ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 8-14
  • Jíjowú fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Ti Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjowú fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Ti Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọmọ Màlúù Oníwúrà
  • Baali Peoru
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín ti Owú ti Ọlọrun
  • Owú Lọ́nà ti Ọlọrun Ṣàǹfààní fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
  • Àwọn Ìṣe Ọjọ́ Ọ̀la ti Owú Àtọ̀runwá
  • Ìfẹ́ Ń ṣẹ́gun Owú Tí Kò Tọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ohun Tí O Ní Láti Mọ̀ Nípa Owú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 8-14

Jíjowú fún Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Ti Jehofa

“Jehofa, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Òjòwú, Ọlọrun owú ni òun.”—EKSODU 34:14, NW.

1. Kí ni ànímọ́ Ọlọrun tí ó hàn gbangba jùlọ, báwo sì ni ó ṣe ní í ṣe pẹ̀lú owú?

JEHOFA ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọlọrun owú.” O lè ṣe kàyéfì nípa ohun tí ó fà á, níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ náà “owú” ti ní ìtumọ̀ òdì. Dájúdájú, ànímọ́ Ọlọrun tí ó hàn gbangba jù lọ ni ìfẹ́. (1 Johannu 4:8) Ìmọ̀lára owú èyíkéyìí láti ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà náà gbọ́dọ̀ jẹ́ fún ire aráyé. Ní tòótọ́, a óò rí i pé owú Ọlọrun ṣe pàtàkì fún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan àgbáyé.

2. Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Heberu náà fún “owú”?

2 Àwọn ọ̀rọ̀ Heberu tí ó fara jọ “owú” wáyé ní ìgbà tí ó lé ní 80 nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì nínú àwọn ìtọ́kasí wọ̀nyí jẹ́ sí Jehofa Ọlọrun. G. H. Livingston ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a bá lò ó fún Ọlọrun, ìpìlẹ̀ èrò owú kò ní ìtumọ̀ èrò ìmọ̀lára tí a gbé gbòdì, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ti ìwonkoko mọ́ ìyàsọ́tọ̀ gédégbé ti ìjọsìn Jehofa.” (The Pentateuch in Its Cultural Environment) Nípa báyìí, Bibeli New World Translation nígbà mìíràn máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Heberu náà sí “ìwonkoko mọ́ ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé.” (Esekieli 5:13) Ìtumọ̀ mìíràn tí ó bá a mu ni “ìgbónára” tàbí “ìtara.”—Orin Dafidi 79:5; Isaiah 9:7.

3. Ní àwọn ọ̀nà wo ni owú nígbà mìíràn lè gbà ṣiṣẹ́ fún ète rere?

3 A dá ènìyàn pẹ̀lú agbára láti jowú, ṣùgbọ́n ìṣubú aráyé sínú ẹ̀ṣẹ̀ ti yọrí sí owú tí a yí sódì. Síbẹ̀síbẹ̀, owú ẹ̀dá ènìyàn lè ṣiṣẹ́ fún ète rere. Ó lè sún ẹnì kan láti dáàbò bo olólùfẹ́ kan kúrò lọ́wọ́ ipa ìdarí búburú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè fi owú hàn fún Jehofa àti ìjọsìn rẹ̀ lọ́nà tí ó dára. (1 Àwọn Ọba 19:10) Láti gbé òye títọ̀nà nípa irú owú bẹ́ẹ̀ fún Jehofa jáde, ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Heberu náà ni a lè túmọ̀ sí “àìfàyè gba ìbánidíje.”—2 Àwọn Ọba 10:16, NW.

Ọmọ Màlúù Oníwúrà

4. Àṣẹ wo tí ó wé mọ́ owú òdodo ni ó tayọ lọ́lá nínú Òfin Ọlọrun fún Israeli?

4 Àpẹẹrẹ owú òdodo ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli gba Òfin ní Òkè Ńlá Sinai. Léraléra, a ti kìlọ̀ fún wọn láti máṣe jọ́sìn àwọn ọlọrun àtọwọ́dá. Jehofa sọ fún wọn pé: “Èmi Jehofa Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun tí ń béèrè fún ìjọsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé [tàbí, “Ọlọrun tí ń jowú (tí ó ní ìtara); Ọlọrun tí kì í fàyè gba ìbánidíje”].” (Eksodu 20:5, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References; fi wé Eksodu 20:22, 23; 22:20; 23:13, 24, 32, 33.) Jehofa wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli, ní ṣíṣèlérí láti bù kún wọn kí ó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Eksodu 23:22, 31) Àwọn ènìyàn náà sì wí pé: “Gbogbo èyí tí OLUWA wí ni àwa óò ṣe, àwa óò sì gbọ́ràn.”—Eksodu 24:7.

5, 6. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà tí ó burú jáì nígbà tí wọ́n pabùdó sí Òkè Ńlá Sinai? (b) Báwo ni Jehofa àti àwọn adúróṣinṣin olùjọsìn rẹ̀ ṣe fi owú òdodo hàn ní Sinai?

5 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun láìpẹ́. Wọ́n ṣì pabùdó sí ẹsẹ̀ Òkè Ńlá Sinai. Mose ti wà ní orí òkè ńlá náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ní gbígba ìtọ́ni síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, àwọn ènìyàn náà sì ti fi ipá mú arákùnrin Mose, Aaroni, láti ṣe ọlọrun kan fún wọn. Aaroni gbà, ó sì rọ ọmọ màlúù kan láti inú wúrà tí àwọn ènìyàn náà pèsè. Wọ́n jẹ́wọ́ pé òrìṣà yìí ṣojú fún Jehofa. (Orin Dafidi 106:20) Ní ọjọ́ kejì wọ́n rúbọ, wọ́n sì “ń bọ ọ́.” Lẹ́yìn náà, wọ́n “ṣiré.”—Eksodu 32:1, 4, 6, 8, 17-19.

6 Mose sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ń ṣàjọyọ̀. Nígbà tí ó rí ìwà títinilójú wọn, ó kígbe jáde pé: “Ta ni wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa?” (Eksodu 32:25, 26, NW) Àwọn ọmọkùnrin Lefi wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ Mose, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni láti mú idà kí wọ́n sì pa àwọn abọ̀rìṣà alárìíyá aláriwo náà. Ní fífi owú wọn fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun hàn, àwọn ọmọ Lefi pa nǹkan bíi 3,000 àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ̀bi. Jehofa fún ìgbésẹ̀ yìí lókun nípa rírán ìyọnu àjàkálẹ̀ sórí àwọn olùlàájá. (Eksodu 32:28, 35) Lẹ́yìn náà, Ọlọrun tún àṣẹ náà pa pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ wólẹ̀ fún ọlọrun mìíràn, nítorí Jehofa, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Òjòwú, Ọlọrun owú ni òun.”—Eksodu 34:14, NW.

Baali Peoru

7, 8. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Israeli ṣe ṣubú sínú ìbọ̀rìṣà wíwúwo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Baali Peoru? (b) Báwo ni àrùn lùkúlùkú láti ọwọ́ Jehofa ṣe wá sí òpin?

7 Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Israeli wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, àwọn obìnrin Moabu àti Midiani tí wọ́n jojú ní gbèsè dẹ àwọn ọmọ Israeli láti wá, kí wọ́n sì gbádùn aájò àlejò wọn. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ì bá ti kọ àjọṣepọ̀ wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn olùjọsìn àwọn ọlọrun èké. (Eksodu 34:12, 15) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sáré bí àgùntàn tí ń lọ sí ibùpa, ní bíbá àwọn obìnrin náà ṣe àgbèrè, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wọn ní fíforíbalẹ̀ fún Baali Peoru.—Numeri 25:1-3; Owe 7:21, 22.

8 Jehofa rán àrùn lùkúlùkú láti pa àwọn wọnnì tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn oníbàálòpọ̀ títinilójú yìí. Ọlọrun tún pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israeli aláìmọwọ́mẹsẹ̀ láti pa àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ̀bi. Nínú ìṣàyàgbàǹgbà aláfojúdi, ìjòyè kan ní Israeli, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simri, mú ọmọ ọba Midiani kan wọ inú àgọ́ rẹ̀ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ní gígán-án-ní èyí, Finehasi, àlùfáà náà tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, pa àwọn oníwà pálapàla méjèèjì náà. Lẹ́yìn náà, àrùn lùkúlùkú náà dáwọ́ dúró, Ọlọrun sì polongo pé: “Finehasi . . . ti yí ìrunú mi padà kúrò lára àwọn ọmọ Israeli; ó fi irú owú ìbínú kan náà tí ó sún mi hàn láàárín wọn, àti nítorí náà, nínú owú mi, èmi kò pa àwọn ọmọ Israeli run pátápátá.” (Numeri 25:11, The New English Bible) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gba orílẹ̀-èdè náà là kúrò lọ́wọ́ ìparun, ó kéré tán, 23,000 àwọn ọmọ Israeli kú. (1 Korinti 10:8) Wọ́n pàdánù ìrètí wọn tí wọ́n ti ń ṣìkẹ́ tipẹ́tipẹ́ ti wíwọnú Ilẹ̀ Ìlérí náà.

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n

9. Kí ni ó ṣubú tẹ àwọn ènìyàn Israeli àti Juda nítorí pé wọn kò jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa?

9 Ó bani nínú jẹ́ pé, kò pẹ́ púpọ̀ tí àwọn ọmọ Israeli fi gbàgbé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí. Wọn kò fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n ń jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa. “Wọ́n sì fi ère fínfín wọn mú [Ọlọrun] jowú.” (Orin Dafidi 78:58) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, Jehofa yọ̀ǹda pé kí àwọn ará Assiria kó àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá ti Israeli ní ìgbèkùn ní 740 B. C. E. Ẹ̀yà méjì ti Juda tí ó ṣẹ́ kù fojú winá irú ìjìyà kan náà, nígbà tí a pa Jerusalemu, olú ìlú wọn run ní ọdún 607 B.C.E. A pa ọ̀pọ̀lọpọ̀, a sì kó àwọn olùlàájá ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ẹ wo irú apẹẹrẹ àríkọ́gbọ́n tí èyí jẹ́ fún àwọn Kristian lónìí!—1 Korinti 10:6, 11.

10. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn abọ̀rìṣà tí wọn kò ronú pìwà dà?

10 Ìdá mẹ́ta nínú àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé—nǹkan bíi 1,900 million—sọ pé àwọn jẹ́ Kristian. (1994 Britannica Book of the Year) Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn wọ̀nyí jẹ́ mẹ́ḿbà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ń lo ère ìsìn, ère, àti àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn. Jehofa kò dá àwọn ènìyàn tirẹ̀ tí wọ́n sún un láti jowú nípasẹ̀ ìbọ̀rìṣà wọn sí. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò dá àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ tí wọ́n ń jọ́sìn nípa lílo àwọn ohun tí ó ṣeé fojú rí sí. Jesu wí pé: “Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí, awọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:24) Síwájú síi, Bibeli kìlọ̀ fún àwọn Kristian láti ṣọ́ra fún ìbọ̀rìṣà. (1 Johannu 5:21) Àwọn abọ̀rìṣà tí wọn kò ronú pìwà dà wà lára àwọn tí kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun.—Galatia 5:20, 21.

11. Báwo ni Kristian kan ṣe lè jẹ̀bi ìbọ̀rìṣà láìjẹ́ pé ó forí balẹ̀ fún òrìṣà, kí sì ni yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti yẹra fún irú ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀? (Efesu 5:5)

11 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristian tòótọ́ kan kì yóò forí balẹ̀ fún òrìṣà kan láé, ó gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tí Ọlọrun bá kà sí ìbọ̀rìṣà, àìmọ́, àti ẹ̀ṣẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli kìlọ̀ pé: “Ẹ sọ awọn ẹ̀yà-ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé di òkú níti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣenilọ́ṣẹ́, ati ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Nítìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọrun fi ń bọ̀.” (Kolosse 3:5, 6) Ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń béèrè fún kíkọ ìwà pálapàla. Èyí ń béèrè fún yíyẹra fún eré ìnàjú tí a wéwèé láti ru ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo aláìmọ́ sókè. Dípò títẹ́ irú ìyánhànhàn bẹ́ẹ̀ lọ́rùn, àwọn Kristian tòótọ́ ń jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun.

Àwọn Àpẹẹrẹ Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín ti Owú ti Ọlọrun

12, 13. Báwo ni Jesu ṣe fi àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá lélẹ̀ ní fífi owú hàn fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun?

12 Àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá jù lọ ti ènìyàn tí ó fi owú hàn fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun ni Jesu Kristi. Ní ọdún àkọ́kọ́ ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó rí àwọn oníwọra oníṣòwò tí ń tajà ní àgbàlá tẹ́ḿpìlì. Àwọn Júù olùṣèbẹ̀wò ti lè nílò iṣẹ́ àwọn olùpààrọ̀ owó wọ̀nyí láti pa owó ilẹ̀ òkèèrè wọn dà sí owó tí yóò ṣe ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí owó-orí tẹ́ḿpìlì. Wọ́n tún ní láti ra àwọn ẹran àti ẹyẹ láti lè ṣe ìrúbọ tí Òfin Ọlọrun béèrè. Irú káràkátà bẹ́ẹ̀ ni wọn ì bá ti máa ṣe ní ẹ̀yìn òde àgbàlá tẹ́ḿpìlì. Èyí tí ó burú jù ni pé, ẹ̀rí hàn gbangba pé àwọn oníṣòwò náà ń lo àǹfààní tí kò tọ́ ti àìní ní ti ìsìn tí àwọn arákùnrin wọn ní nípa ṣíṣá iye gọbọi lé wọn. Nítorí owú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun tí ó jẹ ẹ́ tán, Jesu lo pàṣán láti lé àwọn àgùtàn àti màlúù náà jáde. Ó tún dojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó náà dé, ní sísọ pé: “Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà!” (Johannu 2:14-16) Nípa báyìí, Jesu mú àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 69:9 ṣẹ pé: “Ìtara [tàbí, “owú,” Byington] ilé rẹ ti jẹ mí tán.”

13 Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jesu tún ṣàkíyèsí pé àwọn oníwọra oníṣòwò ń tajà nínú tẹ́ḿpìlì Jehofa. Jesu yóò ha tún fọ̀ ọ́ mọ́ lẹ́ẹ̀kejì bí? Owú rẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọrun ní agbára gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó lé àwọn olùtà àti olùrà jáde. Ó sì fúnni ní ìdí lílágbára fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀, ní sísọ pé: “A kò ha kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a óò máa pe ilé mi fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè’? Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di hòrò awọn ọlọ́ṣà.” (Marku 11:17) Ẹ wo irú àgbàyanu àpẹẹrẹ ìtẹpẹlẹmọ́ tí èyí jẹ́ ní fífi owú ti Ọlọrun hàn!

14. Báwo ni owú Jesu fún ìjọsìn mímọ́ gaara ṣe ní láti nípa lórí wa?

14 Àkópọ̀ ànímọ́ ti Oluwa Jesu Kristi tí a ti ṣe lógo nísinsìnyí kò tí ì yí padà. (Heberu 13:8) Ní ọ̀rúndún ogún yìí, ó ṣì ń jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Bàbá rẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó tí ṣe nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ni a lè rí nínú ìhìn iṣẹ́ Jesu sí àwọn ìjọ méje tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá. Àwọn wọ̀nyí ní ìfisílò pàtàkì wọn lónìí, ní “ọjọ́ Oluwa.” (Ìṣípayá 1:10; 2:1–3:22) Nínú ìran, aposteli Johannu rí Jesu Kristi tí a ti ṣe lógo pẹ̀lú “ojú . . . bí ọwọ́ iná ajófòfò.” (Ìṣípayá 1:14) Èyí fi hàn pé kò sí ohunkóhun tí ó ré kọjá àfiyèsí Kristi bí ó ṣe ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ láti rí i dájú pé wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, tí wọ́n sì yẹ fún iṣẹ́ ìsìn Jehofa. Àwọn Kristian òde òní ní láti fi ìkìlọ̀ Jesu lòdì sí gbígbìyànjú láti sin ọ̀gá méjì sọ́kàn—Ọlọrun àti ọrọ̀. (Matteu 6:24) Jesu sọ fún àwọn mẹ́ḿbà ìjọ Laodikea tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì pé: “Nitori pé iwọ lọ́wọ́ọ́wọ́ tí o kò sì gbóná tabi tutù, emi yoo pọ̀ ọ́ jáde kúrò ní ẹnu mi. . . . Jẹ́ onítara kí o sì ronúpìwàdà.” (Ìṣípayá 3:14-19) Nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ ní láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti yẹra fún páńpẹ́ ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ dáàbò bo agbo kúrò lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ ti ọ̀nà ìwà rere ti ayé tí ìbálòpọ̀ ti gbà lọ́kàn yìí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ènìyàn Ọlọrun kò ní láti gbójú gbóyà láti fàyè gba ipa ìdarí èyíkéyìí tí ó jẹ́ ti Jesebeli nínú ìjọ.—Heberu 12:14, 15; Ìṣípayá 2:20.

15. Báwo ni aposteli Paulu ṣe ṣàfarawé Jesu nínú fífi owú hàn fún ìjọsìn Jehofa?

15 Aposteli Paulu jẹ́ aláfarawé Kristi. Láti dáàbò bo àwọn Kristian tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí kúrò lọ́wọ́ ipa ìdarí tí kò sunwọ̀n nípa tẹ̀mí, ó wí pé: “Nitori emi ń jowú lórí yín pẹlu owú lọ́nà ti Ọlọrun.” (2 Korinti 11:2) Ṣáájú àkókò yìí, owú Paulu fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti sún un láti fún ìjọ kan náà yìí ní ìtọ́ni láti yọ alágbèrè tí kò bá ronú pìwà dà tí ó jẹ́ akéèrànranni lẹ́gbẹ́. Ìtọ́ni tí a mí sí ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn alàgbà lónìí, bí wọ́n ṣe ń làkàkà láti mú kí àwọn ìjọ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó lé ní 75,500 wà ní mímọ́ tónítóní.—1 Korinti 5:1, 9-13.

Owú Lọ́nà ti Ọlọrun Ṣàǹfààní fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀

16, 17. (a) Nígbà tí Ọlọrun fìyà jẹ Juda ìgbàanì, ìṣarasíhùwà wo ni orílẹ̀-èdè náà fi hàn? (b) Lẹ́yìn kíkó Juda nígbèkùn fún 70 ọdún, báwo ni Jehofa ṣe fi owú rẹ̀ fún Jerusalemu hàn?

16 Nígbà tí Ọlọrun fìyà jẹ àwọn ará Juda nípa yíyọ̀ǹda kí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, a fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́. (Orin Dafidi 137:3) Nínú owú oníkòórìíra, àwọn ará Edomu tilẹ̀ ran àwọn ará Babiloni lọ́wọ́ láti mú àjálù ibi wá sórí àwọn ènìyàn Ọlọrun, Jehofa sì ṣàkíyèsí èyí. (Esekieli 35:11; 36:15) Ní ìgbèkùn, àwọn olùlàájá náà ronú pìwà dà, Jehofa sì dá wọn padà sí ilẹ̀ wọn lẹ́yìn 70 ọdún.

17 Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ará Juda wà nínú ìṣòro líle koko. Ìlú-ńlá Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ wà ní ahoro. Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká ta ko gbogbo ìsapá láti ṣàtúnkọ́ tẹ́ḿpìlì náà. (Esra 4:4, 23, 24) Kí ni ìmọ̀lára Jehofa nípa èyí? Àkọsílẹ̀ onímìísí sọ pé: “Báyìí ni Jehofa àwọn ọmọ ogun wí: ‘Mo ti ń jowú fún Jerusalemu àti fún Sioni pẹ̀lú owú ńláǹlà. Pẹ̀lú ìkannú ńláǹlà, mo ń nímọ̀lára ìkannú lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ará rọ̀; nítorí pé èmi, níhà ọ̀dọ̀ mi, nímọ̀lára ìkannú dé ìwọ̀n àyè díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn, níhà ọ̀dọ̀ wọn, ṣètìlẹ́yìn síhà àjálù ibi.’ Nítorí náà, báyìí ni Jehofa wí, ‘Dájúdájú, èmi yóò padà sí Jerusalemu pẹ̀lú àánú. A óò kọ́ ilé tèmi fúnra mi sínú rẹ̀,’ ni ọ̀rọ̀ àsọjáde Jehofa àwọn ọmọ ogun.” (Sekariah 1:14-16, NW) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí yìí, a tún tẹ́ḿpìlì náà àti ìlú ńlá Jerusalemu kọ́ pẹ̀lú àṣeyọrí.

18. Kí ni àwọn Kristian tòótọ́ ní ìrírí rẹ̀ nígbà ogun àgbáyé kìíní?

18 Ìjọ Kristian tòótọ́ ní ìrírí tí ó fara jọ ọ́ ní ọ̀rúndún ogún. Nígbà ogun àgbáyé kìíní, Jehofa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí nítorí pé wọn kò wà láìdá sí tọ̀túntòsì délẹ̀délẹ̀ nínú ìforígbárí ti ayé náà. (Johannu 17:16) Ọlọrun yọ̀ǹda fún àwọn òṣèlú alágbára láti ni wọ́n lára, inú àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm sì dùn sí àjálù yìí. Ní tòótọ́, àwùjọ àlùfáà mú ipò iwájú nínú mímú kí àwọn òṣèlú fòfin de iṣẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà náà.—Ìṣípayá 11:7, 10.

19. Báwo ni Jehofa ṣe fi owú hàn fún ìjọsìn rẹ̀ láti 1919?

19 Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa fi owú hàn sí ìjọsìn rẹ̀ ó sì mú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà padà wá sí ojúrere rẹ̀ lẹ́yìn tí ogun náà parí ní 1919. (Ìṣípayá 11:11, 12) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, iye àwọn olùyin Jehofa ti pọ̀ sí i láti orí iye tí kò tó 4,000 ní 1918 sí iye tí ó lé ní million 5 lónìí. (Isaiah 60:22) Láìpẹ́, owú Jehofa fún ìjọsìn mímọ́ gaara rẹ̀ ni a óò fi hàn ní àwọn ọ̀nà tí ó túbọ̀ rùmọ̀lára sókè.

Àwọn Ìṣe Ọjọ́ Ọ̀la ti Owú Àtọ̀runwá

20. Kí ni Ọlọrun yóò ṣe láìpẹ́ láti fi owú rẹ̀ hàn fún ìjọsìn mímọ́ gaara?

20 Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọmu ti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ti àwọn Júù apẹ̀yìndà tí wọ́n sún Jehofa láti jowú. (Esekieli 8:3, 17, 18) Láìpẹ́, Jehofa Ọlọrun yóò gbé ìgbésẹ̀ nípa gbígbin ìrònú mímúná sínú ọkàn àyà àwọn mẹ́ḿbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Èyí yóò sún àwọn òṣèlú alágbára wọ̀nyí láti sọ Kristẹndọmu àti ìyókù ìsìn èké di ahoro. (Ìṣípayá 17:16, 17) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò la ìmúdàájọ́ṣẹ tí ń kó jìnnìjìnnì báni náà ti ìdájọ́ àtọ̀runwá já. Wọn yóò dáhùn padà sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀dá òkè ọ̀run náà tí wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn! . . . Nitori pé ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá [ìsìn èké] naa tí ó fi àgbèrè rẹ̀ [àwọn ẹ̀kọ́ èké rẹ̀ àti títi ìwà ìbàjẹ́ òṣèlú lẹ́yìn] sọ ilẹ̀-ayé di ìbàjẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ awọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.”—Ìṣípayá 19:1, 2.

21. (a) Kí ni Satani àti ètò-ìgbékalẹ̀ rẹ̀ yóò ṣe lẹ́yìn tí a bá ti pa ìsìn èké run? (b) Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe hùwà padà?

21 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé? Satani yóò sún àwọn òṣèlú alágbára láti gbé ìjà kárí ayé dìde lòdì sí àwọn ènìyàn Jehofa. Báwo ni Ọlọrun òtítọ́ yóò ṣe hùwà padà sí ìgbìdánwò yìí láti ọwọ́ Satani láti pa ìjọsìn tòótọ́ rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Esekieli 38:19-23 sọ fún wa pé: “Ní ìjòwú mi àti ní iná ìbínú mi ni mo [Jehofa] ti sọ̀rọ̀, . . . Èmi óò sì fi àjàkálẹ̀ àrùn àti ẹ̀jẹ̀ bá a [Satani] wíjọ́; èmi óò sì rọ òjò púpọ̀, àti yìnyín ńlá, iná àti brimstone, sí i lórí, àti sórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, àti sórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Èmi óò sì gbé ara mi lékè, èmi óò sì ya ara mi sí mímọ́; èmi óò sì di mímọ́ lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni Oluwa.”—Tún wo Sefaniah 1:18; 3:8.

22. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ń jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa?

22 Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé Ọba Aláṣẹ àgbáyé ń bójú tó àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́ pẹ̀lú owú! Nítorí ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa Ọlọrun. Pẹ̀lú ìtara, ǹjẹ́ kí a máa bá a lọ láti wàásù ìhìnrere náà kí a sì fi pẹ̀lú ìgbọ́kànlé dúró dé ọjọ́ kíkàmàmà náà, nígbà tí Jehofa yóò gbé orúkọ ńlá rẹ̀ ga, tí yóò sì yà á sí mímọ́.—Matteu 24:14.

Àwọn Kókó fún Ṣíṣàṣàrò

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti jowú fún Jehofa?

◻ Kí ni a lè rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ tí àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì fi lélẹ̀?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún sísún Jehofa láti jowú?

◻ Báwo ni Ọlọrun àti Kristi ti ṣe fi owú hàn fún ìjọsìn mímọ́ gaara?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìfẹ́ Kì í Jowú

NÍPA ìlara, Albert Barnes ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bibeli ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà wíwọ́pọ̀ jù lọ tí a gbà ń fi ìwà burúkú hàn, ó sì fi bí ìwà ìbàjẹ́ ènìyàn ti jinlẹ̀ tó hàn ní kedere.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ẹni tí ó bá lè tọpasẹ̀ gbogbo ogun àti asọ̀ àti ìwéwèé ayé dé orísun wọn—gbogbo rìkíṣí àti ète àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ pàápàá, tí ó ṣe púpọ̀ láti kó àbàwọ́n bá ìsìn wọn tí ó sì mú kí wọ́n di ẹlẹ́mìí ayé, dé orísun náà gan-an—yóò ṣe kàyéfì láti rí itú tí ìlara ti pa. Ó ń dùn wá pé àwọn ẹlòmíràn ní aásìkí jù wá lọ; a fẹ́ láti ní ohun tí àwọn ẹlòmíràn ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní ẹ̀tọ́ sí i; èyí sì ń yọrí sí oríṣiríṣi ọ̀nà ẹ̀bi tí a ń gbà láti dín bí wọ́n ṣe ń gbádùn rẹ̀ tó kù, tàbí láti gbà á fún ara wa, tàbí láti fi hàn pé wọn kò ní tó bí ọ̀pọ̀ ṣe lérò pé wọ́n ní. . . . Nípa báyìí a óò tẹ́ ẹ̀mí ìlara tí ń bẹ nínú ọkàn wa lọ́rùn.”—Romu 1:29; Jakọbu 4:5.

Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, Barnes sọ gbólóhùn kan tí ó runi lọ́kàn sókè nípa ìfẹ́, tí “kì í ṣe ìlara.” (1 Korinti 13:4, King James Version) Ó kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ kì í ṣe ìlara ayọ̀ tí àwọn ẹlòmíràn ń gbádùn; ó ń ní inúdídùn nínú ire wọn; bí ayọ̀ wọn ṣe ń pọ̀ sí i . . . , àwọn wọnnì tí ìfẹ́ ń darí . . . kì yóò dín in kù; wọn kì yóò dójú tì wọ́n nítorí àǹfààní wọn; wọn kì yóò dín ayọ̀ yẹn kù; wọn kì yóò kùn tàbí kábàámọ̀ pé a kò fi ojúrere gíga hàn sí àwọn alára. . . . Bí a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn—bí a bá yọ̀ sí ayọ̀ wọn, a kò ní láti ṣe ìlara wọn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Finehasi jowú fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́