Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 8
Orin 56
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! October–Decemebr. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! October–December.) Ìwé ìròyìn méjèèjì ni kó o fún onílé lẹ́ẹ̀kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ọ̀kan nínú ẹ̀ ni àlàyé ẹ máa dá lé.
20 min: Ètò Jèhófà Ni Kó O Dìrọ̀ Mọ́. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 17.
15 min: “Wíwàásù Láìsọ̀rọ̀.”a Jẹ́ káwọn akéde tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí báwọn ṣe kíyè sí ìwà rere àwọn èèyàn Ọlọ́run tí ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Orin 10
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 15
Orin 67
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: Ǹjẹ́ Òtítọ́ Ń So Èso Nínú Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́, February 1, 2005, ojú ìwé 28 sí 30. Fi àlàyé kún un nípa bá a ṣe ṣètò àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọ́nà tí wọ́n á fi ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀, bí irú èyí tó wà ní orí 1, ìpínrọ̀ 19; orí 2, ìpínrọ̀ 4; orí 3, ìpínrọ̀ 24; àti orí 4, ìpínrọ̀ 18. Gba àwọn akéde níyànjú láti lo ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwòrán, àpótí àtàwọn ìbéèrè tó wà fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé náà.
15 min: Ǹjẹ́ O Rántí? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́, August 15, 2007, ojú ìwé 19.
Orin 151
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 22
Orin 175
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! October–December. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! October–December.)
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ìmọ́lẹ̀. Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. A ti fi òkùnkùn ayé yìí sílẹ̀, a sì ti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà máa darí wa. (Éfé. 5:8, 9) Èyí ti jẹ́ kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i, kó sì nítumọ̀. (1 Tím. 4:8) Ìmọ́lẹ̀ yìí náà ló jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Róòmù 15:4) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ti kojú àwọn ìṣòro tó nira, kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, tí wọ́n sì ti borí àwọn ìṣòro náà, síbẹ̀ tí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ò bà jẹ́. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n dojú kọ nígbà tí wọ́n fẹ́ wá sínú òtítọ́? Báwo ni wọ́n ṣe borí àwọn ìṣòro náà? Ọ̀nà wo ni nǹkan gbà sunwọ̀n sí i fún wọn báyìí? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró láìyẹsẹ̀ nínú òtítọ́? Kádìí ọ̀rọ̀ rẹ nípa fífún àwùjọ níṣìírí pé kí wọ́n jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà máa sunwọ̀n sí i, kí wọ́n sì máa fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fáwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Jèhófà ń fi kọ́ wa.—2 Pét. 1:5-8.
Orin 23
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 29
Orin 124
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù October sílẹ̀. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò ní oṣù November, kó o sì ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀.
15 min: Ní Àfojúsùn Tó Jẹ Mọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run Kó O Lè Fìyìn fún Ẹlẹ́dàá Rẹ. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́, July 15, 2004, ojú ìwé 21 sí 23. Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn àfojúsùn tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tí wọ́n ní àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe kọ́wọ́ wọn bàa lè tẹ̀ ẹ́. O lè ti sọ fẹ́nì kan tàbí ẹni méjì kó tó dìgbà tó o máa ṣiṣẹ́ yìí pé kí wọ́n múra àwọn àlàyé kan sílẹ̀.
20 min: “Jẹ́ Káwọn Òtòṣì Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, fi àlàyé kún un látinú Jí!, September 8, 2003, ojú ìwé 24 sí 25.
Orin 7
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 5
Orin 156
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Bó O Ṣe Lè Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Yọ Àwọn Ọmọ Rẹ Nínú Ewu. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́, January 1, 2005, ojú ìwé 23 sí 27.
20 min: “Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Fúnra Wa Níṣìírí.”c Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe rí ìṣírí gbà látọ̀dọ̀ alábòójútó arìnrìn-àjò nígbà tó bẹ ìjọ yín wò. O lè ti sọ fún ẹnì kan tàbí ẹni méjì tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe rí ìṣírí gbà.
Orin 192
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.