ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 14-19
  • Ìfẹ́ Ń ṣẹ́gun Owú Tí Kò Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Ń ṣẹ́gun Owú Tí Kò Tọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Owú Láàárín Àwọn Kristian
  • Nínú Ìjọ
  • Nínú Ìdílé Rẹ
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Dídọ̀gá Owú
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Títayọ Lọ́lá Jù Lọ
  • Dídọ̀gá Lórí Owú Rẹ
  • Ohun Tí O Ní Láti Mọ̀ Nípa Owú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jíjowú fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 14-19

Ìfẹ́ Ń ṣẹ́gun Owú Tí Kò Tọ́

“Ìfẹ́ kì í jowú.”—1 KORINTI 13:4.

1, 2. (a) Kí ni Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ìfẹ́? (b) Ó ha ṣeé ṣe láti jẹ́ onífẹ̀ẹ́, kí a sì tún jẹ́ òjòwú bí, èé sì ti ṣe tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

ÌFẸ́ ni àmì ìdámọ̀yàtọ̀ ti ìsìn Kristian tòótọ́. Jesu Kristi wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:35) A mí sí aposteli Paulu láti ṣàlàyé bí ó ṣe yẹ kí ìfẹ́ nípa lórí ipò ìbátan Kristian. Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ó kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ kì í jowú.”—1 Korinti 13:4.

2 Nígbà tí Paulu kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ó ń tọ́ka sí owú tí kò tọ́. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì bá tí sọ fún ìjọ kan náà pé: “Emi ń jowú lórí yín pẹlu owú lọ́nà ti Ọlọrun.” (2 Korinti 11:2) “Owú” rẹ̀ “lọ́nà ti Ọlọrun” ni a ru sókè nítorí àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ipa ìdarí oníwà ìbàjẹ́ nínú ìjọ náà. Èyí sún Paulu láti kọ lẹ́tà kejì tí a mí sí, tí ó ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ nínú, sí àwọn Kristian ní Korinti.—2 Korinti 11:3-5.

Owú Láàárín Àwọn Kristian

3. Báwo ni ìṣòro kan tí ó wé mọ́ owú ṣe bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn Kristian ní Korinti?

3 Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Korinti, Paulu ní láti yanjú ìṣòro kan tí ń dí àwọn Kristian titun wọ̀nyí lọ́wọ́ láti má ṣe gbé papọ̀ bí ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Wọ́n ń gbé àwọn ọkùnrin kan pàtó ga, ní ‘wíwú fùkẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìfaramọ́ ẹni kan lòdì sí èkejì.’ Èyí yọrí sí ìyapa láàárín ìjọ náà, tí àwọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ń sọ pé: “Emi jẹ́ ti Paulu,” “Ṣugbọn emi ti Apollo,” “Ṣugbọn emi ti Kefa.” (1 Korinti 1:12; 4:6) Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, ó ṣeé ṣe fún aposteli Paulu láti rí ìpìlẹ̀ ìṣòro náà. Àwọn ará Korinti ń hùwà bí àwọn ènìyàn tí ẹran ara ń darí, kì í ṣe bí “awọn ènìyàn ti ẹ̀mí.” Nípa báyìí, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ti ẹran-ara síbẹ̀. Nitori nígbà tí ó jẹ́ pé owú ati gbọ́nmisi-omi-ò-to wà láàárín yín, ẹ̀yin kò ha jẹ́ ti ẹran-ara ẹ̀yin kò ha sì ń rìn bí ènìyàn?”—1 Korinti 3:1-3.

4. Àkàwé wo ni Paulu lò láti ran àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti dé orí ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ̀kọ́ wo ni a sì rí kọ́ láti inú èyí?

4 Paulu ran àwọn ará Korinti lọ́wọ́ láti lóye ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa tálẹ́ńtì àti agbára ìṣe ti olúkúlùkù nínú ìjọ. Ó béèrè pé: “Nitori ta ni mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Nítòótọ́, kí ni iwọ ní tí kì í ṣe pé iwọ gbà? Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé gbígbà ni iwọ gbà á nítòótọ́, èéṣe tí iwọ fi ń ṣògo bí ẹni pé iwọ kò gbà á?” (1 Korinti 4:7) Ní 1 Korinti orí 12, Paulu ṣàlàyé pé àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ apá kan ìjọ náà dà bí ara ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, irú bí ọwọ́, ojú, àti etí. Ó fi hàn pé Ọlọrun ṣe àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà kan tí ó jẹ́ pé wọ́n ń bójú tó ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Paulu tún kọ̀wé pé: “Bí a bá ṣe ẹ̀yà-ara kan lógo, gbogbo awọn ẹ̀yà-ara yòókù á bá a yọ̀.” (1 Korinti 12:26) Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lónìí ní láti fi ìlànà yìí sílò nínú ipò ìbátan wọn pẹ̀lú ẹnì kìíní-kejì. Kàkà tí a óò fi jowú ẹlòmíràn nítorí iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ tàbí àṣeparí rẹ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun, a ní láti bá ẹni náà yọ̀.

5. Kí ni a ṣí payá ní Jakọbu 4:5, báwo sì ni Ìwé Mímọ́ ṣe tẹnu mọ́ ìjótìítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí?

5 A gbà pé, ẹnú dùn ún ròfọ́, agada ọwọ́ sì ṣeé bẹ́ gẹdú. Òǹkọ̀wé Bibeli náà Jakọbu rán wa létí pé “ìtẹ̀sí lati ṣe ìlara” ń gbé nínú gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jakọbu 4:5) Ikú ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ wáyé nítorí pé Kaini juwọ́ sílẹ̀ fún owú tí kò tọ́. Àwọn ara Filisitini ṣe inúnibíni sí Isaaki nítorí pé wọn ṣe ìlara aásìkí rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i. Rakeli jowú bí ọmọ bíbí ṣe jẹ́ arábìnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn ọmọkùnrin Jekọbu jowú ojú rere tí a fi hàn sí Josefu àbúrò wọn. Ó hàn gbangba pé Miriamu jowú ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí kì í ṣe ọmọ Israeli. Kora, Datani, àti Abiramu fi pẹ̀lú ìlara dìtẹ̀ mọ́ Mose àti Aaroni. Ọba Saulu jowú àṣeyọrí ológun tí Dafidi ní. Kò sí iyèméjì pé owú jẹ́ kókó abájọ kan tí ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu kó wọnú àríyànjiyàn léraléra nípa ẹni tí ó tóbi lọ́lá jù láàárín wọn. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, kò sí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tí ó dòmìnira pátápátá kúrò lọ́wọ́ “ìtẹ̀sí” tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ “lati ṣe ìlara.”—Genesisi 4:4-8; 26:14; 30:1; 37:11; Numeri 12:1, 2; 16:1-3; Orin Dafidi 106:16; 1 Samueli 18:7-9; Matteu 20:21, 24; Marku 9:33, 34; Luku 22:24.

Nínú Ìjọ

6. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ṣàkóso ìtẹ̀sí náà láti jowú?

6 Gbogbo Kristian ní láti ṣọ́ra fún ìlara àti owú tí kò tọ́. Èyí kan ẹgbẹ́ àwọn alàgbà tí a yàn sípò láti bójú tó ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọrun. Bí alàgbà kan bá ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, kì yóò fi pẹ̀lú ọ̀kánjúwà gbìyànjú láti ta àwọn yòókù yọ. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí alàgbà kan bá ní agbára ìṣe títayọ lọ́lá gẹ́gẹ́ bí olùṣètò tàbí olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba, àwọn yòókù yóò yọ̀ lórí èyí, ní kíkà á sí ìbùkún fún ìjọ náà. (Romu 12:15, 16) Arákùnrin kan lè máa tẹ̀ síwájú dáradára, ní fífi ẹ̀rí hàn pé òun ń mú èso ẹ̀mí Ọlọrun jáde nínú ìgbèsí ayé rẹ̀. Ní gbígbé ìtóótun rẹ̀ yẹ̀ wò, àwọn alàgbà ní láti ṣọ́ra láti máṣe sọ àwọn àṣìṣe tí kò tó nǹkan di ńlá láti dá àìdámọ̀ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà láre. Ìyẹn yóò fi àìní ìfẹ́ àti àìfòyebánilò hàn.

7. Ìṣòro wo ni ó lè dìde nígbà tí Kristian kan bá rí àwọn iṣẹ́ àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọrun gbà?

7 Bí ẹnì kan bá rí iṣẹ́ àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọrun tàbí ìbùkún nípa tẹ̀mí gbà, àwọn yòókù nínú ìjọ ní láti ṣọ́ra fún ìlara. Fún àpẹẹrẹ, a lè sábà máa lo arábìnrin kan tí ó dáńgájíá láti ṣe àṣefihàn ní àwọn ìpàdé Kristian ju àwọn mìíràn lọ. Èyí lè ru owú sókè níhà ọ̀dọ̀ àwọn arábìnrin kan. Irú ìṣòro tí o fara jọ ọ́ ti lè wà láàárín Euodia àti Sintike ti ìjọ Filippi. Irú àwọn obìnrin òde òní bẹ́ẹ̀ nílò ìṣírí onínúure láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí wọ́n sì jẹ́ ‘elérò-inú kan naa ninu Oluwa.’—Filippi 2:2, 3; 4:2, 3.

8. Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wo ni owú lè yọrí sí?

8 Kristian kan lè mọ̀ nípa àṣìṣe kan tí ẹni náà tí a fi àwọn àǹfààní nínú ìjọ bù kún nísinsìnyí ti ṣe sẹ́yìn. (Jakọbu 3:2) Nítorí owú, ìdẹwò kan lè wáyé láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa èyí, àti láti pe iṣẹ́ àyànfúnni ẹni náà nínú ìjọ níjà. Èyí yóò ta ko ìfẹ́, èyí tíí máa “bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Peteru 4:8) Ọ̀rọ̀ owú lè dabarú àlàáfíà ìjọ. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jakọbu, kìlọ̀ pé: “Bí ẹ bá ní owú kíkorò ati ẹ̀mí asọ̀ ninu ọkàn-àyà yín, ẹ máṣe máa fọ́nnu kí ẹ má sì ṣe máa purọ́ lòdì sí òtítọ́. Èyí kọ́ ni ọgbọ́n tí ó sọ̀kalẹ̀ wá lati òkè, ṣugbọn ó jẹ́ ti ilẹ̀-ayé, ti ẹran, ti ẹ̀mí-èṣù.”—Jakọbu 3:14, 15.

Nínú Ìdílé Rẹ

9. Báwo ni àwọn alábàáṣègbéyàwó ṣe lè ṣàkóso ìmọ̀lára owú?

9 Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ń forí ṣánpọ́n nítorí owú tí kò tọ́. Fífi àìní ìgbẹ́kẹ̀lé hàn nínú alábàáṣègbéyàwó ẹni kò fi ìfẹ́ hàn. (1 Korinti 13:7) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, alábàáṣègbéyàwó kan lè má tètè ṣàkíyèsí ìmọ̀lára owú ní ìhà ọ̀dọ̀ ẹnì kejì. Fún àpẹẹrẹ, aya kan lè jowú nítorí àfiyèsí tí ọkọ rẹ̀ ń fún ẹlòmíràn tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì. Tàbí kí ọkọ kan di òjòwú nítorí iye àkókò tí aya rẹ̀ ń lò ní bíbójútó ìbátan kan tí ó nílò ìrànwọ́. Tí irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ bá kó ìdààmú bá wọn, àwọn alábàáṣègbéyàwó náà lè dákẹ́, kí wọ́n sì fi ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ wọn hàn ní àwọn ọ̀nà tí ó lè mú ìṣòro náà lọ́jú pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, alábàáṣègbéyàwó tí ń jowú ní láti sọ̀rọ̀ jáde, kí ó sì jẹ́ aláìlábòsí nípa ìmọ̀lára rẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábàáṣègbéyàwó kejì yẹ kí ó fi òye hàn kí ó sì mú ìfẹ́ rẹ̀ dá a lójú. (Efesu 5:28, 29) Àwọn méjèèjì lè ní láti pẹ̀rọ̀ sí ìmọ̀lára owú nípa yíyẹra fún àwọn ipò tí ń ru ú sókè. Nígbà mìíràn, Kristian alábòójútó kan lè ní láti ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye pé òun ń fún àwọn mẹ́ḿbà ẹ̀yà òdì kejì ní àfiyèsí tí ó láàlà, tí ó sì yẹ, láti baà lè mú ẹrù-iṣẹ́ òun ṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun. (Isaiah 32:2) Àmọ́ ṣáá o, alàgbà kan ní láti ṣọ́ra láti máṣe fi ìdí tòótọ́ kankan sílẹ̀ fún owú. Èyí ń béèrè ìwà déédéé, ní rírí i dájú pé ó ń lo àkókò ní fífún ipò ìbátan ìgbéyàwó tirẹ̀ fúnra rẹ̀ lókun.—1 Timoteu 3:5; 5:1, 2.

10. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti kojú ìmọ̀lára owú?

10 Àwọn òbí pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti lóye ìpìlẹ̀ èrò owú tí kò tọ́. Àwọn ọmọ sábà máa ń kó wọnú asọ̀-riworiwo tí ń yọrí sí ìjà. Lọ́pọ̀ ìgbà, owú ni okùnfà rẹ̀. Nítorí pé àìní ọmọ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, a kò lè bá àwọn ọmọ lò lọ́nà kan náà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ní láti lóye pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní okun àti àìlera ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí a bá ń sábà fún ọmọ kan ní ìṣírí láti ṣe bíi ti àwọn yòókù, èyí lè gbin ìlara sí ọ̀kan nínú, kí ó sì gbin ìgbéraga sí òmíràn nínú. Nítorí náà, àwọn òbí ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti díwọ̀n ìtẹ̀síwájú wọn wò nípa gbígbé àpẹẹrẹ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹ̀ wò, kì í ṣe nípa bíbá ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì díje. Bibeli sọ pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹlu ara wa lẹ́nìkínní kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nìkínní kejì.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ jẹ́, nígbà naa ni oun yoo ní ìdí fún ayọ̀ àṣeyọrí níti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹlu ẹlòmíràn.” (Galatia 5:26; 6:4) Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, àwọn Kristian òbí ní láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé, ní títẹnu mọ́ àwọn àpẹẹrẹ rere àti búburú tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—2 Timoteu 3:15.

Àwọn Àpẹẹrẹ Dídọ̀gá Owú

11. Báwo ni Mose ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú yíyanjú owú?

11 Láìdà bí àwọn aṣáájú ayé yìí tí ebi agbára ń pa, “Mose, . . . ṣe ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn lọ tí ń bẹ lórí ilẹ̀.” (Numeri 12:3) Nígbà tí ipò aṣáájú lórí àwọn ọmọ Israeli di ẹrù ìnira tí ó pọ̀ jù fún Mose láti nìkan gbé, Jehofa mú kí ẹ̀mí Rẹ̀ ṣiṣẹ́ lórí 70 àwọn ọmọ Israeli mìíràn, ní fífi agbára fún wọn láti ran Mose lọ́wọ́. Nígbà tí méjì lára àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì, Joṣua nímọ̀lára pé èyí dín ipò aṣáájú Mose kù lọ́nà tí kò yẹ. Joṣua fẹ́ láti dá àwọn ọkùnrin náà dúró, ṣùgbọ́n Mose fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ronú pé: “Ìwọ ń jowú nítorí mi? gbogbo ènìyàn OLUWA ì bá lè jẹ́ wòlíì, kí OLUWA kí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” (Numeri 11:29) Bẹ́ẹ̀ ni, Mose láyọ̀ nígbà tí àwọn mìíràn gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Kò fẹ́ fi owú gba ògo fún ara rẹ̀.

12. Kí ni ó ran Jonatani lọ́wọ́ láti yẹra fún ìmọ̀lára owú?

12 Àpẹẹrẹ àtàtà ti bí ìfẹ́ ṣe ń borí ìmọ̀lára owú tí kò tọ́ tí ó ṣeé ṣe kí ó wáyé ni Jonatani fúnni, ọmọkùnrin Saulu Ọba Israeli. Jonatani ni ẹni tí oyè kàn láti jogún ìtẹ́ bàbá rẹ̀, ṣùgbọ́n Jehofa ti yan Dafidi, ọmọkùnrin Jesse, láti jẹ́ ọba tí yóò tẹ̀ lé e. Ọ̀pọ̀ tí ó wà ní ipò Jonatani ì bá ti jowú Dafidi, ní kíkà á sí abánidíje. Bí ó ti wù kí ó rí, ìfẹ́ Jonatani fún Dafidi kò fàyè gba irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ láti jẹ gàba lé e lórí. Nígbà tí ó gbọ́ nípa ikú Jonatani, Dafidi lè sọ pé: “Wàhálà bá mi nítorí rẹ, Jonatani, arákùnrin mi: dídùn jọjọ ni ìwọ jẹ́ fún mi: ìfẹ́ rẹ sí mi já sí ìyanu, ó ju ìfẹ́ obìnrin lọ.”—2 Samueli 1:26.

Àwọn Àpẹẹrẹ Títayọ Lọ́lá Jù Lọ

13. Ta ni àpẹẹrẹ dídára jù lọ nínú ọ̀ràn owú, èé sì ti ṣe?

13 Jehofa Ọlọrun ni àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá jù lọ ti ẹni tí ó dọ̀gá lórí owú tí ó dára pàápàá. Ó ń fi irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ sábẹ́ àkóso pátápátá. Fífi owú àtọ̀runwá lílágbára hàn lọ́nà èyíkéyìí máa ń fi ìgbà gbogbo wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, àti ọgbọ́n Ọlọrun.—Isaiah 42:13, 14.

14. Àpẹẹrẹ wo ni Jesu fi lélẹ̀ ní ìyàtọ̀ sí ti Satani?

14 Àpẹẹrẹ kejì tí ó tayọ lọ́lá ti ẹnì kan tí ó fi hàn pé òun ti dọ̀gá lórí ìmọ̀lára owú ni Ọmọkùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n ti Ọlọrun, Jesu Kristi. “Bí ó tilẹ̀ wà ní àwòrán-ìrísí Ọlọrun,” Jesu “kò ronú rárá nipa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé oun níláti bá Ọlọrun dọ́gba.” (Filippi 2:6) Ẹ wo irú ìyàtọ̀ gédégédé tí èyí jẹ́ sí ipa ọ̀nà tí áńgẹ́lì ọlọ́kàn-án-júwà náà tí ó di Satani Èṣù tọ̀! Gẹ́gẹ́ bí “ọba Babiloni,” Satani ní ọkàn ìfẹ́ láti “dà bí ọ̀gá-ògo jùlọ” lọ́nà tí ń fi owú hàn nípa gbígbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọlọrun abánidíje ní ìlòdì sí Jehofa. (Isaiah 14:4, 14; 2 Korinti 4:4) Satani tilẹ̀ gbìyànjú láti mú kí Jesu ‘wólẹ̀ kí o sì ṣe ìṣe ìjọsìn kan fún òun.’ (Matteu 4:9) Ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun tí yóò mú kí Jesu yẹsẹ̀ kúrò lórí ipa ọ̀nà onírẹ̀lẹ̀ rẹ̀ ti jíjuwọ́sílẹ̀ fún ipò ọba aláṣẹ Jehofa. Ní ìyàtọ̀ sí ti Satani, Jesu “sọ ara rẹ̀ di òfìfo ó sì gbé àwòrán-ìrísí ẹrú wọ̀ ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” Jesu gbé ẹ̀tọ́ ìṣàkóso Bàbá rẹ̀ ga, ní kíkọ ipa-ọ̀nà Èṣù ti ìgbéraga àti owú ní àkọ̀tán. Nítorí ìṣòtítọ́ Jesu, “Ọlọrun . . . gbé e sí ipò gíga tí ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó baà lè jẹ́ pé ní orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ba ti awọn wọnnì tí ń bẹ ní ọ̀run ati awọn wọnnì tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé ati awọn wọnnì tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ fihàn ní gbangba wálíà pé Jesu Kristi ni Oluwa fún ògo Ọlọrun Baba.”—Filippi 2:7-11.

Dídọ̀gá Lórí Owú Rẹ

15. Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti káḿbà ìmọ̀lára owú?

15 Láìdà bí Ọlọrun àti Kristi, aláìpé ni àwọn Kristian. Nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà mìíràn, owú tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ lè sún wọ́n láti gbé ìgbésẹ̀. Dípò tí a óò fi yọ̀ǹda fún owú láti sún wa láti ṣe lámèyítọ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kan nípa àwọn àṣìṣe kan tí kò tó nǹkan tàbí tí a finúwòye pé kò tọ́, nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí: “Má ṣe òdodo àṣelékè, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe fi ara rẹ ṣe ọlọ́gbọ́n àṣelékè; nítorí kí ni ìwọ óò ṣe fa ìparun fún ara rẹ?”—Oniwasu 7:16, NW.

16. Ìmọ̀ràn àtàtà wo ni a fi fúnni lórí owú nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn yìí tí ó ti kọjá?

16 Lórí kókó ẹ̀kọ́ náà owú, Ilé-Ìṣọ́ Náà ti March 15, 1911 (Gẹ̀ẹ́sì), kìlọ̀ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti jẹ́ onítara gan-an, òjòwú gan-an nínú ipa ọ̀nà Oluwa, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ mọ̀ dájú pé kì í ṣe ọ̀ràn ara ẹni; a sì ní láti gbé e yẹ̀wò bóyá ‘olùyọjúràn sí ọ̀ràn awọn ẹlòmíràn’ ni wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lúpẹ̀lù, a ní láti gbé e yẹ̀ wò bóyá ó lè jẹ́ ohun tí ó tọ́ fún àwọn alàgbà láti ṣiṣẹ́ lé lórí àti bóyá yóò jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wa láti tọ àwọn alàgbà lọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Gbogbo wa ní láti ní owú ńláǹlà gan-an fún ipa ọ̀nà Oluwa àti iṣẹ́ Oluwa, ṣùgbọ́n ẹ kíyè sára gidigidi pé kì í ṣe irú èyí tí kò tọ́ . . . ní èdè mìíràn, a ní láti rí i dájú pé kì í ṣe owú ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n owú fún ẹlòmíràn, fún àǹfààní rẹ̀ àti ire rẹ̀ tí ó dára jùlọ.”—1 Peteru 4:15.

17. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ìwà ẹ̀sẹ̀ ti owú?

17 Báwo ni àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristian ṣe lè yẹra fún ìgbéraga, owú, àti ìlara? Ojútùú náà wà nínú yíyọ̀ǹda fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun láti ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìgbésí ayé wa. Fún àpẹẹrẹ, a ní láti gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọrun àti fún ìrànlọ́wọ́ ní fífi èso rere rẹ̀ hàn. (Luku 11:13) A ní láti lọ sí gbogbo àwọn ìpàdé Kristian, tí a ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà tí wọ́n sì ní ẹ̀mí àti ìbùkún Ọlọrun lórí wọn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí Ọlọrun mí sí. (2 Timoteu 3:16) A sì ní láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí a ń ṣe pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́ Jehofa. (Ìṣe 1:8) Ríran àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni tí àwọn ìrírí búburú ti bà lọ́kàn jẹ́ lọ́wọ́ tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn ti jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ipa ìdarí rere ti ẹ̀mí Ọlọrun. (Isaiah 57:15; 1 Johannu 3:15-17) Fífi tìtaratìtara ṣe gbogbo àwọn ojúṣe Kristian wọ̀nyí yóò ṣèrànwọ́ láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ sísọ ẹ̀ṣẹ̀ owú dàṣà, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Ẹ máa rìn nipa ẹ̀mí ẹ̀yin kì yoo sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara rárá.”—Galatia 5:16.

18. Èé ṣe tí a kò fi ní láti máa fìgbà gbogbo jìjàkadì lòdì sí ìmọ̀lára owú tí kò tọ́?

18 Ìfẹ́ ní a kọ ṣáájú nínú àwọn èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. (Galatia 5:22, 23) Lílo ìfẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìtẹ̀sí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n kí ni nípa ti ọjọ́ ọ̀la? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní ìrètí ìwàláàyè nínú Paradise ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀, níbi tí wọ́n ti lè fojú sọ́nà pé a óò ti gbé wọn dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn. Nínú ayé titun náà, ìfẹ́ yóò gbilẹ̀ kò sì sí ẹnì kan tí yóò juwọ́ sílẹ̀ fún ìmọ̀lára owú tí kò tọ́, nítorí pé “a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹlu sílẹ̀ lómìnira kúrò ninu ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́ yoo sì ní òmìnira ológo ti awọn ọmọ Ọlọrun.”—Romu 8:21.

Àwọn Kókó fún Ṣíṣàṣàrò

◻ Àkàwé wo ni Paulu lo láti ràn wá lọ́wọ́ láti gbéjà ko owú?

◻ Báwo ni owú ṣe lè dabarú àlàáfíà ìjọ?

◻ Báwo ni àwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn láti kojú owú?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ìwà ẹ̀sẹ̀ ti owú?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Má ṣe jẹ́ kí owú dabarú àlàáfíà ìjọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kojú ìmọ̀lára owú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́