Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ní 1998, ohun mánigbàgbé kan sẹlẹ̀ tó dùn mọ́ àwọn tó fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́dún yẹn ni ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù táa ti tẹ̀ jáde. Ó ti wá tipa báyìí di ọ̀kan lára àwọn Bíbélì tí a tíì pín kiri jù lọ ní ọ̀rúndún yìí!
ITÚ ńlá la pa yìí, táa bá ronú nípa pé gbàrà tí ìwé yìí jáde, làwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe lámèyítọ́ rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe pé ìwé náà ṣì wà nìkan ni, àmọ́ ó tún ti wá pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ, ó ti wà nínú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé—àti ọkàn-àyà—jákèjádò ayé! Báwo ni ìtumọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Àwọn wo ló túmọ̀ rẹ̀? Báwo lo sì ṣe lè jèrè nínú rẹ̀ tóo bá ń lò ó?
Ìdí Táa Fi Fẹ́ Ìtumọ̀ Tuntun?
Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí, tí Watch Tower Bible and Tract Society, ẹgbẹ́ tí ń ṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin, ti ń pín Bíbélì kiri. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi rí i pé ó pọndandan láti mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jáde ní ìtumọ̀ mìíràn? Ìwé náà, So Many Versions?, ti Sakae Kubo àti Walter Specht tẹ̀ jáde, wí pé: “Kò sí ìtumọ̀ Bíbélì kan tí a lè kà sí àṣekágbá. Bí ìmọ̀ Bíbélì bá ṣe ń jinlẹ̀ sí i, tí èdè sì ń yí padà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtẹ̀síwájú gbọ́dọ̀ máa bá ọ̀nà táa gbà ń túmọ̀ èdè.”
Ọ̀rúndún yìí ti rí ìtẹ̀síwájú gígalọ́lá nínú òye èdè Hébérù, Gíríìkì, àti Árámáìkì—àwọn èdè táa fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti rí àwọn ìwé Bíbélì tí a fọwọ́ kọ, tó ti wà ṣáájú, tó sì tún péye, èyí tí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ní àwọn ìran ìṣáájú lò. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe láti túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà pípéye lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Abájọ tí a fi gbé Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kalẹ̀ láti bójú tó títúmọ̀ Bíbélì sí èdè òde òní.
Lọ́dún 1950, a mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ni Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àkọlé rẹ̀ nìkan ti fi hàn pé a ò jẹ àgbọ̀nrín èṣí lọ́bẹ̀ mọ́, a ti pa ìlànà pípín Bíbélì sí májẹ̀mú “Láéláé” àti “Tuntun” tì. Nígbà tó fi máa tó ọdún mẹ́wàá sí àkókò yẹn, a ti mú àwọn apá tó jẹ́ ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jáde ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Lọ́dún 1961, àpapọ̀ Bíbélì náà lódindi jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Ẹ gbọ́ ná, ta lo túmọ̀ Bíbélì tí ò láfiwé yìí? Ilé Ìṣọ́ ti September 15, 1950 (Gẹ̀ẹ́sì), wí pé: “Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ atúmọ̀ èdè náà sọ pé àwọn ò fẹ́ . . . kí ẹnikẹ́ni mọ àwọn, pàápàá jù lọ, àwọn ò fẹ́ ká gbé orúkọ wọn jáde yálà lójú ayé wọn tàbí lẹ́yìn táwọn bá kú. Ète ìtumọ̀ náà ni láti gbé orúkọ Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run alààyè, ga.” Làwọn olùṣelámèyítọ́ kan bá yarí o, wọ́n ní àwọn ọ̀gbẹ̀rì atúmọ̀ èdè la kó jọ láti ṣiṣẹ́ yìí, àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn olùṣelámèyítọ́ ló fara mọ́ èrò yìí. Alan S. Duthie kọ̀wé pé: “Ká ní a láǹfààní láti mọ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì kan tàbí àwọn tó tẹ̀ ẹ́ jáde, ṣé ìyẹn ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí wọ́n túmọ̀ dáa tàbí ò dáa? Rárá o. Kò sí ohun mìíràn tó yẹ ká ṣe ju pé ká ṣàyẹ̀wò ìtumọ̀ kọ̀ọ̀kan fínnífínní.”a
Àwọn Ohun Fífanimọ́ra Tí Ò Láfiwé Tó Wà Nínú Rẹ̀
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òǹkàwé ló ti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ti wá rí i pé kì í ṣe pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣeé kà nìkan, àmọ́ ó péye gidigidi. Bíbélì èdè Hébérù, Árámáìkì, àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni àwọn tó ṣètumọ̀ rẹ̀ lò, wọ́n sì rí i pé àwọn lo èyí tó péye jù lọ.b Wọ́n tún kíyè sára gidigidi láti rí i pé àwọn túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà ní ṣáńgílítí bó ti ṣeé ṣe tó, àmọ́ o, wọ́n ṣètumọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó lè tètè yé àwọn èèyàn. Ìdí rèé tàwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fi gbóṣùbà fún ìtumọ̀ yìí, wọ́n ní kò figbá kan bọ̀kan nínú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì péye. Fún àpẹẹrẹ, ìwé náà, Andover Newton Quarterly, ti January 1963, wí pé: “Ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun yìí fi hàn pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń bẹ nínú ìjọ yín, àwọn tó dáńgájíá láti fi òye yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà nínú títúmọ̀ Bíbélì.”
Àwọn atúmọ̀ èdè náà mú òye Bíbélì jáde lákọ̀tun. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí òye wa nípa rẹ̀ kò kún tẹ́lẹ̀ tí wá ṣe kedere lọ́nà tó kàmàmà. Fún àpẹẹrẹ, ẹsẹ tó ń rúni lójú nínú Mátíù 5:3 tó sọ pé, “alábùkún-fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí” (ìtumọ̀ Bibeli Mimọ), ni a ṣètumọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání sí: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tún lo ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo délẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì-pàtàkì. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà psy·kheʹ, la túmọ̀ sí “ọkàn” ni gbogbo ibi tó ti fara hàn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn òǹkàwé lè tètè fòye gbé e pé ní ìyàtọ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn, ọkàn lè kú!—Mátíù 2:20; Máàkù 3:4; Lúùkù 6:9; 17:33.
Dídá Orúkọ Ọlọ́run Padà Sí Àyè Rẹ̀
Àwọn ohun fífanimọ́ra tó tún jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tó wà nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni pé, ó dá orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn ni Jèhófà, padà sí àyè rẹ̀. Nínú àwọn Bíbélì Hébérù tó wà láyé àtijọ́, kọ́ńsónáńtì mẹ́rin ló dúró fún orúkọ Ọlọ́run, táa bá pa lẹ́tà wọn dà, a lè pè wọ́n ní YHWH tàbí JHVH. Orúkọ tó yàtọ̀ pátápátá yìí fara hàn ní iye ìgbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] nínú apá táà ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé nìkan ṣoṣo. (Ẹ́kísódù 3:15; Sáàmù 83:18) Kò sí àní-àní níbẹ̀, lóòótọ́, Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn tí ń jọ́sìn òun mọ orúkọ yìí, kí wọ́n sì máa lò ó!
Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló mú kí àwọn Júù pa lílo orúkọ Ọlọ́run tì. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù ti kú, làwọn tó ṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Kyʹri·os (Olúwa) tàbí The·osʹ (Ọlọ́run) rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn atúmọ̀ èdè kan lóde ìwòyí tún ń bá ìwà tó tàbùkù Ọlọ́run yìí nìṣó, ìyẹn ni, yíyọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọn ò tiẹ̀ wá jẹ́ kó hàn sáwọn èèyàn mọ́ pé Ọlọ́run lórúkọ kan. Fún àpẹẹrẹ, nínú Jòhánù 17:6, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù kà pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere.” Àmọ́, ìtumọ̀ Today’s English Version, sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́.”
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ ohun táwọn rí lọ́bẹ, táwọn fi warú sọ́wọ́, wọ́n ní ìdí táwọn fi yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò ni pé, kò sẹ́ni tó mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń pè é mọ́. Ṣùgbọ́n, wọ́n kọ àwọn orúkọ inú Bíbélì táa mọ̀ bí ẹni mówó lọ́nà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá bí wọ́n ṣe ń pè wọ́n lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu, àpẹẹrẹ kan ni àwọn orúkọ bíi, Jeremáyà, Aísáyà, àti Jésù. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Jèhófà ni ọ̀nà tó tọ́ jù lọ láti pe orúkọ Ọlọ́run náà—tó sì jẹ́ pé òun láwọn ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀—tí ẹnì kan bá ta ko lílò ó, àtakò onítọ̀hún kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.
Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun gbé ìgbésẹ̀ onígboyà, ìyẹn ni láti lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ti Gíríìkì. Kì í ṣe àwọn ló kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí tí wọ́n túmọ̀ fún àwọn èèyàn tó wà ní Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, Gúúsù Pàsífíìkì, àti ti Ìlà Oòrùn, ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, lílo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìwé lásán. Bó ṣe jẹ́ pé mímọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ náà ni mímọ orúkọ rẹ̀ ṣe pàtàkì gidigidi. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó kà á níṣìírí láti máa lo orúkọ Ọlọ́run!
Bó Ṣe Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Ò Gbóyìnbó
Láàárín ọdún 1963 sí 1989, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà lódindi tàbí lápá kan, ní èdè mẹ́wàá mìíràn. Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ tó gbomi mu niṣẹ́ ìtumọ̀, òmíràn nínú iṣẹ́ yìí ń gba ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tó ṣe, lọ́dún 1989, a dá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ sílẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lábẹ́ àṣẹ Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ẹ̀ka yìí ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí ìtumọ̀ Bíbélì yá kánkán. Wọ́n gbé ọgbọ́n ìtumọ̀ kan kalẹ̀ èyí tó jẹ́ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì àti lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Báwo lètò yìí ṣe ń ṣiṣẹ́?
Gbàrà tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé bá ti fọwọ́ sí títú Bíbélì sí èdè kan, yóò yan àwọn Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àjọ olùtúmọ́. Ó rọrùn fún àjọ olùtúmọ̀ kan láti mú ìtumọ̀ tó dáa jáde ju kí ẹnì kan dá a túmọ̀. (Fi wé Òwe 11:14.) Ní gbogbo gbòò, gbogbo àwọn mẹ́ńbà àjọ olùtúmọ̀ yìí ló ti ń túmọ̀ ìtẹ̀jáde Society tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ni àjọ olùtúmọ̀ náà yóò wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlànà títú Bíbélì àti bí wọn yóò ṣe lo àwọn ètò kọ̀ǹpútà táa pilẹ̀ ṣe fún wọn. Kì í ṣe kọ̀ǹpútà ló ń túmọ̀ ìwé, ṣùgbọ́n ó lè ran àjọ olùtúmọ̀ lọ́wọ́ láti rí ìsọfúnni pàtàkì àti láti tọ́jú àwọn ìpinnu wọn.
Ipele méjì ni iṣẹ́ títú Bíbélì ní. Nínú ipele àkọ́kọ́, a óò fún àwọn atúmọ̀ èdè ní àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn táa lò nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì. A óò tún ṣàkójọ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ìtumọ̀ wọn fẹ́ bára mu, irú bí “atone,” “atonement,” àti “propitiation,” èyí yóò pe àfiyèsí àwọn atúmọ̀ èdè sí àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ tó wà láàárín ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Wọn yóò wá kó àwọn ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ èyí jọ ní èdè àbínibí wọn. Àmọ́ ṣá o, nígbà mí-ìn, ikun imú olùtúmọ̀ kan máa fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí tòsì kó tó túmọ̀ ẹyọ ẹsẹ kan ṣoṣo. Ètò kọ̀ǹpútà tó wà fún ṣíṣe ìwádìí ló ń ran àwọn olùtúmọ̀ lọ́wọ́ láti rí ìsọfúnni lórí ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì àti Hébérù, nípasẹ̀ ètò yìí kan náà wọ́n lè ka àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society.
Nígbà tí iṣẹ́ náà bá dé ipele kejì, ètò táa ti ṣe sínú kọ̀ǹpútà yóò wá kó àwọn ọ̀rọ̀ táa ti yàn pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè àbínibí wa sínú ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Èyí ń jẹ́ kí ìtumọ̀ náà péye, kí ó sì lè lo ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo délẹ̀ fún ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan. Àmọ́ ṣá o, ìtumọ̀ táa fi ètò “fífi ọ̀rọ̀ rọ́pò ọ̀rọ̀” ṣe yìí, kì í yéni bọ̀rọ̀. Kì iṣẹ́ náà tó lè rọrùn-ún kà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ takuntakun láti tún àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kà léraléra, ká wá tún àwọn gbólóhùn rẹ̀ tò.
Ọ̀nà ìtumọ̀ yìí ti gbéṣẹ́ gan-an. Ó ṣeé ṣe fún àjọ olùtúmọ̀ kan láti túmọ̀ odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láàárín ọdún méjì péré. Fi èyí wé àjọ olùtúmọ̀ kan tó túmọ̀ èdè tó fara pẹ́ ẹ láìlo kọ̀ǹpútà. Ọdún mẹ́rìndínlógún gbáko ló gbà wọ́n. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ti tẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jáde ní èdè méjìdíńlógún mìíràn láti 1989. Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà lódindi tàbí lápá kan, ní èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n. Nípa báyìí, ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ní ó kéré tán Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní èdè àbínibí wọn.
Ẹgbẹ́ United Bible Societies ròyìn pé, nínú èdè ẹgbàáta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [6,500] tó wà láyé, èdè ẹgbàá kan ó lé igba àti méjìlá [2,212] péré ló ní apá kan Bíbélì.c Nítorí náà, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún atúmọ̀ èdè ló ń ṣiṣẹ́ láti rí i pè Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Hébérù wà ní èdè mọ́kànlá, ti èdè Gíríìkì yóò sì wà ní èdè mẹ́jọ. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Kò sí àní-àní pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yóò kó ipa pàtàkì nínú èyí.
Nítorí náà, inú wa dùn pé iye ẹ̀dà ìtumọ̀ yìí tó wà níta báyìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù, àdúrà wa ni pé kí a tún lè tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù sí i láìpẹ́. A rọ̀ ọ́ láti fúnra rẹ yẹ̀ ẹ́ wò. Wàá gbádùn àwọn apá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó ní: ó ṣeé kà dáadáa, ojú ìwé kọ̀ọ̀kan ní nọ́ńbà, ó ní atọ́ka tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá àwọn ẹsẹ tí a sábà ń lò, ó ní àwòrán ilẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́, ó sì tún ní àsomọ́ tó fani mọ́ra. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, o lè fi ìgbọ́kànlé ka Bíbélì yìí pé, ó ló ọ̀rọ̀ to péye láti gbé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀ ní èdè rẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìgbà tí ọ̀rọ̀ yóò sọ ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sẹ́yìn Bíbélì New American Standard Bible Ìtẹ̀jáde Alátọ́ka ti 1971 sọ pé: “A kò lo orúkọ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ èyíkéyìí ká lè rí i tọ́ka sí tàbí ká lè fi polówó ọjà nítorí a gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tó láti polówó ara rẹ̀.”
b The New Testament in the Original Greek, látọwọ́ Westcott àti Hort, ló jẹ́ olórí Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì tí wọ́n lò. Ìwé Biblia Hebraica tí R. Kittel ṣe, ni lájorí ìwé tí wọ́n lò fún Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
c Níwọ̀n tó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló gbọ́ èdè méjì, a gbà gbọ́ pé Bíbélì, lódindi tàbí lápá kan, la ti túmọ̀ sí àwọn èdè tí ó tó fún ìpín àádọ́rùn-ún nínú àwọn olùgbé ayé láti kà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun yìí fi hàn pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń bẹ nínú ìjọ yín, àwọn tó dáńgájíá láti fi òye yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà nínú títúmọ̀ Bíbélì.”—ANDOVER NEWTON QUARTERLY, JANUARY 1963
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
“Bí ìmọ̀ Bíbélì bá ṣe ń jinlẹ̀ sí i, tí èdè sì ń yí padà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtẹ̀síwájú gbọ́dọ̀ máa bá ọ̀nà táa gbà ń túmọ̀ èdè.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
ÀWỌN Ọ̀MỌ̀WÉ AKẸ́KỌ̀Ọ́JINLẸ̀ GBÓṢÙBÀ FÚN ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN
NÍGBÀ tí Edgar J. Goodspeed, ẹni tó túmọ̀ “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gíríìkì nínú An American Translation, ń sọ̀rọ̀ nípa Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó kọ̀wé nínú lẹ́tà kan tó kọ́ ní December 8, 1950 pé: “Inú mi dùn sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí àwọn ènìyàn yín ń ṣe, àti bó ṣe tàn káàkiri ayé, inú mi tún wá dùn gan-an sí ìtumọ̀ tó yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, tó ṣe ṣàkó, tó sì ṣe kedere tẹ́ẹ ṣe. Mo lè fọwọ́ sọ̀yà pé, ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ dáadáa kí ẹ tó mú un jáde.”
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì, Alexander Thomson, kọ̀wé pé: “Ẹ̀rí fi hàn kedere pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, tí wọ́n já fáfá, tí wọ́n sì kún fún làákàyè, ni wọ́n ṣètumọ̀ ìwé yìí, àwọn tí wọ́n gbìyànjú láti mú ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì túmọ̀ sí gan-an jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì.”—The Differentiator, April 1952, ojú ìwé 52 sí 57.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin Kedar, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Hébérù ní Ísírẹ́lì, sọ ní 1989 pé: “Nínú ìwádìí tí mo ṣe nípa Bíbélì Hébérù àti ìtumọ̀ rẹ̀, ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a mọ̀ sí New World Translation, ni mo sábà máa ń tọ́ka sí. Ṣíṣe tí mò ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé iṣẹ́ yìí fi hàn pé àwọn to túmọ̀ rẹ̀ sapá gidigidi láti lè rí i pé a lóye ẹsẹ kan lọ́nà tó péye jù lọ.”—ANDOVER NEWTON QUARTERLY, JANUARY 1963