Ojú Ìwòye Bíbélì
Ipò Òṣì Ha Dá Olè Jíjà Láre Bí?
“Ipò òṣì jẹ́ ọ̀tá lílágbára tí ń dènà ayọ̀ ẹ̀dá; dájúdájú, ó máa ń ba ìgbádùn jẹ́, ó sì ń mú kí a má lè hu àwọn ìwà rere kan, ó sí máa ń mú kí àwọn ìwà rere mìíràn ṣòro ré kọjá ààlà.”—Samuel Johnson, òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kejìdínlógún.
ÒṢÈLÚ ọmọ ilẹ̀ Róòmù náà, Magnus Aurelius Cassiodorus, sọ pé: “Ipò òṣì ni okùnfà ìwà burúkú.” Ó jọ pé àwọn ojú ìwòye wọ̀nyí ń fi hàn pé ipò òṣì ló wulẹ̀ ń ṣokùnfà àwọn irú ìwà burúkú kan. Ó hàn kedere pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ló gbà bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì tí ìwà burúkú náà bá jẹ́ olè jíjà.
Èrò náà pé ìninilára àti ipò òṣì dá olè jíjà láre wọ́pọ̀ gan-an. Ronú nípa orin Gẹ̀ẹ́sì tí a fi ń sọ ìtàn Robin Hood ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, tí ó ṣàpèjúwe ẹni inú ìtàn kan tí ó jẹ́ ìgárá arúfin, tí ń ja àwọn ọlọ́rọ̀ lólè, tí ó sì ń pín ohun tí ó bá jí fún àwọn aláìní. Àwọn ènìyàn kà á sí akọni fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún.
Òtítọ́ ni pé ohun ìgbọ́bùkátà ṣọ̀wọ́n gidigidi fún ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí. Báńkì Àgbáyé ròyìn láìpẹ́ yìí pé, àwọn bílíọ̀nù 1.3 ènìyàn ni iye tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà lójúmọ́ kò tó dọ́là kan. Nínú ìwádìí kan, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará Philippine sọ pé àwọn ka ara àwọn sí òtòṣì. Ní Brazil, ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí wọ́n lọ́rọ̀ jù lọ ń pa ìlọ́po 32 iye owó tí ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí wọ́n tòṣì gan-an ń pa. Àwọn irú ipò bẹ́ẹ̀ lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan débi tí wọn óò fi ọ̀nà èyíkéyìí, kódà olè jíjà, gbọ́ bùkátà àwọn àìní wọn ojoojúmọ́ tí wọ́n nílò láti máa wà nìṣó.
Ní kedere ni Bíbélì dẹ́bi fún olè jíjà. Ìkẹjọ lára àwọn Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.” (Ẹ́kísódù 20:15) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí wọ́n gba Bíbélì gbọ́ ní ìtẹ̀sí láti dá olè jíjà láre tí ó bá jẹ́ ipò àìní ohun ìgbọ́bùkátà ló sún olè náà ṣe é.
Èyí gbé ìbéèrè pàtàkì kan dìde pé: Ipò òṣì ha dá olè jíjà láre ní ti gidi bí? Kí ló yẹ kí ẹnì kan ṣe bí ó bá wà nínú ìṣòro lílekoko ti àìrí ohun ìgbọ́bùkátà? Bí ó bá ní àwọn ọmọ tí ń ṣàìsàn tàbí tí ebi ń pa láti tọ́jú ńkọ́? Jèhófà Ọlọ́run yóò ha fàyè gba olè jíjà nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí àwọn ohun tí a jí bá jẹ́ ti àwọn tí kò pa lára?
Kí Ni Ọlọ́run Wí?
Níwọ̀n bí Jésù ti ṣàgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀, àpẹẹrẹ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ojú ìwòye Ọlọ́run. (Jòhánù 12:49) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ń bá àwọn aláìní lò tìyọ́nútìyọ́nú. Bíbélì sọ pé, “nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀ àánú wọn ṣe é.” (Mátíù 9:36) Síbẹ̀síbẹ̀, kò fàyè gba olè jíjà lábẹ́ ipòkípò rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run pẹ̀lú ṣàníyàn nípa àwọn aláìní, kò ka ipò òṣì sí èyí tí ń dá olè jíjà láre. Nínú Aísáyà 61:8, Bíbélì sọ fún wa pé, Ọlọ́run ‘kórìíra ìjalè nínú àìṣòdodo.’ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ ní kedere pé, àwọn olè kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, a kò ṣiyè méjì nípa ojú ìwòye Ọlọ́run.—Kọ́ríńtì Kíní 6:10.
Ṣùgbọ́n, Òwe 6:30 sọ pé, “wọn kì í gan olè, bí ó bá ṣe pé, ó jalè láti tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn, nígbà tí ebi ń pa á.” Gbólóhùn yí ha gba olè jíjà láyè bí? Rárá. Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé Ọlọ́run yóò ṣì fìyà jẹ olè náà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹsẹ tí ó tẹ̀ lé e sọ pé: “Ṣùgbọ́n bí a bá mú un, yóò san án pa dà níwọ̀n méje; gbogbo ìní ilé rẹ̀ ni yóò fi san ẹ̀san.”—Òwe 6:31.
Bí a kò tilẹ̀ ní pẹ̀gàn ẹni tí ebi sún jalè bíi ti ẹni tí ìwọra sún jalè tàbí nítorí èrò láti ṣèpalára fún ẹni tó jà lólè, kò yẹ kí àwọn tí ń fọkàn fẹ́ ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ irú olè jíjà èyíkéyìí. Kódà nínú ipò òṣì lílégbákan, olè jíjà ń tàbùkù sí Ọlọ́run. Òwe 30:8, 9 sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Fi oúnjẹ tí ó tó fún mi bọ́ mi. . . . Kí èmi má baà tòṣì, kí èmi sì jalè, kí èmi sì ṣẹ̀ sí orúkọ Ọlọ́run mi.” Òtítọ́ ni, olè kan ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Níwọ̀n bí olè jíjà ti jẹ́ ìgbésẹ̀ aláìnífẹ̀ẹ́, ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, yálà ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì ni a jà lólè. Ní ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò, olè jíjà kò tọ̀nà rí.—Mátíù 22:39; Róòmù 13:9, 10.
Àwáwí náà pé ẹnì kan tí nǹkan kò gún régé fún ní ẹ̀tọ́ láti jalè kò bọ́gbọ́n mu. Sísọ èyí yóò wulẹ̀ dà bíi sísọ pé eléré ìdárayá kan tí ìrísí ara rẹ̀ kò ṣe ṣámúṣámú ní ẹ̀tọ́ láti lo oògùn líle, tí a ti fòfin dè, kí ó baà lè gbégbá orókè. Bí ó bá tilẹ̀ gbégbá orókè, ọ̀nà àbòsí ni ó lò láti gbà á. Àwọn mìíràn yóò ronú, lọ́nà ẹ̀tọ́, pé ó ti lo ọ̀nà àìbófinmu láti gba ìṣẹ́gun àwọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí ní ti olè náà. Ó gba ohun tí ó jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn lọ́nà àbòsí. Ipò rẹ̀ tí kò gún régé kò dá ọ̀nà tí ó gbà láre.
Olè èyíkéyìí tí ó bá ń fẹ́ ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ronú pa ọ̀nà ìhùwà rẹ̀ dà. Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.” (Éfésù 4:28) Àwọn tí wọ́n jẹ́ olè tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n ronú pìwà dà láìṣàbòsí, lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò dárí jì wọ́n.—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:14-16.
Kí Ni Àwọn Òtòṣì Lè Ṣe?
Bíbélì ṣèlérí pé: “Olúwa kì yóò jẹ́ kí ebi kí ó pa ọkàn olódodo; ṣùgbọ́n ó yí ìfẹ́ àwọn ènìyàn búburú dà nù.” (Òwe 10:3) Ọlọ́run kì yóò ran àwọn tí ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀ láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ó ń yọ́nú sí àwọn tí ń gbìyànjú láti fi òtítọ́ inú ṣègbọràn sí i, yóò sì bù kún ìsapá wọn láti rí ohun tí wọ́n nílò.—Orin Dáfídì 37:25.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti rí i pé bí àwọn bá pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́, ipò nǹkan yóò sunwọ̀n sí i nínú ìgbésí ayé àwọn. Fún àpẹẹrẹ, fífi àmọ̀ràn Bíbélì sílò láti jẹ́ òṣìṣẹ́kára àti láti yẹra fún àwọn ìwà búburú bíi tẹ́tẹ́ títa, ìmutípara, sìgá mímu, àti ìjoògùnyó, ti mú kí wọ́n ní púpọ̀ sí i lára ohun tí wọ́n nílò ní gidi. (Gálátíà 5:19-21) Èyí ń béèrè pé kí wọ́n lo ìgbàgbọ́, àwọn tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, “rere ni Olúwa” àti pé ó máa ń ran àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́wọ́ ní ti gidi.—Orin Dáfídì 34:8.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Robin Hood: General Research Division/The New York Public Library/Astor, Lenox and Tilden Foundations