Awọn Itumọ Bibeli Ti Africa
Awọn itumọ Bibeli lodindi ti a kọ́kọ́ ṣe si èdè Africa kan ni a ṣe ni Egipti. Ni mímọ̀ ọ́n sí ẹ̀dà itumọ ti Coptic, a gbagbọ pe wọn ti wà lati ọrundun kẹta tabi ikẹrin C.E. Ni nǹkan bii ọrundun mẹta lẹhin naa, Bibeli ni a tumọ si èdè Ethiopia.
Ọgọrọọrun awọn èdè ti a kò kọ silẹ ti a ń sọ ni ìhà guusu Ethiopia ati ni ilẹ Sahara nilati duro de dídé awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni ọrundun 19. Ni 1857 ipele pataki kan ni a dé nigba ti Robert Moffat pari itumọ Bibeli kan si èdè Tswana, èdè ìhà guusu Africa kan. Ó tún tẹ awọn apá ọtọọtọ lori ẹ̀rọ-aláfọwọtẹ̀ kan. Eyi ni odindi Bibeli àkọ́kọ́ ti a tẹ̀ ni Africa ó sì tun jẹ́ itumọ akọkọ si èdè Africa kan ti a kò kọ silẹ tẹlẹri. Lọna ti o fanilọkanmọra, Moffat lo orukọ atọrunwa naa Yehova ninu itumọ tirẹ̀. Ninu ẹ̀dà itumọ ti 1872 tí ẹgbẹ́ Awujọ Bibeli Britain ati Ti Ìdálẹ̀ tẹ̀jáde, orukọ naa Yehova ni a lo ninu gbolohun-ọrọ pataki ti Jesu sọ gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matteu 4:10 áti Marku 12:29, 30.
Nigba ti o fi maa di 1990 Bibeli ni a tumọ si 119 èdè Africa, pẹlu awọn apakan rẹ̀ ti ó wà larọwọọto ni afikun èdè 434.