ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/1 ojú ìwé 24-27
  • Mo Rí Ohun Tó Sàn Ju Wúrà Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Rí Ohun Tó Sàn Ju Wúrà Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Sọnù sí Amẹ́ríkà
  • Mo Bá Àwọn Ọmọ Ìyá Mi Pàdé
  • Níní Ìdílé àti Sísin Òkú
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
  • Ṣíṣàwárí Ibi Tí A Ti Bí Mi
  • Fífi Òtítọ́ Sípò Àkọ́kọ́
  • Láti Ìgbà Èwa Wa ni A ti Rántí Ẹlẹ̀dàá Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/1 ojú ìwé 24-27

Mo Rí Ohun Tó Sàn Ju Wúrà Lọ

GẸ́GẸ́ BÍ CHARLES MYLTON ṢE SỌ Ọ́

Lọ́jọ́ kan, baba mi wí pé: “A ò ṣe rán Charlie lọ sí Amẹ́ríkà, níbi igi gbé ń so owó. Ọwọ́ ẹ̀ lè tẹ díẹ̀ níbẹ̀, kó sì fi ránṣẹ́ sí wa!”

ÀWỌN ènìyàn máa ń rò pé níbi tówó pọ̀ dé ní Amẹ́ríkà, wúrà ni wọ́n fi ń ṣe títì. Nígbà wọ̀nyẹn, ayé le gan-an fún àwọn ará ìlà oòrùn Yúróòpù. Àwọn òbí mi ní oko kékeré kan, wọ́n sì ń sin màlúù díẹ̀ àti adìyẹ mélòó kan. Kò sí iná mànàmáná tàbí omi ẹ̀rọ nílé wa. Àmọ́ nígbà náà, kò sí ẹni tó ní wọn nílé nítòsí wa rárá.

A bí mi ní Hoszowczyk ní January 1, 1893, ní nǹkan bí 106 ọdún sẹ́yìn. Abúlé wa wà ní Galicia, ẹkùn ìpínlẹ̀ kan ní ilẹ̀ ọba Austria òun Hungary. Ní báyìí, Hoszowczyk ti wà ní ìhà ìlà oòrùn Poland tí kò jìn sí Slovakia àti Ukraine. Ìgbà òtútù máa ń tutù jù níbẹ̀, yìnyín sì máa ń pọ̀ gan-an. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méje, mo máa ń rin nǹkan bí ìdajì kìlómítà lọ síbi tí omi òkun díẹ̀ ti ya wọ ilẹ̀, mo sì máa ń fi àáké gbẹ́ ihò nínú yìnyín kí n lè rómi pọn. N ó pọn ọ́n relé, màmá mi yóò sì fi gbọ́únjẹ, yóò tún fi fọ nǹkan. Ibi tí omi òkun díẹ̀ ti ya wọ ilẹ̀ yẹn ni màmá mi ti máa ń fọ aṣọ lórí àwọn ègé yìnyín títóbi náà.

Kò sí ilé ìwé ní Hoszowczyk, ṣùgbọ́n mo kọ́ èdè Polish, Russian, Slovak, àti Ukrainian. Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì la ti tọ́ wa dàgbà, mo sì ṣe ọmọ ìdí pẹpẹ níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tí mo tilẹ̀ jẹ́ ọmọdé pàápàá, inú ń bí mi sí àwọn àlùfáà tí wọ́n sọ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran lọ́jọ́ Friday, àmọ́ tí àwọn alára ń jẹ ẹ́.

Àwọn ọ̀rẹ́ wa mélòó kan padà dé láti ibi iṣẹ́ wọn ní United States, wọ́n sì kówó bọ̀ láti fi tún ilé wọn ṣe, kí wọ́n sì ra àwọn èlò iṣẹ́ oko. Èyí ló mú kí baba mi sọ pé kí àwọn rán mi lọ sí Amẹ́ríkà, kí n bá àwọn aládùúgbò díẹ̀ tí wọ́n fẹ́ lọ síbẹ̀ lọ. Ìyẹn jẹ́ ní ọdún 1907 tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 14.

Mo Sọnù sí Amẹ́ríkà

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo ti wà nínú ọkọ̀ ojú omi, láàárín ọ̀sẹ̀ méjì, a sì ti sọdá Àtìláńtíìkì. Ogún dọ́là lẹnì kan gbọ́dọ̀ ní nígbà yẹn kó tó lè wọ Amẹ́ríkà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn á dá a padà sílé. Mo ní ẹyọwó bàbà ológún dọ́là kan, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tó gba Erékùṣù Ellis, New York, wọ Amẹ́ríkà. Bó ti wù kó rí, owó ò so lórí igi, kò sì sí títí tí wọ́n fi wúrà ṣe níbẹ. Ní gidi, ọ̀pọ̀ títì ni wọn kò da ọ̀dà sí rárá!

A wọkọ̀ ojú irin kan lọ sí Johnstown, Pennsylvania. Àwọn tí a jọ lọ ti débẹ̀ rí, wọ́n sì mọ ilé ìbùwọ̀ kan, tí ń pèsè oúnjẹ fúnni, tí mo lè máa gbé. A ṣe èyí kí n lè rí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tí ń gbé Jerome, Pennsylvania, tí mo wá mọ̀ níkẹyìn pé kìlómítà 25 péré ni síbi tí mo wà. Àmọ́ dípò kí n pe Jerome, Yarome ni mo ń pè, nítorí pé, bí ẹni ń pe “Y” la ń pe “J” nínú èdè ìbílẹ̀ mi. Kò sẹ́ni tó mọ ibi tí ń jẹ́ Yarome, nítorí náà, bí mo ṣe wà nílùú onílùú nìyẹn, láìlè sọ Gẹ̀ẹ́sì, láìsì lówó lọ́wọ́.

Àràárọ̀ ni mo ń wáṣẹ́ kiri. Nílé ìgbanisíṣẹ́, ẹni méjì tàbí mẹ́ta péré ló ń ríṣẹ́ nínú àìmọye èrò tí ń tò síta. Nítorí náà, mo ń padà sílé ìbùwọ̀ mi lójoojúmọ́, mo sì ń kọ́ Gẹ̀ẹ́sì nípa dídá ka àwọn ìwé akọ́mọlédè Gẹ̀ẹ́sì mélòó kan. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ń rí àwọn iṣẹ́ àìròtẹ́lẹ̀ ṣe, àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, owó ọwọ́ mi ń tán lọ.

Mo Bá Àwọn Ọmọ Ìyá Mi Pàdé

Lọ́jọ́ kan, mo gba òtẹ́ẹ̀lì kan tó ní ibi ìtọtí lẹ́bàá ibùdókọ̀ ojú irin kọjá. Òórùn oúnjẹ ibẹ̀ gbámúṣé! Bí ẹnì kan bá ra ọtí bíà tó kún ife ńlá, tí wọ́n ń tà ní sẹ́ǹtì márùn-ún, wọn yóò fi àwọn ìpápánu, ẹran àfihábúrẹ́dì, àti àwọn nǹkan mìíràn tó wà níbi ìtọtí náà ṣèènì fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí mi kéré sí ti ẹni tó lè ra ọtí mu, àánú mi ṣe ẹni tí ń ta ọtí náà, ó sì ta bíà fún mi.

Bí mo ti ń jẹun lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan wọlé, wọ́n ní: “Ṣe kíá kóo mu ohun tóo fẹ́ mu! Ọkọ ojú irin tí ń lọ sí Jerome ti ń bọ̀.”

Mo ní: “Ṣe ọkọ̀ tí ń lọ sí Yarome?”

Wọ́n ní: “Rárá, Jerome.” Ìgbà yẹn ni mo mọ ibi tí ẹ̀gbọ́n mi ń gbé. Ní gidi, mo bá ọkùnrin kan tí ń gbé ojúlé kẹta sí ibi tí ẹ̀gbọ́n mi wà pàdé nílé ìtọtí yẹn gan-an! Nítorí náà, mo sanwó ọkọ̀, mo sì rí ẹ̀gbọ́n mi nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ ní ilé ìbùwọ̀ kan, tí ń pèsè oúnjẹ fúnni, tí wọ́n ń gba àwọn tí ń wa kùsà èédú sí, mo sì ń bá wọn gbé. Wọ́n bá mi wá iṣẹ́ ṣíṣọ́ ọ̀pá ẹ̀rọ omi tí ń da omi nù láti ibi ìwakùsà. Nígbàkigbà tó bá daṣẹ́ sílẹ̀, n ó pe mẹkáníìkì kan. Mo ń gba sẹ́ǹtì 15 lójúmọ́. Lẹ́yìn náà, mo ṣiṣẹ́ líla ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin, mo ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ bíríkì kan, kódà, mo ṣe aṣojú ilé iṣẹ́ ìbánigbófò pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, mo kó lọ sí Pittsburgh lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, Steve. A jọ ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ irin kan. Owó tí mo ń pa kò tó èyí tí mo lè rí fi ránṣẹ́ nínú rẹ̀ sílé rí.

Níní Ìdílé àti Sísin Òkú

Bí mo ṣe ń lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ kan, mo rí ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọ̀dọ̀ kan tó dúró síwájú ilé tó ti ń ṣiṣẹ́. Mo rò nínú ara mi pé, ‘Ọmọbìnrin yìí mà dára ò!’ Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní 1917, èmi àti Helen ṣègbéyàwó. Láàárín ọdún mẹ́wàá to tẹ̀ lé e, a bí ọmọ mẹ́fà, ọ̀kan nínú wọn sì kú ní kékeré.

Ní 1918, ilé iṣẹ́ Rélùwéè Pittsburgh gbà mí bí awakọ̀ ojú irin tí ń kérò nígboro. Ilé ìtakọfí kan wà nítòsí ilé ìgbọ́kọ̀sí náà. Àwọn ọkùnrin Gíríìkì méjì tó ni ibẹ̀ kò bìkítà bóyá o rajà tàbí o kò rajà, sá ti jẹ́ kí wọ́n lè fi Bíbélì wàásù fún ọ. Mo máa ń wí pé: “Ṣé ohun tí ẹ ń sọ ni pé gbogbo ayé ti ṣìnà, ẹ̀yin méjì péré yìí nìkan lẹ tọ̀nà?”

Wọn á sì dáhùn pé: “Kò burú, ìwọ náà wò ó nínú Bíbélì!” Àmọ́ nígbà yẹn, ohun tí wọ́n ń sọ kò yí mi lérò padà.

Ó bà mí nínú jẹ́ pé, Helen mi olùfẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn ní 1928. Kí àwọn ọmọ lè rí ìtọ́jú tó yẹ, mo kó wọn lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ ní Jerome. Wọ́n ti ra oko kan ní àkókò yẹn. Mo máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọmọ náà léraléra, mo sì ń mówó oúnjẹ lọ fún wọn lóṣooṣù. Mo tún ń faṣọ ránṣẹ́ sí wọn. Ó bà mí nínú jẹ́ pé àìsàn Helen le sí i, ó sì kú ní August 27, 1930.

Mo nímọ̀lára ìnìkanwà, ọkàn mi sì dà rú. Nígbà tí mo lọ sọ́dọ̀ àlùfáà láti ṣètò ìsìnkú, ó wí pé: “O kì í ṣe ọmọ ìjọ yìí mọ́. Ó ti lé lọ́dún kan tí o ti dáwó sápò ìjọ kẹ́yìn.”

Mo ṣàlàyé pé ìyàwó mi ti ń ṣàìsàn láti ìgbà pípẹ́ wá, mo sì ti ná gbogbo owó tó bá kù sórí àwọn ọmọ kí wọ́n lè máa rówó dá sápò ìjọ ní Jerome. Síbẹ̀, kí àlùfáà náà tó gbà láti ṣe ìsìnkú náà, mo lọ yá 50 dọ́là láti fi san owó tí mo jẹ ṣọ́ọ̀ṣì. Àlùfáà náà tún fẹ́ gba dọ́là 15 láfikún kó tó lè ṣe ìsìn Máàsì nílé ẹ̀gbọ́n ìyàwó mi, tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí ṣètò láti pé jọ sí, kí wọ́n sì ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Helen. N kò rí dọ́là 15 yẹn san, ṣùgbọ́n àlùfáà náà gbà láti ṣe ìsìn Máàsì náà bí mo bá ti lè gbà láti san án lọ́jọ́ tí mo bá gbowó oṣù.

Nígbà tí mo gbowó oṣù, mo fi ra bàtà àti aṣọ ilé ìwé àwọn ọmọ. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, àlùfáà náà wọ ọkọ̀ ojú irin tí mo ń wà. Ó wí pé, “O ṣì jẹ mí ní dọ́là 15.” Nígbà tó sọ̀ níbi tó ń lọ, ó halẹ̀ pé: “N ó lọ bá ọ̀gá rẹ, n ó sì gba owó náà nínú owó oṣù rẹ.”

Nígbà tí a ṣíwọ́ lọ́jọ́ yẹn, mo lọ bá ọ̀gá mi, mo sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kátólíìkì ni, ó sọ pé: “Bí àlùfáà yẹn bá fi wá síbí, n ó sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ fún un!” Gbólóhùn yẹn mú kí n ronú, ‘Owó wa nìkan làwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ń fẹ́ máa gbà, wọn kò sì kọ́ wa ní ohunkóhun nípa Bíbélì rí.’

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

Nígbà tí mo tún dé ilé ìtakọfí àwọn ọkùnrin Gíríìkì méjì wọ̀nyẹn lẹ́yìn náà, a jíròrò ohun tí àlùfáà yẹn ṣe. Látàrí rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ṣe ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Mo máa ń fi gbogbo òru ka Bíbélì àti àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé Bíbélì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Helen kò sí níbi tó ti ń joró nínú pọ́gátórì, bí àlùfáà ṣe sọ, ṣùgbọ́n ó ń sùn nínú ikú. (Jóòbù 14:13, 14; Jòhánù 11:11-14) Dájúdájú, mo ti rí ohun tó sàn ju wúrà lọ—òtítọ́!

Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, nípàdé àkọ́kọ́ tí mo bá Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ní Gbọ̀ngàn Garden ní Pittsburgh, mo nawọ́ sókè, mo sì wí pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ lálẹ́ yìí ju àpapọ̀ èyí tí mo kọ́ ní gbogbo ọdún tí mo lò ní ṣọ́ọ̀ṣì.” Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n béèrè àwọn tó bá fẹ́ lọ wàásù lọ́jọ́ kejì, mo tún nawọ́.

Nígbà tó di October 4, 1931, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn nípa ṣíṣe batisí inú omi. Láàárín àkókò náà, mo gba ilé kan, mo kó àwọn ọmọ padà sọ́dọ̀ mi, mo sì gba obìnrin kan sílé láti máa tọ́jú wọn. Pẹ̀lú gbogbo bùkátà ìdílé tí mo ní, mo ṣe oríṣi iṣẹ́ ìsìn àkànṣe kan tí a ń pè ní olùrànlọ́wọ́ láti January 1932 sí June 1933, nípa èyí tí mo ń lo 50 sí 60 wákàtí lóṣooṣù láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.

Ní nǹkan bí àkókò yìí ni mo bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí ọ̀dọ́bìnrin arẹwà kan tó sábà máa ń wọ ọkọ̀ tí mo ń wà lọ síbi iṣẹ́, tó sì ń wọ̀ ọ́ padà láti ibi iṣẹ́. Ojú wa sábà máa ń ṣe mẹ́rin nínú gíláàsì tí a fi ń wo ẹ̀yìn ọkọ̀. Bí èmi àti Mary ṣe pàdé nìyẹn. A fẹ́ra wa sọ́nà, a sì wá ṣègbéyàwó ní August 1936.

Nígbà tó di 1949, mo ti dọ̀gá níbi iṣẹ́ débi tí mo lè pinnu ìgbà tí mo fẹ́ ṣiṣẹ́, ìyẹn sì fún mi láyè láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, bí a ti ń pe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọmọbìnrin mi tó kéré jù, Jean, ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní 1945, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pọ̀. Lẹ́yìn náà, Jean pàdé Sam Friend, tí ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, orílé-iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé ní Brooklyn, New York.a Wọ́n ṣègbéyàwó ní 1952. Mo ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ ní Pittsburgh, mo sì ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà kan, mo ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdílé 14 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní 1958, mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin tí ń kérò nígboro. Lẹ́yìn náà, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà wá rọrùn, nítorí n kò ṣe iṣẹ́ bóo-jí-o-jí-mi oníwákàtí mẹ́jọ lóòjọ́ mọ́.

Ni 1983, Mary bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Mo gbìyànjú láti tọ́jú rẹ̀ bí òun náà ti ṣe tọ́jú mi fún nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 50 ọdún. Níkẹyìn, ní September 14, 1986, ó kú.

Ṣíṣàwárí Ibi Tí A Ti Bí Mi

Ní 1989, Jean àti Sam mú mi lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ ní Poland. A ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè tí mo gbé dàgbà. Nígbà tí àwọn ará Rọ́ṣíà gba apá ibẹ̀, wọ́n pa orúkọ àwọn ìlú dà, wọ́n sì kó àwọn ènìyàn lọ sí ilẹ̀ mìíràn. Wọ́n ti mú ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi lọ sí Istanbul, wọ́n sì ti mú ọ̀kan lára àwọn arábìnrin mi lọ sí Rọ́ṣíà. Àwọn tí a sì bi léèrè lágbègbè náà kò gbọ́ orúkọ abúlé mi rí.

Mo wá rí àwọn òkè ńlá kan tó jọ pé mo mọ̀ rí lókèèrè. Bí a ti ń sún mọ́ wọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ojú ilẹ̀ tí mo mọ̀ dunjú—òkè kan, ìkóríta títì kan, ṣọ́ọ̀ṣì kan, afárá orí odò kan. Ó yà wá lẹ́nu bí a ti yọ sí àmì ojú títì kan lójijì, tí ó kà pé, “Hoszowczyk”! Ní àkókò kan tí kò pẹ́, ṣáájú ìgbà tí a lọ, àwọn Kọ́múníìsì kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́, wọ́n sì ti padà sọ àwọn abúlé náà lórúkọ wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Kò sí ilé wa níbẹ̀ mọ́, àmọ́ ààrò tí a ti ń dáná níta wà níbẹ̀, tí ó rì wọlẹ̀ láàbọ̀. Mo wá tọ́ka sí igi ńlá kan, mo sì wí pé: “Ẹ wo igi yẹn. Kí n tó lọ sí Amẹ́ríkà ni mo gbìn ín. Ẹ wo bí ó ti tóbi tó báyìí!” Lẹ́yìn náà, a ṣèbẹ̀wò sí àwọn itẹ́, tí a ń wá orúkọ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àmọ́ a kò rí ọ̀kankan nínú wọn.

Fífi Òtítọ́ Sípò Àkọ́kọ́

Nígbà tí ọkọ Jean kú ní 1993, ó bi mí bí mo bá fẹ́ kí òun kúrò ní Bẹ́tẹ́lì láti máa wá tọ́jú mi. Mo sọ fún un pé ìyẹn ni ohun tó burú jù tó lè ṣe, èrò mi kò sì yí padà nípa rẹ̀. Mo dá gbé títí mo fi pé ọmọ ọdún 102, ṣùgbọ́n ó wá di dandan kí a gbé mi lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Mo ṣì jẹ́ alàgbà nínú Ìjọ Bellevue ní Pittsburgh, àwọn ará sì máa ń wá gbé mi lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọọjọ́ Sunday. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè ṣiṣẹ́ ìwàásù tó bẹ́ẹ̀ mọ́, mo ṣì jẹ́ aṣáájú-ọnà onípò àìlera.

Láàárín àwọn ọdún wọ̀nyí, mo ti jàǹfààní àwọn ilé ìwé àkànṣe tí Watch Tower Society máa ń ṣe fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn alábòójútó. Ní December tó kọjá, mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba tí a ṣe fún àwọn alàgbà ìjọ. Ní April 11 tó kọjá yìí, Jean gbé mi lọ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, ayẹyẹ kan ti mo ń fọkàn ṣìkẹ́ bi mo ti ń ṣe é bọ̀ lọ́dọọdún láti 1931.

Àwọn kan lára àwọn tí mo ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ alàgbà nísinsìnyí, àwọn mìíràn jẹ́ míṣọ́nnárì ní Gúúsù Amẹ́ríkà, àwọn kan jẹ́ àwọn òbí àgbà, tí ń sin Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Mẹ́ta lára àwọn ọmọ tèmi alára—Mary Jane, John, àti Jean—pẹ̀lú àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ tiwọn náà ń fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà Ọlọ́run. Àdúrà mi ni pé kí ọmọbìnrin mi kan tó kù àti ìyókù àwọn ọmọ-ọmọ àti ọmọ-ọmọ-ọmọ mi lè ṣe bákan náà lọ́jọ́ iwájú kan.

Ní báyìí tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 105, mo ṣì ń rọ gbogbo ènìyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n bá kọ́. Ní tòótọ́, ó dá mi lójú pé, bí o bá rọ̀ mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́, a kò ní já ọ kulẹ̀ láéláé. Ìwọ náà lè wá gbádùn ohun tó sunwọ̀n ju wúrà tí ń ṣègbé lọ—òtítọ́ tí ń jẹ́ ká ní ipò ìbátan oníyebíye pẹ̀lú Olùfúnni-níyè wa, Jèhófà Ọlọ́run.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ìgbésí ayé Sam Friend wà nínú Ilé Ìṣọ́nà August 1, 1986, ojú ìwé 22 sí 26.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Nígbà tí mo ń wa ọkọ̀ ojú irin tí ń kérò nígboro

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tí mo ń gbé nísinsìnyí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àmì ojú títì tí a rí ní 1989

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́