Báwo Ni Àwọn Òtòṣì Yóò Ti Níláti Dúró Pẹ́ Tó?
“Bí ẹgbẹ́ àwùjọ olómìnira kò bá lè ran ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n tòṣì lọ́wọ́, kò lè gba àwọn kéréje tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ là.”—John F. Kennedy.
“ÈMI yóò fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la dára fún gbogbo ẹ̀dá—kí ó má sí òṣì, kí ó má sí ẹnikẹ́ni tí ń sùnta, kí ó jẹ́ paradise!” Báyìí ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún 12 láti São Paulo, Brazil sọ. Ṣùgbọ́n ó ha ṣeé ṣe láti kásẹ̀ òṣì nílẹ̀ bí? Báwo ni àwọn òtòṣì yóò ti níláti dúró pẹ́ tó?
Àwọn kan ka ara wọn sí òtòṣì nítorí pé wọn kò lè ra àwọn nǹkan tí wọ́n ń fẹ́. Síbẹ̀, ronú nípa ìṣòro bíbaninínújẹ́ tí àwọn wọnnì tí òṣì ń ta níti gidi ní. Ìwọ ha lè finúro ìnira àti àìláyọ̀ lílékenkà tí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní? Àwọn kan níláti máa bá àwọn ẹyẹ etíkun àti èkúté jìjàdù, lórí ààtàn bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ kiri! Báwo ni irú òṣì bẹ́ẹ̀ yóò ti fi ìyà jẹ aráyé pẹ́ tó? Ẹ̀bẹ̀ tí Federico Mayor, ọ̀gá-àgbà àjọ UNESCO, (Ètò-Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò-Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà-Ìbílẹ̀) bẹ̀, bá a mu wẹ́kú: “Ẹ jẹ́ kí a jáwọ́ kúrò nínú ìráragba-nǹkan-sí onímàgòmágó yìí tí ń mú kí a máa gba nǹkan tí kò yẹ kí a gbà láyè—ipò òṣì, ebi, àti ìjìyà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá ènìyàn.”
Àlá ire-aásìkí fún gbogbogbòò yóò ha ṣẹ bí? Ìrètí wo ni àwọn òtòṣì ní?
Àǹfààní Wo Ni Ó Wà fún Àwọn Òtòṣì?
Àwọn aṣáájú tí wọ́n lọ́kàn rere ń wéwèé iṣẹ́ púpọ̀ síi, owó oṣù tí ó pọ̀ síi, àwọn ètò amáyédẹrùn, àti pípín ilẹ̀-ọ̀gbìn karí tí a mú sunwọ̀n síi. Wọ́n lè fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ààrẹ United States tẹ́lẹ̀rí John F. Kennedy tí ó sọ pé: “Bí ẹgbẹ́ àwùjọ olómìnira kò bá lè ran ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n tòṣì lọ́wọ́, kò lè gba àwọn kéréje tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ là.” Bí ó ti wù kí ó rí, èrò rere kò tó láti mú òṣì kúrò. Fún àpẹẹrẹ, ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé yóò ha ran àwọn òtòṣì ní gbogbogbòò lọ́wọ́ bí? Ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Olórí India tẹ́lẹ̀rí Jawaharlal Nehru sọ pé: “Bí a kò bá ṣàkóso àwọn ipá ẹgbẹ́ àwùjọ olówò bòḿbàtà, níṣe ni àwọn ọlọ́rọ̀ yóò máa lọ́rọ̀ síi tí àwọn òtòṣì yóò sì máa tòṣì síi.” Bí ó ti wù kí ó rí, yàtọ̀ sí ìnira àti ṣíṣàìní àwọn ohun kòṣeémánìí, ìmọ̀lára pé wọn kò jámọ́ nǹkankan tún ń dákún ìnira àwọn òtòṣì. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ha lè ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ láti borí ìmọ̀lára àìlólùrànlọ́wọ́ àti àìnírètí bí?
Dájúdájú, púpọ̀ lára àwọn òtòṣì ti kọ́ láti kojú òṣì kí wọ́n sì borí ìmọ̀lára iyì-ara-ẹni tí ó dínkù lójú ìṣòro ńláǹlà, irú bí owó-ọjà tí ń ròkè lálá àti àìníṣẹ́lọ́wọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyàn, àìnílélórí, àti ìṣẹ́ ni a óò fàtu pátápátá. Èyí ha yà ọ lẹ́nu bí? A késí ọ láti ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e: “Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!”