ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 3-5
  • Ohun Tí O Ní Láti Mọ̀ Nípa Owú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí O Ní Láti Mọ̀ Nípa Owú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìtẹ̀sí Lati Ṣe Ìlara”
  • Ayé kan Láìsí Owú Tí Ó Kún fún Ẹ̀ṣẹ̀
  • Ìfẹ́ Ń ṣẹ́gun Owú Tí Kò Tọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jíjowú fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 3-5

Ohun Tí O Ní Láti Mọ̀ Nípa Owú

KÍ NI owú? Ó jẹ́ èrò ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí ó lè mú kí ẹnì kan máa ṣàníyàn, banújẹ́, tàbí bínú. A lè ní ìrírí owú nígbà tí ó bá dà bí pé ẹnì kan ń ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ kan ju bí a ti ṣe lọ. Tàbí a lè jowú nígbà tí ọ̀rẹ́ kan bá gba ìyìn ju bí a ti gbà lọ. Ṣùgbọ́n ó ha fi ìgbà gbogbo burú láti jowú bí?

Àwọn ènìyàn tí owú ti bò mọ́lẹ̀ ń ní ìtẹ̀sí láti máa fura sí àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá wọn díje. Ọba Saulu ti Israeli ìgbàanì jẹ́ àpẹẹrẹ èyí. Lákọ̀ọ́kọ́, ó nífẹ̀ẹ́ arùhámọ́ra rẹ̀, Dafidi, tí ó tilẹ̀ gbé e ga láti di olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (1 Samueli 16:21; 18:5) Lẹ́yìn náà ní ọjọ́ kan Ọba Saulu gbọ́ tí àwọn obìnrin ń yin Dafidi pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀, Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàarùn-ún tirẹ̀.” (1 Samueli 18:7) Saulu kì bá má ti yọ̀ǹda kí èyí nípa lórí ipò ìbátan dáradára rẹ̀ pẹ̀lú Dafidi. Bí ó ti wù kí ó rí, inú bí i. “Saulu sì ń bá a lọ láti máa wo Dafidi tìfuratìfura láti ọjọ́ náà lọ.”—1 Samueli 18:9, NW.

Òjòwú lè máa gbèrò ibi sí ẹlòmíràn. Ó lè wulẹ̀ fi ìbínú hàn sí àṣeyọrí alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ kan kí ọkàn rẹ̀ sì fà sí níní irú ànímọ́ tàbí àyíká ipò kan náà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìlara jẹ́ irú owú kan ní pàtàkì tí kò dára. Onílara ènìyàn lè fawọ́ ire sẹ́yìn lábẹ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ ẹni náà tí ń ru owú rẹ̀ sókè tàbí kí ó gbèrò ibi sí ẹni náà. Nígbà mìíràn, onílara ènìyàn kò lè pa ìmọ̀lára rẹ̀ mọ́ra. A lè sún un láti pa ẹlòmíràn lára ní gbangba, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọba Saulu ṣe gbìyànjú láti pa Dafidi. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, Saulu ju ọ̀kọ̀ nínú ìgbìdánwò ‘láti pa Dafidi ní àpamógiri.’—1 Samueli 18:11; 19:10.

O lè dáhùn padà pé: ‘Ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe òjòwú.’ Lóòótọ́, owú lè má ṣàkóso ìgbésí ayé rẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, dé ìwọ̀n àyè kan, owú ti nípa lórí gbogbo wa—ìmọ̀lára owú tiwa fúnra wa àti ti àwọn ẹlòmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tètè máa ń ṣàkíyèsí owú àwọn ẹlòmíràn, a lè lọ́ra láti rí i nínú ara wa.

“Ìtẹ̀sí Lati Ṣe Ìlara”

Àkọsílẹ̀ ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe fi hàn, sábà máa ń tẹnu mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ìlara. O ha rántí àkọsílẹ̀ nípa Kaini àti Abeli bí? Àwọn ọmọkùnrin Adamu àti Efa méjèèjì rúbọ sí Ọlọrun. Abeli ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọkùnrin ìgbàgbọ́. (Heberu 11:4) Ó ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọrun láti mú ète kíkàmàmà Rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé ṣẹ. (Genesisi 1:28; 3:15; Heberu 11:1) Abeli tún gbàgbọ́ pé Ọlọrun yóò fi ìgbésí ayé nínú Paradise ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ san èrè fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùṣòtítọ́. (Heberu 11:6) Nípa báyìí, Ọlọrun fi ìdùnnú rẹ̀ hàn ní ti ẹbọ Abeli. Ì bá ṣe pé Kaini ti fi tòótọ́tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ ni, òun ì bá ti láyọ̀ pé Ọlọrun bù kún Abeli. Kàkà bẹ́ẹ̀, Kaini “bínú gidigidi.”—Genesisi 4:5.

Ọlọrun rọ Kaini láti ṣe rere kí òun pẹ̀lú baà lè rí ìbùkún gbà. Lẹ́yìn náà Ọlọrun kìlọ̀ pé: “Bí ìwọ kò bá yí padà sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ ba ní ẹnu-ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ ni ìfẹ́ rẹ̀ yóò sì máa fà sí; ìwọ, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, yóò ha sì dọ̀gá lórí rẹ̀ bí?” (Genesisi 4:7, NW) Ó bani nínú jẹ́ pé, Kaini kò dọ̀gá lórí ìbínú owú rẹ̀. Ó sún un láti pa arákùnrin rẹ̀ olódodo. (1 Johannu 3:12) Láti ìgbà náà wá, ìjà àti ogun ti gbẹ̀mí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́. Ìwé gbédègbéyọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Díẹ̀ lára àwọn ìpìlẹ̀ okùnfà ogun lè jẹ́ ìfẹ́ ọkàn fún ilẹ̀ púpọ̀ sí i, ìfẹ́ ọkàn fún ọrọ̀ púpọ̀ sí i, ìfẹ́ ọkàn fún agbára púpọ̀ sí i, tàbí ìfẹ́ ọkàn fún ààbò.”

Àwọn Kristian tòótọ́ kì í lọ́wọ́ nínú àwọn ogun ayé yìí. (Johannu 17:16) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn Kristian nígbà mìíràn máa ń kó wọnú ìjà àfẹnujà. Bí àwọn mẹ́ḿbà mìíràn nínú ìjọ bá lọ́wọ́ sí i, ìjà yìí lè di ogun àfẹnujà tí ń pani lára. Òǹkọ̀wé Bibeli náà, Jakọbu, béèrè lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Lati orísun wo ni awọn ogun ti wá lati orísun wo sì ni awọn ìjà ti wá láàárín yín?” (Jakọbu 4:1) Ó dáhùn ìbéèrè náà nípa títú ìwọra onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì wọn fó, ó sì fi kún un pé, “Ẹ̀yin ń bá a lọ ní . . . ṣíṣojúkòkòrò,” tàbí jíjẹ́ “òjòwú.” (Jakọbu 4:2, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè yọrí sí ṣíṣojúkòkòrò àti jíjowú àwọn wọnnì tí ó dà bíi pé wọ́n ń gbádùn àwọn àyíká ipò tí ó dára jù. Fún ìdí yìí, Jakọbu kìlọ̀ lòdì sí “ìtẹ̀sí” ẹ̀dá ènìyàn “lati ṣe ìlara.”—Jakọbu 4:5.

Àǹfààní wo ni ó wà nínú ṣíṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn okùnfà owú? Tóò, èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìlábòsí àti láti gbé ipò ìbátan tí ó dára jù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lárugẹ. Ó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ olóye, olùráragba-nǹkan-sí, àti olùdáríjini. Èyí tí ó dára ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, ó tẹnu mọ́ àìní kánjúkánjú tí ẹ̀dá ní fún ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọrun pèsè fún ìgbàlà àti ìdásílẹ̀ kúrò nínú ìtẹ̀sí ẹ̀dá ènìyàn tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.—Romu 7:24, 25.

Ayé kan Láìsí Owú Tí Ó Kún fún Ẹ̀ṣẹ̀

Láti ojú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn, ayé kan láìsí owú tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ lè dún bí èyí tí kò ṣeé ṣe. Òǹṣèwé Rom Landau gbà pé: “Ọgbọ́n tí a ti kó jọ láti ìrandíran, pẹ̀lú gbogbo ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí . . . àti àwọn afìṣemọ̀rònú-ẹ̀dá ti sọ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, kò pèsè ìdarísọ́nà kankan fún ẹ̀dá tí owú ń dá lóró. . . . Dókítà kankan ha ti wo òjòwú ẹ̀dá kankan sàn rí bí?”

Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nawọ́ ìrètí ti dídé ìwàláàyè pípé ti ẹ̀dá ènìyàn nínú ayé titun jáde níbi tí ẹnì kankan kì yóò ti jìyà owú tí kò wu Ọlọrun tàbí ìlara mọ́. Síwájú sí i, àlàáfíà ayé titun náà ni a kì yóò dabarú láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí ń fi irú àwọn ànímọ́ búburú bẹ́ẹ̀ hàn.—Galatia 5:19-21; 2 Peteru 3:13.

Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo owú ni kò tọ́. Ní tòótọ́, Bibeli sọ pé “Ọlọrun owú ni,” Jehofa. (Eksodu 34:14, NW) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Kí sì ni Bibeli sọ nípa owú tí ó tọ́? Ní àkókò kan náà, báwo ni ẹnì kan ṣe lè dọ̀gá lórí owú tí kò tọ́? Wo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́