‘Ilé Àdúrà fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè’
“A kò ha kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a óò máa pe ilé mi fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’?”—MÁÀKÙ 11:17.
1. Irú ipò ìbátan wo ni Ádámù àti Éfà gbádùn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?
NÍGBÀ tí a dá Ádámù àti Éfà, wọ́n gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Bàbá wọn ọ̀run. Jèhófà Ọlọ́run bá wọn jíròrò, ó sì ṣí ète àgbàyanu tí ó ní fún ìran ẹ̀dá ènìyàn payá. Dájúdájú, ìgbà gbogbo ni a máa ń sún wọn láti fi ìyìn fún Jèhófà, nítorí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ tí ó ga lọ́lá. Bí Ádámù àti Éfà bá nílò ìtọ́sọ́nà bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ipa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bíi bàbá àti ìyá ọjọ́ ọ̀la fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láti ibikíbi nínú ilé Párádísè wọn. Wọn kò nílò iṣẹ́ ìsìn àlùfáà inú tẹ́ḿpìlì.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
2. Ìyípadà wo ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀?
2 Ipò náà yí padà nígbà tí áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan tan Éfà sínú ríronú pé, ipò ìgbésí ayé rẹ̀ yóò sunwọ̀n sí i bí ó bá kọ ipò ọba aláṣẹ Jèhófà sílẹ̀, ní sísọ pé “yóò dà bí Ọlọ́run.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, Éfà jẹ èso igi tí Ọlọ́run ti kà léèwọ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, Sátánì lo Éfà láti dán ọkọ rẹ̀ wò. Ó bani nínú jẹ́ pé, Ádámù tẹ́tí sí aya rẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀, èyí fi hàn pé ó ka ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀ sí pàtàkì ju ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4-7) Ní ti gidi, Ádámù àti Éfà yan Sátánì bí ọlọ́run wọn.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 4:4.
3. Kí ni àwọn ìyọrísí búburú tí ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà ní?
3 Nítorí ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ipò ìbátan ṣíṣeyebíye tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan ni tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pàdánù, ṣùgbọ́n, wọ́n tún pàdánù ìfojúsọ́nà fún wíwà láàyè títí láé nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ara ẹlẹ́ṣẹ̀ wọn jagọ̀ títí wọ́n fi kú. Àwọn ọmọ wọn jogún ipò ẹ̀ṣẹ̀ yìí. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 5:12.
4. Ìrètí wo ni Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ sí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀?
4 A nílò ohun kan láti lè mú aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ padà bá Ẹlẹ́dàá mímọ́ wọn rẹ́. Nígbà tí ó ń ṣe ìdájọ́ Ádámù àti Éfà, Ọlọ́run mú kí àwọn ọmọ wọn ọjọ́ ọ̀la ní ìrètí nípa ṣíṣèlérí “irú ọmọ” kan tí yóò gba aráyé là kúrò nínú àwọn ìyọrísí ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ṣí i payá pé Irú Ọmọ náà tí yóò mú ìbùkún wá, yóò wá nípasẹ̀ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Pẹ̀lú ète onífẹ̀ẹ́ yìí lọ́kàn, Ọlọ́run yan àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti di orílẹ̀-èdè rẹ̀ àyànfẹ́.
5. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ní ọkàn ìfẹ́ sí kúlẹ̀kúlẹ̀ májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì dá?
5 Ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú ipò ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n sì gbà láti ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. Májẹ̀mú Òfin yẹn yẹ kí ó jẹ́ ohun tí yóò fa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run lónìí lọ́kàn mọ́ra gidigidi, nítorí pé, ó tọ́ka sí Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà. Pọ́ọ̀lù wí pé, ó ní “òjìji awọn ohun rere tí ń bọ̀” nínú. (Hébérù 10:1) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ gbólóhùn yìí, ó ń jíròrò iṣẹ́ ìsìn àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì nínú àgọ́ àjọ alágbèérìn, tàbí àgọ́ ìjọsìn. A pè é ní “tẹ́ḿpìlì Olúwa” tàbí “ilé Olúwa.” (Sámúẹ́lì Kìíní 1:9, 24) Nípa ṣíṣàyẹ̀wo iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí a ń ṣe nínú ilé orí ilẹ̀ ayé ti Jèhófà, a lè wá túbọ̀ lóye ìṣètò aláàánú náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, nípasẹ̀ èyí tí a lè gbà mú àwọn ẹ̀dá ènìyàn padà bá Ọlọ́run rẹ́ lónìí.
Ibi Mímọ́ Jù Lọ
6. Kí ni ó wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, báwo sì ni a ṣe fi hàn pé Ọlọ́run wà níbẹ̀?
6 Bíbélì sọ pé: “Ẹni Gíga Jù Lọ kì í gbé àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́.” (Ìṣe 7:48) Ṣùgbọ́n, àwọ sánmà tí ó wà nínú iyàrá ìkélé ti inú lọ́hùn-ún, ibi tí a ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ni ó fi hàn pé Ọlọ́run wà nínú ilé rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. (Léfítíkù 16:2) Ó hàn gbangba pé, àwọ sánmà yìí tàn yòò, láti lè pèsè ìmọ́lẹ̀ fún Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ó wà lórí àpótí mímọ́ ọlọ́wọ̀ kan tí a ń pè ní “àpótí ẹ̀rí,” tí ó ní àwọn wàláà òkúta tí a gbẹ́ àwọn kan lára àṣẹ tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì sí. Kérúbù méjì tí a fi wúrà ṣe tí wọ́n na ìyẹ́ wọn jáde wà nínú ìbòrí Àpótí náà, èyí tí ń fi àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí onípò gíga nínú ètò àjọ Ọlọ́run ní òkè ọ̀run hàn. Àgbàyanu àwọ sánmà mímọ́lẹ̀ náà wà lórí ìbòrí àpótí náà àti láàárín àwọn kérúbù náà. (Ẹ́kísódù 25:22) Èyí ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run Olódùmarè ṣe gúnwà sórí ìtẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run, tí àwọn kérúbù alààyè sì wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. (Kíróníkà Kìíní 28:18) Ó ṣàlàyé ìdí tí Ọba Hesekáyà fi gbàdúrà pé: “Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé àárín àwọn kérúbù.”—Aísáyà 37:16.
Ibi Mímọ́
7. Àwọn ohun èèlò wo ni ó wà nínú Ibi Mímọ́?
7 Iyàrá ìkélé kejì nínú àgọ́ àjọ ni à ń pè ní Ibi Mímọ́. Nínú iyàrá yìí, ọ̀pá fìtílà rírẹwà tí ó ní ọwọ́ méje wà ní apá òsì ẹnu ọ̀nà àbáwọlé, tábìlì àkàrà ìfihàn sì wà ní apá ọ̀tún. Pẹpẹ kan wà níwájú gan-an, láti orí èyí tí òórùn dídùn tùràrí ti ń lọ sókè. Ó wà níwájú aṣọ ìkélé tí ó pààlà sí Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
8. Ojúṣe wo ni àwọn àlùfáà ń ṣe déédéé nínú Ibi Mímọ́?
8 Ní òròòwúrọ̀ àti ní gbogbo ìrọ̀lẹ́, àlùfáà kan ní láti wọnú àgọ́ àjọ lọ, kí ó sì sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. (Ẹ́kísódù 30:7, 8) Ní òwúrọ̀, nígbà tí a bá ń sun tùràrí, a ní láti máa bu òróró sí fìtílà méje tí ó wà lórí ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe náà. Ní ìrọ̀lẹ́, a máa ń tan àwọn fìtílà náà, kí ìmọ́lẹ̀ baà lè wà ní Ibi Mímọ́. Ní gbogbo Ọjọ́ Sábáàtì, àlùfáà kan ní láti fi ìṣù àkàrà 12 tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sórí tábìlì àkàrà ìfihàn.—Léfítíkù 24:4-8.
Àgbàlá
9. Kí ni ète agbada omi, ẹ̀kọ́ wo sì ni a rí kọ́ nínú èyí?
9 Àgọ́ àjọ tún ní àgbàlá, tí a fi àwọn aṣọ àgọ́ yí ká. Agbada ńlá kan ń bẹ nínú àgbàlá yìí níbi tí àwọn àlùfáà ti ń fọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n tó wọ Ibi Mímọ́ lọ. Wọ́n tún ní láti wẹ̀, kí wọ́n tó rúbọ lórí pẹpẹ tí ó wà ní àgbàlá náà. (Ẹ́kísódù 30:18-21) Ohun àbéèrè-fún ní ti wíwà ní mímọ́ tónítóní yìí jẹ́ ìránnilétí lílágbára fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí pé, wọ́n gbọ́dọ̀ sakun láti wà ní mímọ́ tónítóní nípa ti ara, ti ìwà híhù, ti èrò orí, àti nípa tẹ̀mí, bí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọrun tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ẹrú inú tẹ́ḿpìlì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ni wọ́n ń pèsè igi ìdáná lórí pẹpẹ àti omi inú agbada.—Jóṣúà 9:27.
10. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìrúbọ tí a ń ṣe lórí pẹpẹ ìrúbọ?
10 Ní òròòwúrọ̀ àti ní gbogbo ìrọ̀lẹ́, a óò dáná sun ọ̀dọ́ àgbò ìrúbọ kan lórí pẹpẹ pẹ̀lú ọkà àti ẹbọ mímu. (Ẹ́kísódù 29:38-41) A máa ń ṣe àwọn ìrúbọ mìíràn ní àwọn ọjọ́ pàtàkì. Nígbà míràn, a ní láti ṣe ìrúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan pàtó tí ẹnì kan dá. (Léfítíkù 5:5, 6) Nígbà míràn, ọmọ Ísírẹ́lì kan lè pèsè ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, èyí tí àwọn àlùfáà àti ẹni tí ó pèsè ẹbọ náà yóò jẹ nínú rẹ̀. Èyí fi hàn pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, ní gbígbádùn bíbá a jẹun pọ̀, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àtìpó olùgbé pàápàá lè di olùjọsìn Jèhófà, kí ó sì ní àǹfààní láti gbé ọrẹ ẹbọ wá sí ilé Rẹ̀. Ṣùgbọ́n láti baà lè fi ọlá tí ó yẹ hàn fún Jèhófà, kìkì àwọn ìrúbọ tí ó dára jù lọ ni àwọn àlùfáà lè tẹ́wọ́ gbà. A ní láti lọ ìyẹ̀fun ọrẹ ẹbọ ọkà náà kúnná, àwọn ẹran ìrúbọ kò sì gbọdọ̀ ní àbùkù kankan.—Léfítíkù 2:1; 22:18-20; Málákì 1:6-8.
11. (a) Kí ni a ti ń ṣe ẹ̀jẹ̀ ẹran ìrúbọ, kí sì ni èyí ń tọ́ka sí? (b) Kí ni ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn àti ti ẹranko?
11 A óò gbé ẹ̀jẹ̀ àwọn ohun ẹbọ wọ̀nyí wá sórí pẹpẹ. Èyí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí ojoojúmọ́ fún orílẹ̀-èdè náà pé, wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì nílò olùràpadà tí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a bá ta sílẹ̀ yóò lè ṣètùtù títí láé fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú. (Róòmù 7:24, 25; Gálátíà 3:24; fi wé Hébérù 10:3) Lílo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà mímọ́ ọlọ́wọ̀ yìí tún rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé, ẹ̀jẹ̀ dúró fún ẹ̀mí àti pé Ọlọ́run ni ó ni ẹ̀mí. Ọ̀nà mìíràn tí ẹ̀dá ènìyàn lè gbà lo ẹ̀jẹ̀ ni Ọlọ́run ti fìgbà gbogbo kà léèwọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Léfítíkù 17:10-12; Ìṣe 15:28, 29.
Ọjọ́ Ètùtù
12, 13. (a) Kí ni Ọjọ́ Ètùtù? (b) Kí àlùfáà àgbà tó gbé ẹ̀jẹ̀ wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, kí ni ó ní láti ṣe?
12 Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní ọjọ́ tí a ń pè ní Ọjọ́ Ètùtù, gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, títí kan àwọn àtìpó olùgbé tí ń jọ́sìn Jèhófà, ní láti ṣíwọ́ iṣẹ́ gbogbo, kí wọ́n sì gbààwẹ̀. (Léfítíkù 16:29, 30) Ní ọjọ́ pàtàkì yìí, a óò wẹ orílẹ̀-èdè náà mọ́ tónítóní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí wọ́n baà lè gbádùn ipò ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọdún mìíràn. Ẹ jẹ́ kí a finú ro ìran náà, kí a sì gbé díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì rẹ̀ yẹ̀ wò.
13 Àlùfáà àgbà wà ní àgbàlá àgọ́ àjọ. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ara rẹ̀ mọ́ níbi agbada omi náà, ó pa akọ màlúù fún ìrúbọ. A da ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà sínú àwokòtò: a óò lò ó lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìdílé àlùfáà Léfì. (Léfítíkù 16:4, 6, 11) Ṣùgbọ́n, kí ó tó máa bá ìrúbọ náà lọ, ohun kan wà tí àlùfáà àgbà gbọ́dọ̀ ṣe. Yóò kó tùràrí olóòórùn dídùn sínú àwo tùràrí tí a fi wúrà ṣe àti ẹ̀yin iná láti orí pẹpẹ sínú àwo iná. Nísinsìnyí, ó wọ Ibi Mímọ́ lọ, ó sì rìn lọ sí ibi aṣọ ìkélé Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ó rọra gba ẹ̀gbẹ́ aṣọ ìkélé náà kọjá, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí. Lẹ́yìn èyí, níbi tí ẹ̀dá ènìyàn míràn kò lè rí, ó da tùràrí náà sórí ẹ̀yin iná náà, ìkùukùu olóòórùn dídùn sì gba Ibi Mímọ́ Jù Lọ kan.—Léfítíkù 16:12, 13.
14. Èé ṣe tí àlùfáà àgbà fi ní láti wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ oríṣi ẹran méjì?
14 Nísinsìnyí, Ọlọ́run ti ṣe tán láti fi àánú hàn, ó sì ti ṣe tán láti jẹ́ kí a tu òun lójú ní ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ. Nítorí ìdí yìí ni a ṣe ń pe ìbòrí Àpótí náà ní “ìjókòó àánú” tàbí “ìbòrí ìpẹ̀tù.” (Hébérù 9:5, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Àlùfáà àgbà jáde kúrò ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó gbé ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ó sì wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Gẹ́gẹ́ bí Òfin ti pàṣẹ, ó tẹ ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì wọ́n ọn síwájú ìbòrí Àpótí náà nígbà méje. (Léfítíkù 16:14) Lẹ́yìn náà, ó padà sí àgbàlá, ó sì pa ewúrẹ́ kan, tí ó jẹ́ ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ “àwọn ènìyàn.” Ó gbé díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ wá sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà. (Léfítíkù 16:15) Àwọn iṣẹ́ ìsìn pàtàkì míràn tún wáyé ní Ọjọ́ Ètùtù. Fún àpẹẹrẹ, àlùfáà àgbà ní láti gbé ọwọ́ lé orí ewúrẹ́ kejì, kí ó sì jẹ́wọ́ “àìṣe déédéé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” lé e lórí. A mú ààyè ewúrẹ́ yìí lọ sínú aginjù láti ru ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀-èdè náà lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí a ṣe ń ṣe ètùtù ọdọọdún “fún àwọn àlùfáà, àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn” nìyẹn.—Léfítíkù 16:16, 21, 22, 33.
15. (a) Báwo ni tẹ́ḿpìlì Sólómọ́nì ṣe bá àgọ́ àjọ mu? (b) Kí ni ìwé Hébérù sọ nípa iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí a ṣe nínú àgọ́ àjọ àti ti inú tẹ́ḿpìlì?
15 Fún ọdún 486 àkọ́kọ́ nínú ìtàn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, àgọ́ àjọ alágbèérìn náà ṣiṣẹ́ fún wọn gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn Ọlọ́run wọn, Jèhófà. Lẹ́yìn náà, a fún Sólómọ́nì ará Ísírẹ́lì ní àǹfààní láti kọ́ ilé kan tí a kì yóò máa gbé kiri. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́ḿpìlì yìí yóò tóbi ju àgọ́ àjọ lọ, tí a óò sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ jù ú lọ, àwòrán ilé tí Ọlọ́run pèsè jẹ́ bátánì kan náà tí a fi kọ́ àgọ́ àjọ. Bíi ti àgọ́ àjọ, ó ń ṣàpẹẹrẹ ìṣètò títóbi jù, tí ó sì túbọ̀ gbéṣẹ́ fún ìjọsìn tí Jèhófà yóò “gbéró, kì í sì í ṣe ènìyàn.”—Hébérù 8:2, 5; 9:9, 11.
Tẹ́ḿpìlì Àkọ́kọ́ àti Ìkejì
16. (a) Ẹ̀bẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wo ni Sólómọ́nì bẹ̀ nígbà tí ó ya tẹ́ḿpìlì náà sí mímọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gba àdúrà Sólómọ́nì?
16 Nígbà tí ó ń ya tẹ́ḿpìlì ológo náà sí mímọ́, Sólómọ́nì fi ẹ̀bẹ̀ onímìísí yìí kún un pé: “Ní ti àlejò, tí kì í ṣe inú Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ ńlá rẹ . . . ; bí wọ́n bá wá tí wọ́n bá sì gbàdúrà síhà ilé yìí: Kí ìwọ kí ó gbọ́ láti ọ̀run, àní láti ibùgbé rẹ wá, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àlejò náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo ènìyàn ayé kí ó lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì lè máa bẹ̀rù rẹ, bí Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ, kí wọn kí ó lè mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a ń pè mọ́ ilé yìí tí èmí kọ́”. (Kíróníkà Kejì 6:32, 33) Lọ́nà tí a lè tètè lóye, Ọlọ́run fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba àdúrà ìyàsímímọ́ tí Sólómọ́nì gbà. Ẹ̀là iná bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó ẹran ẹbọ tí ó wà lórí pẹpẹ, ògo Jèhófà sì bo tẹ́ḿpìlì náà.—Kíróníkà Kejì 7:1-3.
17. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, èé sì ti ṣe?
17 Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàdánù ìbẹ̀rù tí ó gbámúṣé tí wọ́n ní fún Jèhófà. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n gan orúkọ títóbi lọ́lá rẹ̀, nípa híhu ìwà ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìbọ̀rìṣà, panṣágà, bíbá ìbátan ẹni lò pọ̀, àti nípa híhùwà ìkà sí àwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó, àti àlejò. (Ísíkẹ́ẹ̀lì 22:2, 3, 7, 11, 12, 26, 29) Nípa báyìí, ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọlọrun mú ìdájọ́ ṣẹ, nípa gbígbé àwọn ọmọ ogun Bábílónì dìde láti pa tẹ́ḿpìlì náà run. A kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n là á já lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.
18. Nínú tẹ́ḿpìlì kejì, àwọn àǹfààní wo ni ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn ti ìjọsìn Jèhófà lẹ́yìn?
18 Lẹ́yìn 70 ọdún, àṣẹ́kù àwọn Júù tí wọ́n ronú pìwà dà, padà sí Jerúsálẹ́mù, a sì fún wọn ní àǹfààní láti tún tẹ́ḿpìlì Jèhófà kọ́. Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, àwọn àlùfáà àti ọmọ Léfì tí yóò ṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ḿpìlì kejì kò tó. Nítorí èyí, àwọn Nétínímù, tí wọ́n ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹrú inú tẹ́ḿpìlì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ní a fún ní àǹfààní púpọ̀ sí i láti jẹ́ òjíṣẹ́ ilé Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọn kò bá àwọn àlùfáà àti ọmọ Léfì dọ́gba.—Ẹ́sírà 7:24; 8:17, 20.
19. Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe nípa tẹ́ḿpìlì kejì, báwo sì ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe ní ìmúṣẹ?
19 Lákọ̀ọ́kọ́, ó dà bíi pé tẹ́ḿpìlì kejì náà kò ṣeé fi wé ti ìṣáájú. (Hágáì 2:3) Ṣùgbọ́n Jèhófà ṣèlérí pé: “Èmi óò si mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì dé: èmi óò sì fi ògo kún ilé yìí . . . Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ.” (Hágáì 2:7, 9) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, tẹ́ḿpìlì kejì ní ògo tí ó pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ. Ó fi ọdún 164 wà pẹ́ ju ti ìṣáájú lọ, olùjọsìn púpọ̀ sí i láti ilẹ̀ púpọ̀ sí i sì rọ́ wá sí àwọn àgbàlá rẹ̀. (Fi wé Ìṣe 2:5-11.) Títún tẹ́ḿpìlì kejì náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní àkókò Ọba Hẹ́rọ́dù, a sì mú àgbàlá rẹ̀ tóbi sí i. Bí ó ti wà lórí pèpéle òkúta ràbàtà, tí àwọn òpó rírẹwà sì yí i ká, ó bá tẹ́ḿpìlì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Sólómọ́nì kọ́ díje ní ti ìtóbi lọ́lá. Ó ní àgbàlá ìta tí ó tóbi, tí a kọ́ fún àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fẹ́ láti jọ́sìn Jèhófà. Òkúta ìsénà kan pààlà sí Àgbàlá Àwọn Kèfèrí àti àwọn àgbàlá tí inú lọ́hùn-ún tí ó wà fún kìkì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
20. (a) Ìyàtọ̀ pàtàkì wo ni ó sàmì sí tẹ́ḿpìlì tí a tún ṣe náà? (b) Kí ni ó fi hàn pé àwọn Júù fi ojú tí kò tọ́ wo tẹ́ḿpìlì náà, kí sì ni Jésù ṣe ní ìhùwàpadà sí èyí?
20 Tẹ́ḿpìlì kejì yìí gbádùn ìyàtọ̀ gíga lọ́lá ti pé Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, ti kọ́ni nínú àwọn àgbàlá rẹ̀. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi tẹ́ḿpìlì àkọ́kọ́, àwọn Júù ní gbogbogbòò kò ní ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àǹfààní wọn ti jíjẹ́ olùtọ́jú ilé Ọlọ́run. Họ́wù, wọ́n tilẹ̀ yọ̀ọ̀da fún àwọn oníṣòwò láti máa ṣe kárà-kátà nínú àgbàlá àwọn Kèfèrí. Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n yọ̀ọ̀da fún àwọn ènìyàn láti máa lo tẹ́ḿpìlì náà gẹ́gẹ́ bí àbùjá tí a lè gbé nǹkan gbà lọ sí agbègbè mìíràn nínú Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ mẹ́rin ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù fọ tẹ́ḿpìlì náà mọ́ tónítóní kúrò nínú irú àwọn àṣà ayé bẹ́ẹ̀, kò sì dẹ́kun sísọ pé: “A kò ha kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a óò máa pe ilé mi fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Máàkù 11:15-17.
Ọlọ́run Pa Ilé Rẹ̀ Orí Ilẹ̀ Ayé Tì Títí Láé
21. Kí ni Jésù fi hàn nípa tẹ́ḿpìlì Jerúsálẹ́mù?
21 Nítorí ìgbésẹ̀ onígboyà tí Jésù gbé, ní gbígbé ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọ́run lárugẹ, àwọn aṣáájú ìsìn Júù pinnu láti pa á. (Máàkù 11:18) Ní mímọ̀ pé a kò ní pẹ́ pa òun, Jésù wí fún àwọn aṣáájú ìsìn Júù pé: “A ti pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:37, 38) Ó tipa báyìí fi hàn pé, láìpẹ́, Ọlọ́run kì yóò tẹ́wọ́ gba irú ìjọsìn tí a ń ṣe ní tẹ́ḿpìlì Jerúsálẹ́mù tí a lè fojú rí mọ́. Kì yóò jẹ́ ‘ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,’ mọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tọ́ka ilé tẹ́ḿpìlì gàgàrà náà sí Jésù, ó wí pé: “Ṣé ìwọ́ rí àwọn ilé ńlá wọ̀nyí? Lọ́nàkọnà a kì yoo fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yoo sì wó palẹ̀.”—Máàkù 13:1, 2.
22. (a) Báwo ni a ṣe mú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nípa tẹ́ḿpìlì náà ṣẹ? (b) Dípò gbígbé ìrètí wọn karí ìlú ńlá orí ilẹ̀ ayé, kí ni àwọn Kristẹni ìjímìjí ń wá?
22 A mú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ṣẹ ní ọdún 37 lẹ́yìn náà, ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ run. Ìyẹn pèsè ẹ̀rí amúnijígìrì, pé ní tòótọ́ ni Ọlọ́run ti pa ilé rẹ̀ tí a lè fojú rí tì. Jésù kò fìgbà kankan sọ àsọtẹ́lẹ̀ títún tẹ́ḿpìlì míràn kọ́ sí Jerúsálẹ́mù. Nípa ìlú ńlá ti orí ilẹ̀ ayé yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé: “Àwa kò ní ìlú ńlá kan níhìn-ín tí ń bá a lọ ní wíwà, ṣùgbọ́n à ń fi taratara wá ọ̀kan tí ń bọ̀.” (Hébérù 13:14) Àwọn Kristẹni ìjímìjí ń fojú sọ́nà fún dídi apá kan “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run”—Ìjọba Ọlọ́run tí ó dà bí ìlú ńlá. (Hébérù 12:22) Nípa báyìí, ìjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà kò fi tẹ́ḿpìlì kan tí a lè fojú rí lórí ilẹ̀ ayé ṣe ibùjókòó mọ́. Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí yóò tẹ̀ lé èyí, a óò ṣàgbéyẹ̀wò ìṣètò gíga lọ́lá jù lọ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:21, 24.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Ipò wo tí Ádámù àti Éfà ní pẹ̀lú Ọlọ́run ni wọ́n pàdánù?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ní ọkàn ìfẹ́ sí àwọn apá pàtàkì nínú àgọ́ àjọ náà?
◻ Kí ni a rí kọ́ láti inú àwọn ìgbòkègbodò inú àgbàlá àgọ́ àjọ?
◻ Èé ṣe tí Ọlọ́run fi yọ̀ọ̀da pé kí a pa tẹ́ḿpìlì òun run?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Tẹ́ḿpìlì Tí Hẹ́rọ́dù Tún Kọ́
1. Ibi Mímọ́ Jù Lọ
2. Ibi Mímọ́
3. Pẹpẹ Ẹbọ Sísun
4. Agbada Ńlá Dídà
5. Àgbàlá Àwọn Àlùfáà
6. Àgbàlá Ísírẹ́lì
7. Àgbàlá Àwọn Obìnrin