ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/8 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ebi àti Àìjẹunrekánú
  • Àìlera
  • Àìríṣẹ́ṣe àti Owó Kékeré
  • Bíba Àyíká Jẹ́
  • Ìwé Kíkà
  • Ibùgbé
  • Iye Ènìyàn
  • Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
    Jí!—1998
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 6/8 ojú ìwé 4-7

Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn

NÍ ỌDÚN 33 Sànmánì Tiwa, Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.” (Mátíù 26:11) Kí ló ní lọ́kàn gan-an? Ṣé ó ń sọ pé òṣì yóò máa wà títí láé ni?

James Speth, olùdarí Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Ìdàgbàsókè, sọ pé: “A kò lè gbà pé [òṣì] yóò máa wà títí láé. Ayé òde òní ní gbogbo èròjà, ìmọ̀ àti òye iṣẹ́ tí ó lè fi sọ òṣì di ọ̀rọ̀ ìtàn.” Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ayé òde òní lè kásẹ̀ òṣì nílẹ̀?

Ó dájú pé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń retí pé ìsapá ènìyàn lè kásẹ̀ òṣì nílẹ̀, bí ó ti polongo pé àwọn ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ láti 1997 sí 2006 jẹ́ “Ẹ̀wádún Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Láti Kásẹ̀ Òṣì Nílẹ̀,” èkíní irú rẹ̀. Àjọ UN wéwèé láti bá àwọn ìjọba, àwọn ènìyàn, àti àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé lárugẹ, kí wọ́n mú ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn pọ̀ sí i, kí wọ́n mú ipò àwọn obìnrin sunwọ̀n sí i, kí wọ́n sì pèsè àwọn ọ̀nà ìpawówọlé àti ìríṣẹ́ṣe.

Àwọn góńgó wọ̀nyí mà wuyì o! Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ọwọ́ aráyé yóò tẹ̀ wọ́n láé? Ṣàyẹ̀wò àwọn ìdènà mélòó kan tí ń dí ìsapá ènìyàn láti kásẹ̀ òṣì nílẹ̀ lọ́wọ́.

Ebi àti Àìjẹunrekánú

Ayembe, tí ń gbé ní Zaire, ní bùkátà ìbátan 15 láti gbé. Nígbà mìíràn, ìdílé náà lè jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́—àdàlú ẹ̀kọ, ewé pákí, iyọ̀, àti ṣúgà. Nígbà mìíràn, wọn kì í rí oúnjẹ jẹ fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta. Ayembe sọ pé: “Mo máa ń dúró di ìgbà tí àwọn ọmọ bá ń sunkún ebi kí n tó gbọ́únjẹ.”

Àwọn nìkan kọ́ ló wà nínú irú ipò yìí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ẹni 1 nínú 5 kì í jẹun sùn. Kárí ayé, nǹkan bí 800 mílíọ̀nù ènìyàn—tí 200 mílíọ̀nù nínú wọn jẹ́ ọmọdé—kì í jẹunre kánú rárá. Àwọn ọmọ wọ̀nyí kì í dàgbà bó ṣe yẹ; wọ́n máa ń ṣàìsàn léraléra. Wọn kì í ṣe dáadáa nílé ìwé. Nígbà tí wọ́n bá dàgbà, wọ́n máa ń jìyà ìyọrísí nǹkan wọ̀nyí. Nípa bẹ́ẹ̀, òṣì sábà máa ń yọrí sí àìjẹunrekánú, tí òun náà máa ń dá kún òṣì.

Òṣì, ebi, àti àìjẹunrekánú gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń nípa lórí àwọn ìsapá ìṣèlú, ti ètò ọrọ̀ ajé, àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí a ń ṣe láti mú wọn kúrò. Ní gidi, ipò náà kò sunwọ̀n sí i, ńṣe ló ń burú sí i.

Àìlera

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe wí, òṣì ni “àrùn tí ń pani jù lọ lágbàáyé,” òun sì ni “ọ̀kan ṣoṣo tó tóbi jù nínú ohun tí ń fa ikú, àrùn àti ìjìyà.”

Ìwé An Urbanizing World: Global Report on Human Settlements, 1996 sọ pé, ó kéré tán, 600 mílíọ̀nù ènìyàn ní Látìn Amẹ́ríkà, Éṣíà, àti Áfíríkà ń gbé ilé tí kò ní láárí—kò ní omi, ìmọ́tótó, ètò ṣíṣan ẹ̀gbin dà nù tó bó ṣe yẹ—tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wọn àti ìlera wọn fi ń wà nínú ewu nígbà gbogbo. Kárí ayé, àwọn ènìyàn tí kò ní omi tí kò lẹ́gbin lé ní bílíọ̀nù kan. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn kò sì lè rí oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé jẹ. Gbogbo kókó wọ̀nyí ló mú kí ó ṣòro fún àwọn òtòṣì láti dènà àrùn.

Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn òtòṣì kì í tún lè ṣèwòsàn àrùn. Nígbà tí àwọn òtòṣì bá ń ṣàìsàn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má lè rówó ra egbòogi tó yẹ, tàbí kí wọ́n má lè rí owó ìtọ́jú. Àwọn òtòṣì máa ń kú ní rèwerèwe; àwọn tí kò sì kú lè ní àrùn bárakú.

Zahida, tó ń kiri ọjà ní Maldives, sọ pé: “Òṣì ní ń fa àìsàn, tí kì í jẹ́ ká lè ṣiṣẹ́.” Ó dájú pé àìníṣẹ́ máa ń mú kí òṣì burú sí i ni. Ó wá ń yọrí sí àyípoyípo oníláabi tó lè pani, níbi tí òṣì àti àìsàn ti ń fún ara wọn lókun.

Àìríṣẹ́ṣe àti Owó Kékeré

Òmíràn nínú àwọn ẹ̀ka òṣì ni àìríṣẹ́ṣe. Kárí ayé, nǹkan bí 120 mílíọ̀nù ènìyàn tó lè ṣiṣẹ́ ni kò ríṣẹ́. Nígbà kan náà, nǹkan bí 700 mílíọ̀nù ènìyàn mìíràn sábà máa ń fàkókò púpọ̀ ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó rí owó tó kéré tó bẹ́ẹ̀ tí kò ní tó fi pèsè àwọn ohun tí kò ṣeé máà ní gbà.

Ọkọ̀ ajéègboro ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta ni Rudeen ń wà ní Cambodia. Ó wí pé: “Ní tèmi, òṣì ló ń mú mi ṣiṣẹ́ wákàtí 18 lóòjọ́, síbẹ̀, tí owó tí mo ń pa kò tó fi bọ́ èmi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi méjì.”

Bíba Àyíká Jẹ́

Ohun mìíràn tó tún lọ́ mọ́ òṣì ni bíba àyíká jẹ́. Elsa, olùwádìí kan ní Guyana, Gúúsù Amẹ́ríkà sọ pé: “Òṣì ní ń fa bíba ìṣẹ̀dá jẹ́: igbó, ilẹ̀, ẹranko, odò àti adágún.” Àyípoyípo ọlọ́ràn-ìbànújẹ́ mìíràn nìyí—òṣì ń fa bíba àyíká jẹ́, ìyẹn náà sì ń mú kí òṣì máa pọ̀ sí i.

Ríro ilẹ̀ oko títí yóò fi ṣá tàbí títí a óò fi lò ó fún nǹkan mìíràn jẹ́ àṣà tó ti wà láti ọjọ́ pípẹ́. Bákan náà ni pípa igbó run—gígé igbó lulẹ̀ nítorí igi tàbí láti fi dáko. Nítorí iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i lágbàáyé, ipò náà ti lé kenkà.

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìdàgbàsókè Iṣẹ́ Àgbẹ̀ Lágbàáyé ṣe wí, láàárín 30 ọdún tó kọjá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀dú tí a ti pàdánù ní àwọn ilẹ̀ oko, tí ọ̀pọ̀ jù lọ rẹ̀ jẹ́ nítorí àìsí owó àti ìmọ̀ ẹ̀rọ tí a nílò láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìdáàbòbò tó yẹ. Láàárín àkókò kan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ hẹ́kítà ti di aṣálẹ̀ nítorí àwọn ọ̀nà ìbomirinlẹ̀ tí a kò ṣe dáadáa tàbí tí a kò bójú tó dáadáa. A ń gé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ hẹ́kítà igbó lulẹ̀ lọ́dọọdún láti rí ibi dáko tàbí láti rí igi gẹdú tàbí igi ìdáná.

Ìbaǹkanjẹ́ yìí tan mọ́ òṣì lọ́nà méjì. Lọ́nà kìíní, a sábà ń fipá mú àwọn òtòṣì láti ṣàmúlò àwọn nǹkan inú àyíká láìtọ́ nítorí pé wọ́n nílò oúnjẹ àti ohun ìgbẹ́mìíró. Irú ọ̀rọ̀ wo la lè bá àwọn tí ebi ń pa, tí wọ́n tòṣì, tí a sì ń fipá mú láti ba àwọn ohun àdánidá jẹ́ kí wọ́n tó lè gbọ́ bùkátà ara wọn nísinsìnyí sọ nípa ṣíṣàmúlò àwọn ohun àdánidá láìba àyíká tàbí àǹfààní àwọn ìran tó ń bọ̀ jẹ́? Lọ́nà kejì, àwọn ọlọ́rọ̀ sábà máa ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà láyìíká àwọn tálákà fún èrè láìtọ́. Nítorí náà, bíbà tí àtọlọ́rọ̀ àti tálákà ń ba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àdánidá jẹ́ ń mú kí òṣì máa pọ̀ sí i.

Ìwé Kíkà

Alicia, òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re àárín ìlú kan ní Philippines, wí pé: “Òṣì ló ń mú kí obìnrin kan máa rán ọmọ rẹ̀ lọ máa ṣagbe ní òpópó dípò kó rán an lọ sílé ìwé, nítorí bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, kò ní sí ohun tí wọn á jẹ. Ìyá náà mọ̀ pé àyípoyípo ìṣẹ̀lẹ̀ tó há òun mọ́ ni òun tún rawọ́ lé, ṣùgbọ́n kò mọ ọ̀nà àbáyọ kankan.”

Nǹkan bí 500 mílíọ̀nù ọmọ ni kò sí ilé ìwé tí wọ́n lè lọ. Bílíọ̀nù kan àgbàlagbà ni kò wúlò bí ọ̀ràn bá di ti ìwé kíkà tàbí kíkọ. Láìkàwé, ó ṣòro láti rí iṣẹ́ tó gbámúṣé ṣe. Nítorí náà, òṣì ń fa àìkàwé, ìyẹn náà sì túbọ̀ ń yọrí sí òṣì púpọ̀ sí i.

Ibùgbé

Àìsí ibùgbé wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀, àti ní àwọn mélòó kan tó lọ́rọ̀ pàápàá. Ìròyìn kan sọ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́rin mílíọ̀nù lára àwọn tí ń gbé New York City tó jẹ́ pé ibùgbé tí a pèsè fún àwọn aláìnílé ni wọ́n gbé fún àkókò kan láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá. Yúróòpù pẹ̀lú ní àwọn òtòṣì tirẹ̀. Ní London, nǹkan bí 400,000 ló ti forúkọ sílẹ̀ bí aláìnílé. Ní ilẹ̀ Faransé, ìlàjì mílíọ̀nù ènìyàn ni kò nílé.

Ipò náà burú gan-an jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àwọn ènìyàn ń wọ́ lọ sí àwọn ìlú nítorí wọ́n rò pé oúnjẹ àti iṣẹ́ wà, ìgbésí ayé sì rọ̀ sọ̀mù níbẹ̀. Ní àwọn ìlú kan, ó lé ní ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń gbébẹ̀ tí ń gbé ilé onípákó tí wọ́n kọ́ fún àwọn òtòṣì tàbí nínú àgbègbè onílé-ahẹrẹpẹ tí èrò pọ̀ yamùrá. Nípa bẹ́ẹ̀, òṣì tó wà ní àrọko ń dá kún òṣì tó wà nígboro.

Iye Ènìyàn

Iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i ló ń mú kí ipò wọ̀nyí túbọ̀ burú sí i. Iye ènìyàn ti ju ìlọ́po méjì lọ lágbàáyé láàárín ọdún 45 tó kọjá. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fojú bù ú pé iye náà yóò ti ròkè dé bílíọ̀nù 6.2 nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000, yóò sì ti di bílíọ̀nù 9.8 nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2050. Àwọn àgbègbè tó tòṣì jù lọ lágbàáyé ni iye ènìyàn ti ń yára pọ̀ jù lọ. Lára nǹkan bí 90 mílíọ̀nù ọmọ tí a bí ní 1995, a bí mílíọ̀nù 85 ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lè gbọ́ bùkátà wọn.

Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé aráyé yóò wá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lójijì láti kásẹ̀ òṣì nílẹ̀ láéláé nípa yíyanjú ìṣòro ebi, àìsàn, àìríṣẹ́ṣe, bíba àyíká jẹ́, àìkàwé, àìsí ibùgbé, àti ogun? Ó ṣeé ṣe kí o má gbà bẹ́ẹ̀.

Ǹjẹ́ ìyẹn túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan? Rárá, nítorí ojútùú náà ti sún mọ́lé, ó sì dájú pé yóò dé. Àmọ́, kò lè ti ọwọ́ ènìyàn wá. Báwo wá ni yóò ṣe wá? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn sì ńkọ́ pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo”?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Òtòṣì Jù Lọ Láàárín Àwọn Òtòṣì

Ní 1971, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣẹ̀dá àpólà ọ̀rọ̀ náà, “àwọn orílẹ̀-èdè tí kò gòkè àgbà rárá” láti fi ṣàpèjúwe “àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tòṣì jù, tí ètò ọrọ̀ ajé wọn kò sì dúró dáadáa nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Nígbà yẹn, irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ jẹ́ 21. Nísinsìnyí, wọ́n jẹ́ 48, 33 sì wà ní Áfíríkà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ àkókò, wọ́n sí ń gba owó kékeré

[Credit Line]

Godo-Foto

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Afẹ́ àti òṣì wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń gbé ibùgbé tí kò gbámúṣé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́