ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/8 ojú ìwé 8-11
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Òfin Mósè Sọ Nípa Ipò Òṣì
  • Jésù Bìkítà fún Àwọn Òtòṣì
  • Ààbò Nísinsìnyí
  • Kò Ní Wà Títí Láé
  • Máa Ṣàánú Àwọn Tálákà Bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 6/8 ojú ìwé 8-11

Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́

KÍ NI Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo”? (Mátíù 26:11) Ṣé ó ní in lọ́kàn pé òṣì yóò máa wà lọ títí láé láìsí ojútùú kankan ni?

Jésù mọ̀ pé òṣì yóò máa wà títí di ìgbà tí ètò ìsinsìnyí tí ènìyàn ti ń ṣàkoso, kò bá sí mọ́. Ó mọ̀ pé oríṣi ìjọba ènìyàn tàbí ètò ọrọ̀ ajé tàbí ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà èyíkéyìí kò lè mú un kúrò pátápátá. Ìtàn àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn sì jẹ́rìí sí èyí.

Jálẹ̀jálẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ènìyàn ti wà, wọ́n ti dán gbogbo oríṣi ìjọba àti gbogbo oríṣi ètò ọrọ̀ ajé àti ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wò, síbẹ̀, òṣì ṣì ń bá wọn fínra. Ní tòótọ́, láìka ìtẹ̀síwájú tí a ti ṣe ní ìhà sáyẹ́ǹsì, iṣẹ́, àti ìṣègùn sí, òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé iye àwọn ènìyàn tí òṣì ń gbé dè kárí ayé ń pọ̀ sí i ni.

Jésù mọ àwọn kókó ohun tí ń fa ipò òṣì dunjú, bí ìyàn, ọ̀dá, ẹgbẹ́ ogun ọ̀tá tí ń dó tini, ìjọba búburú, ṣíṣe ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè báṣubàṣu, àwọn ọlọ́lá àti alágbára tí ń ni àwọn tálákà àti aláìlágbára lára, ìjàǹbá àti àìsàn, àwọn ọkọ tí ń fi àwọn ọmọ aláìníbaba àti àwọn opó tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú. Síwájú sí i, ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn lè fọwọ́ ara wọn fa òṣì fún ara wọn àti ìdílé wọn nípa àwọn àṣà burúkú bí ìwà ọ̀lẹ, ìmutípara, tẹ́tẹ́ títa, àti ìjoògùnyó.

Nítorí náà, nígbà tí Jésù wí pé “ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé agbára ẹnikẹ́ni nínú ayé yìí kò lè ká mímú ipò òṣì kúrò. Ó ní in lọ́kàn pé, àwọn òtòṣì yóò máa wà títí di ìgbà tí ètò ìsinsìnyí tí ènìyàn ti ń ṣàkóso, kò bá sí mọ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì jẹ́ ìṣòro tó ti wà tipẹ́, kò yẹ kí a parí èrò sí pé Jésù tàbí Baba rẹ̀ ọ̀run kò mọ ipò àwọn òtòṣì lára. Bákan náà ni kò yẹ kí a túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn sí pé òṣì yóò máa wà títí láé. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn náà mú kí èyí ṣe kedere.

Ohun Tí Òfin Mósè Sọ Nípa Ipò Òṣì

Bí àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì nípasẹ̀ Mósè. Ìpèsè kan nínú Òfin náà ni pé, a pín ogún ilẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Kénáánì. (Diutarónómì 11:8-15; 19:14) Àwọn ọmọ Léfì nìkan ni kò gba ogún ilẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, nítorí iṣẹ́ àkànṣe tí wọ́n ní láti ṣe nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá àwọn irè ilẹ̀ náà láti fi gbọ́ bùkátà wọn.—Númérì 18:20, 21, 24.

Síwájú sí i, òfin ogún jíjẹ lábẹ́ Òfin Mósè mú un dájú pé ilẹ̀ náà yóò máa jẹ́ ti ìdílé tàbí ẹ̀yà tí a fi fún títí lọ. (Númérì 27:8-11) Kódà, bí ẹnì kan bá ta ilẹ̀ rẹ̀, kò lè jẹ́ ti ẹni tó rà á títí gbére. Bí àkókò ti ń lọ, a óò dá a padà fún ìdílé ẹni tó tà á náà.

Ní ti àwọn tí wọ́n di òtòṣì nítorí àwọn ìdí mìíràn, bí lílo ilẹ̀ wọn nílòkulò tàbí níná ìná àpà, Òfin náà fún wọn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pèéṣẹ́ ohun jíjẹ nínú àwọn oko, nínú àwọn ọgbà eléso, àti nínú àwọn ọgbà àjàrà àwọn ẹlòmíràn. (Léfítíkù 23:22) Síwájú sí i, ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ṣaláìní lè yáwó láìnísan èlé lórí rẹ̀. Dájúdájú, a retí pé kí a ní ẹ̀mí ọ̀làwọ́ fún àwọn aláìní.—Ẹ́kísódù 22:25.

Jésù Bìkítà fún Àwọn Òtòṣì

Nígbà tí Jésù wáyé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, ó ń fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí ó ti kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀, Jèhófà, hàn nìṣó. Jésù tìkára rẹ̀ fi ìfẹ́ hàn fún àwọn tí wọ́n ṣaláìní nǹkan ti ara. Òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jùmọ̀ ní àpò kan tí wọ́n ti ń mú ohun tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣaláìní.—Jòhánù 12:5-8.

Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn Kristẹni fi irú ìbìkítà kan náà hàn fún àwọn aláìní nígbà tí wọ́n ṣèrànwọ́ ní ti ohun ìní fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí tí kò ní ànító. (Róòmù 15:26) Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ kan náà hàn sí ara wọn lónìí.

Dájúdájú, nígbà kan náà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa níní ẹ̀mí ìyọ́nú fún àwọn tí ayé ń ni lára, ó tún dẹ́bi fún àwọn kan tí ń ‘jẹ ẹran ara àwọn tìkára wọn,’ nítorí pé wọ́n yọ̀lẹ. (Oníwàásù 4:1, 5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” (2 Tẹsalóníkà 3:10) Bákan náà, àwọn tí ń fowó ṣòfò lórí àwọn àṣà bí ìjoògùnyó, tábà mímu, tàbí àmujù ọtí líle lè bá ara wọn ní ipò òṣì. Èyí jẹ́ ìyọrísí ìwàkiwà tiwọn fúnra wọn; ní gidi, wọ́n “ń ká ohun tí wọ́n ti fúnrúgbìn.”—Gálátíà 6:7.

Ààbò Nísinsìnyí

Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ń pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí ipò àwọn tí ó bá ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Nínú Sáàmù 37:25, Dáfídì sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” A kò ṣèlérí fún àwọn olódodo pé wọn yóò ní ọrọ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé, Ọlọ́run yóò rí i dájú pé wọ́n ní ànító ohun ìní tí wọn yóò fi gbọ́ bùkátà. Ẹsẹ 28 nínú sáàmù kan náà sì sọ pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”

Nígbà tí Jésù wà láyé, bíbìkítà tí ó bìkítà fún àwọn aláìní kò mọ síbi ríràn wọ́n lọ́wọ́ ní ti ohun ìní nìkan. Ó mú kí ó dá wọn lójú pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń tiraka láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò rí sí i pé, ó kéré tán, wọ́n ń rí àwọn ohun tí kò ṣeé máà ní fún wọn, nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Jésù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé:

“Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? . . . Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ti ọ̀ràn ti aṣọ, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣàníyàn? Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Sólómọ́nì pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. Wàyí o, bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò ní ọ̀la, òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré? Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Mátíù 6:26-32.

Jésù parí ọ̀rọ̀ nípa rírọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Ẹ wo ìṣírí tí èyí jẹ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ òtòṣì, ṣùgbọ́n tí wọn ń gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run! Ẹ tún kíyè sí i pé Jésù fi hàn pé, Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù mọ̀ pé, nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run láti ọ̀run bá gba àkóso gbogbo ilẹ̀ ayé pátá, nígbà náà nìkan ni a óò mú òṣì kúrò pátápátá.

Kò Ní Wà Títí Láé

Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù fúnni ní ìrètí àgbàyanu nípa ọjọ́ ọ̀la. Nítorí náà, nígbà tí ó wí pé “ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo,” ó ń tọ́ka sí ìgbésí ayé lábẹ́ ètò ìsinsìnyí tí ènìyàn ti ń ṣàkóso. Kò tọ́ka sí ìgbésí ayé ọjọ́ iwájú lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run láti ọ̀run. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn ọlọ́kàn tútù kì yóò ṣègbé láé.” (Sáàmù 9:18) Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run kò sì ní fàyè gba ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbìyànjú láti rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ tí ó sì ń fẹ́ ni wọ́n lára.

Jésù fi ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ṣe lájorí ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 4:17) Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba yẹn, ipò àwọn nǹkan lórí ilẹ̀ ayé yóò rí bí ti ọ̀run gẹ́lẹ́. Ìdí nìyẹn tí ó fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.

Báwo ni ìyẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Ète Ọlọ́run ni láti mú gbogbo ètò ìṣàkóso ènìyàn ti ìsinsìnyí kúrò lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, kí ó sì fi ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ ọ̀run rọ́pò rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 wí pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba [tí ń bẹ nísinsìnyí] wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn [kì í ṣe ìṣàkóso ènìyàn mọ́]. Yóò fọ́ ìjọba [tó wà nísinsìnyí] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Nínú ayé tuntun tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run nígbà náà, a óò wá sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di párádísè tí nǹkan gbé wà lọ́pọ̀ yanturu, láìsí àmì ipò òṣì kankan. Kíyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ díẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, nípa àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ nígbà náà:

“Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn . . . àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn.” (Aísáyà 25:6) “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) “Ọ̀yamùúmùú òjò ìbùkún yóò wà. Igi pápá yóò sì mú èso rẹ̀ wá, ilẹ̀ náà yóò sì mú èso rẹ̀ wá, wọn yóò sì wà lórí ilẹ̀ wọn ní ààbò ní ti tòótọ́.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:26, 27) “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.” (Sáàmù 67:6) “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”—Aísáyà 35:1.

Síwájú sí i, Míkà 4:4 ṣèlérí pé: “Wọn yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” Olúkúlùkù yóò ní ilé tirẹ̀: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn . . . Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé.” (Aísáyà 65:21, 22) Abájọ tí Jésù fi lè ṣèlérí fún àwọn tó bá gba ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbọ́ pé: “[Ẹ̀yin] yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”!—Lúùkù 23:43.

Ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kọ́ni kedere pé ipò òṣì yóò dópin pátápátá. Àkókò yẹn sì ti dé tán, nítorí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ayé yìí ti wà nínú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” rẹ̀ báyìí, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ti wà. (2 Tímótì 3:1-5, 13) A óò mú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí kúrò láéláé láìpẹ́, ipò òṣì yóò sì kọjá lọ pátápátá—kì í ṣe nípa àwọn ìsapá ènìyàn bí kò ṣe nípa dídá tí Ọlọ́run yóò dá sí i. Ọba náà, Jésù Kristi, “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, gbogbo ènìyàn yóò ní ibùgbé tó dára àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nínú ayè tuntun náà, kò ní sí àwọn ọmọdé tí ebi ń pa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́