mátíù 6:9, 10; Tímótì Kejì 3:16, 17) Àwọn ojúlówó Kristẹni wọ̀nyí ń fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí ó wà nínú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, ó sì ń yọrí sí àǹfààní ńláǹlà fún wọn. (Orin Dáfídì 119:105; Aísáyà 48:17, 18) Wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí náà tí kò ṣeé já ní koro pé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sàmì sí àkókò wa gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ pé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí kù sí dẹ̀dẹ̀. (Tímótì Kejì 3:1-5; Mátíù 24:3-14; Pétérù Kejì 3:13) Ó jẹ́ ohun ìdùnnú fún wọn láti ṣàjọpín ìmọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Òwe 2:1-5) Wọ́n mọ̀ pé, kìkì kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ nìkan ni àwọn tí ń wá Ọlọ́run fi lè rí i ní tòótọ́.—Ìṣe 17:26, 27.

Ìwọ ha rántí Albert, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú? Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí kò rí ìdáhùn sí àdúrà rẹ̀ fún iṣẹ́ ìyanu, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀ ẹ́ wò, obìnrin àgbàlagbà kan tí ó fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé karí Bíbélì sílẹ̀ fún un. Lẹ́yìn náà, Albert tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. Bí ó ti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ Bíbélì, ìjákulẹ̀ rẹ̀ yí pa dà di ìdùnnú ńlá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ pé òun ti rí Ọlọ́run nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Ìwé Mímọ́ rọni pé: “Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.” (Aísáyà 55:6) Ìwọ lè ṣe èyí, kì í ṣe nípa dídúró de iṣẹ́ ìyanu òde òní kan láti ọwọ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe nípa jíjèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí pọn dandan, nítorí iṣẹ́ ìyanu nìkan kò lè gbé ìgbàgbọ́ ró.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àní àjíǹde Lásárù lọ́nà ìyanu pàápàá kò sún àwọn ọ̀tá Jésù láti lo ìgbàgbọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A gbọ́dọ̀ gbé ìgbàgbọ́ karí ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́