Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jesu—Ìtàn Tàbí Àròsọ?
“Ní sáà ìṣọ́ kẹrin òru ó wá sọ́dọ̀ wọn, ní rírìn lórí òkun.”—Matteu 14:25, NW.
FÚN àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn káàkiri ilẹ̀-ayé, ìgbàgbọ́ náà pé Jesu Kristi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu fẹ́rẹ̀ ṣe pàtàkì bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun fúnra rẹ̀ ti ṣe pàtàkì. Àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere—Matteu, Marku, Luku, àti Johannu—ṣàpèjúwe nǹkan bíi 35 nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu. Bí ó ti wù kí ó rí, ìròyìn wọn fi hàn pé ó tún ṣe ọ̀pọ̀ ohun àrà tí ó rékọjá agbára ẹ̀dá.—Matteu 9:35; Luku 9:11.
Kò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí láti dá àwọn ènìyàn lára yá. Wọ́n jẹ́ apákan ìjẹ́wọ́ Jesu pé òun jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun, Messia tí wọ́n ti ń dúró dè fún ìgbà pípẹ́. (Johannu 14:11) Mose ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn níwájú orílẹ̀-èdè Israeli tí ó wà lóko ẹrú. (Eksodu 4:1-9) Lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, Messia náà, ẹni tí a sọtẹ́lẹ̀ pé ó tóbi ju Mose lọ, ni a ti níláti retí pẹ̀lú pé kí ó fúnni ni àwọn àmì díẹ̀ pé òun ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá. (Deuteronomi 18:15) Nítorí èyí ni Bibeli ṣe pe Jesu ní “ọkùnrin kan tí Ọlọrun fi hàn ní gbangba fún [àwọn Júù] nípasẹ̀ awọn iṣẹ́ agbára ati àpẹẹrẹ ìyanu ati iṣẹ́ àmì.”—Ìṣe 2:22, NW.
Ní ìgbà àtijọ́, àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò gbà láìsí iyèméjì pẹ̀lú ọ̀nà tí Bibeli gbà ṣàpèjúwe Jesu gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ìyanu. Ṣùgbọ́n ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, àwọn olùṣelámèyítọ́ ti ṣe lámèyítọ́ àwọn ìròyìn Ìhìnrere. Nínú ìwé rẹ̀ Deceptions and Myths of the Bible, Lloyd Graham tọ́ka sí ìròyìn Bibeli nípa rírìn tí Jesu rìn lórí omi tí ó sì tílẹ̀ tún sọ pẹ̀lú pé: “Ó béèrè fún ọ̀pọ̀ àìmọ̀kan láti gba èyí gbọ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi, síbẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn gbà á gbọ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. A sì wá ń ṣe kàyééfì nípa ohun tí ó rọ́lu ayé wa. Ayé wo ni a bá tún retí pé kí ó ti inú àìmọ̀kan bẹ́ẹ̀ wá?”
Kò Ha Ṣeé Ṣe Bí?
Bí ó ti wù kí ó rí, irú àwọn lámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ kò lọ́gbọ́n nínú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìyanu gẹ́gẹ́ bí “ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò ṣeé ṣàlàyé nípasẹ̀ àwọn òfin ìṣẹ̀dá tí a mọ̀.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ yẹn, tẹlifíṣọ̀n aláwọ̀ oríṣiríṣi, tẹlifóònù alágbéérìn, tàbí kọ̀m̀pútà kékeré ni a óò ti kà sí iṣẹ́ ìyanu ní kìkì ọ̀rúndún kan sẹ́yìn! Ó ha bọ́gbọ́nmu láti jẹ́ olójú-ìwòye tèmi-lọ̀gá kí a sì sọ pé ohun kan kò ṣeé ṣe kìkì nítorí pé a kò lè ṣàlàyé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òye ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a ní ní lọ́wọ́lọ́wọ́?
Kókó mìíràn tún nìyí láti gbé yẹ̀wò: Nínú èdè Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a fi kọ “Májẹ̀mú Titun,” ọ̀rọ̀ tí a lò fún “iṣẹ́ ìyanu” ni dyʹna·mis—ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀ sí “agbára” ní ìpìlẹ̀. A tún túmọ̀ rẹ̀ sí “awọn iṣẹ́ agbára” tàbí “agbára ìlèṣe nǹkan.” (Luku 6:19; 1 Korinti 12:10, NW; Matteu 25:15, NW) Bibeli jẹ́wọ́ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu jẹ́ ìfihàn “agbára gígalọ́lá ti Ọlọrun.” (Luku 9:43, NW) Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò ha ṣòro ṣe fún Ọlọrun olodumare—Ẹni tí ó “le ní ipá” bí?—Isaiah 40:26.
Ẹ̀rí Tí Ó Fi Ìjótìítọ́ Rẹ̀ Hàn
Ṣíṣe àyẹ̀wò kínníkínní nínú àwọn Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tún fúnni ní ẹ̀rí síwájú síi pé wọ́n ṣeé gbàgbọ́. Ohun kan ni pé, ìyàtọ̀ kedere wà láàárín àwọn ìròyìn wọ̀nyí àti àwọn ìtàn egbére àti àròfọ̀ àtọwọ́dọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn èké tí a sọ káàkiri nípa Jesu ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀lé ikú rẹ̀. Ìwé àwọn ọ̀rọ̀ tí òtítọ́ rẹ̀ kò dájú ti “Ìhìnrere Thomas” sọ pé: “Nígbà tí ọmọdékùnrin yìí Jesu di ọmọ ọdún márùn ún . . . , ó gba àárín abúlé kọjá, ọmọdékùnrin kan sì sáré ó sì gbá a ní èjìká. Jesu bínú ó sì wí fún un pé: ‘Oò ní lè rìn kọjá ibi tí o dé yẹn’, ọmọ náà sì ṣubú lulẹ̀ lọ́gán ó sì kú.” Kò ṣòro láti lóye ohun tí ìtàn yìí jẹ́—ìtàn àròsọ kan tí a dọ́gbọ́n hùmọ̀. Síwájú síi, irú ọmọ tí ń kùgìrì gbégbèésẹ̀, tí ń bínú wùrùwùrù tí a ṣàpèjúwe níhìn-ín kò jọ Jesu ti inú Bibeli lọ́nàkọnà.—Ṣe ìfiwéra pẹ̀lú Luku 2:51, 52.
Nísinsìnyí ṣàyẹ̀wò ìròyìn Ìhìnrere tí ó jẹ́ òtítọ́. Wọn kò ní àsọdùn àti èrò èyíkéyìí tí ó kún fún ìtàn àròsọ nínú. Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu ní ìdáhùnpadà sí ojúlówó àìní, kì í wulẹ̀ ṣe láti kùgìrì gbégbèésẹ̀. (Marku 10:46-52) Jesu kò lo agbára rẹ̀ fún àǹfààní ti ara rẹ̀ rí. (Matteu 4:2-4) Kò sì lò wọ́n rí láti ṣe àṣehàn. Níti tòótọ́, nígbà tí Ọba Herodu atọpinpin fẹ́ kí Jesu ṣe “iṣẹ́ àmì” ìyanu fún òun, Jesu “kò fún un ní ìdáhùn kankan.”—Luku 23:8, 9, NW.
Àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu tún yàtọ̀ gédégédé sí iṣẹ́ àwọn ògbóǹtarìgì alálùpàyídà, onídán, àti àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn. Nígbà gbogbo ni àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀ máa ń fògo fún Ọlọrun. (Johannu 9:3; 11:1-4) Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ kò níí ṣe pẹ̀lú ààtò àṣà tí ń ru ìmọ̀lára sókè, ògèdè idán pípa, àṣehàn ṣekárími, ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí, àti ìmúnimúyè. Nígbà tí Jesu ṣalábàápàdé afọ́jú alágbe tí ń jẹ́ Bartimeu ẹni tí ó kígbe, “Raboni, jẹ́ kí n jèrè agbára ìríran padà,” Jesu wulẹ̀ sọ fún un pé: “‘Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì jèrè agbára ìríran padà.”—Marku 10:46-52, NW.
Ìròyìn Ìhìnrere fi hàn pé Jesu ṣe àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀ láìlo nǹkan tí ń pèsè ìrànwọ́, pèpéle ìtàgé tí a ṣètò lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀, tàbí iná bàìbàì. Ó máa ń ṣe wọn lójútáyé, lọ́pọ̀ ìgbà níwájú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olùfojúrí. (Marku 5:24-29; Luku 7:11-15) Láìdàbí ìgbìdánwò àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn ti òde-òní, ìsapá rẹ̀ láti wonisàn kò kùnà rí bóyá nítorí pé àwọn olójòjò kan dàbí ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́. Matteu 8:16 (NW) sọ pé: “Ó . . . wo gbogbo awọn tí nǹkan kò sàn fún sàn.”
Nínú ìwé rẹ̀ “Many Infallible Proofs:” The Evidences of Christianity, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Arthur Pierson sọ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Kristi pé: “Bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, bí àwọn ìwòsàn rẹ̀ ti ń wáyé lójú ẹsẹ̀ tó tí wọn kì í sì í bà á tì, àti àìsí ìkùnà kanṣoṣo rí àní nínú ìgbìdánwò láti jí àwọn òkú dìde pàápàá, mú kí ìyàtọ̀ jàn-ànràn jan-anran wà láàárín àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí àti àwọn ohun ìyanu àdíbọ́nṣe ti sànmánì yìí tàbí ti sànmánì mìíràn.”
Ìtìlẹ́yìn Tí Kì í Ṣe ti Ìsìn
Pierson tún ṣàlàyé mìíràn tí ó gbe ìròyìn Ìhìnrere náà lẹ́yìn nígbà tí ó sọ pé: “Kò sí ohun tí ó fìdí àwọn iṣẹ́ ìyanu inú ìwé mímọ́ múlẹ̀ tí ó pẹtẹrí rékọjá àìlèfọhùn àwọn ọ̀tá.” Àwọn aṣáájú Júù ní ohun tí ó rékọjá ète ìsúnniṣe lílágbára fún fífẹ́ láti bu ẹ̀tẹ́ lu Jesu, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ni a mọ̀ dunjú débi pé àwọn tí ń dojú ìjà kọ ọ́ kò jẹ́ gbójúgbóyà láti sẹ́ wọn. Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ni pé kí wọ́n sọ pé agbára ẹ̀mí-èṣù ni ó fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà bẹ́ẹ̀. (Matteu 12:22-24) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú Jesu, àwọn òǹkọ̀wé Talmud ti àwọn Júù ń bá a nìṣó láti gbà pé Jesu ní agbára iṣẹ́ ìyanu. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà Jewish Expressions on Jesus ti sọ, wọ́n kà á sí ẹni tí ó “tẹ̀lé àṣà idán pípa.” Irú àlàyé bẹ́ẹ̀ yóò ha ti wáyé bí ó bá jẹ́ pé ó tilẹ̀ ṣeé ṣe níwọ̀nba láti ka àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu sí àròsọ lásán?
Ẹ̀rí síwájú síi wá láti ọ̀dọ̀ Eusebius, òpìtàn ṣọ́ọ̀ṣì ti ọ̀rúndún kẹrin. Nínú ìwé rẹ̀ The History of the Church From Christ to Constantine, ó fa ọ̀rọ̀ Quadratus tí ó fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí olú-ọba ní ìgbèjà ìsìn Kristian yọ. Quadratus kọ̀wé pé: “Àwọn iṣẹ́ Olùgbàlà wa fìgbà gbogbo wà níbẹ̀ láti rí, nítorí pé wọ́n jẹ́ òtítọ́—àwọn ènìyàn tí a ti mú lára dá àti àwọn wọnnì tí a jí dìde kúrò nínú òkú, tí kì í wulẹ̀ ṣe pé a rí wọn nígbà tí a wò wọ́n sàn tàbí jí wọn dìde, ṣùgbọ́n tí a lè rí nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí Olùgbàlà wà láàárín wa nìkan, ṣùgbọ́n fún àkókò gígùn lẹ́yìn ìgbéralọ Rẹ̀; níti tòótọ́ àwọn kan lára wọn wà láàyè títí di àkókò tèmi.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ William Barclay ṣàkíyèsí pé: “Quadratus ń sọ pé títí di ọjọ́ tòun àwọn ènìyàn tí a ti ṣiṣẹ́ ìyanu fún ní a ṣì lè rí níti tòótọ́. Bí ìyẹn kì í bá ṣe òtítọ́ kò sí ohun tí ìbá rọrùn tó kí ìjọba Romu sọ pé ó jẹ́ irọ́.”
Ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu Jesu lọ́gbọ́nnínú, ó bá ìrònú rere mu, ó sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀rí lọ́nà tí ó kún rẹ́rẹ́. Bí ó tiwù kí ó rí, iṣẹ́ ìyanu Jesu kì í ṣe òkú ìtàn. Heberu 13:8 (NW) rán wa létí pé: “Jesu Kristi jẹ́ ọ̀kan naa lánàá ati lónìí, ati títí láé.” Bẹ́ẹ̀ni, ó wà láàyè nínú àwọn ọ̀run lónìí, ó ṣeé ṣe fún un láti lo agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ọ̀nà títóbilọ́lá ju bí ó ti ṣe lọ nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Síwájú síi, ìròyìn Ìhìnrere nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ (1) ń kọ́ àwọn Kristian ní ẹ̀kọ́ ṣíṣeé múlò lónìí, (2) ń ṣípayá àwọn apá-ìhà fífanimọ́ra nínú àkópọ̀ ànímọ́ Jesu, tí ó sì (3) ń tọ́ka sí àkókò kan ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tilẹ̀ jẹ́ àrímáleèlọ jù bẹ́ẹ̀ lọ yóò wáyé!
Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn ìròyìn Bibeli mẹ́ta tí a mọ̀ dáradára láti fi ṣàkàwé àwọn kókó wọ̀nyí.