ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè àti Ọlọ́run alààyè (1-16)

      • Ìparun àti ìgbèkùn ń bọ̀ lọ́nà (17, 18)

      • Inú Jeremáyà bà jẹ́ (19-22)

      • Àdúrà tí wòlíì náà gbà (23-25)

        • Èèyàn kò lè darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀ (23)

Jeremáyà 10:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:3, 30; 20:23; Di 12:30
  • +Ais 47:13

Jeremáyà 10:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “asán.”

  • *

    Tàbí “ọ̀bẹ aboríkọdọrọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 40:20; 44:14, 15; 45:20; Hab 2:18

Jeremáyà 10:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Hámà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:4; Ais 40:19
  • +Ais 41:7

Jeremáyà 10:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “apálá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hab 2:19
  • +Ais 46:7
  • +Ais 41:23; 44:9; 1Kọ 8:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2017, ojú ìwé 2

Jeremáyà 10:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:11; 2Sa 7:22; Sm 86:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 38

Jeremáyà 10:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 22:28
  • +Sm 89:6; Da 4:35

Jeremáyà 10:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “asán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 51:17; Hab 2:18
  • +Ais 44:19

Jeremáyà 10:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:22

Jeremáyà 10:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 3:10; Da 6:26
  • +Da 4:3; Hab 1:12; Ifi 15:3
  • +Na 1:5

Jeremáyà 10:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ ẹsẹ 11 ní ìbẹ̀rẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 2:18; Jer 51:17, 18; Sef 2:11

Jeremáyà 10:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 3:19; Ais 45:18
  • +Sm 136:3, 5; Ais 40:22; Jer 51:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 51-53

Jeremáyà 10:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “oruku.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 37:2; 38:34
  • +Job 36:27; Sm 135:7
  • +Jẹ 8:1; Ẹk 14:21; Nọ 11:31; Jon 1:4

Jeremáyà 10:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

  • *

    Tàbí “èémí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 42:17; 44:11
  • +Jer 51:17; Hab 2:18, 19

Jeremáyà 10:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Asán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:29

Jeremáyà 10:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ìpín.”

  • *

    Tàbí “ogún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:9; Sm 135:4
  • +Ais 47:4

Jeremáyà 10:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà sọ̀kò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:63; Jer 16:13

Jeremáyà 10:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “egungun mi fọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:21

Jeremáyà 10:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:20
  • +Jer 31:15

Jeremáyà 10:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:31
  • +Jer 2:8; 8:9
  • +Jer 23:1; Isk 34:5, 6

Jeremáyà 10:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akátá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:15; 4:6; 6:22; Hab 1:6
  • +Jer 9:11

Jeremáyà 10:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 17:5; 37:23; Owe 16:3; 20:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 2 2021 ojú ìwé 6

    Jí!,

    No. 1 2019 ojú ìwé 4-5

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2012, ojú ìwé 6

    12/15/2011, ojú ìwé 14

    4/15/2008, ojú ìwé 9-10

    11/1/2005, ojú ìwé 22

    10/15/2000, ojú ìwé 13

    9/1/1999, ojú ìwé 19-20

    10/1/1992, ojú ìwé 27

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 51-53

    Ìmọ̀, ojú ìwé 12

Jeremáyà 10:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 6:1; 38:1
  • +Jer 30:11

Jeremáyà 10:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:2
  • +Jer 51:34
  • +Ais 10:22
  • +Sm 79:6, 7; Jer 8:16; Ida 2:22

Àwọn míì

Jer. 10:2Le 18:3, 30; 20:23; Di 12:30
Jer. 10:2Ais 47:13
Jer. 10:3Ais 40:20; 44:14, 15; 45:20; Hab 2:18
Jer. 10:4Sm 115:4; Ais 40:19
Jer. 10:4Ais 41:7
Jer. 10:5Hab 2:19
Jer. 10:5Ais 46:7
Jer. 10:5Ais 41:23; 44:9; 1Kọ 8:4
Jer. 10:6Ẹk 15:11; 2Sa 7:22; Sm 86:8
Jer. 10:7Sm 22:28
Jer. 10:7Sm 89:6; Da 4:35
Jer. 10:8Jer 51:17; Hab 2:18
Jer. 10:8Ais 44:19
Jer. 10:91Ọb 10:22
Jer. 10:10Joṣ 3:10; Da 6:26
Jer. 10:10Da 4:3; Hab 1:12; Ifi 15:3
Jer. 10:10Na 1:5
Jer. 10:11Ais 2:18; Jer 51:17, 18; Sef 2:11
Jer. 10:12Owe 3:19; Ais 45:18
Jer. 10:12Sm 136:3, 5; Ais 40:22; Jer 51:15, 16
Jer. 10:13Job 37:2; 38:34
Jer. 10:13Job 36:27; Sm 135:7
Jer. 10:13Jẹ 8:1; Ẹk 14:21; Nọ 11:31; Jon 1:4
Jer. 10:14Ais 42:17; 44:11
Jer. 10:14Jer 51:17; Hab 2:18, 19
Jer. 10:15Ais 41:29
Jer. 10:16Di 32:9; Sm 135:4
Jer. 10:16Ais 47:4
Jer. 10:18Di 28:63; Jer 16:13
Jer. 10:19Jer 8:21
Jer. 10:20Jer 4:20
Jer. 10:20Jer 31:15
Jer. 10:21Jer 5:31
Jer. 10:21Jer 2:8; 8:9
Jer. 10:21Jer 23:1; Isk 34:5, 6
Jer. 10:22Jer 1:15; 4:6; 6:22; Hab 1:6
Jer. 10:22Jer 9:11
Jer. 10:23Sm 17:5; 37:23; Owe 16:3; 20:24
Jer. 10:24Sm 6:1; 38:1
Jer. 10:24Jer 30:11
Jer. 10:25Ais 34:2
Jer. 10:25Jer 51:34
Jer. 10:25Ais 10:22
Jer. 10:25Sm 79:6, 7; Jer 8:16; Ida 2:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 10:1-25

Jeremáyà

10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà sí yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì. 2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ má ṣe kọ́ ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè,+

Ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àwọn àmì ojú ọ̀run dẹ́rù bà yín

Nítorí wọ́n ti dẹ́rù ba àwọn orílẹ̀-èdè.+

 3 Àṣà àwọn èèyàn náà jẹ́ ẹ̀tàn.*

Igi igbó lásán ni wọ́n gé lulẹ̀,

Ohun tí oníṣẹ́ ọnà fi irin iṣẹ́* gbẹ́ ni.+

 4 Fàdákà àti wúrà ni wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́+

Òòlù* àti ìṣó ni wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀ kó má bàa ṣubú.+

 5 Wọ́n dà bí aṣọ́komásùn tó wà nínú oko kùkúńbà,* wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

Ńṣe là ń gbé wọn, torí wọn ò lè rìn.+

Má bẹ̀rù wọn, torí wọn ò lè pani lára,

Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ṣeni lóore kankan.”+

 6 Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ.+

O tóbi, orúkọ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.

 7 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè,+ nítorí ó yẹ bẹ́ẹ̀;

Láàárín gbogbo ọlọ́gbọ́n tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè àti ní gbogbo ìjọba wọn,

Kò sí ẹnì kankan tó dà bí rẹ.+

 8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìnírònú àti òmùgọ̀.+

Ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ igi jẹ́ kìkìdá ẹ̀tàn.*+

 9 Àwọn fàdákà pẹlẹbẹ tí wọ́n kó wá láti Táṣíṣì+ àti wúrà láti Úfásì,

Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe àti ohun tí oníṣẹ́ irin ṣe.

Aṣọ wọn jẹ́ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù.

Gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀jáfáfá.

10 Ṣùgbọ́n Jèhófà ni Ọlọ́run lóòótọ́.

Òun ni Ọlọ́run alààyè+ àti Ọba ayérayé.+

Nítorí ìbínú rẹ̀, ayé á mì jìgìjìgì,+

Kò sì sí orílẹ̀-èdè tó lè fara da ìdálẹ́bi rẹ̀.

11 * Ohun tí o máa sọ fún wọn nìyí:

“Àwọn ọlọ́run tí kò dá ọ̀run àti ayé

Yóò ṣègbé kúrò ní ayé àti kúrò lábẹ́ ọ̀run yìí.”+

12 Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a,

Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+

Tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.+

13 Nígbà tó bá fọhùn,

Omi ojú ọ̀run á ru gùdù,+

Á sì mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé.+

Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò,

Ó sì ń mú ẹ̀fúùfù wá láti inú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

14 Kálukú ń hùwà láìronú, wọn ò sì ní ìmọ̀.

Ojú á ti gbogbo oníṣẹ́ irin nítorí ère tí wọ́n ṣe;+

Nítorí ère onírin* rẹ̀ jẹ́ èké,

Kò sì sí ẹ̀mí* kankan nínú wọn.+

15 Ẹ̀tàn* ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni wọ́n.+

Nígbà tí ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn bá dé, wọ́n á ṣègbé.

16 Ọlọ́run* Jékọ́bù kò dà bí àwọn nǹkan yìí,

Nítorí òun ni Ẹni tó dá ohun gbogbo,

Ísírẹ́lì sì ni ọ̀pá tó jẹ́ ohun ìní* rẹ̀.+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+

17 Kó ẹrù rẹ kúrò nílẹ̀,

Ìwọ obìnrin tó ń gbé nínú ìlú tí wọ́n gbógun tì.

18 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Wò ó, màá sọ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà nù bí òkò* ní àkókò yìí,+

Màá sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdààmú.”

19 Mo gbé nítorí àárẹ̀ mi!*+

Ọgbẹ́ mi kò ṣeé wò sàn.

Mo sì sọ pé: “Ó dájú pé àìsàn mi nìyí, màá sì fara dà á.

20 Wọ́n ti sọ àgọ́ mi di ahoro, wọ́n sì ti fa gbogbo okùn àgọ́ mi já.+

Àwọn ọmọkùnrin mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.+

Kò sí ẹni tó ṣẹ́ kù tó máa gbé àgọ́ mi ró tàbí tó máa ta aṣọ àgọ́ mi.

21 Nítorí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti hùwà òmùgọ̀,+

Wọn kò sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+

Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà,

Tí gbogbo agbo ẹran wọn sì fi tú ká.”+

22 Fetí sílẹ̀! Ìròyìn kan ń bọ̀!

Ariwo rúkèrúdò láti ilẹ̀ àríwá,+

Láti sọ àwọn ìlú Júdà di ahoro, ibùgbé àwọn ajáko.*+

23 Jèhófà, mo mọ̀ dáadáa pé ọ̀nà èèyàn kì í ṣe tirẹ̀.

Àní kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.+

24 Jèhófà, fi ìdájọ́ tọ́ mi sọ́nà,

Àmọ́ kì í ṣe nínú ìbínú rẹ,+ kí o má bàa pa mí run.+

25 Da ìrunú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tó pa ọ́ tì+

Àti sórí àwọn ìdílé tí kì í ké pe orúkọ rẹ.

Nítorí wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,+

Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti jẹ ẹ́ ní àjẹtán títí wọ́n fi pa á run,+

Wọ́n sì ti sọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ di ahoro.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́