ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ba ojú ìwé 10-13
  • Ìwé Kan Tí “Ń Sọ” Àwọn Èdè Tí Ó Bóde Mu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Kan Tí “Ń Sọ” Àwọn Èdè Tí Ó Bóde Mu
  • Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìpèníjà Tí Ó Dojú Kọ Àwọn Olùtumọ̀
  • Kíkọ́ Àwọn Èdè Áfíríkà
  • Kíkọ́ Àwọn Èdè Éṣíà
  • Ìwé Kan Tí Ó Wà Fún Gbogbo Ènìyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Awọn Itumọ Bibeli Ti Africa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kẹta
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Wọ́n Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
ba ojú ìwé 10-13

Ìwé Kan Tí “Ń Sọ” Àwọn Èdè Tí Ó Bóde Mu

Bí èdè tí a fi kọ ìwé kan bá di òkú, ìwé náà pẹ̀lú a di òkú ní ti ìwúlò rẹ̀ fún ohunkóhun. Lónìí, ìwọ̀nba ènìyàn mélòó kan ni ó lè ka àwọn èdè ìgbàanì tí a fi kọ Bíbélì. Síbẹ̀ ó ṣì wà láàyè. Ó ń bá a lọ láti wà nítorí pé ó ti “kọ́ bí a ti ń sọ” àwọn èdè aráyé tí ó bóde mu. Àwọn olùtumọ̀ tí ó “kọ́” ọ láti sọ àwọn èdè míràn kojú àwọn ohun tí ó dà bíi kongbári ìdìgbòlù nígbà míràn.

TÍTÚMỌ̀ Bíbélì—pẹ̀lú èyí tí ó ju 1,100 orí àti 31,000 ẹsẹ tí ó ní—jẹ́ iṣẹ́ kan tí ó gbomi mu. Bí ó ti wù kí ó rí, láti àwọn ọ̀rúndún wá, àwọn olùtumọ̀ tí ń ṣiṣẹ́ tọkàn tara tẹ́wọ́ gba ìpèníjà náà tìyárítìyárí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣe tán láti fara gba ìnira àní láti kú pàápàá ní tìtorí iṣẹ́ wọn. Ìtàn nípa bí Bíbélì ṣe wá di èyí tí a túmọ̀ sí àwọn èdè aráyé jẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó bùáyà nípa ìforítì àti ìdánúṣe. Ṣàgbéyẹ̀wò kìkì ìwọ̀nba kékeré nínú àkọsílẹ̀ agbàfiyèsí náà.

Àwọn Ìpèníjà Tí Ó Dojú Kọ Àwọn Olùtumọ̀

Báwo ni ìwọ yóò ṣe túmọ̀ ìwé kan sí èdè kan tí kò ní ìwé kankan tí a kọ ní èdè náà? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ni ó kojú irú ìpèníjà bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Ulfilas, ti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè kan—èdè Goth—tí ó lòde nígbà náà ṣùgbọ́n tí a kò tí ì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ sílẹ̀. Ulfilas borí ìpèníjà náà nípa híhùmọ̀ álífábẹ́ẹ̀tì 27 fún èdè Goth, èyí tí ó gbé karí álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gírí ìkì àti ti Látìn ní pàtàkì. Iṣẹ́ ṣíṣe ìtumọ̀ gbogbo Bíbélì sí èdè Goth ni òun parí ṣáájú 381 Sànmánì Tiwa.

Ní ọ̀rúndún kẹsàn án, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí ń sọ èdè Gírí ìkì, Cyril (tí ń jẹ́ Constantine tẹ́lẹ̀) àti Methodius, tí àwọn méjèèjì jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti onímọ̀ èdè púpọ̀, fẹ́ láti túmọ̀ Bíbélì fún àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Slav. Ṣùgbọ́n èdè Slav àtijọ́—tí ó jẹ́ aṣáájú àwọn èdè Slav tòní—kò ní ìwé kankan tí a kọ ní èdè náà. Nítorí náà, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yí hùmọ̀ álífábẹ́ẹ̀tì láti lè mú ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì kan jáde. Nípa báyìí, Bíbélì wá lè “bá” àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i “sọ̀rọ̀,” àwọn tí ó wà ní ìhà tí ń sọ èdè Slav.

Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, William Tyndale bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì láti inú àwọn èdè ti èyí tí a kọ́kọ́ kọ, ṣùgbọ́n ó ṣalábàápàdé àtakò líle koko láti ọ̀dọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba. Tyndale, tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní Yúnifásítì Oxford, fẹ́ láti mú ẹ̀dà ìtumọ̀ kan jáde tí ó jẹ́ pé, àní, “ọmọdékùnrin kan tí ń wa ohun èlò ìtúlẹ̀” pàápàá yóò lè lóye.1 Ṣùgbọ́n láti lè ṣe èyí, ó di dandan fún un láti sá lọ sí Germany, níbi tí a ti tẹ “Májẹ̀mú Tuntun” tí ó mú jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní 1526. Nígbà tí a yọ́lẹ̀ mú àwọn ẹ̀dà rẹ̀ wọ ilẹ̀ England, inú bí àwọn aláṣẹ débi pé ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jó wọn ní gbangba. A dalẹ̀ Tyndale lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kété ṣáájú kí wọ́n tó fún un lọ́rùn pa tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀, ó fi ohùn rara sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Olúwa, la Ọba ilẹ̀ England lójú!”2

Ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì ń bá a nìṣó; a kò ní dá àwọn tí ń ṣe ìtumọ̀ rẹ̀ dúró. Ó kéré tán, ní nǹkan bí 1800, àwọn apá kan lára Bíbélì ti “kọ́ bí a ti ń sọ” èdè 68. Lẹ́yìn náà, ní dídá tí a dá Àwọn Ẹgbẹ́ Bíbélì sílẹ̀—ní pàtàkì Ẹgbẹ́ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Òkèèrè, tí wọ́n fi lọ́lẹ̀ ní 1804—àní kíá ni Bíbélì tún ti “kọ́” àwọn èdè tuntun mìíràn sí i. Ọ̀rọ̀ọ̀rún ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin ń yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, tí olórí ète ọ̀pọ̀ nínú wọ́n jẹ́ láti túmọ̀ Bíbélì.

Kíkọ́ Àwọn Èdè Áfíríkà

Ní 1800, kìkì nǹkan bí èdè 12 péré ní Áfíríkà ni ó wà tí a ń kọ sílẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èdè míràn tí ó jẹ́ èyí tí a ń sọ lẹ́nu nìkan wà bẹ́ẹ̀ títí tí ẹnì kan fi máa hùmọ̀ ọ̀nà tí a lè gbà kọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn míṣọ́nnárì wá, wọ́n sì kọ́ àwọn èdè wọ̀nyí, láìsí àrànṣe àwọn ìwé atọ́nisọ́nà tàbí ti ìwé atúmọ̀ èdè. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣakitiyan láti mú bí a ti ń kọ ọ́ sílẹ̀ jáde, lẹ́yìn náà, wọ́n sì kọ́ àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe lè ka àwọn ìwé náà. Wọ́n ṣe èyí kí àwọn ènìyàn baà lè ka Bíbélì ní èdè tiwọn lọ́jọ́ kan ṣá.3

Irú míṣọ́nnárì kan bẹ́ẹ̀ ni Robert Moffat tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Scotland. Ní 1821, nígbà tí ó jẹ́ ẹni ọdún 25, Moffat dá ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Tswana ní gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà. Ó ń bá àwọn ènìyàn náà ṣe wọléwọ̀de kí ó baà lè kọ́ èdè wọn tí a kì í kọ sílẹ̀, nígbà míràn a sì máa rìnrìn àjò lọ sí àwọn eréko láti lọ gbé láàárín wọn. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Àwọn ènìyàn yẹn jẹ́ onínúure, ẹ̀rín wọn a sì kọ lálá nígbà tí mo bá ṣe àwọn àṣìṣe nínú sísọ èdè wọn. Kò ṣẹlẹ̀ rí pé kí ẹnì kan ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ kan tàbí gbólóhùn kan, àyàfi bí ó bá kọ́kọ́ sín Moffat jẹ dáadáa bí ó ṣe sọ ọ́ gan-an débi pé yóò fi máa dẹ́rìn-ín pa àwọn yòó kù.”4 Moffat tẹra mọ́ ọn, ó sì mọ èdè náà ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó sì ṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà tí a lè gbà kọ ọ́.

Ní 1829, lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ láàárín àwọn Tswana fún ọdún mẹ́jọ, Moffat parí ṣíṣe ìtumọ̀ Ìhìn Rere Lúùkù. Láti lè tẹ̀ ẹ́, ó fi kẹ̀kẹ́ tí akọ màlúù ń fà rìnrìn àjò fún nǹkan bí 600 ibùsọ̀ lọ sí etíkun, lẹ́yìn náà, ó wọ ọkọ̀ òkun lọ sí ìlú Cape Town. Ibẹ̀ ni gómìnà ti fún un láṣẹ láti lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti ìjọba, ṣùgbọ́n Moffat ní láti to àwọn lẹ́tà rẹ̀ sórí abala ìtẹ̀wé kí ó sì fúnra rẹ̀ tẹ̀ ẹ́, ó sì ṣe ìwé Ìhìn Rere jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní 1830. Ní ìgbà àkọ́kọ́, àwọn Tswana lè ka apá kan Bíbélì ní èdè tiwọn. Ní 1857, Moffat parí títúmọ̀ Bíbélì lódindi sí èdè Tswana.

Lẹ́yìn náà, Moffat ṣàpèjúwe ìhùwàpadà àwọn elédè Tswana nígbà tí Ìhìn Rere Lúùkù kọ́kọ́ tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Ó kọ̀wé pé: “Mo mọ àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ pé ó wá láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀ láti wá gba àwọn ẹ̀dà Lúùkù Mímọ́. . . . Mo ti rí i tí wọ́n gba àwọn apá kan lára Lúùkù Mímọ́, tí wọ́n sì sunkún lé wọn lórí, tí wọ́n sì gbá wọn mọ́ àyà wọn, tí omijé ọpẹ́ sì ń dà lójú wọn, títí mo fi ní láti sọ fún púpọ̀ nínú wọn pé, ‘Ẹ ó mà fi omijé yín bá ìwé yín jẹ́.’ ”5

Nípa báyìí, àwọn olùtumọ̀ tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntara irú bíi Moffat fún ọ̀pọ̀ ará Áfíríkà—tí àwọn kan lára wọn kò rí ìdí fún níní èdè kan tí a lè kọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀—ní àǹfààní àkọ́kọ́ láti bá ará wọn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ kíkọ̀wé. Àmọ́ ṣáá, àwọn olùtumọ̀ gbà gbọ́ pé ẹ̀bùn tí ó tilẹ̀ tún níye lórí ju ìyẹn lọ ni àwọn ń fún àwọn ènìyàn Áfíríkà—Bíbélì ní èdè tiwọn. Lónìí, Bíbélì, lódindi tàbí lápá kan, “ń sọ” ohun tí ó ju 600 nínú àwọn èdè Áfíríkà.

Kíkọ́ Àwọn Èdè Éṣíà

Bí àwọn olùtumọ̀ ní Áfíríkà ṣe ń jìjàkadì láti ṣàmújáde ọ̀nà tí a lè gbà kọ àwọn èdè tí a ń sọ lẹ́nu nìkan sílẹ̀, ní ìhà kejì ayé, àwọn olùtumọ̀ yòó kù ń bá àwọn ìdìgbòlù tí ó yàtọ̀ pátápátá pàdé—ṣíṣe ìtumọ̀ sí àwọn èdè tí wọ́n ti ní àwọn ìwé tí a kọ lọ́nà ìkọ̀wé tí ó díjú. Irú èyí ni ìpèníjà tí ó dojú kọ àwọn tí ó túmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè Éṣíà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, William Carey àti Joshua Marshman lọ sí Íńdíà, wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè wọn tí ó wà ní kíkọ, wọ́n sì mọ̀ wọ́n dunjú. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ William Ward tí ó jẹ́ òǹtẹ̀wé, ó kéré tán, wọ́n mú àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ àwọn apá kan lára Bíbélì jáde ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 èdè.6 Òǹkọ̀wé J. Herbert Kane ṣàlàyé nípa William Carey pé: “Ó hùmọ̀ ọ̀nà ìgbàkọ̀wé [ní èdè ilẹ̀ Bengal] tí ó bá bí a ti ń sọ̀rọ̀ mu, tí ó já gaara tí ó sì wuni, èyí tí ó dípò ti ògbólógbòó tí wọ́n hùmọ̀ fún ìwé kíkọ́ nìkan, tí ó sì tipa báyìí mú kí ó ṣeé lóye kí ó sì fa àwọn òǹkàwé òde òní mọ́ra.”7

Adoniram Judson, tí a bí tí a sì tọ́ dàgbà ní United States, rìnrìn àjò lọ sí Burma, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètumọ̀ Bíbélì sí èdè àwọn ará Burma ní 1817. Nígbà tí ó ń ṣàlàyé ìṣòro tí ó wà nínú kíkọ́ àti mímọ èdè àwọn ará Ìlà Oòrùn dé ipò tí ó yẹ láti fi lè túmọ̀ Bíbélì, ó kọ̀wé pé: ‘Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè tí àwọn ènìyàn ní ìhà kejì ayé ń sọ, àwọn ẹni tí ọ̀nà ìgbàronú wọn yàtọ̀ sí tiwa, tí bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé ara wọn sì tipa báyìí jẹ́ tuntun pátápátá sí wa, tí àwọn lẹ́tà álífábẹ́ẹ̀tì wọn àti ọ̀rọ̀ wọn kò ní àfijọ rárá pẹ̀lú èdè èyíkéyìí tí a tí ì bá pàdé rí; nígbà tí a kò ní ìwé atúmọ̀ èdè tàbí ògbufọ̀ tí a sì ní láti ní òye díẹ̀ láti inú èdè náà kí a tó lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀—iṣẹ́ gbáà nìyẹn!’8

Nínú ọ̀ràn ti Judson, iṣẹ́ àf ìṣọ́raṣe fún ọdún 18 ni èyí túmọ̀ sí. Apá tí ó kẹ́yìn lára Bíbélì ní èdè àwọn ará Burma ni a tẹ̀ ní 1835. Àmọ́ o, ohun ńlá ni gbígbé tí ó gbé ní Burma ná an. Nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ ìṣètumọ̀ náà, a fẹ̀sùn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kàn án, nítorí èyí, ó lo ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì nínú ẹ̀wọ̀n tí ẹ̀fọn kún bámú. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a tú u sílẹ̀, àrùn ibà pa aya rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré.

Nígbà tí Robert Morrison tí ó jẹ́ ẹni ọdún 25 dé China ní 1807, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ líle koko ti ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè ilẹ̀ China, ọ̀kan lára àwọn èdè tí a ń kọ sílẹ̀ tí kíkọ rẹ̀ díjú jù lọ. Ìwọ̀nba ni ó lè sọ nínú èdè ilẹ̀ China, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ní kìkì ọdún méjì péré sí ìgbà yẹn. Morrison tún ní láti kojú òfin ilẹ̀ China, tí ó ń wá bí dídá tí China dá wà yóò ṣe máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. A kà á léèwọ̀ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ China, lábẹ́ ìyà ikú, láti kọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní èdè náà. Pé kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan túmọ̀ Bíbélì sí èdè ilẹ̀ China jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú ikú lọ́wọ́.

Láìrẹ̀wẹ̀sì ṣùgbọ́n tìṣọ́ratìṣọ́ra, Morrison ń bá a lọ ní kíkọ́ èdè náà, ní yíyára kọ́ ọ. Láàárín ọdún méjì ó gba iṣẹ́ olùtumọ̀ fún ilé iṣẹ́ East India Company. Lójúmọmọ, òun a bá ilé iṣẹ́ náà ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n níkọ̀kọ̀ àti lábẹ́ ewu ìgbà gbogbo náà pé ohun tí ó ń ṣe lè lu síta, ó ń ṣiṣẹ́ lórí ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì. Ní 1814, ọdún méje lẹ́yìn tí ó dé ilẹ̀ China, ó gbé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì sílẹ̀ fún títẹ̀.9 Ọdún márùn ún lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ William Milne, ó parí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Àṣeyọrí tí ó gadabú ni èyí jẹ́—nísinsìnyí Bíbélì lè “sọ̀rọ̀” ní èdè tí iye àwọn ènìyàn tí ń sọ ọ́ ti pọ̀ ju ti èyíkéyìí mìíràn lọ ní ayé. Ọpẹ́ ni fún àwọn olùtumọ̀ tí ó dáńgájíá, àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ sí àwọn èdè Éṣíà yòó kù tẹ̀ lé èyí. Lónìí, àwọn apá kan Bíbélì wà ní ohun tí ó ju 500 nínú àwọn èdè Éṣíà.

Èé ṣe tí àwọn ènìyàn bíi Tyndale, Moffat, Judson, àti Morrison fí ṣòpò fún ọ̀pọ̀ ọdún—tí àwọn kan tilẹ̀ fi ìwàláàyè wọn wewu—láti túmọ̀ ìwé kan fún àwọn ènìyàn tí wọn kò mọ̀, àti ní àwọn ìgbà míràn, fún àwọn ènìyàn tí a kì í kọ èdè wọn sílẹ̀? Dájúdájú kì í ṣe nítorí àtigbògo tàbí torí èrè owó. Wọ́n gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé ó yẹ kí ó bá àwọn ènìyàn “sọ̀rọ̀”—gbogbo ènìyàn—ní èdè tiwọn.

Yálà o rò pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí o kò rò bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o gbà pé irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí àwọn olùtumọ̀ tí ń ṣiṣẹ́ tọkàntara wọ̀nyẹn fi hàn ṣọ̀wọ́n gidigidi láyé òde òní. Ìwé kan tí ń ru irú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ sókè kò ha yẹ fún àyẹ̀wò bí?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Iye àwọn èdè tí a ti tẹ àwọn apá kan Bíbélì sí láti 1800

68 107 171 269 367 522 729 971 1,199 1,762 2,123

1800 1900 1995

[Credit Line]

Orísun: United Bible Societies

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Tyndale ń túmọ̀ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Robert Moffat

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Adoniram Judson

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Robert Morrison

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́