Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kìíní
Apá kejì àti ìkẹta yóò fara hàn nínú ìtẹ̀jáde September 15 àti October 15.
NÍNÚ ṣọ́ọ̀bù kékeré kan, òǹtẹ̀wé kan pẹ̀lú ọ̀dọ́mọ-kùnrin kan tí ń kọ́ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ jùmọ̀ ń fi ẹ̀rọ onígi kan tẹ̀wé, ní rírọra fi àwọn abala bébà lé ojú ẹ̀rọ náà. Bí wọ́n ti ń fa àwọn ojú ìwé náà yọ, wọ́n ń yẹ̀ wọ́n wò. Wọ́n sá àwọn ojú ìwé tí wọ́n ti ká pa pọ̀ sórí okùn tí wọ́n ta sára ògiri kí wọn baà lè tètè gbẹ.
Lójijì, ẹnì kan kàn bẹ̀rẹ̀ sí í lu ilẹ̀kùn gbàgbàgbà. Ìdágìrì bá wọn, òǹtẹ̀wé náà ṣílẹ̀kùn, agbo ọmọ ogun kan sì rọ́ wọlé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò bófin mu tí a sì ti fòfin dè lọ́nà tí ó lágbára jù lọ—ìwé náà ni Bíbélì ní èdè àwọn gbáàtúù ènìyàn!
Wọ́n ti pẹ́ kí wọ́n tó dé. Lẹ́yìn tí a ti ta wọ́n lólobó nípa ewu náà, olùtumọ̀ náà àti ẹnì kan tí ń ràn án lọ́wọ́ ti sáré lọ sí ṣọ́ọ̀bù náà, wọ́n di ẹrù ìwé séjìká wọn, wọ́n sì ti ń sá gba ọ̀nà Odò Rhine lọ báyìí. Ó kéré tán wọ́n ti dáàbò bo apá díẹ̀ nínú iṣẹ́ wọn.
William Tyndale ni olùtúmọ̀ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí, tí ń gbìyànjú láti tẹ “Májẹ̀mú Tuntun” rẹ̀ tí a fòfin dè lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní Cologne, Germany, ní 1525. Ìrírí rẹ̀ kò ṣàjèjì rárá. Jálẹ̀ ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,900 ọdún láti ìgbà tí a ti parí kíkọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ti fi gbogbo ohun tí wọ́n ní wewu láti túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì pín in kiri. Àwa lónìí ṣì ń jàǹfààní iṣẹ́ wọn. Kí ni wọ́n ṣe? Báwo ni Bíbélì tí ó wà lọ́wọ́ wa lónìí ṣe tẹ̀ wá lọ́wọ́?
Ṣíṣe Àdàkọ Bíbélì àti Títúmọ̀ Rẹ̀ Ní Ìjímìjí
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ti fìgbà gbogbo fojú tí ó ṣe pàtàkì gidigidi wo Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Bíi ti àwọn Júù baba ńlá wọn, àwọn Kristẹni ìjímìjí mọyì kíka Àwọn Ìwé Ọlọ́wọ̀ náà. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù (Mt 4.4; 5.18; Lk 24.44; Jn 5.39), àwọn Àpọ́sítélì gbádùn dídi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú M[ájẹ̀mú] T[untun] ìyẹn ni pé wọ́n ń kà á dáradára fún àkókò gígùn, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wọ́n sì rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn láti ṣe èyí (Rom 15.4; 2 Tim 3.15-17).”
Nítorí ìdí èyí, a ní láti ṣe àwọn ẹ̀dà Bíbélì jáde. Ní àkókò tí ó ṣááju sànmánì Kristẹni, ‘àwọn ọ̀jáfáfá adàwékọ’ tí wọ́n kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ gidigidi ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ yìí, àwọn tí ṣíṣe àṣìṣe máa ń kó jìnnìjìnnì bá. (Ẹ́sírà 7:6, 11, 12, NW) Ní sísakun láti pèsè ìwé tí kò ní àṣìṣe kankan, wọ́n gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga kalẹ̀ fún gbogbo àwọn ada-Bíbélì-kọ tí yóò wá lẹ́yìn wọn.
Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, ìpèníjà kan dìde. Alẹkisáńdà Ńlá fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ayé kọ́ àṣà àwọn Gíríìkì. Ṣíṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èdè Gíríìkì tí ó wọ́pọ̀, tàbí Koine, ni èdè tí wọn yóò máa lò jàkéjádò Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù dàgbà di ẹni ti kò lè ka èdè Hébérù, èyí kò sì jẹ́ kí wọ́n lè ka Ìwé Mímọ́. Nítorí náà, ní nǹkan bíi 280 ṣááju Sànmánì Tiwa, a kó àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ Hébérù jọ sí Alẹkisáńdíríà, Íjíbítì, láti tú Bíbélì Hébérù sí èdè Koine tí ó gbajúmọ̀. Itúmọ̀ wọn di èyí tí a mọ̀ sí Septuagint, èdè Látìn fún “Àádọ́rin,” tí ń tọ́ka sí iye àwọn olùtúmọ̀ tí a fojú díwọ̀n tí a gbà gbọ́ pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú rẹ̀. A parí rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 150 ṣááju Sànmánì Tiwa.
Ní àkókò Jésù, a ṣì ń sọ èdè Hébérù ní Palẹ́sìnì. Síbẹ̀ èdè Koine ni ó wọ́pọ̀ jù lọ níbẹ̀ àti ní àwọn apá ẹkùn ilẹ̀ jíjìnnà réré ti ayé Róòmù. Nítorí náà, àwọn Kristẹni òǹkọ̀wé Bíbélì lo èdè Gíríìkì tí ó wọ́pọ̀ yí láti lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè bí ó ti ṣeé ṣe tó. Bákan náà, wọ́n ṣàyọlò fàlàlà láti inú Septuagint, wọ́n sì lo ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ìjímìjí ti jẹ́ míṣọ́nnárì onítara, kíá ni wọ́n di ọ̀jáfáfá nínú lílo Septuagint láti fẹ̀rí hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà tí a ti ń retí fún ìgbà pípẹ́. Èyí mú inú bí àwọn Júù, ó sì sún wọn láti mú àwọn ìtumọ̀ tuntun kan jáde ní èdè Gíríìkì, tí wọ́n wéwèé láti fi dènà ìjiyàn àwọn Kristẹni nípa yíyí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó ti ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn pa dà. Fún àpẹẹrẹ, ní Aísáyà 7:14 Septuagint lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí ó túmọ̀ sí “wúńdíá,” ní títọ́ka sí ìyá Mèsáyà náà lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀. Àwọn ìtumọ̀ tuntun náà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ó yàtọ̀, tí ó túmọ̀ sí “ọ̀dọ́bìnrin.” Bíbá a lọ tí àwọn Kristẹni ń bá a lọ láti lo Septuagint mú kí àwọn Júù nígbẹ̀yìngbẹ́yín pa ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn dà pátápátá, kí wọ́n sì gbé pípadà sí èdè Hébérù lárugẹ. Ní àbárèbábọ̀, ìgbésẹ̀ yí di ìbùkún fún ìtumọ̀ Bíbélì tí a ṣe lẹ́yìn náà, nítorí pé ó ṣèrànwọ́ láti mú kí iná ìmọ̀ tí ó tó nípa èdè Hébérù máa jó geerege.
Àwọn Kristẹni Tí Ó Kọ́kọ́ Ṣèwé Jáde
Àwọn Kristẹni ìjímìjí onítara bẹ̀rẹ̀ sí í pèsè ọ̀pọ̀ ẹ̀dà Bíbélì bí ó ti lè ṣeé ṣe tó, ọwọ́ sì ni wọ́n fi kọ gbogbo rẹ̀. Wọ́n tún pilẹ̀ lílo ìwé àfọwọ́kọ alábala, tí ó ní ojú ìwé bíi ti àwọn ìwé òde òní, dípò tí wọn yóò fi máa lo àwọn àkájọ ìwé. Yàtọ̀ sí pé ó mú kí títètè wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ rí túbọ̀ rọrùn, ohun tí ìdìpọ̀ ìwé àfọwọ́kọ alábala kan lè gbà ju ohun tí àkájọ ìwé kan lè gbà lọ—fún àpẹẹrẹ, ó lè gba gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tàbí odindi Bíbélì pàápàá.
Àwọn ìwé tí àpọ́sítélì tí ó kú kẹ́yìn, Jòhánù, kọ ni a fi parí àwọn ìwé tí ó para pọ̀ jẹ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Tiwa. Àjákù ẹ̀dà Ìhìn Rere Jòhánù kan ń bẹ, tí a pè ní Òrépèté Rylands 457 (P52), tí a ti kọ láti ọdún 125 Sànmánì Tiwa. Tipẹ́tipẹ́ ní ọdún 150 sí 170 Sànmánì Tiwa, Tatian, akẹ́kọ̀ọ́ Justin Martyr kan, mú Diatessaron jáde, àkọsílẹ̀ alápá púpọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù tí a kó jọ láti inú ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin kan náà tí ó wà nínú Bíbélì tiwa lónìí.a Èyí fi hàn pé kìkì àwọn Ìhìn Rere wọ̀nyẹn ni ó gbà pé ó jóòótọ́, tí wọ́n sì ti wà lọ́wọ́ káàkiri. Ní nǹkan bí ọdún 170 Sànmánì Tiwa, àkọsílẹ̀ pípẹ́ jù lọ tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ti àwọn ìwé “Májẹ̀mú Tuntun,” tí a pè ní Àjákù Muratoria, ni a mú jáde. Ó to ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lẹ́sẹẹsẹ.
Kò pẹ́ tí ìtànkálẹ̀ ìgbàgbọ́ Kristẹni fi béèrè fún àwọn ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì àti ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtumọ̀ ní àwọn èdè bí Armenia, Coptic, Georgian, àti Síríákì ni a ṣe nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Lọ́pọ̀ ìgbà a ní láti hùmọ̀ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì fún ète yẹn nìkan. Fún àpẹẹrẹ, Ulfilas, bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù kan ní ọ̀rúndún kẹrin, ni a gbọ́ pé ó hùmọ̀ álífábẹ́ẹ̀tì Gothic láti túmọ̀ Bíbélì. Ṣùgbọ́n ó fo ìwé Àwọn Ọba nítorí pé ó rò pé wọn yóò fún ẹ̀mí ogun tí àwọn Goth ní níṣìírí. Ṣùgbọ́n, ìgbésẹ̀ yí kò dí àwọn Goth “tí a sọ di Kristẹni” lọ́wọ́ láti piyẹ́ Róòmù ní 410 Sànmánì Tiwa!
Bíbélì Èdè Látìn àti Èdè Slavic
Láàárín àkókò yí, èdè Látìn di gbajúmọ̀, onírúurú ìtumọ̀ èdè Látìn Àtijọ́ sì jẹyọ. Ṣùgbọ́n wọ́n yàtọ̀ síra ní ti ọ̀nà ìkọ̀wé àti ìpéye. Nítorí náà ní ọdún 382 Sànmánì Tiwa, Póòpù Damasus fàṣẹ fún akọ̀wé rẹ̀, Jerome, láti mú Bíbélì Èdè Látìn tí ó lọ́lá àṣẹ jáde.
Jerome bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣàtúnṣe àwọn ìtumọ̀ èdè Látìn ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ṣùgbọ́n, ní ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó rin kinkin mọ́ ọn pé inú Ìwé Mímọ́ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni òun yóò ti túmọ̀ rẹ̀. Nípa báyìí, ní ọdún 386 Sànmánì Tiwa, ó ṣí lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti kọ́ èdè Hébérù àti láti wá ìrànlọ́wọ́ rábì kan. Nítorí èyí, ó dá awuyewuye ńláǹlà sílẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn kan, títí kan Augustine tí ó jẹ́ alájọgbáyé Jerome, gbà gbọ́ pé Septuagint jẹ́ ìwé tí a mí sí, wọ́n sì fẹ̀sùn kan Jerome pé “ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Júù.” Ní títẹ̀síwájú, Jerome parí iṣẹ́ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 400 Sànmánì Tiwa. Nípa sísúnmọ́ orísun èdè àti àkọsílẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti nípa títúmọ̀ wọn sí èdè tí wọ́n ń sọ nígbà náà, Jerome fi ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ọ̀nà ìtumọ̀ ti òde òní. A mọ ìwé rẹ̀ sí Vulgate, tàbí Ìtumọ̀ Wíwọ́pọ̀, ó sì ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Ní Kirisẹ́ńdọ̀mù tí ó wà ní ìlà oòrùn ayé, ọ̀pọ̀ ṣì lè ka Septuagint àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríììkì. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó yá, àwọn ẹ̀yà èdè àti àwọn èdè àdúgbò ti Slavic di èdè tí a ń lò ní àwọn apá ìlà oòrùn Europe. Ní ọdún 863 Sànmánì Tiwa, àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ń sọ èdè Gíríìkì, Cyril àti Methodius, lọ sí Moravia, tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech nísinsìnyí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Bíbélì sí èdè Slavic Àtijọ́. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n hùmọ̀ álífábẹ́ẹ̀tì Glagolitic, tí àlífábẹ́ẹ̀tì Cyrillic, tí a fi orúkọ Cyril pè, wá gbapò lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Èyí ni orísun àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala ti èdè Russian, Ukrainian, Serbian, àti Bulgarian ti òde òní. Bíbélì èdè Slavic ni àwọn ènìyàn àgbègbè náà lò fún ọ̀pọ̀ ìran. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, tí èdè sì ń yí pa dà, ó di ohun tí ẹnì kan tí kò kàwé púpọ̀ kò lè lóye mọ́.
Bíbélì Èdè Hébérù Là Á Já
Láàárín àkókò yí, láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹfà sí ọ̀rúndún kẹwàá Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn Júù kan tí a mọ̀ sí àwọn Masorete hùmọ̀ ọ̀nà àdàkọ kan láti pa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù mọ́. Wọ́n lọ jìnnà débi kíka gbogbo ìlà àti lẹ́tà kọ̀ọ̀kan pàápàá, ní kíkíyèsí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìsapá láti pa ìwé kan tí ó ṣeé gbára lé mọ́. Ìsapá wọn kò já sí asán. Láti fi àpẹẹrẹ kan hàn, nígbà tí a fi àwọn ìwé Masorete òde òní wéra pẹ̀lú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, tí a kọ láàárín ọdún 250 ṣáaju Sànmánì Tiwa àti 50 Sànmánì Tiwa, ní èyí tí ó lé ní 1,000 ọdún, kò sí ìyàtọ̀ kankan ní ti ẹ̀kọ́ ìsìn.b
Ní Europe, ní gbogbogbòò kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ kankan láàárín Sànmánì Agbedeméjì àti Sànmánì Ojú Dúdú. Mímọ̀wéékọ àti mímọ̀wéékà kéré púpọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àlùfáà pàápàá kò lè ka èdè Látìn ti ṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀pọ̀ nínú wọn kò sì lè ka èdè àbínibí wọn pàápàá. Àkókò yí kan náà ni ìgbà tí a kó àwọn Júù lọ sí àdádó ní Europe. Lápá kan, nítorí tí wọ́n wà ní àdádó yí, a pa ẹ̀kọ́ èdè Hébérù ti Bíbélì mọ́. Ṣùgbọ́n, nítorí ẹ̀tanú àti àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ènìyàn, àwọn Júù kò jẹ́ ṣàjọpín ìmọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn tí kì í gbé ní àdádó náà. Ní ìwọ̀ oòrùn Europe, ìmọ̀ èdè Gíríìkì tún ń lọ sílẹ̀. Bíbọlá tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ìwọ̀ Oòrùn bọlá fún Bíbélì Vulgate Lédè Látìn tí Jerome ṣe, túbọ̀ dá kún ìṣòro náà. Ní gbogbogbòò, a kà á sí ìtumọ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ọlá àṣẹ, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí sáà àwọn Masorete yóò fi parí, èdè Látìn ti ń di òkú èdè. Nípa báyìí, bí ìfẹ́ ọkàn láti lóye Bíbélì ṣe ń dàgbà díẹ̀ díẹ̀, ọ̀nà ìforígbárí ńláǹlà ti wá ń là wàyí.
Ìtumọ̀ Bíbélì Kojú Àtakò
Ní ọdún 1079, Póòpù Gregory Keje gbé àkọ́kọ́ nínú àwọn òfin ṣọ́ọ̀ṣì nígbà sànmánì agbedeméjì jáde, ní fífòfinde mímú àwọn ìtumọ̀ ti èdè ìbílẹ̀ jáde tàbí nígbà míràn níní wọn lọ́wọ́ pàápàá. Ó fagi le ìyọ̀ǹda láti ṣe ààtò ìsìn Máàsì ní èdè Slavic lórí ìpìlẹ̀ pé yóò béèrè pé kí a tú àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́. Ní ìtakora pátápátá sí ipò tí àwọn Kristẹni ìjímìjí dì mú, ó kọ̀wé pé: “Ó dùn mọ́ Ọlọ́run Olódùmarè nínú pé ìwé mímọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun àṣírí ní àwọn ibì kan.” Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ ipò àfàṣẹtìlẹ́yìn tí ṣọ́ọ̀ṣì wà, a ka àwọn tí ń ṣagbátẹrù kíka Bíbélì sí àwọn tí wọ́n léwu gidigidi.
Láìka àyíká ipò tí kò bára dé sí, ṣíṣe àdakọ àti títúmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè tí ó wọ́pọ̀ ń bá a lọ. A pín àwọn ìtumọ̀ ní ọ̀pọ̀ èdè káàkiri ní bòókẹ́lẹ́ ní Europe. Ọwọ́ ni a fi ṣe àdàkọ gbogbo ìwọ̀nyí, níwọ̀n bí a kò ti hùmọ̀ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò ní Europe títí di àárín àwọn ọdún 1400. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn ẹ̀dà ti gbówó lórí, tí wọn kò sì pọ̀, inú ẹni tí kò rí já jẹ yóò dùn jọjọ tí ó bá lè ní apá kan ìwé Bíbélì tàbí ojú ìwé díẹ̀. Ọ̀pọ̀ há apá púpọ̀ sórí, àní gbogbo Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pàápàá!
Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, akitiyan láti mú àtúnṣe bá ṣọ́ọ̀ṣì ń gbilẹ̀. Lápá kan, àwọn wọ̀nyí ni a ru sókè nítorí òye tí wọ́n pa dà ní nípa ìjẹ́pàtàkì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Báwo ni àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí àti ìdásílẹ̀ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ṣe nípa lórí Bíbélì? Kí sì ni ó ṣẹlẹ̀ sí William Tyndale àti ìtumọ̀ rẹ̀, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀? A óò tọ ìtàn fífani mọ́ra yìí dé àkókò tiwa nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ń bọ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde jẹ́ àpẹẹrẹ òde òní ti ìṣọ̀kan tí ó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
b Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 315, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn Ọjọ́ Pàtàkì Nínú Títàtaré Bíbeĺlì
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ṢÁÁJU SÀNMÁNÌ TIWA (B.C.E.)
Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù parí ní nǹkan bí 443 B.C.E.
400 B.C.E.
Alẹkisáńdà Ńlá (ní 323 B.C.E.)
300 B.C.E.
Ìtumọ̀ Septuagint Bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí 280 B.C.E.
200 B.C.E.
100 B.C.E. Ọ̀pọ̀ Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ní nǹkan bí 100 B.C.E. sí 68 C.E.
SÀNMÁNÌ TIWA (C.E.)
A pa Jerúsálẹ́mù run ní 70 C.E.
A parí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ní 98 C.E.
100 C.E.
Òrépèté Rylands ti Jòhánù (ṣáájú 125 C.E.)
200 C.E.
300 C.E.
Ìtumọ̀ Vulgate ti Jerome Lédè Látìn ní nǹkan bí 400 C.E.
400 C.E.
500 C.E.
600 C.E.
A Kọ Ìwé Àwọn Masorete
700 C.E.
800 C.E.
Cyril ní Moravia ní 863 C.E.
900 C.E.
1000 C.E.
A ṣòfin lòdì sí Bíbélì èdè ìbílẹ̀ ní 1079 C.E.
1100 C.E.
1200 C.E.
1300 C.E.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Kristẹni ìjímìjí ni ó kọ́kọ́ lo ìwé àfọwọ́kọ alábala
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jerome lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti kọ́ èdè Hébérù