ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 2/15 ojú ìwé 3
  • Gbádùn Ilé Ayé Wa Ẹlẹ́wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbádùn Ilé Ayé Wa Ẹlẹ́wà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Oòrùn Àtàwọn Pílánẹ́ẹ̀tì Tó Ń yí i Po Ṣe Dèyí Tó Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Agbára Ìṣẹ̀dá—“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ohun Tí Ayé Àtàwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Jẹ́ Ká Mọ̀
    Jí!—2021
  • Ẹ̀bùn Tó Máa Wà Títí Láé Tí Ẹlẹ́dàá Fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 2/15 ojú ìwé 3

Gbádùn Ilé Ayé Wa Ẹlẹ́wà

ÀWỌN onímọ̀ nípa sánmà ti rí i pé bíńtín ní ilé ayé rí nínú òfuurufú tó lọ salalu. Ayé nìkan ni wọ́n tíì rí tí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí ń gbé. Òun nìkan ló ní àwọn ohun tó mú kó ṣeé gbé fún ẹ̀dá ẹlẹ́mìí.

Yàtọ̀ síyẹn, ilé ayé wa ẹlẹ́wà jẹ́ ibi tá a ti lè gbádùn ìwàláàyè wa. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń dùn mọ́ wa gan-an tí oòrùn bá ta yẹ́ẹ́ sí wa lára lọ́jọ́ tí òtútù bá mú. Ta ni kì í sì í dùn mọ́ nígbà tó bá rí yíyọ oòrùn àti wíwọ̀ rẹ̀ tó jẹ́ àrímáleèlọ? Àmọ́, kì í ṣe kí oòrùn kàn dùn mọ́ wa nìkan ló wà fún o. Láìsí oòrùn, a ò lè wà láàyè.

Láti àìmọye ọdún ni agbára òòfà tí oòrùn ní tí ń mú kí ayé àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì míì máa yí oòrùn po lójú òpó tí wọ́n ń tọ̀ tí wọn ò sì yẹ̀ kúrò lójú òpó náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì kọ́ níléèwé, ńṣe ni oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po, èyí tí ayé jẹ́ ọ̀kan lára wọn, jọ ń yí po lójú òpó wọn nítòsí àárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà (Milky Way galaxy). Àmọ́ ńṣe ni oòrùn wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù táwọn náà ń yí po nítòsí àárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà.

Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára nǹkan bí ogójì ó dín márùn-ún [35] ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí agbára òòfà so pọ̀. Àwọn àgbájọ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míì tó tóbi gan-an máa ń ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ nínú. Ká ní àárín àwọn àgbájọ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó tóbi bẹ́ẹ̀ ni oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po wà ni, ó ṣeé ṣe kí èyí ṣàkóbá fún wọn. Nínú ìwé tí Guillermo Gonzalez àti Jay W. Richards ṣe tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Privileged Planet, wọ́n sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé apá ibi tá a wà nínú òfuurufú tó lọ salalu nìkan “ni ibi tí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí lè gbé.”

Ṣé nípa èèṣì làwọn ohun abẹ̀mí fi wà lórí ilẹ̀ ayé ni? Àbí ohun kan tó jù bẹ́ẹ̀ lọ wà tó mú káwọn ohun alààyè wà lórí ilẹ̀ ayé wa ẹlẹ́wà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá gbà pé ńṣe lẹnì kan dìídì ṣe ilé ayé lọ́nà tí ohun ẹlẹ́mìí á fi lè máa gbé níbẹ̀.a Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, akéwì kan tó jẹ́ Hébérù wo ayé òun ọ̀run, ó wá kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú?” (Sáàmù 8:3, 4) Akéwì yìí gbà pé Ẹlẹ́dàá kan ní láti wà tó dá àwọn ohun wọ̀nyí. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́ láyé òde òní tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbilẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Sáàmù, pàápàá Sáàmù 8.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Illustrated Science Encyclopedia—Amazing Planet Earth sọ pé “téèyàn bá ń wo ayé láti òkèèrè, ńṣe ló ń tàn yinrin bí ohun ọ̀ṣọ́ aláwọ̀ búlúù tó ń tàn láàárín ibi tó ṣòkùnkùn.”

[Credit Line]

Àwòrán ayé: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́