ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Máa Ṣàánú Àwọn Tálákà Bí Jésù Ti Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣàánú Àwọn Tálákà Bí Jésù Ti Ṣe
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Ṣàánú Àwọn Tálákà
  • Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Kò Fọ̀rọ̀ Àwọn Tálákà Ṣeré
  • Ìrànwọ́ Tí Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ń Ṣe Kò Lópin
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
    Jí!—1998
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Káwọn Òtòṣì Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/1 ojú ìwé 4-7

Máa Ṣàánú Àwọn Tálákà Bí Jésù Ti Ṣe

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé àtìgbà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà ni ìṣẹ́ àti ìpọ́njú ti wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin láti dáàbò bo àwọn tálákà àti láti dín ìyà wọn kù, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn ò tẹ̀ lé Òfin náà. (Ámósì 2:6) Wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn tálákà lò kò dára rárá. Ó ní: “Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ń bá ìpètepèrò lílu jìbìtì nìṣó, wọ́n sì ń já nǹkan gbà ní jíjanilólè, wọ́n sì ṣe àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì níkà, wọ́n sì lu àtìpó ní jìbìtì láìsí ìdájọ́ òdodo.”—Ìsíkíẹ́lì 22:29.

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ìṣòro yìí kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Àwọn olórí ìsìn kò bìkítà rárá fáwọn tálákà àtàwọn aláìní. Bíbélì pe àwọn olórí ìsìn wọ̀nyí ní “olùfẹ́ owó” tí wọ́n “jẹ ilé àwọn opó run.” Títẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sì ká wọn lára ju bíbójú tó àwọn arúgbó àtàwọn aláìní lọ. (Lúùkù 16:14; 20:47; Mátíù 15:5, 6) A lè kíyè sí i pé nínú àkàwé Jésù nípa aláàánú ará Samáríà, dípò kí àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan sún mọ́ ọkùnrin kan táwọn ọlọ́ṣà ṣe léṣe kí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n lọ gba ibòmíràn.—Lúùkù 10:30-37.

Jésù Ṣàánú Àwọn Tálákà

Àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere nípa ìgbésí ayé Jésù fi hàn pé ó mọ ìṣòro tó ń bá àwọn tálákà fínra, àánú wọn sì máa ń ṣe é gan-an nítorí ipò àìní tí wọ́n wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Jésù ń gbé tẹ́lẹ̀, ó bọ ara ẹ̀mí sílẹ̀, ó di èèyàn, ‘ó sì wá di òtòṣì nítorí wa.’ (2 Kọ́ríńtì 8:9) Nígbà tí Jésù rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn, “àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Ìtàn Bíbélì tó sọ nípa opó aláìní fi hàn pé owó táṣẹ́rẹ́ tí opó náà fi ṣètọrẹ wú Jésù lórí ju owó ńláńlá táwọn ọlọ́rọ̀ fi ṣètọrẹ lọ, nítorí pé “láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn” ni wọ́n ti mú owó tí wọ́n fi ṣètọrẹ náà. Ohun tí opó náà ṣe wọ Jésù lọ́kàn gan-an nítorí pé “láti inú àìní rẹ̀, [ló ti] sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú” àpótí náà.—Lúùkù 21:4.

Kì í ṣe pé àánú àwọn òtòṣì máa ń ṣe Jésù nìkan ni, ó tún máa ń rí i pé òun ṣe nǹkan kan nípa ìṣòro tí wọ́n ní. Òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní àpótí kan tí wọ́n máa ń fi owó sí láti lè ṣètọrẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìní. (Mátíù 26:6-9; Jòhánù 12:5-8; 13:29) Jésù sọ fún àwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Ó sọ fún ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tó sì tún jẹ́ alákòóso pé: “Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Níwọ̀n bí ọkùnrin yìí kò ti múra tán láti yááfì àwọn ohun ìní rẹ̀, ó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ ju Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ. Ó sì tún fi hàn pé kò ní àwọn ànímọ́ téèyàn gbọ́dọ̀ ní kó tó lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Lúùkù 18:22, 23.

Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Kò Fọ̀rọ̀ Àwọn Tálákà Ṣeré

Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọlẹ́yìn Kristi yòókù kò dáwọ́ dúró láti máa ṣàánú àwọn tálákà tó wà láàárín wọn. Ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣèpàdé pẹ̀lú Jákọ́bù, Pétérù, àti Jòhánù, ó sì bá wọn jíròrò iṣẹ́ ìsìn tó gbà látọ̀dọ̀ Jésù Kristi Olúwa, ìyẹn láti wàásù ìhìn rere. Gbogbo wọn ló jọ gbà pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sọ́dọ̀ “àwọn orílẹ̀-èdè” kí wọ́n sì máa wàásù fáwọn Kèfèrí ní pàtàkì. Àmọ́ Jákọ́bù àtàwọn yòókù rọ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pé kí wọ́n “fi àwọn òtòṣì sọ́kàn.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù sì “fi taratara sakun láti ṣe” nìyẹn.—Gálátíà 2:7-10.

Lákòókò tí Olú Ọba Kíláúdíù ń ṣàkóso, ìyàn kan mú, ìyàn náà sì le gan-an, ọ̀pọ̀ àgbègbè tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso lé lórí ni ìyàn náà sì dé. Àwọn Kristẹni tó wà nílùú Áńtíókù kò fọwọ́ lẹ́rán, wọ́n “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà; èyí ni wọ́n sì ṣe, wọ́n fi í ránṣẹ́ sí àwọn àgbà ọkùnrin láti ọwọ́ Bánábà àti Sọ́ọ̀lù.”—Ìṣe 11:29, 30.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí náà mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ ṣàánú àwọn tálákà àtàwọn aláìní, pàápàá jù lọ, àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn tó jẹ́ aláìní. (Gálátíà 6:10) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1998, ọ̀dá kan tó burú jáì ba ọ̀pọ̀ àgbègbè jẹ́ ní àríwá ìlà oorun ilẹ̀ Brazil. Ọ̀dá náà ba àwọn irè oko bí ìrẹsì, ẹ̀wà, àti àgbàdo jẹ́, ó sì fa ìyàn ní ọ̀pọ̀ àgbègbè náà. Kò tíì sí ìyàn tó burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún títí dìgbà yẹn. Kódà láwọn ibì kan, kò sí omi tó ṣeé mu. Kíákíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti apá ibòmíràn lórílẹ̀-èdè náà ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó ètò ìrànwọ́, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ jọ tí wọ́n sì tún san owó tí yóò kó àwọn ẹrù náà dé ibi tó ń lọ.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣètọrẹ kọ̀wé pé: “A láyọ̀ gan-an pé a lè ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́, àmọ́ ohun tó fún wa láyọ̀ jù ni pé, ó dá wa lójú pé a ti múnú Jèhófà dùn. A ò gbàgbé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jákọ́bù 2:15, 16.” Ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́?”

Nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú São Paulo, eku káká ni arábìnrin tálákà kan tó jẹ́ onítara tó sì tún lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ fi ń gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tálákà ni mí, àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì ti mú kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀ gan-an. Mi ò mọ ohun tí ì bá ti ṣẹlẹ̀ sí mi ká ní kì í ṣe ti àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi tó ń ràn mí lọ́wọ́.” Lákòókò kan, ó pọn dandan kí arábìnrin tó jẹ́ aláápọn yìí ṣe iṣẹ́ abẹ kan, àmọ́ kò ní owó tó máa san fún iṣẹ́ abẹ náà. Lákòókò yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ rẹ̀ dìde ìrànwọ́, wọ́n sì bá a san owó náà. Níbi gbogbo kárí ayé làwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń ṣe irú ìrànwọ́ báyìí fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́.

Àmọ́ bó ti wù kí irú àwọn ìrírí báwọ̀nyí dùn mọ́ni nínú tó, ó dájú pé irú àwọn ìsapá tá a fínnúfíndọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ kò lè mú ipò òṣì kúrò pátápátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìjọba tó lágbára àtàwọn àjọ tó ń ṣèrànwọ́ lágbàáyé ti ṣe àwọn àṣeyọrí díẹ̀, síbẹ̀, kò tíì ṣeé ṣe fún wọn láti mú ìṣòro ipò òṣì tó ti wà látayébáyé yìí kúrò. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè kan tó ń fẹ́ ìdáhùn ni pé, Ọ̀nà wo la máa gbà mú ìṣẹ́ òun òṣì àtàwọn ìṣòro mìíràn tó ń yọ aráyé lẹ́nu kúrò pátápátá?

Ìrànwọ́ Tí Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ń Ṣe Kò Lópin

Àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé gbogbo ìgbà ni Jésù Kristi máa ń ṣe àwọn ohun tó dára fáwọn aláìní tàbí àwọn tó nílò ìrànwọ́ lọ́nà mìíràn. (Mátíù 14:14-21) Àmọ́ iṣẹ́ wo ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́? Nígbà kan, lẹ́yìn tí Jésù ti lo àkókò díẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú.” Kí nìdí tí Jésù fi dáwọ́ ohun tó ń ṣe fáwọn aláìsàn àtàwọn tó jẹ́ aláìní dúró láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ? Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí fún ète yìí [ìyẹn láti wàásù] ni mo ṣe jáde lọ.” (Máàkù 1:38, 39; Lúùkù 4:43) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù fọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣe ohun rere fáwọn aláìní, síbẹ̀ wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ni olórí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.—Máàkù 1:14.

Níwọ̀n bí Bíbélì ti gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ [Jésù] pẹ́kípẹ́kí,” àwọn Kristẹni lónìí ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere, èyí tí wọ́n lè máa tẹ̀ lé láti mọ ohun tó yẹ kí wọ́n fi ṣáájú bí wọ́n ti ń sapá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (1 Pétérù 2:21) Bíi ti Jésù, wọ́n ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù tún ṣe, iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ń fi ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn. (Mátíù 5:14-16; 24:14; 28:19, 20) Àmọ́ o, kí nìdí tó fi jẹ́ pé nínú gbogbo àwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà ran àwọn mìíràn lọ́wọ́, wíwàásù ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kó gbawájú?

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé àwọn èèyàn níbi gbogbo láyé fi hàn pé táwọn èèyàn bá lóye ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n sì fi sílò, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti rí ojútùú sáwọn ìṣòro tó ń yọjú lójoojúmọ́, títí kan ìṣòro ipò òṣì. Yàtọ̀ síyẹn, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ lónìí ń fún àwọn èèyàn ní ìrètí pé ọjọ́ iwájú yóò dára. Ìrètí yìí ń mú kí wọ́n rí i pé ayé dùn, kódà béèyàn tiẹ̀ wà nínú àwọn ìṣòro tó le gan-an pàápàá. (1 Tímótì 4:8) Ìrètí wo nìyẹn?

Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sọ bí ọjọ́ iwájú wa ṣe máa rí, ó mú un dá wa lójú pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Nígbà míì tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ilẹ̀ ayé,” àwọn èèyàn tó ń gbénú rẹ̀ ló ń tọ́ka sí. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Nípa bẹ́ẹ̀, àwùjọ èèyàn kan tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà ni “ayé tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó ń bọ̀ yìí. Síwájú sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ṣèlérí pé lábẹ́ ìṣàkóso Kristi, àwọn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà yóò gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé, wọn yóò sì máa fi ayọ̀ gbé inú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Máàkù 10:30) Gbogbo èèyàn pátá ni irú ọjọ́ ọ̀la tó mìrìngìndìn yìí lè tẹ̀ lọ́wọ́ o, títí kan àwọn tálákà. Nínú “ayé tuntun” yẹn, ipò òṣì yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

BÁWO NI JÉSÙ YÓÒ ṢE “DÁ ÒTÒṢÌ . . . NÍDÈ”?—Sáàmù 72:12

ÌDÁJỌ́ ÒDODO: “Kí ó ṣe ìdájọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn, kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là, kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.” (Sáàmù 72:4) Nígbà tí Kristi bá ń ṣàkóso lé ayé lórí, gbogbo èèyàn ni yóò rí ìdájọ́ òdodo gbà. Kò ní sí ìwà wọ̀bìà mọ́, ìyẹn ohun tó ń sọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ì bá jẹ́ ọlọ́rọ̀ di ẹdun arinlẹ̀.

ÀLÀÁFÍÀ: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.” (Sáàmù 72:7) Ìjà àti ogun táwọn èèyàn ń bára wọn jà ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú ìṣẹ́ àti ìyà tó wà nínú ayé. Kristi yóò mú kí ojúlówó aláfíà wà lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì tipa báyìí mú àwọn ohun tó ń fa ìṣẹ́ àti ìyà kúrò pátápátá.

ÌYỌ́NÚ: “Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.” (Sáàmù 72:12-14) Àwọn táwọn èèyàn ò kà sí, àwọn tálákà, àtàwọn tí àwọn èèyàn ń ni lára, yóò para pọ̀ di ìdílé kan tí wọ́n láyọ̀ tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìṣàkóso Ọba náà, Jésù Kristi.

AÁSÌKÍ: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀.” (Sáàmù 72:16) Nígbà ìṣàkóso Kristi, ọrọ̀ rẹpẹtẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan yóò wà. Àìtó oúnjẹ àti ìyàn tó sábà ń fa ipò òṣì lónìí tó sì ń pọ́n àwọn èèyàn lójú kò ní sí mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Jésù máa ń rí i pé òun ṣe nǹkan kan nípa ìṣòro táwọn tálákà ní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì ń fún àwọn èèyàn ní ìrètí gidi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́