ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 36-37
Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù jẹ́ ká rí àkóbá tí owú máa ń fà. A to àwọn ìdí tí kò fi yẹ ká máa jowú sí ìsàlẹ̀ yìí, fàlà sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mu.
ÌWÉ MÍMỌ́
ÌDÍ TÍ KÒ FI YẸ KÁ MÁA JOWÚ
Àwọn tó bá ń jowú ò ní jogún ìjọba Ọlọ́run
Owú máa ń fa ìyapa nínú ìjọ, kì í sì í jẹ́ kí àlàáfíà wà
Owú máa ń ṣàkóbá fún ìlera wa
Owú kì í jẹ́ ká rí ibi táwọn míì dáa sí
Kí làwọn nǹkan tó lè mú ká máa jowú àwọn míì?