ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/15 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ẹ̀tàn Ni àbí Agbára Ọlọ́run?
  • Àwọn Ohun Tó Fi Hàn Pé Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Jóòótọ́
  • Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Ìwé Ìhìn Rere Ṣe É Gbára Lé?
  • Ẹni Tó Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Náà
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jesu—Ìtàn Tàbí Àròsọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé Òótọ́ Ni Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Iṣẹ́ Ìyanu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Jésù Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/15 ojú ìwé 4-7

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?

Ó LÈ yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé nínú ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé, kò síbì kankan tó ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tó túmọ̀ sí “iṣẹ́ ìyanu.” Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà (dyʹna·mis) tá a máa ń tú sí “iṣẹ́ ìyanu” nígbà mìíràn túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni “agbára.” (Lúùkù 8:46) A tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “agbára ìlèṣe-nǹkan” tàbí “àwọn iṣẹ́ agbára.” (Mátíù 11:20; 25:15) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí “tẹnu mọ́ àwọn iṣẹ́ ribiribi tó wáyé, àti ní pàtàkì, ó tẹnu mọ́ agbára tí a fi ṣe àwọn iṣẹ́ ribiribi ọ̀hún. Agbára Ọlọ́run ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.”

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn (teʹras) ni a sábà máa ń túmọ̀ sí “àmì àgbàyanu” tàbí “iṣẹ́ àgbàyanu.” (Jòhánù 4:48; Ìṣe 2:19) Gbólóhùn yìí jẹ́ ká mọ ipa tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa ń ní lórí àwọn tó bá ṣẹlẹ̀ níṣojú wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun kàyéfì àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ agbára tí Jésù máa ń ṣe jẹ́ lójú àwọn èrò àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.—Máàkù 2:12; 4:41; 6:51; Lúùkù 9:43.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kẹta (se·meiʹon) tó tọ́ka sí iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ “àmì pé Ọlọ́run fún un ní àṣẹ.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robert Deffinbaugh sọ pé ọ̀rọ̀ náà “tẹnu mọ́ ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ tí iṣẹ́ ìyanu náà ní.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àmì yìí jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó sọ òtítọ́ kan nípa Jésù Olúwa wa.”

Ṣé Ẹ̀tàn Ni àbí Agbára Ọlọ́run?

Bíbélì kò ṣàpèjúwe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tó jẹ́ wàyó tàbí ẹ̀tàn tá a gbé kalẹ̀ káwọn èèyàn lè ríran wò. Ó jẹ́ ìfihàn “agbára gíga lọ́lá ti Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ọmọdékùnrin kan tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára rẹ̀. (Lúùkù 9:37-43) Ṣé Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹni tí Bíbélì sọ pé ó ní ‘ọ̀pọ̀ yanturu agbára gíga’ kò wá ní lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ agbára bẹ́ẹ̀ ni? (Aísáyà 40:26) Ó lè ṣe e mọ̀nà!

Àwọn ìwé Ìhìn Rere tọ́ka sí nǹkan bí iṣẹ́ ìyanu márùnlélọ́gbọ̀n tí Jésù ṣe. Àmọ́, kò sọ gbogbo iye àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Mátíù 14:14 sọ pé: “Ó [Jésù] rí ogunlọ́gọ̀ ńlá; àánú wọn ṣe é, ó sì wo àwọn aláìsàn wọn sàn.” Bíbélì ò sọ fún wa iye àwọn aláìsàn tí Jésù wò sàn lọ́jọ́ náà.

Irú àwọn iṣẹ́ agbára bẹ́ẹ̀ ló mú kí sísọ tí Jésù sọ pé òun jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn Mèsáyà tá a ṣèlérí, fìdí múlẹ̀. Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí i pé agbára tí Ọlọ́run fún Jésù ló jẹ́ kó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jésù jẹ́ “ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn ní gbangba fún yín nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀.” (Ìṣe 2:22) Ní àkókò mìíràn, Pétérù sọ ní pàtó pé “Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án [Jésù], ó sì la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣe 10:37, 38.

A ò lè ya àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe kúrò lára àwọn ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni. Máàkù 1:21-27 jẹ́ ká mọ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ṣe sí ẹ̀kọ́ Jésù àti sí ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe. Máàkù 1:22 sọ pé “háà . . . ṣe wọ́n sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,” ẹsẹ 27 sọ pé ‘ẹnu ya’ àwọn èèyàn nígbà tó lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ẹnì kan. Àwọn iṣẹ́ agbára tí Jésù ṣe àti ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni jẹ́ ẹ̀rí pé òun ni Mèsáyà náà tá a ṣèlérí.

Jésù ò kàn wúlẹ̀ sọ pé òun ni Mèsáyà náà; àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn tó ṣe títí kan àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe tó fi hàn pé Ọlọ́run fún un lágbára ló fi ẹ̀rí hàn pé òun ni Mèsáyà. Nígbà táwọn èèyàn fẹ́ mọ̀ nípa ipò Jésù àti ọlá àṣẹ tó ní, ó fi ìgboyà dá wọn lóhùn pé: “Èmi ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Jòhánù [Olùbatisí] lọ, nítorí pé àwọn iṣẹ́ náà gan-an tí Baba mi yàn lé mi lọ́wọ́ láti ṣe ní àṣeparí, àwọn iṣẹ́ náà tìkára wọn tí èmi ń ṣe, ń jẹ́rìí nípa mi pé Baba ni ó rán mi wá.”—Jòhánù 5:36.

Àwọn Ohun Tó Fi Hàn Pé Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Jóòótọ́

Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ti gidi, àti pé wọ́n jóòótọ́? Gbé lára àwọn ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n jóòótọ́ yẹ̀ wò.

Nígbà tí Jésù ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, kò pariwo ara rẹ̀ rí pé òun lòún ṣe wọn. Ó rí i dájú pé Ọlọ́run ló ń gba ìyìn àti ògo iṣẹ́ ìyanu èyíkéyìí tóun bá ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣááju kí Jésù tó wo ọkùnrin afọ́jú kan sàn, ó fi yé àwọn èèyàn pé òun yóò ṣe ìwòsàn náà “kí a lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn rẹ̀.”—Jòhánù 9:1-3; 11:1-4.

Jésù ò dà bí àwọn alálùpàyídà, àwọn onídán àtàwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn, òun kì í mú àwọn èèyàn níyè, kì í lo ẹ̀tàn, kì í ṣe àṣehàn, kì í pe ọfọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í lo ààtò mẹ́mìí-mẹ́mìí láti fi ṣe iṣẹ́ ìyanu. Kò lo ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tàbí àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí mímọ́. Ẹ wo bí Jésù ṣe rọra la ojú àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ afọ́jú. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “bí àánú ti ṣe é, Jésù fọwọ́ kan ojú wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n sì ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” (Mátíù 20:29-34) Kò sí ààtò, kò sí pẹ́pẹ́fúúrú tàbí àṣehàn kankan. Gbangba ni Jésù ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, ọ̀pọ̀ ìgbà ni èyí sì máa ń jẹ́ níṣojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Kò lo nǹkan atànmọ́lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò lo pèpéle tàbí àwọn ohun èlò orí ìtàgé. Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí, nítorí pé iṣẹ́ ìyanu wọn kì í sábà ní ẹ̀rí gidi tí a lè padà tọ́ka sí.—Máàkù 5:24-29; Lúùkù 7:11-15.

Nígbà mìíràn, Jésù máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìyanu fún. Àmọ́, Jésù kò tìtorí pé ẹnì kan ò nígbàgbọ́ kó má ṣe iṣẹ́ ìyanu fún onítọ̀hún o. Nígbà tí Jésù wà ní Kápánáúmù ti Gálílì, “àwọn ènìyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè wá sọ́dọ̀ rẹ̀; òun sì fi ọ̀rọ̀ lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún sàn.”—Mátíù 8:16.

Nítorí àtiyanjú ìṣòro táwọn èèyàn ní nípa tara ni Jésù ṣe ṣe iṣẹ́ ìyanu, kì í ṣe káwọn alátojúbọ̀ lè ríran wò. (Máàkù 10:46-52; Lúùkù 23:8) Àti pé Jésù ò ṣe iṣẹ́ ìyanu nítorí kó bàa lè ṣe ara rẹ̀ láǹfààní.—Mátíù 4:2-4; 10:8.

Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Ìwé Ìhìn Rere Ṣe É Gbára Lé?

Àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Ǹjẹ́ ìdí tiẹ̀ wà tó fi yẹ ká gba ohun táwọn ìwé yìí sọ gbọ́ bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó fi hàn pé òótọ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n sọ pé Jésù ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ìdí wà.

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, gbangba ni Jésù ti máa ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tirẹ̀, níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ìgbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà níbi tí Jésù ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn ṣì wà láàyè ni wọ́n kọ èyí tí wọ́n kọ́kọ́ kọ pàá nínú ìwé Ìhìn Rere náà. Ohun tí ìwé The Miracles and the Resurrection sọ nípa ìwà àìlábòsí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere náà ni pé: “Kò tọ̀nà rárá àti rárá láti fi ẹ̀sùn kan àwọn tó kọ ìwé ìhìn rere pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ki ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi bọnú oríṣiríṣi ìtàn nípa iṣẹ́ ìyanu láti lè fi polówó ìgbàgbọ́ wọn. . . . Wọ́n rí i dájú pé àwọn ò fi dúdú pe funfun nínú àkọsílẹ̀ wọn.”

Kódà, àwọn Júù tí wọ́n ta ko ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá ò ṣiyèméjì rí nípa àwọn iṣẹ́ agbára tí ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ibi tí agbára tí wọ́n fi ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ọ̀hún ti wá nìkan ló kọ wọ́n lóminú. (Máàkù 3:22-26) Bẹ́ẹ̀ làwọn tó wá ń ṣe lámèyítọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn pàápàá ò lè sọ pé Jésù ò ṣe iṣẹ́ ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, láàárín ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì Sànmánì Tiwa, a rí àwọn ibi tí wọ́n ti tọ́ka sí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Ní kedere, a ní ẹ̀rí tó dájú láti gbà gbọ́ pé àkọsílẹ̀ inú ìwé ìhìn Rere nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣé jóòótọ́.

Ẹni Tó Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Náà

Tó bá jẹ́ pé àyẹ̀wò nípa bóyá ìtàn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jóòótọ́ tàbí kì í ṣòótọ́ nìkan là ń ṣe ni, á jẹ́ pé àyẹ̀wò náà kò tíì pé nìyẹn. Nígbà tí ìwé Ìhìn Rere ń sọ nípa àwọn iṣẹ́ agbára tí Jésù ṣe, ó fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ẹnì tí ọrọ̀ àwọn èèyàn máa ń ká lára, tó ní ẹ̀mí ìyọ́nú tí kò láfiwé, tí ire àwọn èèyàn sì máa ń jẹ lọ́kàn.

Wo àpẹẹrẹ adẹ́tẹ̀ kan tó wá bá Jésù, tó ń bẹ̀ ẹ́ lójú méjèèjì pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Nítorí pé “àánú ṣe” Jésù, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fọwọ́ kan adẹ́tẹ̀ náà, ó sì sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ara ọkùnrin náà yá gáú. (Máàkù 1:40-42) Jésù tipa báyìí fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn, ìyẹn ànímọ́ tó mú kó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ṣe iṣẹ́ ìyanu.

Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé òkú kan tí wọ́n fẹ́ lọ sin jáde látinú ìlú Náínì? Ọmọkùnrin tó kú yìí nìkan ni ìyà rẹ̀ tó jẹ́ opó bí. Nítorí pé “àánú” obìnrin yìí ṣe Jésù, ó sún mọ́ ọn, ó sì wí fún un pé: “Dẹ́kun sísunkún.” Lẹ́yìn náà, ó jí ọmọkùnrin yìí dìde.—Lúùkù 7:11-15.

Ẹ̀kọ́ kan tó ń tuni nínú tá a lè rí kọ́ látinú ìtàn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ni pé ‘àánú ṣe é,’ ó sì ṣe nǹkan kan láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́, ìtàn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí kì í ṣe ìtàn àròsọ lásán o. Hébérù 13:8 sọ pé, “Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé.” Ó sì ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lókè ọ̀run báyìí, ó ti múra tán bẹ́ẹ̀ ló sì tóótun láti lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́nà tó gbòòrò ju èyí tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Láìpẹ́, Jésù yóò lo agbára náà láti wo aráyé onígbọràn sàn. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i nípa àǹfààní kíkọyọyọ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ “agbára gíga lọ́lá ti Ọlọ́run”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù jẹ́ ẹnì kan tí ọrọ̀ èèyàn máa ń ká lára

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́