Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 24. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Àwọn wo ni ó “hó yèè nínú ìyìn” nígbà tí Ọlọ́run “fi òkúta igun” ilẹ̀ ayé “lélẹ̀”? (Jóòbù 38:4-7)
2. Kí ni kò ní ṣẹlẹ̀ láé sí Ìjọba Ọlọ́run? (Dáníẹ́lì 2:44)
3. Kí ni Dáfídì fi ara rẹ̀ wé láti fi han Sọ́ọ̀lù pé kò já mọ́ nǹkan kan fún Sọ́ọ̀lù láti máa lépa òun kiri? (1 Sámúẹ́lì 24:14)
4. Inú kí ni áńgẹ́lì keje da àwokòtò ìbínú Ọlọ́run tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí? (Ìṣípayá 16:17)
5. Kí ló dé tí a fi ń pe àwọn àtọmọdọ́mọ Jákọ́bù ní Ọmọ Ísírẹ́lì? (Jẹ́nẹ́sísì 32:28)
6. Àgbájọ omi wo ló ní iyọ̀ nínú jù lọ lórí ilẹ̀ ayé? (Wo Jẹ́nẹ́sísì 14:3.)
7. Kí ló fà á tí a fi gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa gbàdúrà “nípa àwọn ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga”? (1 Tímótì 2:1, 2)
8. Ọ̀rọ̀ èdè Júù wo ni Jésù lò nígbà tí ó ń wo ọkùnrin adití kan tí ó sì ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ sàn? (Máàkù 7:34)
9. Ibo ni Jésù ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ kìíní? (Jòhánù 2:11)
10. Orúkọ àníjẹ́ wo ni wọ́n sọ Ísọ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 36:1)
11. Ẹyẹ wo ni Jésù lò nínú àpèjúwe kan láti fi ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ láti kó Jerúsálẹ́mù tó ti ya páńdukú jọpọ̀? (Lúùkù 13:34)
12. Mẹ́táàlì wo ni a fi ń pọ́n àwọn ohun tí a fi mẹ́táàlì kan náà ṣe? (Òwe 27:17)
13. Ọ̀gangan ibo ni àpọ́sítélì Jòhánù rí, tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti àwọn 144,000 dúró sí? (Ìṣípayá 14:1)
14. Ta ló mú ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ àwọn tí kì í ṣe Júù, tó fẹ́ dá yánpọnyánrin sílẹ̀, tọ ẹgbẹ́ olùṣàkóso lọ ní Jerúsálẹ́mù? (Ìṣe 15:2)
15. Ibo ni olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ìhà àríwá Ísírẹ́lì? (1 Àwọn Ọba 16:29)
16. Kí ni nọ́ńbà “ẹranko ẹhànnà náà”? (Ìṣípayá 13:18)
17. Kí ló mú kí ọbabìnrin Ṣébà lọ sí Jerúsálẹ́mù? (1 Àwọn Ọba 10:4)
18. Ọba Júdà wo ló ní ìtara fún ìjọsìn mímọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó mú ìyá rẹ̀ àgbà kúrò nípò tó wà nínú ìjọba náà nítorí tí obìnrin náà ṣe “òrìṣà bíbanilẹ́rù kan”? (1 Àwọn Ọba 15:13)
19. Inú kí ni áńgẹ́lì kejì da àwokòtò ìbínú Ọlọ́run tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí? (Ìṣípayá 16:3)
20. Ta ni ọba burúkú tó jẹ ní Ísírẹ́lì, tó hùwà búburú sí Tífísà? (2 Àwọn Ọba 15:16)
21. Ohun ìjà wo ni a sábà máa ń jù? (Jóṣúà 8:18)
22. Orúkọ wo ni a ń pe oṣù òṣùpá Étánímù lẹ́yìn ìgbèkùn Bábílónì?
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Àwọn áńgẹ́lì ọmọ Ọlọ́run
2. ‘A kì yóò run ún’
3. “Ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo”
4. Afẹ́fẹ́
5. Nítorí pé Ọlọ́run pa orúkọ rẹ̀ dà di Ísírẹ́lì
6. Òkun Òkú
7. “Kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́”
8. Éfátà (tó túmọ̀ sí “là”)
9. Kánà
10. Édómù
11. Àgbébọ̀ adìyẹ
12. Irin
13. Lórí Òkè Ńlá Síónì ti ọ̀run
14. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà
15. Samáríà
16. 666
17. Kí ó lè gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì
18. Ásà
19. Òkun
20. Ménáhémù
21. Ẹ̀ṣín
22. Tíṣírì