ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 10/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
    Jí!—1998
  • Ìhìn Rere fún Àwọn Òtòṣì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 10/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ǹjẹ́ ìṣẹ́ àti òṣì lè dópin láyé?

Obìnrin kan di abọ́ òfìfo mú, ó sì gbá ọmọbìnrin kékeré kan mọ́ra

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì?—Mátíù 6:9, 10.

Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù ló ń kú lọ́dọọdún nítorí pé wọn kì í jẹunre kánú, wọn kò sì rówó tọ́jú ara wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan rí towó ṣe, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ tálákà paraku. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn òtòṣì ti wà.—Ka Jòhánù 12:8.

Kí ìṣẹ́ àti òṣì tó lè dópin, a máa nílò ìjọba kan tó máa lè pín nǹkan lọ́gbọọgba, tí ìka kan kò sì ní gùn ju ọ̀kan lọ. Irú ìjọba yìí tún máa ní láti fòpin sí ogun, torí ogun ló sábà máa ń fa òṣì. Ọlọ́run sì ti ṣèlérí pé òun máa mú ìjọba yìí wá.—Ka Dáníẹ́lì 2:44.

Ta ló lè fòpin sí ìṣẹ́ àti òṣì?

Ọlọ́run tí yan Jésù ọmọ rẹ̀ láti ṣàkóso gbogbo ayé. (Sáàmù 2:4-8) Jésù máa gba àwọn òtòṣì lọ́wọ́ ìnilára àti ìwà ipá.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.

Jésù tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlááfíà,” máa mú kí àlááfíà àti ààbò wà kárí ayé. Nígbà náà, gbogbo èèyàn máa ní ilé tara wọn, wọ́n á máa ṣiṣẹ́ tó gbádùn mọ́ wọn, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ sì máa wà.—Ka Aísáyà 9:6, 7; 65:21-23.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 8 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

Also available at www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́