Ìtẹ̀síwájú Nínú Iṣẹ́ Títúmọ̀ àti Títẹ Bíbélì Sí Àwọn Èdè Ilẹ̀ Áfíríkà
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn tó ń fi tọkàntọkàn ka Bíbélì nílẹ̀ Yúróòpù àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà Ti Àríwá ti rí i pé ó yẹ káwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè ìbílẹ̀ wọn. Kí ohun pàtàkì yìí bàa lè ṣeé ṣe làwọn ọkùnrin kan ṣe wá sílẹ̀ Áfíríkà láti kọ́ àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà. Àwọn kan ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kọ àwọn kan lára èdè ilẹ̀ Áfíríkà sílẹ̀, wọ́n sì tún ṣe ìwé atúmọ̀ èdè lédè wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè ilẹ̀ Áfíríkà. Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yẹn o. Ìwé The Cambridge History of the Bible sọ pé: “Nígbà míì, atúmọ̀ èdè kan lè ṣe wàhálà títí fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó rí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá a mú tó lè fi túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni tó rọrùn àmọ́ tó ṣe pàtàkì.”
Àwọn ẹ̀yà Tswana ló kọ́kọ́ ní Bíbélì lódindi nínú gbogbo èdè ilẹ̀ Áfíríkà tí wọn kì í kọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ọdún 1857 niṣẹ́ sì parí lórí títúmọ̀ Bíbélì yẹn.a Ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ ni wọ́n ṣe Bíbélì náà, wọn ò ṣe é pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí odindi ìwé kan. Nígbà tó yá, wọ́n túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì tí wọ́n ń sọ ní ilẹ̀ Áfíríkà. Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà wà nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn Bíbélì ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ wọ̀nyí. Orúkọ náà wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, táwọn kan ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé” ó sì tún wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, táwọn kan ń pè ní “Májẹ̀mú Tuntun.” Àmọ́ àwọn tí ò bọ̀wọ̀ fórúkọ mímọ́ Jèhófà, Ẹni tó ni Bíbélì, wá ń ṣàtúnṣe sí àwọn Bíbélì wọ̀nyí, wọ́n sì ń ṣe ìtumọ̀ tuntun. Dípò kí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì tí wọ́n ń ṣe, ńṣe ni wọ́n tẹ̀ lé àṣà asán táwọn Júù ń tẹ̀ lé, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa fi àwọn orúkọ oyè, irú bí Ọlọ́run tàbí Olúwa rọ́pò Jèhófà. Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nílẹ̀ Áfíríkà ní Bíbélì tó lo orúkọ Jèhófà ní gbogbo ibi tó yẹ kó wà.
Láti nǹkan bí ọdún 1980 ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò pé ká máa túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sáwọn èdè pàtàkì-pàtàkì kan tí wọ́n ń sọ nílẹ̀ Áfíríkà. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì tó tètè ń yéni yìí sí àwọn èdè pàtàkì mìíràn tí wọ́n ń sọ ní ìwọ̀ oòrùn, àárín gbùngbùn àti gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà. Iṣẹ́ ìtumọ̀ yìí ti mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tí wọ́n mọyì Bíbélì nílẹ̀ Áfíríkà rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kà lédè ìbílẹ̀ wọn. Ní báyìí, àtèyí tó wà ní apá kan àtèyí tó wà lódindi, a ti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè mẹ́tàdínlógún lára èdè tó jẹ́ èdè ilẹ̀ Áfíríkà.
Inú àwọn tó ń ka Bíbélì tó wà lédè ilẹ̀ Áfíríkà wọ̀nyí dùn gan-an láti ní Bíbélì tó lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ ológo. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà ní sínágọ́gù nílùú Násárétì, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun wá ṣe láyé nípa kíka ibì kan nínú àkájọ ìwé Aísáyà, níbi tí orúkọ Bàbá rẹ̀ ti fara hàn. (Aísáyà 61:1, 2) Ohun tí Jésù sọ nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”—Lúùkù 4:18, 19.
Ìtẹ̀síwájú pàtàkì mìíràn tó dé bá iṣẹ́ títúmọ̀ àti títẹ Bíbélì sí àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà wáyé lóṣù August ọdún 2005. Lóṣù yẹn, ó lé ní ẹgbàá méjìdínlógójì [76,000] ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n tẹ̀ tí wọ́n sì dì pọ̀ lódindi ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà. Lára iye yẹn la ti rí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] Bíbélì tó wà lédè Shona. A mú Bíbélì èdè Shona yìí jáde nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wáyé lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè.
Lóṣù mánigbàgbé yẹn, inú àwọn tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà dùn láti rí bí wọ́n ṣe ń tẹ Bíbélì tuntun láwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà. Arákùnrin Nhlanhla tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó sì ń ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ ìdìwépọ̀ níbẹ̀ sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo wà lára àwọn tó ń tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Shona àtàwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà mìíràn.” Ńṣe lohun tí arákùnrin yìí sọ jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà.
Nísinsìnyí, kò ní máa pẹ́ mọ́ rárá tí Bíbélì á fi máa tẹ àwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà lọ́wọ́. Kò ní dà bíi ti ìgbà tá à ń ṣe wọ́n lókè òkun. Ìnáwó rẹ̀ á sì tún dín kù. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé Bíbélì tó péye tó sì lo orúkọ mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì, ti wà káàkiri báyìí fáwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lọ́dún 1835, iṣẹ́ parí lórí títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Malagásì tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Madagásíkà. Nígbà tó sì di ọdún 1840, wọ́n parí títúmọ̀ Bíbélì èdè Amharic tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Etiópíà. Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọ̀nyí ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn èdè náà sílẹ̀ o, wọ́n ti ń kọ wọ́n sílẹ̀ tipẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì Tswana tí wọ́n ṣe lọ́dún 1840
[Credit Line]
Harold Strange Library of African Studies
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn àlejò tó wá láti ilẹ̀ Swaziland sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Gúúsù Áfíríkà ń wo bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀rọ tẹ Bíbélì tuntun