Jẹ́ Káwọn Òtòṣì Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
1 Jésù ò fọ̀ràn àwọn aláìní ṣeré rárá. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu kó lè fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò, ó sì tún mú àwọn aláìsàn lára dá, àmọ́ olórí ohun tó gbájú mọ́ ni bó ṣe máa wàásù “ìhìn rere” fáwọn òtòṣì. (Mát. 11:5) Títí dòní olónìí, iṣẹ́ ìwàásù táwa Kristẹni ń ṣe kò tíì yé ṣàǹfààní fáwọn òtòṣì àtàwọn ẹlòmíì.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
2 Ọ̀nà Àbáyọ Tó Dájú: Àwọn aṣáájú ìsìn sábà máa ń ṣèlérí fáwọn òtòṣì pé nǹkan á ṣẹnuure fún wọn bí wọ́n bá ń dáwó sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Àmọ́, Bíbélì kọ́ni pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa ṣọ̀nà àbáyọ kúrò nínú òṣì tó sì máa yanjú gbogbo ìṣòro ẹ̀dá. (Sm. 9:18; 145:16; Aísá. 65:21-23) Bá a ti ń ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an, ńṣe là ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run.—Mát. 5:3.
3 Nígbà tí Jésù wà láyé, ẹni àbùkù làwọn Farisí ka àwọn òtòṣì sí, wọ́n sì ń fi tẹ̀gàntẹ̀gàn pè wọ́n ní ‘am-ha·’aʹrets, tàbí “àwọn èèyàn ilẹ̀.” Àmọ́, “ẹ̀jẹ̀ wọn” tàbí ẹ̀mí wọn ṣe “iyebíye” lójú Jésù. (Sm. 72:13, 14) A lè fara wé Jésù nípa fífi “ojú rere hàn” sáwọn òtòṣì ká sì tún máa bá wọn kẹ́dùn. (Òwe 14:31) Kò ní dáa ká máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa àwọn aládùúgbò wa tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán fún tàbí ká máa lọ́ra láti wàásù fún wọn. Ó ṣe tán irú àwọn bẹ́ẹ̀ ló ń fetí sí ìwàásù wa.
4 Àkókò Nìyí Láti Ràn Wọ́n Lọ́wọ́: Bá a ti ń kọ́ àwọn òtòṣì ní ìlànà Bíbélì láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, à ń tipa báyìí mú kí ìṣòro àìríná àìrílò tó bá wọn dín kù. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dẹ́bi fún àmupara, tẹ́tẹ́ títa, ìwà ọ̀lẹ, sìgá mímu àtàwọn àṣà míì tó ń sọni di òtòṣì. (Òwe 6:10, 11; 23:21; 2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 5:5) Ìwé Mímọ́ kọ́ wa pé ká jẹ́ aláìlábòsí, ká sì máa ṣiṣẹ́ “tọkàntọkàn,” ìyẹn sì ni ànímọ́ táwọn agbanisíṣẹ́ ń wá. (Kól. 3:22, 23; Héb. 13:18) Kódà, nínú ìwádìí kan, àwọn agbaniṣíṣẹ́ sọ pé ìwà tó máa ń wu àwọn jù lọ lára àwọn tó ń wáṣẹ́ ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin.
5 Ó wu Jèhófà pé kó ṣe nǹkan kan nípa ìyà tó ń jẹ àwọn òtòṣì. Nítorí náà, Jésù Kristi máa tó dá àwọn “òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè.” (Sm. 72:12) Títí dìgbà náà, a láǹfààní láti máa tu àwọn míì nínú nípa wíwàásù ìhìn rere àwọn ohun tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wọn, èyí ò sì yọ àwọn òtòṣì sílẹ̀.