ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/15 ojú ìwé 8-9
  • ‘Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn àti Ìgbà Òtútù Kì Yóò Kásẹ̀ Nílẹ̀ Láé’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn àti Ìgbà Òtútù Kì Yóò Kásẹ̀ Nílẹ̀ Láé’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Oòrùn Àtàwọn Pílánẹ́ẹ̀tì Tó Ń yí i Po Ṣe Dèyí Tó Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ọlọ́run “Ìgbà Àti Àsìkò”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìgbà Àti Àsìkò Wà Lọ́wọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/15 ojú ìwé 8-9

Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà

‘Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn àti Ìgbà Òtútù Kì Yóò Kásẹ̀ Nílẹ̀ Láé’

OÒRÙN tó ń ràn sórí aṣálẹ̀ yìí mú janjan. Láwọn apá ibòmíràn láyé sì rèé, ńṣe ló máa ń mú ara àwọn èèyàn yá gágá lẹ́yìn ìgbà òtútù nini. Ká sòótọ́, ooru tó ń tinú oòrùn wá ńbẹ lára nǹkan tó ń jẹ́ ká ní ojú ọjọ́ tó yàtọ̀ síra àti onírúurú ìgbà.

Ojú ọjọ́ àti ìgbà yàtọ̀ síra káàkiri ayé. Àmọ́ báwo làwọn ìgbà tá a máa ń ní ṣe máa ń rí lára rẹ? Ṣé inú rẹ máa ń dùn tí ìgbà òjò bá bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀ẹ̀rùn ti mú fún ọ̀pọ̀ oṣù? Báwo lára rẹ ṣe máa ń rí láwọn ìrọ̀lẹ́ tó tuni lára nígbà ẹ̀ẹ̀rùn? Ṣé o máa ń gbádùn ìgbà ìkórè, nígbà táwọn àgbẹ̀ máa ń kórè iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ti ṣe?

Kí ló ń mú ká ní onírúurú ìgbà? Ní kúkúrú, nítorí dídagun tí ayé dagun ni. Ipa ọ̀nà tí ayé máa ń tọ̀ láti yípo oòrùn dagun diẹ̀. Ká ní pé kò dagun ni ì bá má sí onírúurú ìgbà. Bákan náà ni ojú ọjọ́ ì bá máa rí ní gbogbo ìgbà. Èyí á sì ṣàkóbá fáwọn ewéko àtàwọn irè oko tó máa ń jáde látìgbàdégbà.

A lè ri pé Ẹlẹ́dàá ló ṣètò àwọn ìgbà tó máa ń tẹ̀ léra yìí. Nígbà tí onísáàmù náà ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó sọ lọ́nà tó yẹ pé: “Ìwọ ni ó pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé; ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù—ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣẹ̀dá wọn.”—Sáàmù 74:17.a

Àwọn ohun tá a lè rí lójú sánmà bí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ jẹ́ àwọn nǹkan tá a lè gbára lé fún mímọ ìgbà. Nígbà tí Ọlọ́run ń dá oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yípo rẹ̀, ó pàṣẹ pé: “Kí orísun ìmọ́lẹ̀ wà ní òfuurufú ọ̀run . . . , wọn yóò sì wà fún àmì àti fún àwọn àsìkò àti fún àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:14) Láàárín ọdún kan, bí ayé ṣe ń yípo, àwọn ọ̀gangan ibi méjì kan wà tó máa ń dé tá dà bíi pé oòrùn wà ní ọ̀gangan àtàrí ẹni lọ́sàn-án. Ìgbà tí ọ̀sán àti òru dọ́gba ni wọ́n máa ń pè é. Lọ́pọ̀ ilẹ̀, ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìgbà ìrúwé àti ìgbà ìwọ́wé bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Lákòókò yìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bákan náà ni gígùn ọ̀sán àti òru máa ń jẹ́ níbi gbogbo láyé.

Kì í ṣe ibi tí oòrùn, òṣùpá tàbí ìràwọ̀ wà lójú sánmà àti bí wọ́n ṣe ń yípo nìkan ló ń mú ká ní onírúurú ìgbà. Ìgbà àti ojú ọjọ́ wọnú ara wọn gan-an, èyí sì jẹ́ ètò tó díjú síbẹ̀ tó ń gbé ẹ̀mí ró. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ń bá àwọn tó wà ní Éṣíà Kékeré sọ̀rọ̀, tí ọ̀pọ̀ lára wọn mọ̀ nípa iṣẹ́ oko dáadáa àti mímú oúnjẹ jáde, wọ́n sọ pé Ọlọ́run lẹni tí “ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:14-17.

Ìlànà àgbàyanu tá a mọ̀ sí photosynthesis ń jẹ́ káwọn ewéko orí ilẹ̀ àtàwọn ewé tá ò lè fi ojúyòójú rí lábẹ́ òkun máa rí oúnjẹ nípasẹ̀ oòrùn. Fún ìdí yìí, ipò ojú ọjọ́ máa ń mú káwọn ohun ẹlẹ́mìí tó gbára léra wọn fún oúnjẹ àti onírúurú ohun alààyè máa ṣe dáadáa. Àmọ́ ọ̀nà tí èyí gbà ń ṣẹlẹ̀ díjú. Pọ́ọ̀lù tọ̀nà nígbà tó tọ́ka sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó sọ pé: “Ilẹ̀ tí ń fa òjò tí ó máa ń wá sórí rẹ̀ mu, àti lẹ́yìn náà, tí ń mú ewéko jáde èyí tí ó yẹ fún àwọn tí a tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìdápadà.”—Hébérù 6:7.

Ọ̀rọ̀ náà, “ìbùkún,” yóò túbọ̀ lágbára lọ́kàn rẹ bó o bá dúró tó o sì ronú lórí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn àgbègbè tí ooru kò mú jù tí òtútù kò sì mú jù nígbà ìrúwé, tí ọ̀sán gùn ju òru lọ, tí oòrùn ràn dáadáa tí òjò sì rọ̀ bó ṣe yẹ. Àwọn òdòdó máa ń rú, àwọn kòkòrò sì máa ń jáde látinú àwọn ibi tí wọ́n forí pa mọ́ sí nígbà òtútù, tí wọ́n á sì wà ní sẹpẹ́ láti mú kí àwọn ohun ọ̀gbìn gbakọ. Àwọn ẹyẹ, bí ọ̀kan tó ò ń wò níbí yìí tó ń jẹ́ Jay tó láwọ̀ búlúù máa ń kún inú igbó tàwọn ti àwọ̀ wọn àti orin wọn aládùn, ojú ilẹ̀ sì máa ń jà yọ̀yọ̀. Ìgbésí ayé á tún wá bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí á máa bá ìgbésí ayé wọn nìṣó bí wọ́n ti ń bímọ, tí ara wọn ń jí dọ̀tun, tí wọ́n sì ń dàgbà. (Orin Sólómọ́nì 2:12, 13) Gbogbo ìwọ̀nyí ló ń jẹ́ ká rí nǹkan kórè nígbà ìkórè.—Ẹ́kísódù 23:16.

Bí Jèhófà ṣe mú kí ayé wa rọra dagun fi bí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àgbàyanu tó hàn, èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ọ̀sán àti òru, onírúurú ìgbà, àkókò ọ̀gbìn àti àkókò ìkórè. Ọkàn wa máa ń balẹ̀ pé ìgbà òjò yóò tẹ̀ lé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ó ṣe tán, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí pé: “Ní gbogbo ọjọ́ tí ilẹ̀ ayé yóò máa bá a lọ ní wíwà, fífún irúgbìn àti ìkórè, àti òtútù àti ooru, àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, àti ọ̀sán àti òru, kì yóò kásẹ̀ nílẹ̀ láé.”—Jẹ́nẹ́sísì 8:22.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù July àti August nínú 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Òṣùpá Ṣe Pàtàkì Gan-An fún Ìwàláàyè

Látọjọ́ tí èèyàn ti wà láyé ni òṣùpá ti ń jẹ́ ohun àràmàǹdà sí wọn. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé òṣùpá ní ipa tó ń kó nínú onírúurú ìgbà tí a ní? Òṣùpá ló jẹ́ ki ayé wà ní ipò dídagun tó wà bó ti ń yípo. Andrew Hill tó jẹ́ òǹṣèwé lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé èyí jẹ́ “ohun pàtàkì kan tó ń jẹ́ ká ní onírúurú ìgbà lórí Ilẹ̀ Ayé tó sì ń gbé ẹ̀mí ró.” Ká ni kò sí àwọn sátẹ́láìtì àdánidá hẹ̀rìmọ̀ bí òṣùpá ni, tí kì í jẹ́ kí ayé máa ṣe ségesègé bó ṣe ń yípo oòrùn, ayé ì bá gbóná kọjá ààlà débi pé kò ní sí ohun alààyè kankan tí ì bá lè gbénú rẹ̀. Èyí gan-an lohun tó mú kí àwọn kan lára àwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà sọ pé: “Ká kúkú sọ pé Òṣùpá ni kò jẹ́ kí ojú ọjọ́ máa ṣe ségesège lórí Ilẹ̀ Ayé.”—Sáàmù 104:19.

[Credit Line]

Òṣùpá: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./Bart O’Gara

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Ràkúnmí ní Àríwá Áfíríkà àti Àgbègbè Arébíà tí Omi Fẹ́rẹ̀ẹ́ Yí Ká

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́