Bí Oòrùn Àtàwọn Pílánẹ́ẹ̀tì Tó Ń yí i Po Ṣe Dèyí Tó Wà
IBI tí oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po tí ayé jẹ́ ọ̀kan lára wọn wà nínú òfuurufú tó lọ salalu jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì mú kó rí bẹ́ẹ̀. Apá ibi tí ìràwọ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí láàárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà ni oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po wà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ìràwọ̀ tá a máa ń rí lálẹ́ ni ọ̀nà wọn jìn débi pé nígbà tí wọ́n fi àwọn awò awọ̀nàjíjìn tó lágbára jù lọ wò wọ́n, bíńtín náà ni wọ́n ṣì rí. Ǹjẹ́ ó yẹ kí oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po jìnnà sáwọn ìràwọ̀ náà tó bẹ́ẹ̀?
Ká ní àárín gbùngbùn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà ni oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po wà ni, àárín ibi tí ìràwọ̀ ti pọ̀ jù ni ayé yìí ì bá wà, ìyẹn ì bá sì ṣèpalára fún ayé. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ìyípadà bá ọ̀nà tí ayé gbà ń yí po oòrùn, ìyẹn ì bá sì ṣàkóbá fáwa èèyàn. Àmọ́ ńṣe ni ayé àtàwọn pílánẹ́ẹ́tì míì tí wọ́n jọ ń yí po oòrùn wà níbi tó yẹ kí wọ́n wà gẹ́lẹ́ láàárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà. Ibi tí wọ́n wà yìí ni ò jẹ́ kí ìpalára kankan wà fún ayé tí kò sì jẹ́ káwọn nǹkan búburú míì ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká ní kì í ṣe ibẹ̀ ni wọ́n wà ni, ayé ì bá máa gba àwọn ibi ìkùukùu gáàsì tó lè mú kí ayé gbóná jù, ayé ì bá sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn ìràwọ̀ tó ń bú gbàù àtàwọn nǹkan míì tó ní ìtàṣán tó lè ṣekú pani, ewu ńlá nìyẹn ì bá sì jẹ́.
Oòrùn ni irú ìràwọ̀ tó lè ṣe ayé láǹfààní. Ńṣe ló ń yọ iná lala láìdáwọ́dúró, ó máa wà pẹ́ títí, kò tóbi jù kò sì gbóná jù. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà ni kò tóbi tó oòrùn, irú ìmọ́lẹ̀ tí wọ́n ń tàn àti ìwọ̀n ìgbóná wọn kò sì lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ohun ẹlẹ́mìí láti gbé nínú àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wọn tó rí bí ayé. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ ìràwọ̀ ni agbára òòfà so méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn pọ̀ tí wọ́n sí ń yí po ara wọn. Àmọ́ oòrùn yàtọ̀ ní tiẹ̀, ńṣe ló dá wà. Kò dájú pé oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po, títí kan ayé, á dúró bí wọ́n ṣe dúró yìí, ká ní pé àwọn oòrùn míì tún wà tí agbára òòfà tiwọn àti ti oòrùn jọ ń fa ara wọn.
Ohun míì tó tún mú kí oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ni ibi táwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá lára wọn wà. Àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá náà jìnnà sóòrùn, ipa ọ̀nà tí wọ́n ń tọ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ rí róbótó, agbára òòfà wọn kò sì ṣàkóbá fún ayé àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì kékeré tó dà bí ayé tí wọn ò jìnnà sóòrùn.a Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá wọ̀nyí ń gba àwọn ohun tó lè ṣèpalára fáwọn pílánẹ́ẹ̀tì kékeré náà mọ́ra, wọ́n sì ń taari àwọn míì sọ nù. Nínú ìwé kan tó jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà, Peter D. Ward àti Donald Brownlee ṣe, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Irú Ayé Ṣọ̀wọ́n—Ìdí Tó Fi Jẹ́ Pé Ayé Nìkan La Ti Rí Ohun Abẹ̀mí, wọ́n sọ pé: “Àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá tí gáàsì kúnnú wọn, irú bíi Júbítà tó wà ní ìkọjá ayé, ni ò jẹ́ kí àwọn àpáta kan tí wọ́n ń pè ní asteroid àti ìràwọ̀ onírù máa fi bẹ́ẹ̀ já lu ayé.” Yàtọ̀ sí oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po, wọ́n ti ṣàwárí àwọn ìràwọ̀ míì tí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá ń yí po. Àmọ́ ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá yìí gbà ń yí po lè ṣàkóbá fún pílánẹ́ẹ̀tì kékeré bí ayé wa yìí.
Iṣẹ́ Tí Òṣùpá Ń Ṣe
Ó pẹ́ tí òṣùpá ti ń ya ọmọ aráyé lẹ́nu. Àwọn akéwì ti fi kéwì, àwọn akọrin sì ti fi kọrin. Bí àpẹẹrẹ, Hébérù kan tó jẹ́ akéwì láyé ọjọ́un sọ pé òṣùpá ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà.’—Sáàmù 89:37.
Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tí òṣùpá gbà ń ṣe ohun alààyè láǹfààní lórí ilẹ̀ ayé ni bí agbára òòfà rẹ̀ ṣe máa ń mú kí omi òkun máa wá sókè kó sì máa lọ sílẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé èyí ló máa ń fa ìgbì òkun, èyí tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó máa ń pinnu bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí.
Ohun pàtàkì míì tí òṣùpá ń ṣe ni pé agbára òòfà rẹ̀ kì í jẹ́ kí ayé yẹ̀ kúrò lójú òpó tó ń tọ̀ bó ṣe ń yí oòrùn po. Bí ìwé ìròyìn Nature tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe sọ, ká ní kò sí òṣùpá ni, bí àkókò ṣe ń lọ, ayé á “fẹ́rẹ̀ẹ́ yí pátápátá” kúrò lápá ibi tó yẹ kó dagun sí bó ṣe ń lọ yí po. Ìwọ ro bí nǹkan ì bá ṣe rí ká ní kì í ṣe pé ayé dagun bó ṣe ń yí oòrùn po! Kì bá má sí onírúurú ìgbà tá a máa ń ní lọ́dọọdún, òjò ì bá má sì máa rọ̀ tó bó ṣe yẹ. Yàtọ̀ síyẹn, bí ayé ṣe dagun ni ò jẹ́ kó gbóná jù tàbí kó tutù jù débi tí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí ò fi ní lè gbébẹ̀. Onímọ̀ nípa sánmà náà Jacques Laskar sọ pé: “Òṣùpá ló mú kí ojú ọjọ́ máa rí bó ṣe ń rí yìí, tí kì í ṣe ségesège.” Títóbi tí òṣùpá tóbi gan-an ló jẹ́ kó lè máa ṣe èyí. Ní ti òṣùpá àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá, wọ́n kéré gan-an ni sí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì náà.
Ẹni tó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ nǹkan míì tí òṣùpá ń ṣe. Ohun náà ni pé òṣùpá máa ń tan ìmọ́lẹ̀ ní òru.—Jẹ́nẹ́sísì 1:16.
Ṣé Wọ́n Ṣèèṣì Wà Ni, àbí Olóye Kan Ló Ṣe Wọ́n?
Báwo ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí, tó para pọ̀ mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé tó sì ń jẹ́ ká gbádùn ìwàláàyè, ṣe wáyé? Nǹkan méjì ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Yálà kó jẹ́ pé àwọn ohun wọ̀nyí ṣèèṣì wà ni tàbí kó jẹ́ pé ẹnì kan tó jẹ́ olóye ló dìídì dá wọn.
Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, Ìwé Mímọ́ sọ pé Ẹlẹ́dàá tí í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè ronú àtidá ayé òun ìsálú ọ̀run, ó sì dá wọn. Nítorí náà, kì í ṣe pé oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po ṣèèṣì wà bó ṣe wà, ẹnì kan ló dìídì dá wọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́dàá fún wa ní àkọsílẹ̀ kan nípa àwọn ohun tó ṣe kó lè ṣeé ṣe fáwọn ohun ẹlẹ́mìí láti máa gbé orí ilẹ̀ ayé. O jẹ́ mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ àkọsílẹ̀ náà, ó bá ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mu nípa bí ayé òun ìsálú ọ̀run ṣe dèyí tó wà. Inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ni àkọsílẹ̀ náà wà. Wo ohun tó sọ.
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì Sọ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Àwọn Nǹkan
Gbólóhùn àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ohun tí èyí ń sọ ni bí Ọlọ́run ṣe dá oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po tí ayé jẹ́ ọ̀kan lára wọn, àti bó ṣe dá àwọn ìràwọ̀ tó wà nínú ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ inú òfuurufú tó lọ salalu. Ní ti ayé, Bíbélì sọ pé, nígbà kan, ńṣe ni ayé wà ní “bọrọgidi, ó sì ṣófo.” Kò sí ìyàngbẹ ilẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé alagbalúgbú omi ló wà, èyí sì làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ wà ní pílánẹ́ẹ̀tì kan kó tó lè ṣeé gbé fún ẹ̀dá ẹlẹ́mìí. Bíbélì sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run “ń lọ síwá-sẹ́yìn lójú omi.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:2.
Pílánẹ́ẹ̀tì kan ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ oòrùn jù kó má lọ gbóná jù tí omi ibẹ̀ á fi gbẹ, kò sì gbọ́dọ̀ jìn sí i jù kó má lọ tutù jù tí omi ibẹ̀ á fi di yìnyín. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Andrew Ingersoll tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn pílánẹ́ẹ̀tì sì sọ, “pílánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Máàsì ti tutù jù, èyí tó ń jẹ́ Àgùàlà ti gbóná jù, àmọ́ ayé ò tutù jù kò sì gbóná jù.” Yàtọ̀ sí èyí, kí ewéko tó lè máa dàgbà, ìmọ́lẹ̀ tó tó gbọ́dọ̀ wà. Kó o sì máa wò ó o, Bíbélì sọ pé nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀dá, ó mú kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ràn kọjá gba inú kùrukùru tó bo òkun bí ìgbà tí wọ́n fi “ọ̀já ìwémọ” wé ọmọ kékeré kan.—Jóòbù 38:4, 9; Jẹ́nẹ́sísì 1:3-5.
Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Ẹlẹ́dàá dá “òfuurufú.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:6-8) Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé wa ló sì kúnnú òfuurufú yìí.
Lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run mú kí ayé yí padà kúrò ní bọrọgidi nípa mímú kí ìyàngbẹ ilẹ̀ wà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:9, 10) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run mú kí ilẹ̀ abẹ́ ibú omi lanu tí àwọn ọ̀gbun ńláńlá fi wà, tí alagbalúgbú omi wá rọ́ sínú wọn, èyí tó mú kí ìyàngbẹ ilẹ̀ yọrí jáde látinú agbami òkun.—Sáàmù 104:6-8.
Ọlọ́run dá àwọn ewéko tín-tìn-tín tá ò lè fojú rí sínú òkun, àmọ́ Bíbélì ò mẹ́nu kan àkókò pàtó tí Ọlọ́run ṣèyẹn. Àwọn ewéko yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi agbára ìmọ́lẹ̀ oòrùn pèsè oúnjẹ fúnra wọn nípa sísọ afẹ́fẹ́ carbon dioxide di oúnjẹ, wọ́n á wá tú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn jáde síta. Ní ọjọ́ kẹta ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá àwọn ewéko mìíràn tó wá bo gbogbo ilẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í tú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn jáde síta. Èyí mú kí ìwọ̀n afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó wà nínú atẹ́gùn pọ̀ sí i. Afẹ́fẹ́ ọ́síjìn téèyàn àtẹranko ń mí sínú ló sì jẹ́ kí wọ́n lè wà láàyè.—Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 12.
Kí ilẹ̀ ayé lè lọ́ràá, Ẹlẹ́dàá dá ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò tín-tìn-tín tá ò lè fojú rí sínú ilẹ̀. (Jeremáyà 51:15) Àwọn kòkòró yìí ló máa ń mú kí òkú ẹran, igi àtàwọn nǹkan míi bẹ́ẹ̀ jẹrà, kí èròjà ara wọn lè padà sínú ilẹ̀ láti di ọ̀rá inú ilẹ̀ tó ń mú kí ewéko dàgbà. Àwọn kòkòrò àrà ọ̀tọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń fa afẹ́fẹ́ nitrogen wá sínú ilẹ̀ láti sọ ọ́ di èròjà tó ń mú kí ewéko dàgbà. Àní ẹ̀kúnwọ́ kan ilẹ̀ tó lọ́ràá dáadáa lè ní tó bílíọ́nù mẹ́fà àwọn kòkòrò tín-tìn-tín téèyàn ò lè fojú rí. Áà, iṣẹ́ Ọlọ́run mà pọ̀ o!
Jẹ́nẹ́sísì 1:14-19 sọ pé Ọlọ́run dá oòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀ ní ọjọ́ kẹrin ìṣẹ̀dá. Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ó lè dà bíi pé ohun tí ẹsẹ yìí sọ, pé ọjọ́ kẹrin ni Ọlọ́run dá àwọn ohun wọ̀nyí, ta ko gbogbo àlàyé inú Ìwé Mímọ́ tá a ti ń sọ bọ̀. Àmọ́ ṣá o, rántí pé ńṣe ni Mósè tó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀dá bó ṣe máa rí lójú ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣẹ̀dá yẹn. Ó hàn gbangba pé ọjọ́ kẹrin ìṣẹ̀dá yẹn lẹni tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé tó lè rí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀.
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé ọjọ́ karùn-ún ìṣẹ̀dá ni Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá inú òkun, ó sì sọ pé ọjọ́ kẹfà ló dá àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àti èèyàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:20-31.
Ọlọ́run Dá Ayé Kéèyàn Lè Gbádùn Rẹ̀
Ǹjẹ́ o kò rí i pé ńṣe ni Ọlọ́run fi ìwàláàyè jíǹkí wa lórí ilẹ̀ ayé bí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣe sọ, ká lè gbádùn rẹ̀? Tó o bá jí láàárọ̀, tó o rí tí oòrùn yọ, tó o sì mí atẹ́gùn tó tura sínú, ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn pé o wà láàyè? Tó o bá sì ń rìn nínú ọgbà kan, tó o rí bí àwọn òdòdó ibẹ̀ ṣe lẹ́wà tó, tí òórùn wọn sì gbádùn mọ́ ọ, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ? Ká sì sọ pé ńṣe lò ń gbafẹ́ nínú ọgbà eléso kan tó o sì jẹ èso adùnyùngbà ibẹ̀, ǹjẹ́ kò ní dùn mọ́ ọ? Irú ìgbádùn bẹ́ẹ̀ kì bá má ṣeé ṣe ká ní kì í ṣe pé: (1) omi pọ̀ láyé, (2) à ń rí ìwọ̀n ooru àti ìmọ́lẹ̀ tó tó látinú oòrùn, (3) ìwọ̀n onírúurú afẹ́fẹ́ tó yẹ wà lófuurufú, (4) ilẹ̀ ọlọ́ràá wà.
Gbogbo ohun wọ̀nyí kò sí ní pílánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Máàsì, èyí tó ń jẹ́ Àgùàlà àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù tí wọ́n ń yí po oòrùn, àmọ́ wọ́n wà ní ayé. Kì í ṣe pé wọ́n ṣèèṣì wà níbẹ̀ o. Ńṣe ni Ẹlẹ́dàá dìídì ṣe wọ́n ní ìwọ̀n tó yẹ ká lè gbádùn ìwàláàyè wa lórí ilẹ̀ ayé. Bí àpilẹ̀kọ tó kàn sì ṣe fi hàn, Bíbélì tún sọ pé ńṣe ni Ẹlẹ́dàá dá ilé ayé wa ẹlẹ́wà lọ́nà tí yóò fi wà títí láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìyàngbẹ ilẹ̀ wà láwọn pílánẹ́ẹ̀tì mẹ́rin tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sóòrùn, ìyẹn Mẹ́kúrì, Àgùàlà (Venus), Ayé àti Máàsì. Àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kìkì gáàsì tó dà bí ìgbà tí èéfín wọ́ jọ pọ̀ làwọn pílánẹ́ẹ̀tì ńláńlá tí wọ́n jìnnà sóòrùn gan-an, ìyẹn Júbítà, Sátọ̀n, Uranus àti Neptune.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọ̀gbẹ́ni Wallace Pratt tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ohun tó wà nínú ilẹ̀ sọ pé: “Tí wọ́n bá ní kí n ṣàlàyé ṣókí fáwọn èèyàn tó ń gbé ìgbèríko bí irú àwọn tí wọ́n kọ Ìwé Jẹ́nẹ́sísì fún nígbà yẹn lọ́hùn-ún, nípa èrò táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní báyìí nípa bí ayé ṣe dèyí tó wà àti bí ẹ̀dá alààyè ṣe dénú rẹ̀, ọ̀nà tí màá gbà ṣàlàyé rẹ̀ kò ní jìnnà sí ti ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó TÚN JẸ́ IBI TÓ DÁRA JÙ LỌ LÁTI MỌ̀ NÍPA ÀWỌN ÌRÀWỌ̀
Ká ní ibòmíì ni oòrùn wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà, ì bá má ṣeé ṣe fún wa láti máa rí àwọn ìràwọ̀ dáadáa. Ìwé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ The Privileged Planet ṣàlàyé pé: “Oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po . . . jìnnà sí apá ibi tí kùrukùru wà, tí ìmọ́lẹ̀ sì ti pọ̀ jù. Èyí ló mú kéèyàn lè rí àwọn ìràwọ̀ tó wà nítòsí àtàwọn apá ibi tó jìnnà réré nínú òfuurufú.”
Yàtọ̀ síyẹn, bí òṣùpá ṣe jìnnà sí ayé ní ìwọ̀n tó yẹ mú kó lè máa ṣókùnkùn bo ayé, èyí tá à ń pè ní ọ̀sándòru. Ohun àwòyanu tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló máa ń ṣẹlẹ̀ yìí, ìyẹn kí ọ̀sán dòru, máa ń mú káwọn onímọ̀ nípa sánmà lè ṣèwádìí nípa oòrùn. Irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ sì ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan tá ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn ìràwọ̀ ṣe ń tàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Títóbi tí òṣùpá tóbi ló fi ni agbára òòfà tó pọ̀ tó, èyí tí ò jẹ́ kí ayé yẹ̀ kúrò lápá ibi tí ayé dagun sí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kí ló mú kí ohun abẹ̀mí lè wà lórí ilẹ̀ ayé? Omi tó pọ̀ níbẹ̀, ìwọ̀n ìmọ́lẹ̀ àti ooru tó tó, afẹ́fẹ́ àti ilẹ̀ ọlọ́ràá tó wà níbẹ̀
[Àwọn Credit Line]
Àwòrán ayé: Inú fọ́tò NASA la ti rí i; àlìkámà: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.