ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/1 ojú ìwé 26-30
  • “New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ Pamọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ Pamọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Yatọ—Ṣugbọn Ko Ṣaitọna
  • Awọn Ọmọwe Akẹkọọ Jinlẹ Miiran Fohunṣọkan
  • Orukọ Ara-ẹni Ti Ọlọrun
  • Ki Ni O Fa Lameyitọ Lilekoko?
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ṣé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Péye?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/1 ojú ìwé 26-30

“New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ Pamọ

“O KUN fun ìṣèké!” Ohun ti awọn alatako sọ nipa itumọ Bibeli ti Martin Luther ni ọgọrun-un ọdun kẹrindinlogun lẹhin lọhun-un niyẹn. Wọn gbagbọ pe awọn le fi ẹri hàn pe Bibeli Luther ní “1,400 aṣiṣe aladaamọ ati irọ” ninu. Lonii, Bibeli Luther ni a nfi oju wò gẹgẹ bi itumọ pataki kan ninu ọ̀rọ̀-ìtàn. Iwe naa Translating the Bible tilẹ pe e ni “iṣẹ onijinlẹ ọgbọ́n titayọ!”

Ni ọ̀rúndún lọna ogún yii, New World Translation pẹlu ni a ti fi ẹsun ìṣèké kan. Eeṣe? Nitori pe oun ya kuro ni ọna ti a gbà ṣètumọ̀ ọpọlọpọ ẹsẹ iwe gẹgẹ bi àṣà atọwọdọwọ o sì fi ijẹpataki sori lilo orukọ Ọlọrun naa, Jehofa. Fun ìdí yii, oun ko ba àṣà ti o gbilẹ mu. Ṣugbọn eyi ha mu ki o jẹ eke bi? Bẹẹkọ. A ṣe e jade pẹlu iṣọra pupọ ati fifi afiyesi sori kulẹkulẹ, ohun ti o si le farahan bi ajeji yii duro fun isapa olotiitọ inu lati fi pẹlu ifarabalẹ gbe awọn iyatọ diẹdiẹ ti nbẹ ninu awọn èdè ipilẹṣẹ naa jade. Fun apẹẹrẹ, C. Houtman ti o jẹ ẹlẹkọọ isin ṣalaye idi ti New World Translation ko fi tọ ọna ti ọpọlọpọ tọ̀ pe: “Oniruuru awọn itumọ atọwọdọwọ fun awọn èdè ìsọ̀rọ̀ pataki lati inu ọrọ-ẹsẹ-iwe ipilẹṣẹ naa ni a ti patì, ti o han gbangba pe o jẹ lati lè fàbọ̀ sori òye didara julọ ti o ṣeeṣe.” Ẹ jẹ ki a gbe diẹ yẹwo ninu awọn apẹẹrẹ yii.

O Yatọ—Ṣugbọn Ko Ṣaitọna

Idi kan niyii, awọn ọrọ titanmọra pẹkipẹki ninu awọn èdè Bibeli ipilẹṣẹ maa nfi awọn ọ̀rọ̀ Gẹẹsi ọtọọtọ tumọ nibi ti o ba ti ṣeeṣe, ti o tipa bayii pe afiyesi akẹkọọ Bibeli si iyatọ fẹẹrẹfẹ ti o ṣeeṣe ki o wà ninu itumọ. Nipa bayii, syn·teʹlei·a ni a tumọsi “ipari” ati teʹlos “opin,” bi o tilẹ jẹ pe awọn ọ̀rọ̀ mejeeji ni a tumọsi “opin” ninu ọpọlọpọ itumọ miiran. (Matiu 24:3, 13) Ọ̀rọ̀ naa koʹsmos ni a tumọsi “ayé,” ai·onʹ “eto igbekalẹ awọn nnkan,” ati oi·kou·meʹne “ilẹ-aye gbigbe.” Lẹẹkan sii, ọpọlọpọ itumọ Bibeli lo “aye” lasan lati duro fun meji tabi gbogbo awọn ọ̀rọ̀ Giriiki mẹtẹẹta wọnyi, bi o tilẹ jẹ pe, nitootọ, iyatọ wa laaarin wọn.—Matiu 13:38, 39; 24:14.

Lọna ti o farajọra, New World Translation farabalẹ kiyesi iyatọ ti o wa laaarin gnoʹsis (“imọ”) ati e·piʹgno·sis (ti a tumọsi “imọ pipeye”)—iyatọ kan ti pupọ awọn miiran ṣaifiyesi. (Filipi 1:9; 3:8) O tun fi iyatọ han laaarin taʹphos (“saree,” ibi ti a sin ẹnikan sí), mneʹma (“iboji”), mne·meiʹon (“iboji iranti”), ati haiʹdes (“hades,” ti ntọka ninu Bibeli si saree araye lapapọ). (Matiu 27:60, 61; Johanu 5:28; Iṣe 2:29, 31) Awọn itumọ Bibeli melookan fi iyatọ hàn laaarin taʹphos ati mne·meiʹon ni Matiu 23:29 ṣugbọn laiṣedeedee delẹ nibomiran.—Wo Matiu 27:60, 61, New International Version.

Awọn ọrọ-iṣe aṣapejuwe koko ọrọ ni a tumọ lọna ṣiṣedeedee. Fun apẹẹrẹ, ninu Revised Standard Version, 1 Johanu 2:1 ka pe: “Bi ẹnikẹni ba ṣẹ̀, awa ni alagbawi kan pẹlu Baba, Jesu Kristi olododo.” Laipẹ lẹhin naa, itumọ kan naa tumọ 1 Johanu 3:6 pe: “Ko si ẹni ti ngbe ninu [Jesu] ti o maa nṣẹ.” Bi ko ba si ọmọlẹhin Jesu ti o ńṣẹ̀, bawo ni a ṣe lè fi 1 Johanu 2:1 silo?

New World Translation wa ojútùú fun ohun ti o dabi itakora yii. Ni 1 Johanu 2:1, o wipe: “Emi nkọwe awọn nnkan wọnyi si yin ki ẹyin ma baa da ẹ̀ṣẹ̀. Ati sibẹ, bi ẹnikẹni ba si da ẹ̀ṣẹ̀, awa ni oluranlọwọ kan pẹlu Baba, Jesu Kristi, ẹni olododo.” Johanu lo ọ̀rọ̀ iṣe atọka iṣẹlẹ ninu ẹsẹ iwe yii, ti ntọkasi dida ẹ̀ṣẹ̀ kan ti o dayatọ, iru ohun ti gbogbo wa maa nṣe lati igba de igba nitori pe awa jẹ alaipe. Bi o ti wu ki o ri, 1 Johanu 3:6 kà pe: “Olukuluku ẹni ti o nduro ninu irẹpọ pẹlu rẹ̀ kii sọ ẹ̀ṣẹ̀ dida dàṣà; ko si ẹni kankan ti nsọ ẹ̀ṣẹ̀ dida dàṣà ti o ti ri i tabi wá lati mọ̀ ọ́n.” Nihin-in Johanu lo ọrọ ti ntọka si iṣẹlẹ isinsinyi, ti ntọkasi ipa-ọna ẹṣẹ dida kan ti nbaa lọ lọwọlọwọ, ti o ti mọnilara, eyi ti yoo sọ sisọ ti ẹnikan sọ pe oun jẹ Kristian di alaijoootọ.

Awọn Ọmọwe Akẹkọọ Jinlẹ Miiran Fohunṣọkan

Awọn èdè isọrọ ajeji kan bayii ti a gbagbọ pe a humọ wọn lati ọwọ awọn Ẹlẹrii Jehofa ni a tilẹhin nipasẹ awọn itumọ Bibeli tabi iṣẹ́ itọkasi miiran. Ni Luuku 23:43, New World Translation ṣakọsilẹ awọn ọ̀rọ̀ Jesu fun ọdaran ti a pa pẹlu rẹ̀ pe: “Loootọ ni mo sọ fun ọ lonii, Iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.” Ninu Giriiki ipilẹṣẹ, ko si awọn ami ikọwe iru bii ami idanuro diẹ; ṣugbọn niye igba iru awọn ami ikọwe kan ni awọn olutumọ nfi si i lati ṣeranlọwọ ninu kika. Bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ, mu ki a ka Luuku 23:43 bi ẹni pe Jesu ati ọlọṣa naa nlọ si Paradise ni ọjọ yẹn gan-an. New English Bible ka pe: “Mo sọ eyi fun ọ: iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise lonii.” Bi o ti wu ki o ri, kii ṣe gbogbo itumọ ni o gbe ero yii yọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Wilhelm Michaelis tumọ ẹsẹ iwe naa pe: “Loootọ, ni lọwọlọwọ lonii mo fi idaniloju naa fun ọ pe: (ni ọjọ kan) iwọ yoo wa papọ pẹlu mi ninu paradise.” Itumọ yii ba ọgbọ́n mu pupọpupọ ju ti The New English Bible lọ. Ọlọṣa ti nku lọ naa kò le lọ si Paradise pẹlu Jesu ni ọjọ yẹn kan naa. Jesu ni a kò ji dide titi di ọjọ kẹta lẹhin iku rẹ̀. Laaarin akoko naa oun wà ninu Hades, sàréè araye lapapọ.—Iṣe 2:27, 31; 10:39, 40.

Gẹgẹ bi Matiu 26:26 ti wi ninu New World Translation, nigba ti Jesu nfidi ayẹyẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa mulẹ, o sọ nipa àkàrà ti o gbe yika laaarin awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Eyi tumọsi ara mi.” Ọpọ julọ awọn itumọ miiran tumọ ẹsẹ iwe yii pe: “Eyi ni ara mi,” eyi ni a sì lò lati ṣetilẹhin ẹkọ igbagbọ naa pe nigba ayẹyẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa, àkàrà naa di ẹran-ara Kristi niti gidi. Ọ̀rọ̀ ti a tumọ ninu New World Translation gẹgẹ bi “tumọsi” (es·tinʹ, iru ei·miʹ kan) wa lati inu ọ̀rọ̀ Giriiki naa ti o tumọsi “lati jẹ́,” ṣugbọn o tun le duro fun “lati tumọsi” pẹlu. Nipa bayii, Greek-English Lexicon of the New Testament lati ọwọ́ Thayer wipe ọ̀rọ̀-ìṣe yii “niye igba [baramu pẹlu] lati tọkasi, tumọsi, gbe itumọ yọ.” Nitootọ, “tumọsi” ni itumọ ti o ba ọgbọ́n mu nihin-in. Nigba ti Jesu fidi Ounjẹ Alẹ Ti O Kẹhin mulẹ, ẹran-ara rẹ̀ ṣì wà lara egungun rẹ̀, nitori naa bawo ni àkàrà ṣe lè ti jẹ ẹran-ara rẹ̀ gidi?a

Ni Johanu 1:1 New World Translation kà pe: “Ọ̀rọ̀ naa jẹ ọlọrun kan.” Ninu ọpọlọpọ itumọ ọ̀rọ̀ yii wulẹ kà pe: “Ọ̀rọ̀ naa jẹ Ọlọrun” a sì ńlò ó lati ti ẹkọ igbagbọ Mẹtalọkan lẹhin. Ko jẹ iyalẹnu pe, awọn onigbagbọ Mẹtalọkan kò nifẹẹ si bi a ṣe tumọ rẹ̀ ninu New World Translation. Ṣugbọn Johanu 1:1 ni a kò fi èké yipada ki a baa lè fi ẹ̀rí han pe Jesu kii ṣe Ọlọrun Olodumare. Awọn Ẹlẹrii Jehofa, papọ pẹlu ọpọlọpọ awọn miiran, ti gbe ibeere dide si fifi lẹta gadagba bẹrẹ “ọlọrun” tipẹ ṣaaju ki New World Translation to jade, eyi ti o sapa lati tumọ èdè ipilẹṣẹ lọna pipeye. Awọn olutumọ Bibeli lede German marun-un bakan naa lo èdè ìsọ̀rọ̀ naa “ọlọrun kan” ninu ẹsẹ-iwe yii.b O keretan awọn mẹtala miiran ti lo awọn ọ̀rọ̀ bii “jẹ iru ti ọrun” tabi “iru ẹni bi Ọlọrun.” Awọn itumọ wọnyi baramu pẹlu awọn apa Bibeli miiran ti o fihan pe, bẹẹni, Jesu ni ọrun jẹ́ ọlọrun kan ni ero itumọ ti jijẹ ẹni ti ọrun. Ṣugbọn Jehofa ati Jesu kii ṣe olùwà kannaa, Ọlọrun kannaa.—Johanu 14:28; 20:17.

Orukọ Ara-ẹni Ti Ọlọrun

Ni Luuku 4:18, gẹgẹ bi New World Translation ti wi, Jesu fi asọtẹlẹ ti o wa ninu Aisaya silo fun ara rẹ̀, ni wiwipe: “Ẹmi Jehofa nbẹ lara mi.” (Aisaya 61:1) Ọpọlọpọ tako lilo orukọ naa Jehofa nihin-in. Bi o ti wu ki o ri, o wulẹ jẹ ọkan lara ibi ti o ju 200 lọ nibi ti orukọ yẹn ti farahan ninu New World Translation ti Iwe Mimọ Kristian lede Giriiki, eyi ti a npe ni Majẹmu Titun. Nitootọ, ko si iwe afọwọkọ Giriiki ijimiji ti “Majẹmu Titun” ti o ṣì wà ti o ni orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun ninu. Ṣugbọn orukọ naa ni a fikun un ninu New World Translation fun awọn ìdí ti o yekooro, kii wulẹ ṣe lori èrò aibọgbọnmu. Awọn miiran sì ti tẹle ipa-ọna kannaa. Ninu èdè German nikan, o keretan awọn ẹda itumọ 11 lo “Jehofa” (tabi itumọ iyilẹta pada ti Heberu naa, “Yahweh”) ninu ọrọ ẹsẹ iwe “Majẹmu Titun” naa, nigba ti awọn olutumọ mẹrin fi orukọ naa kun un ninu àkámọ́ lẹhin “Oluwa.”c Ohun ti o ju aadọrin itumọ èdè German lo o ninu awọn akiyesi ẹsẹ iwe tabi awọn alaye.

Ni Israẹli, orukọ Ọlọrun ni a npe jade laisi ikaleewọ fun ohun ti o ju ẹgbẹrun ọdun kan lọ. O jẹ orukọ ti o farahan lemọlemọ julọ ninu Iwe Mimọ lede Heberu (“Majẹmu Laelae”), kò sì si ẹri ti nyinilero pada kankan pe awọn eniyan ni gbogbogboo kò mọ̀ ọ́n tabi pé pípè rẹ̀ ni a ti gbagbe ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní ti Sanmanni Wa, nigba ti a misi awọn Kristian Juu lati ṣakọsilẹ awọn iwe ti o wa ninu “Majẹmu Titun.”—Ruutu 2:4.

Wolfgang Feneberg sọrọ ninu iwe irohin Jesuit Entschluss/Offen (April 1985) pe: “Oun [Jesu] ko fi orukọ baba rẹ̀ YHWH pamọ fun wa, ṣugbọn o fi le wa lọwọ. Kì bá ti ṣoro lati ṣalaye idi ti adura ẹ̀bẹ̀ akọkọ ninu Adura Oluwa fi nilati kà pe: ‘Jẹ ki orukọ rẹ di mímọ́!’” Siwaju sii Feneberg ṣakiyesi pe “ninu awọn iwe afọwọkọ ṣaaju akoko Kristian fun awọn Juu ti nsọ èdè Giriiki, orukọ Ọlọrun ni a kò tunsọ lọ́rọ̀ miiran ni lilo kýrios [Oluwa], ṣugbọn a kọ ọ ni iru ọ̀rọ̀ onilẹta mẹrin (tetragram) [YHWH] ni ede Heberu tabi awọn àmì lẹta Heberu ti laelae. . . . A ri awọn itunkojọ orukọ naa ninu ikọwe awọn Baba Ṣọọṣi; ṣugbọn wọn ko nifẹẹ si i. Nipa titumọ orukọ yii ni kýrios (Oluwa), awọn Baba Ṣọọṣi nifẹẹ ọkan jù ninu fifi ọlanla ti kýrios naa fun Jesu Kristi.” New World Translation mu orukọ naa padabọsipo sinu ọrọ ẹsẹ iwe Bibeli nibikibi ti ìdí ti o yekooro, ti o fi ijinlẹ ẹkọ hàn ba wa lati ṣe bẹẹ.—Wo Appendix 1D ninu Reference Bible.

Awọn kan ṣe lámèyítọ́ “Jehofa” ọna ti New World Translation gba tumọ orukọ Ọlọrun. Ninu iwe afọwọkọ lede Heberu, orukọ naa farahan gẹgẹ bi kọnsonanti mẹrin, YHWH, ọpọlọpọ sì fi dandan le e pe pipe ti o tọna ni “Yahweh,” kii ṣe “Jehofa.” Fun ìdí yii, wọn nimọlara pe lilo “Jehofa” jẹ aṣiṣe kan. Ṣugbọn, nitootọ, awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ ko sí ni ifohunṣọkan pe “Yahweh” duro fun pipe ti ipilẹṣẹ naa. Otitọ naa ni pe nigba ti Ọlọrun pa sípẹ́lì orukọ rẹ̀ naa “YHWH” mọ ni nnkan ti o ju 6,000 ìgbà lọ ninu Bibeli, oun kò pa pipe rẹ̀ ti Mose gbọ lori Oke Sinai mọ. (Ẹkisodu 20:2) Nitori naa, pipe naa ni kii ṣe ohun ti o ṣe pataki julọ ni akoko yii.

Ni Europe “Jehofa” ni a ti mọ dunju lọna gbigbooro fun ọpọ ọgọrun-un ọdun a sì lo o ninu ọpọlọpọ Bibeli, titikan awọn itumọ ti Juu. O farahan ni aimọye igba lara awọn ile, lara owo ẹyọ ati awọn ohun ti a lè ri miiran, ati ninu ọgọrọọrun iwe orin ṣọọṣi. Nitori naa dipo gbigbiyanju lati fi ọrọ kan duro fun pípè ti ipilẹṣẹ lede Heberu, New World Translation lo iru orukọ Ọlọrun ti ọpọlọpọ tẹwọgba ninu gbogbo awọn èdè ọtọọtọ ti a fi tumọ rẹ̀. Eyi gan-an ni awọn ẹda itumọ Bibeli miiran ṣe pẹlu gbogbo awọn orukọ miiran ninu Bibeli.

Ki Ni O Fa Lameyitọ Lilekoko?

Bibeli Luther ni a ṣe lameyitọ si nitori pe a mú un jade lati ọwọ́ ọkunrin kan ti o tudii aṣiri awọn aṣiṣe isin atọwọdọwọ ní ọjọ rẹ̀. Itumọ rẹ̀ ṣi ọna silẹ fun awọn eniyan gbáàtúù lati ri otitọ ọpọ julọ ohun ti o sọ. Lọna ti o farajọra, New World Translation ni a ṣe lameyitọ si nitori pe a tẹ ẹ jade lati ọwọ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa, awọn ti wọn polongo laifọrọsabẹ ahọ́n pe ọpọlọpọ ẹkọ-igbagbọ Kristẹndọm ni ko sí ninu Bibeli. New World Translation—nitootọ, Bibeli eyikeyii—mu eyi ṣe kedere.

Nitootọ, New World Translation jẹ iṣẹ ti o fi ijinlẹ ẹ̀kọ́ hàn. Ni 1989, Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin Kedar ti Israel wipe: “Ninu iwadii mi nipa ede ni isopọ pẹlu Bibeli lede Heberu ati itumọ rẹ̀, niye ìgbà mo maa nwo inu ẹda itẹjade Gẹẹsi naa eyi ti a mọ̀ si New World Translation. Ni ṣiṣe bẹẹ, mo rii pe imọlara mi mú un tubọ daju leralera pe iṣẹ yii fi isapa olotiitọ inu lati ṣaṣeyọri iloye ọrọ ẹsẹ iwe pipeye ti o ṣeeṣe julọ hàn. Ni fifi ẹri iloye ede ipilẹṣẹ naa delẹdelẹ han, o tumọ awọn ọrọ ipilẹṣẹ naa si ede miiran lọna ti o yeni laiyapa kuro lainidii ninu igbekalẹ ṣiṣe pato ti ede Heberu. . . . Gbogbo ọrọ èdè yọnda fun iwọn ominira ero ninu ṣiṣalaye itumọ tabi titumọ si ede miiran. Nitori naa ojutuu ti èdè ti a fun ọran eyikeyii lè ṣi silẹ fun ariyanjiyan. Ṣugbọn ninu New World Translation emi kò tii ri ipete ẹlẹtanu eyikeyii lati gbé itumọ ohun kan ti ọrọ ẹsẹ-iwe naa kò ni ninu jade.”

Araadọta ọkẹ awọn onkawe Bibeli yika aye nlo New World Translation nitori pe o jẹ itumọ ede ti ode oni ti o tumọ awọn èdè isọrọ Bibeli lọna pipeye. Odidi Bibeli naa nisinsinyi wà larọọwọto ni èdè mẹsan-an, Iwe Kristian lede Giriiki nikan sì wà ni èdè meji sii ni afikun; a nṣeto rẹ̀ silẹ ni ogún awọn èdè miiran. Itumọ pipeye beere fun ọpọlọpọ ọdun iṣẹ takuntakun, ṣugbọn awa nwo iwaju lati ri ki New World Translation farahan ni gbogbo awọn èdè ọtọọtọ wọnyi nikẹhin ki o baa le ran ọpọlọpọ sii lọwọ lati ni òye “ọ̀rọ̀ ìyè” lọna didara ju. (Filipi 2:16) Nitori pe o ti ran araadọta ọkẹ lọwọ tẹlẹ lati ṣe bẹẹ, o yẹ fun ìsọ̀rọ̀yìn nitootọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ni Iṣipaya 1:20, olutumọ ara Germany naa Curt Stage tumọ ọ̀rọ̀ iṣe kan naa bayii: “Ọpa fitila meje tumọsi [ei·sinʹ] ijọ meje.” Bakan naa ni Matiu 12:7, Fritz Tillmann ati Ludwig Thimme tumọ rẹ̀ gẹgẹ bi “tumọsi” [es·tinʹ].

b Jürgen Becker, Jeremias Felbinger, Oskar Holtzmann, Friedrich Rittelmeyer, ati Siegfried Schulz. Emil Bock wipe, “olùwà bi Ọlọrun kan.” Tun wo itumọ Gẹẹsi naa: Today’s English Version, The New English Bible, Moffatt, Goodspeed pẹlu.

c Johann Babor, Karl F. Bahrdt, Petrus Dausch, Wilhelm M. L. De Wette, Georg F. Griesinger, Heinrich A. W. Meyer, Friedrich Muenter, Sebastian Mutschelle, Johann C. F. Schulz, Johann J. Stolz, ati Dominikus von Brentano. August Dächsel, Friedrich Hauck, Johann P. Lange, ati Ludwig Reinhardt ni orukọ naa ninu awọn àkámọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]

New World Translation wa lẹnu titumọ si ogún awọn èdè siwaju sii

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

ITUMỌ KAN TI O SỌ̀RỌ̀YIN ARA RẸ̀

Ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa ni Germany jiroro pẹlu obinrin agbalagba kan, ẹni ti oun ka Habakuku 1:12 fun: “Iwọ kò ha wà lati igba pipẹ sẹhin, Óò Jehofa? Óò Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ mi, iwọ kii kú.” Obinrin naa yarí nitori pe Bibeli rẹ̀ kà pe, “Awa kì yoo kú.” Ẹlẹrii naa tọka jade pe New World Translation rọ̀ timọtimọ mọ́ awọn ìwé afọwọkọ ipilẹṣẹ. Niwọnbi agbalagba obinrin naa ti nsọ èdè Heberu, o mu Bibeli Heberu rẹ̀ jade o sì wa rii si iyalẹnu rẹ̀ pe New World Translation pe perepere. Awọn Sopherim (Awọn akọwe ofin Juu) yí ọ̀rọ̀ ẹsẹ iwe yii pada tipẹ-sẹhin nitori wọn nimọlara pe ayọka ọ̀rọ̀ naa ni ipilẹṣẹ fi aibọwọ fun Ọlọrun han. Yatọ si awọn melookan, awọn itumọ Bibeli lede German kò ṣe awọn iyipada lati ṣatunṣe ìyíwèé awọn akọwe ofin yii. New World Translation ti dá ọrọ ẹsẹ iwe ipilẹṣẹ naa padabọ sipo.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

New World Translation ti o pe perepere wà nisinsinyi ni: Danish, Dutch, Gẹẹsi, French, German, Italian, Japanese, Portuguese, ati Spanish

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́