Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kẹta
NÍ BURMA, ní ọdún 1824—Àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọn ilé míṣọ́nnárì tí Adoniram àti Ann Judson ń gbé yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ tán ni, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n rò pé ó ṣeyebíye lọ. Ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan tí ó ṣeyebíye jù lọ—Bíbélì tí a túmọ̀, tí a fọwọ́ kọ, tí Ann ti bò mọ́lẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ sábẹ́ ilé wọn. Adoniram, olùtúmọ̀ náà, tí a fẹ̀sùn kàn pé ó ń ṣamí, dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ó kún fún ẹ̀fọn. Wàyí o, ọ̀rinrin ti fẹ́ ba ìwé àfọwọ́kọ náà jẹ́. Kí ni a lè ṣe kí ó má baà bà jẹ́? Ann gbé e sínú ìrọ̀rí líle koránkorán kan, ó rán ìrọ̀rí náà lẹ́nu pa, ó sì lọ gbé e fún ọkọ rẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. A tọ́jú ìrọ̀rí náà, ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ sì wá di apá kan Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Burmese.
Jálẹ̀ ìtàn, Bíbélì ti la ọ̀pọ̀ irú ewu bẹ́ẹ̀ kọjá. Nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ó ti kọjá, a ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe túmọ̀ Bíbélì àti bí a ṣe pín in kiri láti ìgbà tí a ti parí rẹ̀, títí dé ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1600. Kí ni ó ti wá ṣẹlẹ̀ sí Bíbélì láti ìgbà náà títí di ìsinsìnyí? Ó ha lè ṣeé ṣe kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn bí? Ipa wo ni Watch Tower Society ti kó?
Àwọn Míṣọ́nnárì àti Àwọn Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìlọsókè gidigidi nínú iye àwọn tí ń ka Bíbélì sàmì sí àwọn ọdún 1600 àti 1700. Ní pàtàkì, Bíbélì nípa lórí England gidigidi ní àkókò yí. Ní tòótọ́, àwọn ìtàn Bíbélì àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ gba gbogbo àwọn tí ń gbé orílẹ̀-èdè náà lọ́kàn tán, látorí ọba títí dórí ọmọdékùnrin tí ń túlẹ̀. Ṣùgbọ́n ipa tí Bíbélì ní tún lọ jìnnà sí i. Nígbà náà, England jẹ́ ibùjókòó ìṣòwò ojú òkun àti ìgbókèèrè ṣàkóso, àwọn ọkùnrin Gẹ̀ẹ́sì kan sì máa ń kó Bíbélì lọ́wọ́ bí wọ́n bá ti ń rin ìrìn àjò. Èyí fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìmúgbòòrò ìgbétásì Bíbélì.
Nígbà tí àwọn ọdún 1700 ń parí lọ, Bíbélì ru àwọn kan ní England sókè láti ronú nípa àìní tẹ̀mí ti àwọn ọmọ ìbílẹ̀, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ilẹ̀ jíjìnnà réré tí ó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ibi gbogbo ni a ti ṣe irú àníyàn yí. Ọ̀pọ̀ àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́, nítorí bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí àwọn kan máà rí ìgbàlà. Nígbà tí míṣọ́nnárì lọ́la, William Carey, sọ̀rọ̀ onítara láti ru àwọn ènìyàn sókè láti gbárùkù ti ẹgbẹ́ tí a fẹ́ rán lọ sí Íńdíà lẹ́yìn, ẹnì kan bá a wí pé: “Àwé, lọ jókòó; nígbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ yí àwọn abọgibọ̀pẹ̀ lọ́kàn pa dà, Yóò ṣe é láìsí ìrànlọ́wọ́ rẹ!” Síbẹ̀síbẹ̀, Carey wọkọ̀ òkun lọ sí Íńdíà ní 1793. Ó yani lẹ́nu pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó tú Bíbélì lódindi tàbí lápá kan sí èdè Íńdíà 35.
Àwọn míṣọ́nnárì wá rí i pé Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ ni irin iṣẹ́ wọn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. Ṣùgbọ́n, ta ni yóò pèsè Bíbélì? Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, láìmọ̀, Mary Jones, ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún kan, tí ó jẹ́ ará Wales, tanná ran ìdásílẹ̀ àjọ kan tí yóò tan Bíbélì ká gbogbo ayé. Ní ọdún 1800, Mary fẹsẹ̀ rin 40 kìlómítà láìwọ bàtà, láti lọ ra Bíbélì èdè Welsh lọ́wọ́ àlùfáà kan. Ọdún mẹ́fà ni ó fi tu owó tí ó fẹ́ fi rà á jọ, nígbà tí Mary sì gbọ́ pé a ti ta gbogbo Bíbélì náà tán, ó bú sẹ́kún kíkorò. Nítorí tí àánú rẹ̀ ṣe é, àlùfáà náà fún Mary ní ọ̀kan nínú Bíbélì tirẹ̀ fúnra rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, àlùfáà náà ronú nípa ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n nílò Bíbélì, ó sì jíròrò ìṣòro náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó wà ní London. Ohun tí ó yọrí sí ni dídá Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Britain àti Ilẹ̀ Àjèjì sílẹ̀, ní ọdún 1804. Ète rẹ̀ kò díjú: Láti pèsè Bíbélì tí agbára àwọn ènìyàn lè ká, tí a tẹ̀ “láìní àkíyèsí tàbí àlàyé etí ìwé,” ní èdè tiwọn. Nípa yíyọ àlàyé etí ìwé kúrò, àwọn olùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ náà retí láti yẹra fún awuyewuye lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì náà kì í fohùn ṣọ̀kan lórí ìwé Apocrypha, batisí nípa ìrìbọmi, àti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.
Ìtara àkọ́kọ́ tàn kálẹ̀ kíákíá, nígbà tí yóò sì fi di ọdún 1813, a ti dá àwọn ẹgbẹ́ mìíràn tí iṣẹ́ wọn so mọ́ ọn sílẹ̀ ní Germany, Netherlands, Denmark, àti Rọ́ṣíà. Nígbà tí ó yá, a fi àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì ní àwọn ilẹ̀ míràn kún un. Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì ti àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbé àwọn ète wọn kalẹ̀, wọ́n rò pé èdè pàtàkì tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lágbàáyé ń lò kò tó nǹkan. Wọn kò lálàá rẹ̀ rí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè pàtàkì bẹ́ẹ̀ ni ó wà! Ní ìfiwéra, àwọn olùtúmọ̀ tí wọ́n ní ìmọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì kò pọ̀ tó láti ṣètumọ̀ ní tààràtà sí èdè ìbílẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Britain àti Ilẹ̀ Àjèjì ṣonígbọ̀wọ́ ìṣètumọ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùtúmọ̀ máa ń gbé iṣẹ́ wọn ka Bíbélì King James Version lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Àdánwò Olùtúmọ̀ Kan
Ọ̀pọ̀ ohun tí ó wà nínú Bíbélì jẹ́ ìtàn àti àkàwé tí a gbé ka ìrírí ojoojúmọ́. Èyí mú kí títúmọ̀ rẹ̀ rọrùn ju kí ó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ oréfèé, ti ọgbọ́n èrò orí ni a fi kọ ọ́. Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, ìsapá àwọn míṣọ́nnárì ní ìbẹ̀rẹ̀ mú ìtumọ̀ tí ó ń rúni lójú tàbí tí ń pani lẹ́rìn-ín jáde. Fún àpẹẹrẹ, ìtumọ̀ kan fún àwọn tí ń gbé ní apá ibì kan ní Íńdíà ní èrò náà pé aláwọ̀ dúdú bí aró ni Ọlọ́run jẹ́. Ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n lò fún “ọ̀run” nínú gbólóhùn náà “Bàbá . . . ọ̀run” túmọ̀ sí “ẹni tí ó ní àwọ̀ tí ó jọ ti sánmà”—ojú ọ̀run!
Nípa ìṣòro tí àwọn olùtúmọ̀ ń bá pàdé, Adoniram Judson kọ̀wé ní ọdún 1819 pé: ‘Nígbà tí a ń kọ́ èdè tí àwọn mìíràn ní apá kejì ayé ń sọ, àwọn tí ìsọ̀rọ̀ wọn jẹ́ tuntun pátápátá sí wa, tí gbogbo lẹ́tà àti ọ̀rọ̀ wọn kò sì bá ti èdè míràn tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí mu rárá; tí a kò ní ìwé atúmọ̀ èdè tàbí ògbufọ̀, tí a sì gbọ́dọ̀ gbọ́ èdè náà díẹ̀, kí a tó lè gba olùkọ́ tí yóò kọ́ wa—iṣẹ́ ńlá ni ìyẹn jẹ́!’ Iṣẹ́ àwọn olùtúmọ̀ bíi Judson ti mú kí Bíbélì túbọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó.—Wo ṣáàtì ní ojú ìwé 12.
Ann Judson ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí ó ṣòro ti títúmọ̀. Ṣùgbọ́n àdánwò tí ìdílé Judson dojú kọ ju ti ìmọ̀ lọ. Ó kù fẹ́ẹ́rẹ́ kí Ann bímọ, ni àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba wọ́ Adoniram lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Pẹ̀lú ìgboyà, fún oṣù 21, ó rọ àwọn ẹmẹsẹ̀ ọba tí wọ́n rorò pé kí wọ́n tú ọkọ òun sílẹ̀. Ìrírí agbonijìgì náà pẹ̀lú àìsàn tí ó ń ṣe é, gbò ó gidigidi. Kò pẹ́ tí wọ́n tú Adoniram sílẹ̀ ni àrùn ibà pa Ann rẹ̀ onígboyà àti ọmọdébìnrin rẹ̀ kékeré. Ọkàn Adoniram bà jẹ́ gidigidi. Síbẹ̀, ó yíjú sí Ọlọ́run fún okun, ó sì ń bá iṣẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀ lọ, ní píparí Bíbélì lédè Burmese ní ọdún 1835. Láàárín àkókò náà, àwọn ìpèníjà míràn tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ dìde nípa Bíbélì.
Awuyewuye Yí Bíbélì Ká
Awuyewuye ńláǹlà ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìṣèlú wáyé ní àwọn ọdún 1800, nígbà míràn, awuyewuye náà máa ń dá lórí Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífi olú ọba àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe aláfẹ̀yìntì wọn, kò pẹ́ kò jìnnà tí wọ́n fi tú ẹgbẹ́ náà ká, tí wọ́n sì fòfin dè wọ́n. (Àwọn alátakò Ẹgbẹ́ náà ti dáná sun ẹgbẹẹgbẹ̀rún Bíbélì ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú.) Wàyí o, àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ń fi ìgbóná ọkàn wá ọ̀nà láti fòpin sí ohun tí àwọn Kristẹni ìjímìjí ti fi ìtara bẹ̀rẹ̀—pípín Bíbélì káàkiri gbogbo ayé. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún rin kinkin mọ́ ọn pé Bíbélì ń wu ọlá àṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì àti ti Ìjọba léwu. Lọ́nà títakora, ẹgbẹ́ ìṣèlú aṣèyípadà tegbò tigaga tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ka Bíbélì sí irin iṣẹ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba ń lò láti mú kí àwọn aráàlú panu mọ́, kì í sì í ṣe ìwé tí ń wu ọlá àṣẹ léwu. Ìhà méjèèjì ni a ti ń gbógun ti Bíbélì!
Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e, “àwọn ọlọ́gbọ́n” gbé àtakò púpọ̀ sí i dìde sí Bíbélì. Ní ọdún 1831, Charles Darwin rìnrìn àjò òkun láti ṣèwádìí tí ó yọrí sí àbá èrò orí rẹ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n. Ní ọdún 1848, Marx àti Engeles tẹ Communist Manifesto jáde, ó fi ẹ̀sìn Kristẹni hàn gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ ìninilára. Bákan náà ní àkókò yí, àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ gbé ìbéèrè dìde sí ìjótìítọ́ Ìwé Mímọ́ àti ìṣeégbáralé ìtàn àwọn ẹ̀dá inú Bíbélì—àní ti Jésù alára! Ṣùgbọ́n àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onílàákàyè rí àṣìrò tí ó wà nínú àwọn àbá èrò orí tí ó kọ Ọlọ́run àti Bíbélì sílẹ̀, wọ́n sì wá àwọn onímọ̀ gíga tí ó lè jẹ́rìí sí ìṣeégbáralé Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí ni Konstantin von Tischendorf, ọmọ ilẹ̀ Germany tí ó lẹ́bùn èdè púpọ̀.
Àwọn Àwárí Ṣèrànwọ́ Láti Fìdí Àwọn Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Múlẹ̀
Tischendorf rìnrìn àjò jákèjádò Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ní wíwá àwọn ìwé Bíbélì ìgbàanì tí a fọwọ́ kọ kiri, tí ó sì ní in lọ́kàn láti fìdí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ múlẹ̀ dáradára. Ní ọdún 1859, ọdún kan náà tí Darwin tẹ ìwé rẹ̀ The Origin of Species jáde, nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan tí ó wà lẹ́sẹ̀ Òkè Sínáì, Tischendorf rí odindi Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí ọjọ́ rẹ̀ ṣì pẹ́ jù lọ. A mọ̀ ọ́n sí Codex Sinaiticus, ó sì ṣeé ṣe kí a ti tẹ̀ ẹ́ jáde ní nǹkan bí 50 ọdún ṣáájú kí Jerome tó parí Bíbélì Vulgate lédè Látìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjiyàn ń lọ lọ́wọ́ lórí bóyá mímú tí ó mú ìwé àfọwọ́kọ alábala náà kúrò nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tọ́ tàbí kò tọ́, Tischendorf tẹ̀ ẹ́ jáde, ní títipa báyìí mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ rí i lò.a
Nítorí tí Sinaiticus jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ, kì í ṣe pé ó ṣí i payá pé Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì kò tí ì yí pa dà nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ran àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lọ́wọ́ láti fi àwọn àṣìṣe tí ó ti yọ́ wọnú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí ó dé kẹ́yìn hàn. Fún àpẹẹrẹ, ibi tí a ti tọ́ka sí Jésù nínú Tímótì Kíní 3:16 nínú Sinaiticus kà pé: “A fi í hàn nínú ẹran ara.” Dípò “í,” ọ̀rọ̀ ìkékúrú fún “Ọlọ́run” ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí a mọ̀ nígbà náà lò, wọ́n ṣe èyí nípa yíyí ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “í” pa dà díẹ̀. Ṣùgbọ́n, a ti kọ Sinaiticus fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìwé àfọwọ́kọ Gíríìkì èyíkéyìí tí ó lo “Ọlọ́run” nínú ìtumọ̀ tirẹ̀. Nípa báyìí, ó ṣí i payá pé lẹ́yìn àkókò díẹ̀, awúrúju wọ inú ẹsẹ náà, ó sì hàn gbangba pé a mú un wọ̀ ọ́ láti lè fi ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn.
Láti ìgbà ayé Tischendorf wá, ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ mìíràn ti wá sí ojútáyé. Lónìí, àpapọ̀ iye ìwé àfọwọ́kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a mọ̀ tó nǹkan bí 6,000, ti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sì lé ní 13,000. Àfiwéra ìwádìí tí a ṣe nípa ìwọ̀nyí ti fi hàn pé wọ́n jẹ́ ìwé èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá. Bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ F. F. Bruce ti sọ: “Ìyàtọ̀ nínú ọ̀nà ìtumọ̀ . . . kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú òtítọ́ ìtàn tàbí ìgbàgbọ́ àti ìṣe Kristẹni.” Bí títúmọ̀ Bíbélì sí ọ̀pọ̀ èdè ṣe ń bá a nìṣó, báwo ni ìmọ̀ tí ń pọ̀ sí i yìí ṣe lè ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn?
Watch Tower Society àti Bíbélì
Ní ọdún 1881 akérékorò ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dá ohun tí a wá mọ̀ sí Watch Tower Bible and Tract Society sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, Bíbélì tí àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì míràn ń tẹ̀ jáde ni wọ́n ń pín kiri, títí kan Ìwé Mímọ́ ti Tischendorf Lédè Gíríìkì. Ṣùgbọ́n, nígbà tí yóò fi di ọdún 1890, wọ́n ti wọnú títẹ Bíbélì jáde ní tààràtà, ní ṣíṣonígbọ̀wọ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì. Ní 1926, Society bẹ̀rẹ̀ sí tẹ Bíbélì jáde lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tirẹ̀. Ṣùgbọ́n ó túbọ̀ ń hàn gbangba pé a nílò ìtumọ̀ Bíbélì tí ó bá ìgbà mu. A ha lè mú ìmọ̀ tí a jèrè nípasẹ̀ àwárí àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ọ̀rúndún tí ó kọjá wọnú Bíbélì kan tí ó rọrùn láti lóye, tí owó rẹ̀ kò sì ní pọ̀ bí? Pẹ̀lú ète yìí lọ́kàn, ní ọdún 1946, àwọn alábàáṣiṣẹ́ Society bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti mú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ tuntun jáde.
Ìtumọ̀ Kan, Ọ̀pọ̀ Èdè
A ṣètò ìgbìmọ̀ olùtúmọ̀ ti àwọn ọkùnrin Kristẹni onírìírí tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró láti mú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. A tẹ̀ ẹ́ sí ìdìpọ̀ mẹ́fà, a mú wọn jáde láti ọdún 1950 títí di 1960, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni a sì fi bẹ̀rẹ̀. Láti 1963, a ti tú u sí èdè 27 mìíràn, ọ̀pọ̀ sì ń lọ lọ́wọ́. Góńgó kan náà tí a ní fún èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a ní fún àwọn èdè yòó kù. Àkọ́kọ́ ni pé, ìtumọ̀ náà gbọ́dọ̀ ṣe rẹ́gí, kí ó sún mọ́ èrò tí ó wà nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. A kò gbọ́dọ̀ yí ìtumọ̀ rẹ̀ pa dà láti bá ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan pàtó mu. Èkejì ni pé, a gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ dan-indan-in mú mímú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ bára mu délẹ̀, ìtumọ̀ tí a bá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì pàtàkì gbọ́dọ̀ bára mu délẹ̀ bí àyíká ọ̀rọ̀ wọn bá ti yọ̀ǹda tó. Irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àwọn òǹkàwé rí bí àwọn tí ó kọ Bíbélì ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ kan. Ìkẹta ni pé, ìtumọ̀ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣangiliti bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, láìfi ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí pa mọ́. Ìtumọ̀ ṣangiliti ń mú kí òǹkàwé túbọ̀ mọ adùn àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn èrò tí ó so mọ́ ọn. Ìkẹrin ni pé, ó gbọ́dọ̀ rọrùn fún àwọn gbáàtúù ènìyàn láti kà, kí wọ́n sì lóyè.
Ìtumọ̀ ṣangiliti tí Bíbélì New World Translation lédè Gẹ̀ẹ́sì ni mú kí títúmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè míràn rọrùn. Nítorí ìdí yìí, ẹgbẹ́ olùtúmọ̀ tí Society ń lò ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ń lo àwọn ohun èlò tí ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́, tí ìtẹ̀síwájú ti dé bá, láti mú kí iṣẹ́ wọn túbọ̀ yá kánkán sí i, kí ó sì túbọ̀ péye. Ohun èlò tí ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ yìí ń ṣèrànwọ́ fún àwọn olùtúmọ̀ láti kó àwọn ọ̀rọ̀ èdè ìbílẹ̀ tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì jọ. Ó tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wo ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí a fún ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì fínnífínní.
Títúmọ̀ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì, dípò títúmọ̀ ní tààràtà láti èdè Hébérù àti Gíríìkì, ń mú àwọn àǹfààní pàtàkì wá. Yàtọ̀ sí pé ó ń dín àkókò tí a fi ń túmọ̀ kù, ó ń mú kí bíbáramu ọ̀rọ̀ ní gbogbo èdè túbọ̀ ṣeé ṣe. Èé ṣe? Nítorí pé ó rọrùn láti tú èdè òde òní kan sí èdè òde òní mìíràn lọ́nà ṣíṣe rẹ́gí ju títú èdè àtijọ́ kan sí onírúurú èdè òde òní lọ. Ó ṣe tán, àwọn olùtúmọ̀ lè kàn sí àwọn tí ń sọ èdè ìbílẹ̀ òde òní ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn èdè tí a sọ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.
Ìhìn Rere fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
Ọ̀pọ̀ nǹkan ń bẹ tí a lè kọ nípa àwọn akíkanjú ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti ṣèrànwọ́ láti sọ Bíbélì di ìwé tí a tí ì pín kiri lọ́nà gbígbòòrò jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, ó kéré tán a ti tẹ mílíọ̀nù mẹ́rin Bíbélì àti àwọn apá kan nínú Bíbélì jáde ní èdè tí ó lé ní ẹgbàá kan, tí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ayé ń sọ!
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìpolongo Ìjọba Ọlọ́run ní ọjọ́ wa. Ní ti èyí, ó hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti lọ́wọ́ nínú mímú kí Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó káàkiri àgbáyé. (Mátíù 13:47, 48; 24:14) Nígbà àtijọ́, àwọn olùtúmọ̀ Bíbélì àti àwọn tí ó tẹ̀ ẹ́ jáde, tí wọ́n láyà bíi kìnnìún, ti fara wọn wewu pátápátá láti fún wa ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí kan ṣoṣo nínú ayé tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ti ìwà rere. Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ wọn sún ọ láti ka Ọ̀rọ̀ náà, láti lò ó nínú ìgbésí ayé rẹ, kí o sì fi ìdálójú kan náà tí wọ́n ní ṣàjọpín rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, lójoojúmọ́, lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní láti ka Bíbélì ṣíṣeé gbára lé tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ!—Aísáyà 40:6-8.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Yíyọ Codex Sinaiticus Ninu Ewu” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti October 15, 1988.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìtẹ̀síwájú Nínú Ìtumọ̀ Bíbélì
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Iye Èdè
1 Àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí Gíríìkì ní nǹkan bí 280 B.C.E.
12 Jerome parí Bíbélì Vulgate Lédè Látìn ní nǹkan bí 400 C.E.
35 Gutenberg parí Bíbélì tí a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní nǹkan bí 1455
81 A dá Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Britain àti Ilẹ̀ Àjèjì sílẹ̀ ní 1804
Iye Èdè tí A Fojú
Díwọ̀n Lọ́dọọdún
522
1900
600
700
800
900
1,049
1950
1,100
1,200
1,300
1,471
1970
2,123
1996
2,200
2,300
2,400
[Credit Line]
Orísun Ìsọfúnni: Christianity Today, United Bible Society
[Credit Line on page 9]
Mountain High Maps® Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 1995 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
A de Judson, a sì wọ́ ọ lọ
[Credit Line]
Láti inú ìwé náà, Judson the Hero of Burma, láti ọwọ́ Jesse Page
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Tischendorf rí ìwé àfọwọ́kọ ṣíṣeyebíye kan nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé yìí lẹ́sẹ̀ Òkè Sínáì
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.