ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/8 ojú ìwé 20-23
  • Kọfí Espresso—Ògidì Kọfí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọfí Espresso—Ògidì Kọfí
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Mú Kí Ó Jẹ́ Kọfí Espresso?
  • Ohun Tí A Fi Ń Ṣe Kọfí Espresso Nílé
  • Kọfí Ti O Ń Rà
  • Ọnà Tí A Ń Gbà Ṣe É
  • Kaféènì Ńkọ́?
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2009
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
Jí!—1997
g97 11/8 ojú ìwé 20-23

Kọfí Espresso—Ògidì Kọfí

‘Kọfí ì bá dùn lẹ́nu bó ṣe ń ta sánsán ni!’ Ìwọ ha ti sọ bẹ́ẹ̀ rí bí? Ò bá fẹ́ láti tọ́ “caffè espresso” wò. Àwọn tí wọ́n mọ adùn nǹkan ti pè é ní “àgbà kọfí” àti “kọfí tí ó ládùn jù lọ.”

BÓYÁ o ti tọ́ kọfí espresso wò rí? Bóyá kíki àti ìtasánsán aládùn tó ní gbádùn mọ́ ọ. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, o lè ti pinnu pé: ‘Ní tèmi, èyí kì í ṣe kọfí gidi. Abájọ tí wọ́n ń fi ife tóńtóló bù ú—ta ló tilẹ̀ lè mu ju tín-ńtín lọ nínú ohun tó le, tó sì korò tó báyìí? Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó dájú pé ó ní ìwọ̀n kaféènì tí kò dára lára!’

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣe kọfí espresso tí wọ́n ṣe dáadáa máa ń korò ni? Àti pé ṣé ife kọfí espresso kan ní kaféènì púpọ̀ nínú ju ife kọfí lásán kan lọ ni? Àwọn ìdáhùn náà lè yà ọ́ lẹ́nu.

Kí Ló Mú Kí Ó Jẹ́ Kọfí Espresso?

Ítálì ni kọfí espresso ti pilẹ̀ ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú orílẹ̀-èdè àti ìbílẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é. Báwo ló ṣe rí lẹ́nu? Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí kọfí espresso ṣàpèjúwe rẹ̀ bí èyí tí ń ta sánsán, tí ó léròjà nínú, tí ó ládùn, tí kò le, tí ó nítọ̀ọ́wò adùn òun ìkorò, tí ó korò fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí ó sì ní òórùn dídùn. Ife kọfí espresso kan tí a ṣe dáradára máa ń ní ohun kan lójú tí a ń pè ní crema—ìfófòó aláwọ̀ ilẹ̀ tí ó lómi góòlù, tí kì í yọ bọ̀rọ̀, tí kì í jẹ́ kí ó dì, tí ó sì ń gba díẹ̀ lára ìtasánsán rẹ̀ dúró.

Ife kan jẹ́ ìwọ̀n 30 sí 40 mìlílítà. Ní gbogbogbòò, a máa ń fi ife ìbukọfí tóńtóló kan bù ú fúnni pẹ̀lú ṣúgà nínú lẹ́sẹkẹsẹ̀ tí a bá ṣe é tán—ògidì gbáà ni!

Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Ṣíṣe kọfí espresso ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àkànṣe irú èso kọfí kan, tí a ń yan di aláwọ̀ ilẹ̀ (àmọ́ kì í di dúdú), a óò sì lọ̀ ọ́ kúnná ju àwọn tí a ń lò fún kọfí lásán lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe irú èso kọfí tí a yan tàbí bí a ṣe lọ̀ ọ́ ló ń mú kọfí espresso jáde ní pàtàkì—ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí a ń gbà ṣe é ni, èyí tí ń lo ipá dípò òòfàmọ́lẹ̀. Ìwọ̀n kọfí tí a ń lò fún ife kan fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta èyí tí a ń ṣe nípa dída omi gbígbóná sí i, ṣùgbọ́n ní lílo omi tí ó kéré gan-an. Ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é yìí ń mú kí èròjà inú èso tí a fi ṣe kọfí náà jáde.

O lè béèrè fún ife kan tàbí méjì ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé àrójẹ àti ilé ìmukọfí. Àmọ́, ṣọ́ra: Kọfí espresso tí wọn kò ṣe dáradára máa ń korò. Nítorí náà, tí wọ́n bá bu kọfí espresso fún ọ ní ilé àrójẹ tàbí ilé ìmukọfí kan, yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ife rẹ bá kún jù tàbí tí kò sí crema lójú kọfí náà, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ èyí tí wọ́n sè jù, tí ó le, ni wọ́n bù fún ọ.

Onírúurú àwọn ohun mímu tí ó ní espresso nínú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú kọfí espresso. Bí kọfí espresso bá le jù fún ọ, o kò ṣe tọ́ kọfí cappuccino aládùn tàbí kọfí espresso onímílíìkì sísè wò?

Ohun Tí A Fi Ń Ṣe Kọfí Espresso Nílé

Ìwọ yóò ha fẹ́ láti ṣe kọfí espresso nílé bí? Fífiyèsí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀ ṣe pàtàkì, kí o baà lè ṣe èyí tó dùn, tí ó sì léròjà nínú.

Irú ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣe kọfí espresso wo ni ó yẹ kí o rà? Kò sí irú èyí tí wọ́n fi ń ṣe kọfí nípa dída omi gbígbóná gba inú rẹ̀ kọjá tí yóò ṣe kọfí espresso gidi, láìka irú èso kọfí yíyan tàbí ọ̀nà tí a gbà lọ̀ ọ́ sí. Ìwọ yóò nílò àwọn ohun èlò tí a pilẹ̀ ṣe.

Ohun èlò ìsekọfí lórí iná ni kì í sábà wọ́n jù. Ọ̀pọ̀ ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí kọfí espresso tí a sè lórí iná nínú ilé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kọfí náà kì í ki, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó máà ní crema. O lè ṣe kọfí espresso tó dára nípa fífìṣọ́ra díwọ̀n omi tí o máa bù síbi ìbomisí lára ohun èlò náà tàbí nípa ṣíṣí i sílẹ̀ kí o sì gbé ìgbékaná náà kúrò lórí iná nígbà tí o bá ṣe é dé bí ìdajì.

Ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ amóoruwá ń lo ooru láti fagbára da omi sórí kọfí náà. Báwo ni o ṣe lè ṣe èyí tí ó dára jù lọ? Nípa dídá kọfí tí ń jáde dúró lẹ́yìn ṣíṣe ìwọ̀n 30 mìlílítà sí 60 mìlílítà, kí ó má baà di àsèjù, kí a sì ṣẹ́ ooru tí ó tó kù fún ṣíṣe mílíìkì onífòófòó. Nítorí náà, wá ẹ̀rọ tí ó ní ibi tí a ti ń paná rẹ̀ tàbí ọ̀nà míràn tí a fi lè dá kọfí tí ń jáde dúró. Àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ amóoruwá dára fún ṣíṣe cappuccino àti kọfí espresso onímílíìkì ṣùgbọ́n, bíi ti àwọn ohun èlò ìsekọfí lórí iná, wọn kò lè ṣe ògidì kọfí espresso tí ó dára jù lọ.

Àwọn ẹ̀rọ alágbàá alọsókèsódò nínú ẹ́ńjìnnì ló sábà máa ń wọ́n jù lọ, àwọn ni wọ́n sì lè ṣe kọfí espresso tó dára jù lọ. Láti lo ẹ̀rọ alágbàá alọsókèsódò nínú ẹ́ńjìnnì, ìwọ yóò fún un ní agbára nípa títẹ ọwọ́ kan wálẹ̀, tí yóò tẹ àgbá alọsókèsódò nínú ẹ́ńjìnnì kan tí ó ní irin lílọ́ nínú mọ́lẹ̀, tí èyí sì ń ti omi gbígbóná gba inú kọfí náà. Àwọn kan nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀rọ alágbàá alọsókèsódò nínú ẹ́ńjìnnì jù nítorí pé a lè fi ọwọ́ darí wọn, wọ́n sì jojú nígbèsè. Ó ṣòro fún àwọn kan láti lò wọ́n, wọn kì í sì í tètè mú omi gbóná.

Ẹ̀rọ onípọ́ǹpù pẹ̀lú ń mú agbára tí ó pọ̀ tó láti ṣe kọfí espresso tí ó dára jáde. Wọ́n rọrùn, wọ́n sì yára ju ẹ̀rọ alágbàá alọsókèsódò nínú ẹ́ńjìnnì lọ. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n fẹ́ kọfí espresso tó dára jù lọ sábà máa ń yan ẹ̀rọ onípọ́ǹpù. Ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ rẹ̀ ń yàtọ̀ síra, àwọn ẹ̀rọ onípọ́ǹpù sì máa ń lálòtọ́ ju àwọn mìíràn lọ dé àyè kan. Nítorí náà, wò ó ní ilé ìtajà bíi mélòó kan kí o tó rà á. Àwọn ilé ìtajà tí ń dán ìṣiṣẹ́ àwọn ẹ̀rọ wọn wò yóò jẹ́ kí o lè ra èyí tí ó dára.

Kọfí Ti O Ń Rà

Ra ògidì kọfí espresso yíyan. Àwọn kọfí tí a ń tà ní ilé ìtajà ńlá ti máa ń pẹ́ nílé, nítorí náà, wá ṣọ́ọ̀bù tó jẹ́ kọfí nìkan ni wọ́n ń tà—ó tilẹ̀ sàn jù bí wọ́n bá ń yan án níbẹ̀. Kọfí lílọ̀ kì í dùn mọ́ tí ọjọ́ bá ti lọ lórí rẹ̀, àmọ́ odindi èso kọfí yóò ṣì wà lọ́tun fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan ó kéré tán. Nítorí náà, bí ó bá ṣeé ṣe, ra odindi èso kọfí kí o sì lọ̀ ọ́ nílé, bí o bá ṣe fẹ́ ẹ sí. Èyí tí a lọ kúnná ló dára, àmọ́ kí ó máà kúnná lúbúlúbú. Bí o bá ní láti ra kọfí lílọ́, ra ìwọ̀nba díẹ̀, kí o sì tètè lò ó.

Láti mú kí kọfí rẹ wà lọ́tun, dà á sínú agolo tí atẹ́gùn kò lè dé inú rẹ̀, tí ó sì dé dáradára. Bí o bá fẹ́ láti lò ó láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, gbé agolo kọfí náà sí ibi tí kò móoru, tí kò sí ìmọ́lẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbé e sínú fìríìjì.

Ọnà Tí A Ń Gbà Ṣe É

Kódà pẹ̀lú ohun èlò àti kọfí tó dára jù lọ, a gbọ́dọ̀ kọ́ nípa ọ̀nà tí a ń gbà ṣe kọfí espresso ni, a kò lè fowó rà á. Irú ẹ̀rọ tí o lò yóò mú kí ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é yàtọ̀, nítorí náà, tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí ó bá a wá. Lo kọfí lílọ̀ tí ó pọ̀ tó. Ìwọ̀n tí ó dára yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ kún asẹ́ tí wọ́n fi sínú rẹ̀ fún ọ, tí yóò sì fi àyè díẹ̀ sílẹ̀ kí kọfí lílọ̀ náà fi wú. Yóò gba kí a ní ìrírí díẹ̀ láti lè da kọfí kún inú asẹ́ náà dáradára, tàbí láti lè sẹ́ kọfí tí ó wà nínú rẹ̀ kí ó lè yọ̀ sísàlẹ̀, kí omi náà lè rọra máa lọ geerege nínú kọfí lílọ̀ náà, kí ó sì lè gbé ìtasánsán rẹ̀ jáde ní kíkún.

Kí ni àṣìṣe kan tí a ní láti yẹra fún? Fífi omi tí ó pọ̀ jù ṣe kọfí náà. Bí o bá gbìyànjú láti ṣe 60 mìlílítà tàbí 90 mìlílítà láti inú ìwọ̀n tí ó yẹ kí a fi ṣe ife kan, kọfí náà yóò ṣàn, yóò sì korò. Dípò kọfí espresso, ohun mímu tí ó jọ kọfí líle ni ìwọ yóò rí—kì í ṣe ohun tí o ń retí.

Nítorí náà, kókó pàtàkì kan ni mímọ ìgbà tí a ní láti ṣíwọ́ sísè é. Àwọn tí wọ́n mọ adùn nǹkan dámọ̀ràn pé ó yẹ kí ife kọfí espresso lílọ̀ kan lè mú 30 mìlílítà sí 40 mìlílítà ohun mímu tí a sè láàárín nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú àáyá sí ìṣẹ́jú àáyá 25 jáde. Ní àkókò yí, èròjà inú àwọn kọfí lílọ̀ náà ti yọ tán, a sì ní láti sọ ọ́ nù.

Kódà bí ó bá jẹ́ ife kọfí espresso lílọ̀ méjì ni a ń sè, “Bí ó ṣe kéré tó ni ohun tí yóò jáde nínú rẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó.” Bí kọfí lílọ̀ tí o sè bá ṣe kéré tó ni ohun mímu náà yóò ṣe dùn tó. Ohun tí a ní lọ́kàn nípa ife méjì yàtọ̀ síra láti ibì kan sí òmíràn, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ife kọfí espresso méjì tí a ń rí nínú ife kan èyí tí a lọ̀, ní lílo ìlọ́po méjì kọfí tí a lọ̀.

Kaféènì Ńkọ́?

Kaféènì tí ó wà nínú ife kọfí espresso kan lè má pọ̀ tó ti inú ife kọfí lásán. Ìyẹn ha yà ọ́ lẹ́nu bí? Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí a mọ̀ pé kọfí espresso le gan-an?

Kókó abájọ kan ni bí èso kọfí yíyan náà ṣe dúdú tó. Àwọn èso kọfí yíyan tí wọ́n dúdú gan-an kì í ní kaféènì púpọ̀ nínú. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀bù tó jẹ́ kọfí nìkan ni wọ́n ń tà máa ń lo èso kọfí arabica, tí kò ní kaféènì púpọ̀ tó èso kọfí robusta tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀pọ̀ lára àwọn kọfí alágolo tí wọ́n ń tà ní ilé ìtajà ńlá.

Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni bí ó ṣe pọ̀ tó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kaféènì inú ìwọ̀n 30 mìlílítà kọfí espresso kan pọ̀ ju ti inú kọfí lásán lọ, ìwọ̀n tí ó wà nínú ife kan kò tó nǹkan. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìwádìí kan fi hàn pé ife kọfí lásán kan tí ó jẹ́ 180 mìlílítà lè ní kaféènì ìwọ̀n 100 mílígíráàmù tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú, tí ife kọfí espresso kan sì lè ní ìwọ̀n tí kò tó bẹ́ẹ̀ nínú.

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun tí àwọn ìwádìí fi hàn máa ń yàtọ̀ síra, ìwọ̀n kaféènì yóò sì sinmi lé èso tí a lò àti gbogbo ìgbésẹ̀ tí a gbé nígbà tí a ń sè é. Dájúdájú, ife kọfí espresso méjì yóò ní ìwọ̀n kaféènì tó pọ̀ ju ti ife kan lọ. Bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí lẹ́yìn tí o mu ún tán lè jẹ́ ohun tí ó dára jù lọ láti fi pinnu bí kaféènì náà ṣe pọ̀ tó. Bí o bá fẹ́ láti dín ìwọ̀n kaféènì tí o ń mu kù, kí o sì máa gbádùn kọfí espresso síbẹ̀, o lè lo èso kọfí espresso yíyan tí a ti yọ kaféènì inú rẹ̀ kúrò tàbí kí o lọ̀ ọ́ pọ̀ mọ́ èso kọfí espresso yíyan lásán, ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n kaféènì tí o fẹ́.

Ṣé o ti ṣe tán láti se kọfí espresso ní ilé ìgbọ́únjẹ rẹ? Ṣíṣe é léraléra yóò mú ìyọrísí dáradára wá, nítorí náà ìwọ fúnra rẹ ni kí o ṣe àyẹ̀wò náà—ṣe ìdánrawò fúnra rẹ kí o tó bù ú fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ìwọ yóò nílò ìrírí kí ó tó lè ṣe crema àti mílíìkì onífòófòó. Bí ó ti wù kí ó rí, ṣíṣe é léraléra yóò ṣàǹfààní nígbà tí o bá bu kọfí espresso tí ó dà bí èyí tí wọ́n ń tà ní ṣọ́ọ̀bù kọfí ládùúgbò rẹ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. O tilẹ̀ lè wá gbà pé kọfí espresso ni ògidì kọfí gan-an.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìtọ́sọ́nà fún Ṣíṣe Mílíìkì Onífòófòó

Láti ṣe àti/tàbí láti mú mílíìkì gbóná láti fi ṣe kọfí cappuccino àti kọfí espresso onímílíìkì, ìwọ yóò nílò ife alábọ́ kan, mílíìkì tútù, àti ẹ̀rọ tí a fi ń mú mílíìkì gbóná. Bí ohun tí o fi ń se kọfí espresso rẹ kò bá ní ọ̀pá tín-ínrín tí a fi ń mú mílíìkì gbóná, o lè ra ohun èlò kan tí ó dá wà fún ète yìí.

1. Da mílíìkì tútù sínú kete onípáànù kan dé ìdajì.

2. Ki ọ̀pá tín-ínrín tí a fi ń mú mílíìkì gbóná náà bọnú mílíìkì náà, kí o sì ṣí ọ̀nà ooru ìseǹkan náà.

3. Jẹ́ kí orí ọ̀pá tín-ínrín náà wọ abẹ́ rẹ̀ díẹ̀, kí o sún kete onípáànù náà sísàlẹ̀, kí o sì jẹ́ kí afẹ́fẹ́ púpọ̀ máa wọnú rẹ̀ bí ìfófòó náà ṣe ń yọ.

4. Ó sábà máa ń gbóná tó nígbà tí kete onípáànù náà bá gbóná jù láti fọwọ́ kàn.

5. Ti ọ̀nà ooru ìseǹkan náà, kí o sì yọ kete onípáànù náà kúrò nísàlẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ṣí ọ̀nà ooru ìseǹkan náà láti da mílíìkì tó kù kúrò, kí o sì fi aṣọ tí a wọ́n omi sí nù ún.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èso kọfí máa ń wà lọ́tun ju kọfí lílọ̀ lọ

A fi èrọ amóoruwá tí a fi ń ṣe kọfí “espresso” hàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́