Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
GẸ́GẸ́ BÍ EDITH MICHAEL ṢE SỌ Ọ́
Ní kùtùkùtù àwọn ọdún 1930, a ń gbé lẹ́bàá St. Louis, Missouri, U.S.A., nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí wa. Ní àkókò yẹn gan-an ni okùn ìsáṣọ já, tí aṣọ ọ̀gbọ̀ Mọ́mì tí ń dán gbinrin sì já sínú ẹrẹ̀. Ó tẹ́wọ́ gba àwọn ìwé tí wọ́n fi lọ̀ ọ́, kò pẹ́ púpọ̀ tí obìnrin náà lọ, ó fi wọ́n sórí pẹpẹ, ó sì gbàgbé nípa wọn.
ÀWỌN ọdún wọ̀nyẹn jẹ́ ọdún ìjórẹ̀yìn ọrọ̀ ajé gígọntíọ, a sì ti dá Dádì dúró níbi iṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, ó béèrè bí ohunkóhun bá wà nínú ilé tí òún lè kà. Mọ́mì sọ fún un nípa àwọn ìwé náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó polongo pé: “Onítèmi, òtítọ́ náà nìyí!”
Ó fèsì pé: “Óò, ọ̀kan nínú àwọn ìsìn tí ń fẹ́ owó bíi ti àwọn yòókù mà ni.” Ṣùgbọ́n, Dádì rọ̀ ọ́ láti jókòó, kí ó sì yẹ ìwé mímọ́ wò pẹ̀lú òun. Nígbà tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, òun pẹ̀lú gbà gbọ́ dájú. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn Ẹlẹ́rìí kiri, wọ́n sì rí i pé wọ́n ń pàdé ní gbọ̀ngàn kan tí wọ́n háyà nítòsí àárín gbùngbùn St. Louis, gbọ̀ngàn kan tí a tún ń lò fún ijó àti àwọn ètò míràn.
Dádì àti Mọ́mì mú mi lọ—mo jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta—a sì rí gbọ̀ngàn náà, ṣùgbọ́n ijó ń lọ lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Dádì gbọ́ àkókò tí a ń ṣe ìpàdé, a sì padà lọ. A sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nítòsí ibi tí a ń gbé. A ń ṣe é nínú ilé obìnrin tí ó kọ́kọ́ kàn sí wa. Ó béèrè pé: “Èé ṣe tí o kò fi mú àwọn ọmọdékùnrin rẹ wá pẹ̀lú?” Ojú ti Màmá láti sọ pé wọn kò ní bàtà. Nígbà tí ó sọ bẹ́ẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n pèsè bàtà, àwọn arákùnrin mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá wa lọ sí ìpàdé.
A fún Màmá ní agbègbè ìpínlẹ̀ ìwàásù lẹ́bàá ilé wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Mò ń tẹ̀ lé e lọ, ní sísá pamọ́ sẹ́yìn rẹ̀. Kí ó tó mọ ọkọ̀ wà, a óò fẹsẹ̀ rin ohun tí ó lé ní kìlómítà kan láti lè rí bọ́ọ̀sì tí yóò gbé wa lọ sí ìpàdé ní St. Louis. Kódà nígbà tí yìnyín àti òjò dídì bá wà, a kì í pa ìpàdé jẹ.
Ní ọdún 1934, Mọ́mì àti Dádì ṣe ìrìbọmi. Èmi pẹ̀lú fẹ́ ṣe ìrìbọmi, mo sì ń tẹnu mọ́ ọn ṣáá, títí tí Màmá fi ní kí àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí kan bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́nà tí mo lè lóye. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún àwọn òbí mi pé, wọn kò ní láti dí mi lọ́wọ́ fún ṣíṣe ìrìbọmi; ó lè pa ìdàgbàsókè mi nípa tẹ̀mí lára. Nítorí náà mo ṣe ìrìbọmi ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà.
Mo fẹ́ràn ìwé pẹlẹbẹ náà, Home and Happiness, tí ó máa ń wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo, kódà bí mo bá sùn mo máa ń fi pamọ́ sábẹ́ ìrọ̀rí mi. Léraléra, mo bẹ Màmá láti kà á sí mi létí, títí tí mo fi mọ̀ ọ́n sórí. Àwòrán ọmọdébìnrin kékeré kan tí ó wà pẹ̀lú kìnnìún nínú Párádísè wà lẹ́yìn rẹ̀. Mo sọ pé èmi ni ọmọdébìnrin kékeré yẹn. Àwòrán yẹn ti jẹ́ kí ń tẹjú mi mọ́ ẹ̀bùn ìyè nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
Ojú máa ń tì mí púpọ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ bí ẹ̀rù tilẹ̀ ń bà mí, ìgbà gbogbo ni mo máa ń dáhùn ìbéèrè ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ìjọ.
Ó bani nínú jẹ́ pé, ẹ̀rù bá Dádì pé òun yóò pàdánù iṣẹ́ òun, nítorí náà, kò bá àwọn Ẹlẹ́rìí kẹ́gbẹ́ pọ̀ mọ́. Àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún
Màmá máa ń jẹ́ kí àwọn aṣáájú ọ̀nà, tàbí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, gbé ọkọ̀ onílé àgbérìn wọn sí ẹ̀yìnkùlé wa, lẹ́yìn tí a bá sì jáde ilé ẹ̀kọ́, mo máa ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Láìpẹ́, mo fẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà, ṣùgbọ́n Dádì ta kò ó, ní rírò pé ó yẹ kí ń túbọ̀ kàwé sí i. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Màmá yí i lérò padà láti jẹ́ kí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Nítorí náà, ní June ọdún 1943, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 14, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Láti ṣètìlẹyìn fún bùkátà agbo ilé, mo ń ṣe iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́, nígbà míràn mo sì ń ṣe iṣẹ́ tí ń gba gbogbo ọjọ́. Síbẹ̀ mò ń lé góńgó mi oṣooṣù ti 150 wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù bá.
Bí àkókò ti ń lọ, mo rí aṣáájú ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan, Dorothy Craden, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ́ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà ní January 1943, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 17. Kátólíìkì olùfọkànsìn ni, ṣùgbọ́n, lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣe ìrìbọmi. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó jẹ́ orísun ìṣírí àti okun fún mi, èmi pẹ̀lú sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un. A sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí ju ọmọ ìyá lọ.
Bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1945, a jùmọ̀ ṣe aṣáájú ọ̀nà ní àwọn ìlú kéékèèké ní Missouri, níbi ti kò sí ìjọ kankan. Ní Bowling Green, a mú kí gbọ̀ngàn ìpàdé wà létòlétò; Màmá wá, ó sì ràn wá lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà a ṣèbẹ̀wò sí gbogbo ilé tí ó wà ní ìlú náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a sì ké sí àwọn ènìyàn fún àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí a ṣètò pé kí àwọn arákùnrin láti St. Louis wá sọ. Àwọn 40 sí 50 máa ń pésẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn náà, a ṣe ohun kan náà ní Louisiana, níbi tí a ti háyà tẹ́ḿpìlì àwọn Mason. Láti lè kájú owó àfiháyà gbọ̀ngàn náà, a gbé àpótí ọrẹ síta, a sì ń kájú ìnáwó lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Lẹ́yìn èyí, a lọ sí Mexico, Missouri, níbi tí a ti háyà yàrá inú ilé ńlá kan. A ṣètò rẹ̀ fún ìjọ kékeré tí ó wà níbẹ̀ láti máa lò ó. Ilé náà ní àwọn iyàrá tí ó so mọ́ ọn, èyí tí a ń gbé inú rẹ̀. A tún ṣèrànwọ́ láti ṣètò fún àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní Mexico. Lẹ́yìn náà, a lọ sí olú ìlú náà, Jefferson City, níbi tí a ti ń kàn sí àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ní ọ́fíìsì wọn láràárọ̀ àwọn ọjọ́ àárín ọ̀sẹ̀. A ń gbé nínú yàrá kan lókè Gbọ̀ngàn Ìjọba náà pẹ̀lú Stella Willie, ẹni tí ó dà bí ìyá fún wa.
Láti ibẹ̀, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ sí ìlú Festus àti Crystal City, tí wọn kò jìnnà sí ara wọn. A gbé nínú ilé adìyẹ tí a ti sọ di ilé gbígbé, lẹ́yìn ilé ìdílé olùfìfẹ́hàn kan. Níwọ̀n bí kò ti sí ọkùnrin kankan tí ó tí ì ṣe ìrìbọmi, àwa ni a ń darí gbogbo ìpàdé. Fún iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́, a ń ta ohun ìṣaralóge. A kò ní púpọ̀ nípa ti ara. Àní, a kò lè dí ihò tí ó wà nísàlẹ̀ bàtà wa, nítorí náà, láràárọ̀ ni a máa ń gé páálí tuntun sínú wọn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò sì fọ aṣọ kan ṣoṣo tí ó ní, ní alẹ́.
Ní kùtùkùtù ọdún 1948, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 19, èmi àti Dorothy gba ìkésíni láti wá sí kíláàsì kejìlá ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead fún àwọn míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún, ọgọ́rùn-ún akẹ́kọ̀ọ́ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní February 6, 1949. Ó jẹ́ àkókò aláyọ̀ gidigidi. Àwọn òbí mi ti kó lọ sí California, Màmá sì wá láti ibẹ̀ láti pésẹ̀.
A Gbéra Lọ sí Ibi Iṣẹ́ Àyànfúnni Wa
A yan àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege 28 sí Ítálì—mẹ́fà, títí kan èmi àti Dorothy, lọ sí ìlú Milan. Ní March 4, 1949, a wọkọ̀ ojú omi Vulcania ti Ítálì kúrò ní New York. Ìrìn àjò náà gba ọjọ́ 11, ìrugùdù òkun sì mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wá ṣàìsàn ìrìn àjò lórí òkun. Arákùnrin Benanti wá sí èbútékọ̀ òkun ti Genoa láti pàdé wa àti láti mú wa padà lọ sí Milan nípa wíwọ ọkọ̀ ojú irin.
Nígbà tí a gúnlẹ̀ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì ní Milan, a rí òdòdó tí ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré ará Ítálì kan ti gbé sí yàrá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọmọbìnrin yìí, Maria Merafina, lọ sí Gilead, ó padà sí Ítálì, èmi pẹ̀lú rẹ̀ sì ṣiṣẹ́ sìn pa pọ̀ nínú ilé míṣọ́nnárì kan!
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí a dé Milan, a bojú wo ìta láti ojú fèrèsé ilé ìwẹ̀. A rí ilé gbígbé kan tí a fi bọ́m̀bù bà jẹ́ níta lẹ́yìn ilé wa. Ọkọ̀ òfuurufú ajubọ́ḿbù ti America ti ṣèèṣì ju bọ́m̀bù kan tí ó pa 80 ìdílé tí ń gbé ibẹ̀. Ní àkókò míràn, bọ́m̀bù tàsé ilé iṣẹ́ kan, ó sì bọ́ sí ilé ẹ̀kọ́ kan, ó sì pa 500 ọmọ. Nítorí ìdí èyí, àwọn ènìyàn kì í fẹ́ rí àwọn ará America sójú.
Ogun ti sú àwọn ènìyàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wí pé bí ogun mìíràn bá bẹ̀rẹ̀, wọn kì yóò lọ sí àwọn ilé ààbò kúrò lọ́wọ́ bọ́m̀bù, ṣùgbọ́n wọn yóò jókòó sílé, wọn yóò sì tan gáàsì, wọn yóò sì kú síbẹ̀. A mú un dá wọn lójú pé, wíwà níbẹ̀ wa kì í ṣe láti ṣojú fún United States tàbí ìṣàkóso èyíkéyìí mìíràn tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀, bí kò ṣe Ìjọba Ọlọ́run, tí yóò fòpin sí gbogbo ogun àti ìjìyà tí wọ́n ń mú wá.
Nínú ìlú ńlá Milan, ìjọ kan ṣoṣo tí ó ní nǹkan bí 20 ènìyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ń pàdé nínú ilé àwọn míṣọ́nnárì. A kò ṣètò agbègbè ìpínlẹ̀ ìwàásù kankan títí di àkókò yẹn, nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nínú ilé ńlá kan. Ní ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́, a pàdé Ọ̀gbẹ́ni Giandinotti, tí ó fẹ́ kí aya òún fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, nítorí náà, ó gba ọ̀kan nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Olóòótọ́ inú ni Ìyáàfin Giandinotti, ó máa ń béèrè ìbéèrè gan-an. Ó wí pé: “Inú mi yóò dùn nígbà tí ẹ bá kọ́ èdè Italian, kí ẹ baà lè kọ́ mi ní Bíbélì.”
Òrùlé ilé wọ́n ga, iná kò sì mọ́lẹ̀ tó, nítorí náà yóò gbé àga rẹ̀ sórí tábìlì ní alẹ́ láti lè sún mọ́ iná láti ka Bíbélì. Ó béèrè pé: “Bí mo bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú yín, mo ha ṣì lè máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bí?” A sọ fún un pé ọwọ́ rẹ̀ ni ìyẹ́n kù sí. Yóò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní òwúrọ̀ Sunday, yóò sì wá sí ìpàdé ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ kan ó wí pé, “N kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́.”
A béèrè pé: “Kí ló dé?”
“Nítorí pé wọn kò fi Bíbélì kọ́ni, mo sì ti rí òtítọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú yín.” Ó ṣe ìrìbọmi, ó sì bá ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lójoojúmọ́ kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó sọ fún wa pé, bí a bá ti sọ pé kí òun má lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, òun ì bá ti dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ dúró, bóyá òun ì bá má sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ mọ́.
Àwọn Iṣẹ́ Àyànfúnni Tuntun
Nígbà tí ó ṣe, a yan èmi àti Dorothy, pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin mìíràn, sí ìlú Ítálì ti Trieste, tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Britain àti ti America ti gbà nígbà náà. Kìkì nǹkan bí Ẹlẹ́rìí mẹ́wàá ni ó wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n iye yìí pọ̀ sí i. A wàásù ní Trieste fún ọdún mẹ́ta, nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, 40 jẹ́ akéde Ìjọba, ti 10 lára wọ́n sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
Ìlú Verona ni iṣẹ́ àyànfúnni wa tí ó tẹ̀ lé e, níbi tí kò sí ìjọ kankan. Ṣùgbọ́n nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì fúngun mọ́ àwọn aláṣẹ ayé, a kàn án nípa fún wa láti kúrò níbẹ̀. A yan èmi àti Dorothy sí Róòmù. Níbẹ̀ ni a ti háyà yàrá kan, a sì ṣiṣẹ́ ní agbègbè ìpínlẹ̀ tí ó sún mọ́ Vatican. Nígbà tí a wà níbẹ̀ ni Dorothy lọ sí Lebanon láti di aya John Chimiklis. A ti wà pa pọ̀ fún nǹkan bí ọdún 12, àárò rẹ̀ sọ mí púpọ̀.
Ní ọdún 1955, a ṣi ilé tuntun kan fún àwọn míṣọ́nnárì ní apá ibòmíràn ní Róòmù, ní àdúgbò kan tí a ń pè ní New Appian Way. Ọ̀kan nínú àwọn ẹni mẹ́rin tí ń gbé inú ilé náà ni Maria Merafina, ọmọdébìnrin tí ó gbé òdòdó sí yàrá wa ní alẹ́ ọjọ́ tí a gúnlẹ̀ sí Milan. A dá ìjọ tuntun sílẹ̀ ní agbègbè yìí ní ìlú náà. Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Róòmù ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, mo ní àǹfààní láti lọ sí àpéjọpọ̀ ní Nuremberg, Germany. Ẹ wo bí ó ti múni lórí yá tó láti pàdé àwọn tí wọ́n ti fara da ohun púpọ̀ lábẹ́ àkóso Hitler!
A Pada sí United States
Ní ọdún 1956, nítorí ìṣòro àìlera, mo gba àkókò ìsinmi nítorí àìsàn, láti padà sí United States. Ṣùgbọ́n n kò fìgbà kankan yí ojú mi kúrò lórí ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà nísinsìnyí àti títí láé nínú ayé tuntun rẹ̀. Mo ṣètò láti padà sí Ítálì. Ṣùgbọ́n, mo bá Orville Michael pàdé, tí n ṣiṣẹ́ sìn ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. A ṣègbéyàwó lẹ́yìn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York City, ní 1958.
Kété lẹ́yìn náà, a ṣí lọ sí Front Royal, Virginia, níbi tí a ti gbádùn ṣíṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú ìjọ kékeré kan. A ń gbé nínú ilé kékeré kan lẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní March ọdún 1960, ó pọn dandan pé kí a padà sí Brooklyn láti wá iṣẹ́ àmúṣe láti lè gbọ́ bùkátà wa. A ṣiṣẹ́ lálẹ́ ní onírúurú ilé ìfowópamọ́ kí a baà lè dúró nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
Nígbà tí a wà ní Brooklyn, bàbá mi kú, àrùn ẹ̀gbà ráńpẹ́ kan sì kọlu ìyakọ mi. Nítorí náà a pinnu láti ṣí lọ sí Oregon láti wà nítòsí àwọn ìyá wa. Àwa méjèèjì rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ aláàbọ̀ṣẹ́, a sì ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa lọ. Ní ìgbà ìkórè ọdún 1964, àwa pẹ̀lú àwọn ìyà wa lọ ré kọjá orílẹ̀-èdè láti lọ sí ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society ní Pittsburgh, Pennsylvania.
Nígbà ìbẹ̀wò wa sí Erékùṣù Rhode, alábòójútó àyíká kan, Arlen Meier, àti aya rẹ̀ fún wa níṣìírí láti ṣí lọ sí olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, Providence, níbi tí àìní gbé pọ̀ jù fún àwọn akéde Ìjọba. Àwọn ìyá wa rọ̀ wá láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni tuntun yìí, nítorí náà, gbàrà tí a padà dé Oregon, a ta ọ̀pọ̀ jù lọ ohun ìní wa, a sì ṣí lọ.
A Lọ sí Gilead Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1965, a lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní Pápá Ìṣeré Yankee. Níbẹ̀ ni a ti kọ̀wé béèrè fún wíwá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà, ó yà wá lẹ́nu láti ri fọ́ọ̀mù gbà, tí a ní láti dá padà láàárín 30 ọjọ́. Lílọ sí orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré kò àníyàn bá mi níwọ̀n bí ìlera Màmá kò ti dára tó. Ṣùgbọ́n ó fún mi níṣìírí pé: “Fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Ó mọ̀ pé ó ní láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún ọ!”
Ìyẹ́n yanjú ọ̀ràn náà. A fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà, a sì fi í ránṣẹ́. Ẹ wo bí ó ti yani lẹ́nu tó láti rí ìkésíni sí kíláàsì kejìlélógójì gbà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní April 25, 1966! Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead wà ní Brooklyn, New York, nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ní èyí tí kò tó oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, àwa 106 kẹ́kọ̀ọ́ yege ní September 11, 1966.
A Yàn Wá sí Argentina
Ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege, a wà lẹ́nu ìrìn àjò sí Argentina nínú ọkọ̀ òfuurufú Peruvian Airlines. Nígbà tí a gúnlẹ̀ sí Buenos Aires, alábòójútó ẹ̀ka, Charles Eisenhower, pàdé wa ni pápákọ̀ òfuurufú. Ó ràn wá lọ́wọ́ nípa òfin ìkẹ́rùwọlé, ó sì mú wa lọ sí ẹ̀ka náà. A ní ọjọ́ kan láti fi tú ẹrù wa kí a sì ṣètò rẹ̀; lẹ́yìn náà kíláàsì èdè Spanish wa bẹ̀rẹ̀. A ń kọ́ èdè Spanish fún wákàtí 11 lójúmọ́ fún oṣù àkọ́kọ́. Ní oṣù kejì, a kọ́ èdè náà fún wákàtí mẹ́rin ní ọjọ́ kan, a sì bẹ̀rẹ̀ sí nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.
A wà ní Buenos Aires fún oṣù márùn-ún, lẹ́yìn náà a yàn wá lọ sí Rosario, ìlú ńlá kan tí ó tó ìrìn àjò wákàtí mẹ́rin sí ìhà àríwá pẹ̀lú ọkọ̀ ojú irin. Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀ fún oṣù 15, a rán wa lọ síbi tí ó jìnnà ní ìhà àríwá ní Santiago del Estero, ìlú ńlá kan ní ẹkùn aṣálẹ̀ olóoru. Nígbà tí a wà níbẹ̀, ní January 1973, màmá mi di olóògbé. N kò fojú kàn án fún ọdún mẹ́rin. Ìrètí àjíǹde àti ìmọ̀ pé mo ń ṣiṣẹ́ sìn níbi tí Màmá fẹ́ kí n wà ni ó ràn mí lọ́wọ́ láti fara da ẹ̀dùn ọkàn mi.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Àwọn ará Santiago del Estero yá mọ́ni, ó sì rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí a dé ní ọdún 1968, nǹkan bí 20 tàbí 30 ènìyàn ní ń wá sí ìpàdé, ṣùgbọ́n ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àwọn tí ó wà nínú ìjọ wá ti lé ní ọgọ́rùn-ún. Ní àfikún sí i, àwọn ìjọ tuntun méjì ti wà tí ó ní akéde 25 sí 50 ní àwọn ìlú tí ó wà nítòsí.
Pípadà sí United States Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Nítorí ìṣòro àìlera, ní 1976 a yàn wá padà sí United States gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe—sí Fayetteville, Àríwá Carolina. Àwọn tí ń sọ èdè Spanish pọ̀ níbẹ̀, tí wọ́n wá láti Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù America, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Dominican, Puerto Rico, àti Sípéènì pàápàá. A ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò pẹ́ púpọ̀ tí a sì fi dá ìjọ èdè Spanish sílẹ̀. A lo nǹkan bí ọdún mẹ́jọ ní ibi iṣẹ́ àyànfúnni yẹn.
Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti túbọ̀ sún mọ́ ìyakọ mi, ẹni tí ó ti dàgbà, tí ó sì jẹ́ aláàbọ̀ ara. Ó ń gbé ní Portland, Oregon, nítorí náà, a gba iṣẹ́ àyànfúnni tuntun sí ìjọ èdè Spanish ní Vancouver, Washington, tí kò jìnnà sí Portland. Ìjọ náà kéré nígbà tí a dé ibẹ̀ ní December ọdún 1983, ṣùgbọ́n a ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun.
Ní June ọdún 1996, mo ti lo ọdún 53 nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ọkọ mi sì ti lo ọdún 55 ní January 1, 1996. Ní ọ̀pọ̀ ọdún wọ̀nyí, mo ti ní àǹfààní ríran ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́wọ́ láti wá sí ìmọ̀ òtítọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nísinsìnyí.
Nígbà míràn, a máa ń bi mí bóyá àìbímọ mú kí n pàdánù ohunkóhun. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, Jèhófà ti bù kún mi pẹ̀lú àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ nípa tẹ̀mí. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbésí ayé mi ti nítumọ̀, ó sì ti kun fún èrè nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mo lè tọ́ka sí ọmọbìnrin Jẹ́fútà, tí ó lo ìgbésí ayé rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn tẹ́ḿpìlì, tí kò sì bímọ nítorí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ńláǹlà tí ó ní.—Onídàájọ́ 11:38-40.
Mo ṣì ń rántí yíya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà nígbà tí mo wà ní ọmọdébìnrin kékeré. Àwòrán Párádísè sì ṣe rekete nínú ọkàn mi nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gan-an nígbà yẹn. Mo ṣì pa gbogbo àfiyèsí mi pọ̀ sórí ẹ̀bùn ìyè àìlópin nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ ọkàn mi ni láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, kì í ṣe fún 50 ọdún péré, ṣùgbọ́n títí láé—lábẹ́ Ìsàkóso Ìjọba rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Dorothy Craden, pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ ní èjìká mi, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi ní ọdún 1943
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ní Róòmù, Ítálì, pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ mi ní ọdún 1953
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Pẹ̀lú ọkọ mi