Jerome—Òléwájú Tí Ọ̀ràn Rẹ̀ Ń Fa Àríyànjiyàn Nínú Ìtumọ̀ Bíbélì
NÍ April 8, 1546, Àpérò Trent pàṣẹ pé Bíbélì Vulgate ti èdè Látìn “ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fọwọ́ sí, . . . kí ẹnì kankan má sì dá a láṣà tàbí dágbá lé àtifọwọ́ rọ́ ọ tì, fún ìdí èyíkéyìí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún tí iṣẹ́ ti parí lórí rẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì Vulgate àti Jerome, olùtúmọ̀ rẹ̀, ti di ohun tí a ń jiyàn lé lórí. Ta ni Jerome? Èé ṣe tí òun àti Bíbélì tó túmọ̀ fi ń fa àríyànjiyàn? Ipa wo ni iṣẹ́ rẹ̀ ní lórí ìtumọ̀ Bíbélì lóde òní?
Bó Ṣe Di Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀
Eusebius Hieronymus lorúkọ Jerome lédè Látìn. A bí i ní nǹkan bí ọdún 346 Sànmánì Tiwa ní Stridon, ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù tí a ń pè ní Dalmatia, nítòsí ààlà tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Ítálì àti Slovenia ní báyìí.a Bọ̀rọ̀kìnní làwọn òbí ẹ̀, ó sì rówó fi lògbà ní àárọ̀ ọjọ́, ó kàwé ní Róòmù lọ́dọ̀ Donatus, gbajúmọ̀ onímọ̀ gírámà. Jerome jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó lẹ́bùn gírámà, ọ̀rọ̀ sísọ, àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí. Àkókò yìí náà ló bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Gíríìkì.
Lẹ́yìn tí Jerome fi Róòmù sílẹ̀ lọ́dún 366 Sànmánì Tiwa, ó rìn káàkiri, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó wá fìdí tì sí Aquileia, Ítálì, níbi tí wọ́n ti fojú ẹ̀ mọ èròǹgbà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Èròǹgbà nípa ìsẹ́ra ẹni pátápátá wọ̀ ọ́ lọ́kàn, fún ìdí yìí, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan kóra jọ, wọ́n sì lo ọdún tó pọ̀ díẹ̀ láti fi gbé ìgbé-ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́.
Lọ́dún 373 Sànmánì Tiwa, wàhálà kan tí a ò mọ̀dí ẹ̀, tú ẹgbẹ́ yìí ká. Ìjákulẹ̀ dé bá Jerome, ó gbọ̀nà ìlà oòrùn ní ìsọdá Bítíníà, Gálátíà, àti Sìlíṣíà, ó sì dé Áńtíókù ti Síríà nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.
Ìrìn jíjìn náà fàbọ̀ sí i lára. Jerome kò ní ìmí nínú mọ́, ara rẹ̀ kò le, díẹ̀ ló sì kù kí ibà gbẹ̀mí ẹ̀. Ó kọ̀wé sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, pé: “Óò, inú mi ì bá dùn ká ṣe pé Jésù Kristi Olúwa gbé mi páá, dé ọ̀dọ̀ rẹ. Èmi jáńjálá, tó jẹ́ pé nígbà tí n kò ṣàìsàn gan-an n kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, mo ti wá di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.”
Àfi bí ẹni pé àìsàn, ìdánìkanwà, ìdààmú ọkàn kò tó, ni Jerome bá tún dojú kọ ìṣòro mìíràn—ìṣòro tẹ̀mí. Nínú àlá, ó rí i “tí a wọ́ òun wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́” Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n ní kó sọ ẹni tí òun í ṣe, Jerome fèsì pé: “Kristẹni ni mí.” Ṣùgbọ́n alága fìbínú dá a lóhùn pé: “Ìwọ òpùrọ́ yìí, ọmọlẹ́yìn Cicero ni ẹ́, o kì í ṣe ọmọlẹ́yìn Kristi.”
Títí di ìgbà yẹn, Jerome kò nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn kèfèrí ló nífẹ̀ẹ́ sí. Ó sọ pé: “Iná ẹ̀rí ọkàn dá mi lóró.” Nínú ìrètí àtiṣe àtúnṣe, Jerome jẹ́jẹ̀ẹ́ lójú àlá pé: “Olúwa, bí mo bá tún ní ìwé ayé lọ́wọ́ pẹ́nrẹ́n, tàbí bí mo bá tún kà á pẹ́nrẹ́n, á jẹ́ pé mo ti sẹ́ Ọ.”
Lẹ́yìn ìgbà náà, Jerome sọ pé kò sẹ́ni tó lè mú òun tìtorí ẹ̀jẹ́ tóun jẹ́ lójú àlá. Síbẹ̀, ó pinnu láti mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ—ì báà tiẹ̀ jẹ́ lóréfèé. Nítorí náà, Jerome fi Áńtíókù sílẹ̀, ó wá ibi àdádó lọ sí Chalics ní aṣálẹ̀ Síríà. Bó ti ń gbé gẹ́gẹ́ bí ayẹrafẹ́gbẹ́, ó fara jin ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìwé nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn. Jerome sọ pé: “Ìtara tí mo fi ka àwọn ìwé Ọlọ́run pọ̀ ju ìtara ti tẹ́lẹ̀ tí mo fi ka àwọn ìwé èèyàn.” Ó tún kọ́ èdè Síríákì tí wọ́n ń sọ ládùúgbò yẹn, Júù kan tó ti di Kristẹni sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lédè Hébérù.
Iṣẹ́ Tí Póòpù Gbé fún Un
Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún márùn-ún tí Jerome fi dá gbé, ó padà sí Áńtíókù láti máa bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, ìgbà tó dé, ó rí i pé ìjọ ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ní tòótọ́, nígbà tí Jerome ṣì wà ní aṣálẹ̀, ó sọ fún Póòpù Damasus pé kó gba òun nímọ̀ràn, ó ní: “Ìjọ ti pín sọ́nà mẹ́ta, ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan sì ń wá bí wọ́n ṣe máa sọ mí di mẹ́ńbà.”
Nígbà tó yá, Jerome pinnu láti dara pọ̀ mọ́ Paulinus, ọ̀kan lára àwọn èèyàn mẹ́ta tó sọ ara wọn di bíṣọ́ọ̀bù Áńtíókù. Jerome lóun máa gbà pé kí Paulinus sọ òun di òjíṣẹ́ bí ó bá gba kókó méjì tóun fẹ́ là kalẹ̀. Èkíní, ó fẹ́ kí wọ́n fòun lọ́rùn sílẹ̀, kí òun lè ráyè lépa àwọn góńgó òun láti máa dá gbé. Àti èkejì, ó ranrí pé òun ò ní tẹ̀ lé òfin kankan tó bá sọ pé inú ìjọ kan pàtó ni kí àlùfáà ti máa ṣèsìn.
Lọ́dún 381 Sànmánì Tiwa, Jerome bá Paulinus lọ sí Àpérò Constantinople, lẹ́yìn náà ó tún bá a dé Róòmù. Kíá ni Póòpù Damasus rí i pé ọlọ́pọlọ pípé àti ògbóǹtagí onímọ̀ èdè ni Jerome. Láàárín ọdún kan, wọ́n ti gbé Jerome ga di akọ̀wé fún Damasus.
Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé, Jerome kò sá fún àríyànjiyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló dà bíi pé ó máa ń dá a sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó ń bá a lọ ní gbígbé ìgbé-ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ nínú àgbàlá póòpù tó kún fún fàájì. Ní àfikún, nípa ṣíṣe alágbàwí ìgbé-ayé ìpọ́nra-ẹni-lójú àti nípa fífọ̀rọ̀ gún àwọn àlùfáà tí ẹ̀mí ayé tiwọn tún yọyẹ́, Jerome sọ ara rẹ̀ dọ̀tá ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Ṣùgbọ́n o, láìka ohun táwọn ẹlẹ́gàn ń sọ nípa Jerome sí, gbágbáágbá ni Póòpù Damasus wà lẹ́yìn rẹ̀. Póòpù ní ìdí gúnmọ́ láti fún Jerome ní ìṣírí láti máa ṣe iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ nípa Bíbélì nìṣó. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ ẹ̀dà Bíbélì ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó lédè Látìn. Púpọ̀ wọn ló jẹ́ pé àjàǹbàkù ni ohun tí wọ́n tú sínú wọn, àṣìṣe rẹpẹtẹ tó hàn gbangba wà nínú wọn. Ohun mìíràn tí ń kó ìdààmú bá Damasus ni pé èdè ti bẹ̀rẹ̀ sí pín àgbègbè Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwọ̀nba làwọn tó gbọ́ èdè Látìn ní Ìlà Oòrùn; àwọn tó sì gbọ́ èdè Gíríìkì ní Ìwọ̀ Oòrùn kò tó nǹkan.
Fún ìdí yìí, Póòpù Damasus ń wọ̀nà lójú méjèèjì fún ṣíṣe àtúnṣe sí ìtumọ̀ Ìhìn Rere lédè Látìn. Damasus fẹ́ ìtumọ̀ tí yóò gbé èrò Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ yọ lọ́nà pípéye, síbẹ̀ tí yóò já gaara, tí yóò sì ṣe kedere ní èdè Látìn. Jerome jẹ́ ọ̀kan lára ìwọ̀nba àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ díẹ̀ tó lè ṣe irú ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó tóótun gidigidi fún iṣẹ́ náà, nítorí pé ó gbọ́ èdè Gíríìkì, Látìn, àti èdè Síríákì dáadáa, kò sì kẹ̀rẹ̀ nínú èdè Hébérù. Nítorí náà, pẹ̀lú àṣẹ Damasus, Jerome bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí yóò gbà ju ogún ọdún nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
Àríyànjiyàn Náà Gbóná Janjan
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Jerome yá gan-an lẹ́nu iṣẹ́ títú Ìhìn Rere, iṣẹ́ tó ṣe dáńgájíá, ó pegedé. Ó ṣe ìfiwéra gbogbo ìwé àfọwọ́kọ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà yẹn lédè Gíríìkì, ó ṣe àtúnṣe ẹ̀dà ti Látìn, àtúnṣe tó jẹ mọ́ ọ̀nà ìkọ̀wé àti kókó ọ̀rọ̀, kí ó bàa lè sún mọ́ ẹ̀dà ti èdè Gíríìkì pẹ́kípẹ́kí.
Àwọn èèyàn lápapọ̀ fayọ̀ gba ìtumọ̀ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Jerome ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n fayọ̀ gba àtúnṣe tó ṣe sí ìwé Sáàmù lédè Látìn, èyí tó gbé ka ẹ̀dà Septuagint lédè Gíríìkì. Síbẹ̀, kò ṣàìní alátakò. Jerome kọ̀wé pé: “Àwọn ẹ̀dá játijàti kan mọ̀ọ́mọ̀ ń gbógun tì mí pẹ̀lú ẹ̀sùn náà pé mo ti fagídí ṣàtúnṣe àwọn ibì kan nínú ìhìn rere, pé èyí lòdì sí ọlá àṣẹ àwọn amòye ìgbàanì àti èrò gbogbo ayé.” Irú ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn bẹ́ẹ̀ wá légbá kan lẹ́yìn ikú Póòpù Damasus lọ́dún 384 Sànmánì Tiwa. Níwọ̀n bí àjọṣe Jerome àti póòpù tuntun kò ti dán mọ́rán, ó pinnu láti fi Róòmù sílẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jerome forí lé ìlà oòrùn.
Bó Ṣe Di Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Nínú Èdè Hébérù
Lọ́dún 386 Sànmánì Tiwa, Jerome ti fìdí kalẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ibi tí yóò ti lo ìyókù ayé ẹ̀. Àwùjọ kékeré kan, àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn, tẹ̀ lé e, lára wọn sì ni Paula, ọ̀tọ̀kùlú obìnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Róòmù. Paula ti tẹ́wọ́ gba ìgbé-ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ nítorí ìwàásù Jerome. Pẹ̀lú owó tí obìnrin yìí fi ṣètìlẹyìn, wọ́n dá ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé sílẹ̀ lábẹ́ ìdarí Jerome. Ibẹ̀ ló ti tẹra mọ́ iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ń ṣe, ibẹ̀ ló sì ti parí iṣẹ́ tó ga jù lọ tó ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
Gbígbé ní Palẹ́sínì fún Jerome ní àǹfààní láti túbọ̀ gbọ́ èdè Hébérù dáadáa. Ó sanwó fún àwọn olùkọ́ Júù mélòó kan, kí wọ́n lè là á lóye àwọn apá kan tó le nínú èdè náà. Ṣùgbọ́n o, èdè ọ̀hún le fún olùkọ́ tó fẹ́ fi kọ́ni pàápàá. Jerome sọ nípa olùkọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baraninas ará Tìbéríà, pé: “Wàhálà tí mo ṣe àti owó tí mo ná pọ̀ gan-an, kí Baraninas lè kọ́ mi lóru.” Kí ló dé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lóru? Nítorí pé ẹ̀rù ń ba Baraninas nípa ohun tí àwọn Júù máa sọ nípa bíbá tí òun ń bá “Kristẹni” kan rìn!
Lọ́jọ́ Jerome, àwọn Júù sábà máa ń fi àwọn Kèfèrí tí ń sọ èdè Hébérù ṣe yẹ̀yẹ́, nítorí pé wọn kì í lè pe àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń fi àfàsé pè. Síbẹ̀, lẹ́yìn ìsapá púpọ̀, Jerome mọ̀ ọ́n pè. Jerome pẹ̀lú gbé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù wá sínú Látìn. Ìgbésẹ̀ yìí ràn án lọ́wọ́ láti rántí ọ̀rọ̀ wọnnì, ìyẹn nìkan kọ́, kò tún jẹ́ kí bí a ti ń pè wọ́n lédè Hébérù nígbà yẹn parẹ́.
Àríyànjiyàn Jerome Tó Ga Jù Lọ
A ò mọ bí àwọn apá Bíbélì tí Póòpù Damasus fẹ́ kí Jerome tú ti pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyèméjì ní ti ọwọ́ tí Jerome fi mú ọ̀ràn náà. Jerome pọkànpọ̀ pátápátá, kò sì mikàn. Ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí ẹ̀ ni láti mú ohun kan jáde “tí yóò wúlò fún Ṣọ́ọ̀ṣì, tí yóò jọ ìran ọjọ́ ọ̀la lójú.” Nípa báyìí, ó pinnu láti mú àtúnṣe ìtumọ̀ òdindi Bíbélì lédè Látìn jáde.
Ní ti Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, Jerome pète àtigbé iṣẹ́ rẹ̀ ka Septuagint. Ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù yìí tí a tú sí Gíríìkì, tí a kọ́kọ́ tú ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbà pé Ọlọ́run mí sí ní tààràtà. Fún ìdí yìí, Septuagint ní ìpínkiri tó pọ̀ láàárín àwọn Kristẹni tí ń sọ èdè Gíríìkì nígbà yẹn.
Ṣùgbọ́n o, bí Jerome ti ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó rí i pé irú àìbáramu tí òun bá pàdé nínú èdè Látìn pọ̀ láàárín àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Gíríìkì. Nǹkan wá túbọ̀ ń dojú rú fún Jerome. Níkẹyìn, ó dé ìparí èrò náà pé, láti lè mú ìtumọ̀ tó ṣeé gbára lé jáde, òun gbọ́dọ̀ pa àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Gíríìkì tì, títí kan Septuagint tí àwọn èèyàn ń gbé gẹ̀gẹ̀, kí òun sì lọ tààrà sínú ẹ̀dà ti Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Ìpinnu yẹn fa arukutu. Àwọn kan sọ pé ṣe ni Jerome ń ṣàríwísí Ìwé Mímọ́, wọ́n ló tàbùkù Ọlọ́run, wọ́n ló pa àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tì, nítorí àwọn Júù. Augustine pàápàá—òléwájú onímọ̀ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ìgbà yẹn—rọ Jerome pé kó padà lọ lo ẹ̀dà Septuagint, ó ní: “Bí gbogbo èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí ka ìtumọ̀ rẹ nínú ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, yóò mà burú o, pé kíka Ìwé Mímọ́ yóò dá ọ̀pọ̀ ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn Ìjọ tí ń sọ èdè Látìn àti àwọn Ìjọ tí ń sọ èdè Gíríìkì.”
Bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀rù Augustine ni pé ṣọ́ọ̀ṣì lè pín bí àwọn ìjọ Ìwọ̀ Oòrùn bá ń lo Bíbélì èdè Látìn tí Jerome tú—tó tú tààrà láti inú ti èdè Hébérù—nígbà tí àwọn ìjọ Ìlà Oòrùn, tí ń sọ èdè Gíríìkì, ṣì ń lo ẹ̀dà ti Septuagint.b Kò tán síbẹ̀ o, Augustine tún sọ pé báa bá tìtorí ìtumọ̀ kan tó jẹ́ pé Jerome nìkan ló lè gbèjà rẹ̀ pa Septuagint tì, yóò dá wàhálà sílẹ̀ o.
Báwo ni Jerome ṣe hùwà padà sí gbogbo àwọn alátakò wọ̀nyí? Gẹ́gẹ́ bí ìwà Jerome, kò tiẹ̀ dá wọn lóhùn. Ó ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ ràì láti inú èdè Hébérù tààrà, nígbà tó sì máa fi di ọdún 405 Sànmánì Tiwa, ó ti parí Bíbélì rẹ̀ lédè Látìn. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n pe ìtumọ̀ rẹ̀ ní Vulgate, tó túmọ̀ sí ẹ̀dà tí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gbà (ọ̀rọ̀ Látìn náà, vulgatus túmọ̀ sí “ti gbogbo gbòò, èyí tó gbajúmọ̀”).
Àwọn Àṣeyọrí Wíwà Pẹ́ Títí
Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí Jerome tú kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe àtúnṣe ẹ̀dà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Fún àwọn ìran ẹ̀yìn ìgbà náà, ó pa ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìtumọ̀ Bíbélì dà. Òpìtàn náà, Will Durant, sọ pé: “Ìtumọ̀ Vulgate ṣì ni ìwé tó dára jù lọ, tó sì gbayì jù lọ ní ọ̀rúndún kẹrin.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu Jerome mú bérébéré, tó sì fẹ́ràn àtimáa jiyàn púpọ̀, òun ló nìkan dá iṣẹ́ ìwádìí nípa Bíbélì padà tààrà sí Ìwé Mímọ́ Hébérù tí ó ní ìmísí. Pẹ̀lú ojú tó ríran dáadáa, ó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì lédè Hébérù àti ti Gíríìkì ìgbàanì tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó wa lónìí. Iṣẹ́ rẹ̀ tún ṣáájú ti àwọn Másórétì tí í ṣe Júù. Nítorí náà, Vulgate jẹ́ ìwé ṣíṣeyebíye fún ṣíṣe ìfiwéra àwọn ọ̀nà mìíràn táa lè gbà tú àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì.
Bí àwọn olùfẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò tilẹ̀ fara mọ́ ìwà àṣejù rẹ̀ àti ojú ìwòye tó ní nípa ẹ̀sìn, síbẹ̀ wọ́n lè mọrírì iṣẹ́ taakuntaakun òléwájú yìí, tí ọ̀ràn rẹ̀ ń fa àríyànjiyàn nínú ìtumọ̀ Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jerome lé góńgó rẹ̀ bá—ó mú ohun kan jáde tó “jọ ìran ọjọ́ ọ̀la lójú.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe gbogbo òpìtàn ló fara mọ́ àwọn déètì àti bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra nínú ìgbésí ayé Jerome.
b Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, ìtumọ̀ tí Jerome ṣe ló wá di Bíbélì pàtàkì fún apá Ìwọ̀ Oòrùn Kirisẹ́ńdọ̀mù, nígbà tó jẹ́ pé wọ́n ń lo Septuagint nìṣó ní apá Ìlà Oòrùn Kirisẹ́ńdọ̀mù títí dòní olónìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ère Jerome ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Òkè lápá òsì, ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù: Lọ́lá àṣẹ Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem; Ìsàlẹ̀ lápá òsì, ìwé àfọwọ́kọ lédè Síríákì: A tún un gbé jáde nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda olójú àánú ti The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin; Òkè láàárín, ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì: Lọ́lá àṣẹ Israel Antiquities Authority