ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òtòṣì
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Lè Kojú Ipò Òṣì
  • Níkẹyìn, Kò Sí Òsì Mọ́!
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
    Jí!—1998
  • Máa Ṣàánú Àwọn Tálákà Bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ipò Òṣì Bó Ṣe Máa Dópin Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 5/1 ojú ìwé 4-7

Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!

“ẸMÁ bẹ̀rù, nitori, wò ó! emi ń polongo fún yín ìhìnrere ti ìdùnnú-ayọ̀ ńlá kan tí gbogbo awọn ènìyàn yoo ní.” (Luku 2:10) Àwọn ọ̀rọ̀ rírunisókè wọ̀nyí ni àwọn olùṣọ́ àgùtàn tí ń bẹ nítòsí Betlehemu gbọ́ ní òru ọjọ́ tí a bí Jesu. Ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo yẹn, Jesu gbé ìtẹnumọ́ ńláǹlà karí “ìhìnrere” ní àkókò iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Lónìí, nígbà tí a gbáralé owó gan-an láti bójútó àwọn àìní wa, báwo ni ìhìnrere nípa Jesu ṣe lè ṣe wa láǹfààní?

Jesu Kristi polongo “ìhìnrere fún awọn òtòṣì.” (Luku 4:18) Gẹ́gẹ́ bí Matteu 9:35 ti sọ, “Jesu sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n ninu ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo awọn ìlú-ńlá ati awọn abúlé, ó ń kọ́ni ninu awọn sinagọgu wọn ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba naa.” Ní pàtàkì ni ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ ń fún àwọn tí òṣì ń ta ní ìṣírí. “Nígbà tí ó rí awọn ogunlọ́gọ̀ àánú wọ́n ṣe é, nitori a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” (Matteu 9:36) Ní tòótọ́, Jesu wí pé, “Ẹ̀yin ní awọn òtòṣì nígbà gbogbo pẹlu yín,” ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò níláti mú wa parí èrò sí pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn aláìní. (Johannu 12:8) Bí ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ti ìsinsìnyí bá ṣì ń bá a lọ, àwọn òtòṣì yóò ṣì wà, láìka ohun tí ó lè fa ìṣòro wọn sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò ṣá jíjẹ́ tí òṣì jẹ́ òtítọ́ gidi tì, ṣùgbọ́n kò pe àfiyèsí púpọ̀ sórí àwọn apá tí kò báradé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pèsè ìrànwọ́ láti kojú àwọn àníyàn ìgbésí-ayé fún àwọn òtòṣì.

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òtòṣì

Lọ́nà tí ó pe àfiyèsí, a ti sọ ọ́ pé: “Ìnira títóbi jùlọ tí ó lè débá ẹnì kan ni kí ó mọ̀ pé kò sí ẹnì kan tí ó bìkítà tàbí lóye òun.” Síbẹ̀, láìka pé àwọn tí ó pọ̀ jùlọ kò ní àánú sí, ìhìnrere ṣì wà fún àwọn òtòṣì—ní ìsinsìnyí àti ní ọjọ́ ọ̀la.

Ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ríran àwọn òtòṣì lọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, àwọn kan gbàgbọ́ pé “àwọn ènìyàn nínú ẹgbẹ́ àwùjọ máa ń jìjàdù láti lè wàláàyè àwọn . . . ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n yọrí-ọlá jù sì ń túbọ̀ ní agbára àti ọrọ̀ síi.” Àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àbá èrò-orí yìí, tí a pè ní àbá èrò-orí Darwin nípa ìdàgbàsókè ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, lè máa wo àwọn òtòṣì gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlẹ lásán tàbí onínàá-àpà. Síbẹ̀, àwọn lébìrà ìgbèríko, àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣí káàkiri, àti àwọn mìíràn, láìka bí owó tí wọ́n ń gbà ti kéré tó, máa ń ṣiṣẹ́ kára lọ́pọ̀ ìgbà láti bọ́ àwọn ìdílé wọn.

Òṣì wọ́pọ̀ gidigidi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òtòṣì—àwọn tí wọ́n pọ̀ jùlọ—ni a kò mú kí wọ́n nímọ̀lára pé wọ́n jẹ́ aláìṣàṣeyọrí. Síbẹ̀síbẹ̀, ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ àwọn ènìyàn tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún ń gbé láàárín ipò òṣì náà. Àwọn ilé títunilára, tí ó rí kàǹkà-kàǹkà wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ilé ẹgẹrẹmìtì tí ó fún pọ̀ gádígádí, tí ó rí wúruwùru. Àwọn ènìyàn tí a ń san owó tí ó jọjú fún ń wa àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn láàárín òpópónà tí àwọn tí kò-rí-bá-ti-ṣé àti aláìníṣẹ́lọ́wọ́ kún fọ́fọ́. Ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ àwọn òtòṣì máa ń nímọ̀lára ìṣòro wọn pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn. Òtítọ́ ni ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé, “Kì í ṣe àìjẹunrekánú, ilé jákujàku, àti àìsí ìtọ́jú ìṣègùn tí ó gbámúṣé nìkan ni ohun tí ń jẹ àwọn òtòṣì níyà, ṣùgbọ́n àníyàn ìgbà gbogbo nípa ipò wọn tún ń dákún un. Nítorí àìrí iṣẹ́ tí ó dára kí wọ́n sì máa ṣe é nìṣó, wọ́n ń pàdánù gbogbo ìmọ̀lára iyì àti ọ̀wọ̀ ara-ẹni.” Nígbà náà, báwo ni àwọn kan tí wọ́n tòṣì gidigidi ṣe ń kojú ipò wọn? Kí ni ìhìnrere nípa Jesu níí ṣe pẹ̀lú kíkojú ipò-ọ̀ràn wọn?

Lákọ̀ọ́kọ́, rántí pé ìwà òmùgọ̀ lè mú kí òṣì burú síi. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò. Valdecir jẹ́wọ́ pé nígbà tí ó jẹ́ pé aya àti àwọn ọmọ òun kéékèèké kò ní ohun tí ó pọ̀ tó láti jẹ, òun ń fi owó ṣòfò bí òun ti ń gbé ìgbésí-ayé oníwà pálapàla nìṣó. Ó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo níṣẹ́ lọ́wọ́, èmi kì í ní owó kankan fún ìdílé mi, ṣùgbọ́n mo máa ń ní onírúurú ìwé lọ́tìrì nínú àpò mi.” Milton, pàdánù òwò àti àwọn 23 tí ó gbà síṣẹ́, nítorí ọtí àmujù àti sìgá. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ òru ní mo máa ń wà ní òpópó-ọ̀nà, tí n kò ní lè lọ sílé, ìdílé mi sì jìyà gidigidi nítorí mi.”

João pẹ̀lú fi owó oṣù rẹ̀ ṣòfò lórí ìwà abèṣe. “Ọ̀pọ̀ òru ni n kì í sí nílé. Gbogbo ohun tí mo ń gbà kò tó láti ná lórí ìwà abèṣe àti ìṣekúṣe. Ipò náà kò báradé mọ́, aya mi sì fẹ́ kí a pínyà.” Ní àfikún sí ìṣòro ìṣúnná owó àti ti ìdílé, àwọn mìíràn tún wà. Ó sọ pé: “Mo ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí àti aládùúgbò, èmi gan-an sì ní ìṣòro ni ibi iṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìgbà gbogbo ni iṣẹ́ máa ń bọ́ lọ́wọ́ mi.” Júlio jẹ́ ajoògùnyó. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí owó oṣù mi kò ti tó láti máa bá ìwà ìjoògùnyó mi nìṣó, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ títa oògùn líle kí n má baà máa ra oògùn mọ́.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé òtòṣì ọlọ́mọ mẹ́jọ ni a ti tọ́ ọ dàgbà, José fẹ́ láti ni nǹkan fún ara rẹ̀. Ní ríronú pé kò sí ohun kankan tí òun lè pàdánù, òun àti àwọn ọ̀dọ́ mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí ja àwọn ènìyàn lólè. Nítorí àìnírètí, ọ̀dọ́ mìíràn di mẹ́ḿbà àjọ-ìpàǹpá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aluni-Lálùbolẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí púpọ̀ jùlọ lára wa ti jẹ́ òtòṣì, a máa ń rí ìtẹ́lọ́rùn nínú bíba nǹkan jẹ àti kíkọlu àwọn ènìyàn.”

Síbẹ̀, lónìí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí àti ìdílé wọn kò jìyà lílégbákan mọ́ nítorí àìní ohun kòṣeémánìí tàbí ìmọ̀lára ìbànújẹ́ àti ìbínú. Wọn kì í ṣe aláìlólùrànlọ́wọ́ tàbí aláìnírètí mọ́. Èéṣe? Nítorí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere náà tí Jesu wàásù rẹ̀. Wọ́n fi ìmọ̀ràn Bibeli sílò wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ẹni tí ó ní irú ọkàn kan náà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n sì kọ́ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì gidigidi nípa ọrọ̀ àti òṣì.

Ìrànlọ́wọ́ Láti Lè Kojú Ipò Òṣì

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé bí a bá fi àwọn ìlànà Bibeli sílò, a lè dín ipa tí òṣì lè ní kù. Bibeli dẹ́bi fún ìwà pálapàla, ìmùtípara, tẹ́tẹ́ títa, àti oògùn ìlòkulò. (1 Korinti 6:9, 10) Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń náni lówó. Wọ́n lè sọ ọlọ́rọ̀ di òtòṣì, kí òtòṣì sì túbọ̀ tòṣì síi. Pípa àwọn ìwà abèṣe wọ̀nyí àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ tì ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ipò ọrọ̀-ajé ìdílé sunwọ̀n síi.

Èkejì, wọ́n rí i pé àwọn nǹkan mìíràn wà nínú ìgbèsí-ayé tí ó ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí gbé ojú-ìwòye tí ó wàdéédéé kalẹ̀: “Ààbò ni ọgbọ́n, àní bí owó ti jẹ́ ààbò: ṣùgbọ́n èrè ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n fi ìyè fún àwọn tí ó ní in.” (Oniwasu 7:12) Bẹ́ẹ̀ni, owó ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí a gbékarí Bibeli àti ìmọ̀ ète Ọlọrun wúlò gidigidi. Ní tòótọ́, lójú ẹni tí kò gbọ́n, níní owó púpọ̀ jù lè jẹ́ ìnira gidigidi bíi ṣíṣàì ní tó. Òǹkọ̀wé Bibeli náà gbàdúrà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé: “Máṣe fún mi ní òṣì, máṣe fún mi ní ọrọ̀; fi oúnjẹ tí ó tó fún mi bọ́ mi. Kí èmi kí ó má baà yó jù, kí èmi kí ó má sì sẹ́ ọ, pé ta ni Oluwa? tàbí kí èmi má baà tòṣì, kí èmi sì jalè, kí èmi sì ṣẹ̀ sí orúkọ Ọlọrun mi.”—Owe 30:8, 9.

Ẹ̀kẹta, wọ́n rí i pé bí ẹnì kan bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìhìnrere tí Jesu wàásù, kò yẹ kí ó nímọ̀lára pé a ṣá òun tì láéláé. Ìhìnrere náà níí ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọrun. Ìhìn-iṣẹ́ náà ni a pè ní “ìhìnrere ìjọba,” ní ọjọ́ wa a sì ti ń wàásù rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé. (Matteu 24:14) Jesu sọ fún wa pé a óò tì wá lẹ́yìn bí a bá fi ìrètí wa sínú Ìjọba yẹn. Ó wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo [Ọlọrun] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọnyi ni a óò sì fi kún un fún yín.” (Matteu 6:33) Ọlọrun kò ṣèlérí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mèremère àti ilé aláruru. Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun kòṣeémánìí nínú ìgbésí-ayé, àwọn nǹkan bí oúnjẹ àti aṣọ. (Matteu 6:31) Ṣùgbọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lónìí lè jẹ́rìí sí i pé ìlérí Jesu ṣeé gbáralé. A kò fi ẹnì kan, àní ẹnì kan tí ó tòṣì gidigidi, sílẹ̀ pátápátá bí ó bá fi Ìjọba náà ṣáájú.

Ẹ̀kẹrin, wọ́n rí i pé ìṣòro ọrọ̀-ajé kì í mú ìbànújẹ́ débá ẹnì kan tí ó bá fi Ìjọba Ọlọrun ṣáájú. Bẹ́ẹ̀ni, ẹni tí ó bá tòṣì níláti ṣiṣẹ́ kára. Ṣùgbọ́n bí ó bá ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun, ó ní ipò-ìbátan aláǹfààní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹni tí Bibeli sọ nípa rẹ̀ pé: “Kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni kò kórìíra ìpọ́njú àwọn olùpọ́njú; bẹ́ẹ̀ ni kò pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò lára rẹ̀; ṣùgbọ́n nígbà tí ó kígbe pè é, ó gbọ́.” (Orin Dafidi 22:24) Ní àfikún síi, ẹnì kan tí ó jẹ́ òtòṣì ní ìrànlọ́wọ́ ní kíkojú ìṣòro ìgbésí-ayé. Ó ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ó sì ní ìmọ̀ àti ìgbọ́kànlé nínú ìfẹ́-inú Jehofa tí ó ṣípayá. Àwọn nǹkan wọ̀nyí “ju wúrà dáradára púpọ̀.”—Orin Dafidi 19:10.

Níkẹyìn, Kò Sí Òsì Mọ́!

Lákòótán, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n kọbiara sí ìhìnrere náà ń kẹ́kọ̀ọ́ pé Jehofa Ọlọrun ti pète láti yanjú ìṣòro òṣì títí láé fáàbàdà nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Bibeli ṣèlérí pé: “A kì yóò gbàgbé àwọn aláìní láéláé: àbá àwọn tálákà kì yóò ṣègbé láéláé.” (Orin Dafidi 9:18) Ìjọba náà jẹ́ ìṣàkóso gidi, tí a gbé kalẹ̀ ní àwọn ọ̀run pẹ̀lú Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso. Láìpẹ́, Ìjọba yẹn yóò rọ́pò ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn ní dídarí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn. (Danieli 2:44) Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ó ti gun orí ìtẹ́, Jesu ‘yóò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà-agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ̀ wọn ní ojú rẹ̀.’—Orin Dafidi 72:13, 14.

Ní fífojúsọ́nà fún àkókò yẹn, Mika 4:3, 4 sọ pé: “Wọn óò jókòó olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnì kan kì yóò sì dáyà fò wọ́n: nítorí ẹnu Oluwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ti sọ ọ́.” Àwọn wo ni a ń sọ̀rọ̀ nípa wọn níhìn-ín? Họ́wù, gbogbo àwọn tí wọ́n bá tẹríba fún Ìjọba Ọlọrun ni. Ìjọba yẹn yóò yanjú gbogbo ìṣòro tí ń pọ́n aráyé lójú—àní ìṣòro àìsàn àti ikú pàápàá. “Òun óò gbé ikú mì láéláé: Oluwa Jehofa yóò nu omijé nù kúrò ni ojú gbogbo ènìyàn.” (Isaiah 25:8; 33:24) Ẹ wo irú ayé tí ó yàtọ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́! Sì rántí pé, a lè ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí wọ̀nyí nítorí pé Ọlọrun fúnra rẹ̀ mí sí wọn. Ó wí pé: “Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ibùgbé àlàáfíà, àti ní ibùgbé ìdánilójú, àti ní ibi ìsinmi ìparọ́rọ́.”—Isaiah 32:18.

Ìgbọ́kànlé nínú Ìjọba Ọlọrun ń borí àìní ọ̀wọ̀ ara-ẹni tí òṣì sábà máa ń mú wá. Kristian òtòṣì kan mọ̀ pé òun ṣe pàtàkì lójú Ọlọrun gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristian kan tí ó lọ́rọ̀ ti ṣe pàtàkì. Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ àwọn méjèèjì bákan náà, àwọn méjèèjì sì ní ìrètí kan náà. Àwọn méjèèjì ń fi pẹ̀lú ìháragàgà fojúsọ́nà fún àkókò náà nígbà tí, òṣì yóò di nǹkan àtijọ́, lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun. Ẹ wo irú àkókò ológo tí ìyẹn yóò jẹ́! Níkẹyìn, ẹnikẹ́ni kì yóò tòṣì mọ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Èéṣe tí o fi ń fi ohun-àmúṣọrọ̀ ṣòfò lórí tẹ́tẹ́ títa, sìgá mímu, ọtí àmujù, oògùn ìlòkulò, tàbí ìgbésí-ayé oníwà pálapàla?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jehofa Ọlọrun yóò yanjú ìṣòro ẹ̀dá ènìyàn nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́