Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kejì
I ná ń yọ bùlàbùlà sójú ọ̀run bí wọ́n ṣe ń kó ohun amúnájó dà sínú iná tí ń jó hàhàhìhì tí a dá sí gbangba. Àmọ́ èyí kì í ṣe iná lásán. Àwọn àlùfáà àti àwọn bíṣọ́ọ̀bù fọwọ́ lẹ́rán bí a ti ń kó Bíbélì dà sínú iná ńlá aṣèparun náà. Ṣùgbọ́n, bíṣọ́ọ̀bù ti London kò mọ̀ pé rírà tí òun ń ra Bíbélì láti dáná sún un ń ṣèrànwọ́ fún olùtúmọ̀ náà, William Tyndale, láti rí owó ná lórí títẹ àwọn ẹ̀dà púpọ̀ sí i!
Kí ni ó sún ìhà méjèèjì nínú ọ̀ràn yí láti dé orí irú ìpinnu bẹ́ẹ̀? Nínú ìtẹ̀jáde ìṣáájú, a ṣàyẹ̀wò ìtàn títẹ Bíbélì jáde títí wọnú Sànmánì Agbedeméjì. Wàyí o, a ti dé ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun, nígbà tí ìhìn iṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ọlá àṣẹ rẹ̀ ti fẹ́ máa ní ipa jíjinlẹ̀ láwùjọ.
Òléwájú Kan Fara Hàn
John Wycliffe, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní Oxford tí a bọ̀wọ̀ fún, wàásù, ó sì kọ̀wé lílágbára lòdì sí àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu tí ó gbilẹ̀ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ní gbígbé ọlá àṣẹ rẹ̀ ka ‘òfin Ọlọ́run,’ ìyẹn ni Bíbélì. Ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àwọn Lollard, jáde lọ sí ìgbèríko England láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fetí sílẹ̀. Kí ó tó dolóògbé ní ọdún 1384, ó bẹ̀rẹ̀ títúmọ̀ Bíbélì láti èdè Látìn sí èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ọjọ́ rẹ̀.
Ṣọ́ọ̀ṣì rí ọ̀pọ̀ ìdí láti tẹ́ńbẹ́lú Wycliffe. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó bá àwọn àlùfáà wí fún àṣejù àti ìwà pálapàla wọn. Ní àfikún sí i, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń kan sáárá sí Wycliffe ṣi ẹ̀kọ́ rẹ̀ lò láti dá ìwà ọ̀tẹ̀ wọn láre. Bí òun kò tilẹ̀ fìgbà kankan rí ṣalágbàwí rúkèrúdò oníwà ipá, àwọn àlùfáà di ẹ̀bi rẹ̀ ru Wycliffe, àní lẹ́yìn ikú rẹ̀ pàápàá.
Nínú lẹ́tà kan tí ó kọ sí Póòpù John Kẹtàlélógún ní ọdún 1412, Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Arundel tọ́ka sí John Wycliffe gẹ́gẹ́ bí “akúṣẹ̀ẹ́ àti amúnibínú ẹ̀dá, ẹni tí ìrántí rẹ̀ ń kóni nírìíra, ọmọ ejò láéláé nì, oun gan-an ni òléwájú nínú aṣòdì sí Kristi, ó tún jẹ́ ọmọ aṣòdì sí Kristi.” Ní bíbá ìfibú rẹ̀ dé òtéńté, Arundel kọ̀wé pé: “Kí òṣùwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lè kún, ó hùmọ̀ ọ̀nà láti tú Ìwé Mímọ́ sí èdè àbínibí.” Ní tòótọ́, ohun tí ó bí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì nínú jù lọ ni pé, Wycliffe fẹ́ kí àwọn ènìyàn ní Bíbélì ní èdè tiwọn.
Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún àwọn olókìkí ènìyàn díẹ̀ láti ní Ìwé Mímọ́ lédè ìbílẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn ni Anne Bohemia, tí ó fẹ́ Ọba Richard Kejì ti England ní ọdún 1382. Ó ní ìtumọ̀ Ìhìn Rere ti Wycliffe lédè Gẹ̀ẹ́sì, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ nígbà gbogbo. Nígbà tí ó di ayaba, ẹ̀mí rere rẹ̀ ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tẹ̀ síwájú—kì í sì í ṣe ní England nìkan. Anne fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì Prague ní Bohemia níṣìírí láti wá sí Oxford. Níbẹ̀ wọ́n fi ìtara kẹ́kọ̀ọ́ ìtumọ̀ Wycliffe, wọ́n sì kó díẹ̀ nínú rẹ̀ lọ sí Prague. Ìgbajúmọ̀ ẹ̀kọ́ Wycliffe ní Yunifásítì Prague ran Jan Hus lọ́wọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, tí ó sì di olùkọ́ni níbẹ̀ lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Hus mú ìtumọ̀ èdè Czech tí ó rọrùn láti kà jáde láti inú ìtumọ̀ àtijọ́ ti èdè Slavic. Akitiyan rẹ̀ gbé lílo Bíbélì lọ́nà wíwọ́pọ̀ ní Bohemia àti ní àwọn ilẹ̀ tí ó wà nítòsí lárugẹ.
Ṣọ́ọ̀ṣì Gbẹ̀san
Inú tún bí àwọn àlùfáà sí Wycliffe àti Hus fún kíkọ́ni pé “ojúlówó àkọsílẹ̀,” Ìwé Mímọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a mí sí tí kò ní àfikún rárá, ní ọlá àṣẹ tí ó tóbi ju ti “àlàyé etí ìwé,” àwọn àlàyé rẹpẹtẹ àtọwọ́dọ́wọ́, tí ó wà ní etí àwọn Bíbélì tí ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sí. Ìhìn iṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò lábùlà kankan ni àwọn oníwàásù wọ̀nyí fẹ́ kí ó tẹ àwọn gbáàtúù lọ́wọ́.
Ní fífẹnu lásán ṣèlérí ààbò fún un, a tan Hus sínú wíwá síwájú Ìgbìmọ̀ Kátólíìkì ti Constance, Germany, ní ọdún 1414 láti wá gbè sí èrò tirẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn àlùfáà, bíṣọ́ọ̀bù, àti àwọn kádínà 2,933 ni ó para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ náà. Hus gbà láti kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ bí wọ́n bá lè lo Ìwé Mímọ́ láti fi hàn pé àwọn ẹ̀kọ́ òun lòdì. Lójú ìgbìmọ̀ náà, ìyẹn kọ́ ni kókó ibẹ̀. Pípè tí ó pe ọlá àṣẹ wọn níjà ti tó fún wọn láti dáná sun ún lórí òpó igi ní ọdún 1415, bí ó ṣe ń gbàdúrà sókè ketekete.
Ìgbìmọ̀ kan náà tún dá John Wycliffe lẹ́bi ìkẹyìn, wọ́n sì tàbùkù rẹ̀ nípa pípàṣẹ pé kí a hú egungun rẹ̀ jáde ní England, kí a sì dáná sun ún. Àṣẹ yìí kóni nírìíra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a kò fi tẹ̀ lé e títí di ọdún 1428, nígbà tí póòpù fi dandan gbọ̀n béèrè fún un. Ṣùgbọ́n, bí ó ti sábà máa ń rí, irú àtakò gbígbóná janjan bẹ́ẹ̀ kò bomi paná ìtara àwọn mìíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi kún ìpinnu wọn láti tẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jáde.
Ipa Tí Ìwé Títẹ̀ Kó
Nígbà tí yóò fi di ọdún 1450, ọdún 35 péré lẹ́yìn ikú Hus, Johannes Gutenberg bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀rọ tí lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tẹ̀wé ní Germany. Ìtumọ̀ Vulgate lédè Látìn, tí a parí ní nǹkan bí ọdún 1455 ni ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó tẹ̀. Nígbà tí yóò fi di ọdún 1495, a ti tẹ odindi tàbí apá kan Bíbélì jáde ní èdè German, Ítálì, Faransé, Czech, Dutch, Hébérù, Catalan, Gíríìkì, Spanish, Slavic, Potogí, àti Serbian—ní bí a ṣe tò wọ́n tẹ̀ léra.
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Netherlands náà, Desiderius Erasmus, mú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì tí ó jẹ́ èyí tí a kọ́kọ́ tẹ̀ lódindi jáde ní ọdún 1516. Ó wu Erasmus pé kí “a tú” Ìwé Mímọ́ “sí gbogbo èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ.” Ṣùgbọ́n, ó lọ́ tìkọ̀ láti fi òkìkí ńlá tí ó ní wewu nípa fífúnra rẹ̀ tú u. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn tí wọ́n gbóyà dìde. Ẹni títayọ jù lọ nínú àwọn wọ̀nyí ni William Tyndale.
William Tyndale àti Bíbélì Lédè Gẹ̀ẹ́sì
Tyndale kàwé ní Oxford, nígbà tí ó sì di nǹkan bí ọdún 1521, ó wá sí ilé Alàgbà John Walsh, gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé Tyndale ọ̀dọ́mọdé pẹ̀lú àwọn àlùfáà àdúgbò máa ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu ara wọn bí wọ́n ti ń jẹun lórí tábìlì oúnjẹ Walsh, tí oúnjẹ máa ń kún fọ́fọ́. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, Tyndale ta ko èrò wọn nípa ṣíṣí Bíbélì àti fífi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ hàn wọ́n. Nígbà tí ó yá, ìdílé Walsh gba ohun tí Tyndale ń sọ gbọ́, wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ ké sí àwọn àlùfáà mọ́, ìtara tí wọ́n sì fi hàn sí wọn sì dín kù. Lọ́nà tí ẹ̀dá, èyí túbọ̀ mú inú bí àwọn àlùfáà sí Tyndale àti ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Nígbà kan tí awuyewuye kan ń lọ lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn onísìn tí ó jẹ́ alátakò Tyndale sọ pé: “Ó sàn kí o wà láìní òfin Ọlọ́run ju kí o máà ní Póòpù lọ.” Finú wòye ìdálójú ìgbàgbọ́ Tyndale bí ó ti fèsì pé: “Ááyán-ńga Póòpù àti gbogbo òfin rẹ̀. Bí Ọlọ́run bá dá ẹ̀mí mi sí, ní ọdún díẹ̀ sí i, n óò mú kí ọmọdékùnrin tí ń túlẹ̀ mọ Ìwé Mímọ́ jù ọ́ lọ.” Ìpinnu Tyndale ṣe kedere. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ìrírí ti jẹ́ kí n róye pé kò ṣeé ṣe láti fi ọkàn àwọn ọmọ ìjọ mọ òtítọ́ kankan, àyàfi bí a bá jẹ́ kí wọ́n rí Ìwé Mímọ́ kedere ní èdè àbínibí wọn, kí wọn baà lè rí kókó, ìjẹ́pàtàkì, àti ìtumọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́.”
Ní àkókò yẹn, kò tí ì sí Bíbélì kankan tí a tẹ̀ jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nítorí náà, ní ọdún 1523, Tyndale lọ sí London láti wá ìtìlẹ́yìn Bíṣọ́ọ̀bù Tunstall fún iṣẹ́ ìtumọ̀ kan. Nítorí tí a pẹ̀gàn rẹ̀, ó fi England sílẹ̀ láti lọ lépa ète rẹ̀, kò sì pa dà síbẹ̀ mọ́. Ní Cologne, Germany, a kó ẹrù lọ ní ibi ìtẹ̀wé rẹ̀ àkọ́kọ́, agbára káká sì ni Tyndale fi lè sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ojú ìwé mélòó kan ṣíṣeyebíye, tí a kò tí ì dì pọ̀. Ṣùgbọ́n, ní Worms, Germany, ó kéré tán, a ti parí 3,000 ẹ̀dà “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gẹ̀ẹ́sì. A kó ìwọ̀nyí ránṣẹ́ lọ sí England, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í pín wọn kiri níbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1526. Àwọn Bíbélì tí Bíṣọ́ọ̀bù Tunstall rà tí ó sì dáná sun láìmọ̀ pé ṣe ni òun ń ran Tyndale lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó, wà lára àwọn wọ̀nyí!
Ìwádìí Mú Òye Tí Ó Túbọ̀ Ṣe Kedere Wá
Ó ṣe kedere pé Tyndale gbádùn iṣẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Cambridge History of the Bible ṣe sọ ọ́, “Ìwé Mímọ́ mú inú rẹ̀ dùn, ohun kan sì wà nínú ọ̀nà ìkọ̀wé rẹ̀ tí ń fi ayọ̀ rẹ̀ hàn.” Góńgó Tyndale jẹ́ láti mú kí Ìwé Mímọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn gbáàtúù, ní èdè tí ó pé pérépéré tí ó sì rọrùn láti lóye. Ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ ń fi ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ti mú kí ó rújú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún hàn. Láìbẹ̀rù ikú tí a fi ń halẹ̀ mọ́ ọn tàbí ìwé burúkú tí ọ̀tá rẹ̀ lílágbára náà, Alàgbà Thomas More, ń kọ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, Tyndale mú ohun tí ó ṣàwárí wọnú ìtumọ̀ rẹ̀.
Ní lílo ìtumọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Erasmus ṣe dípò ti èdè Látìn, Tyndale yàn láti lo “ìfẹ́” dípò “inúure” láti tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·gaʹpe, lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ó tún lo “ìjọ” dípò “ṣọ́ọ̀ṣì,” “ronú pìwà dà” dípò “jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,” ó sì lo “alàgbà” dípò “àlùfáà.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:1-3; Kólósè 4:15, 16; Lúùkù 13:3, 5; Tímótì Kíní 5:17, Tyndale) Àwọn àtúnṣe wọ̀nyí ba ọlá àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn àṣà ìsìn àtọwọ́dọ́wọ́ rẹ̀ jẹ́, irú bíi jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà.
Bákan náà, Tyndale kò yí ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” pa dà, ó kọ pọ́gátórì àti wíwà láàyè lẹ́yìn ikú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Nípa àwọn òkú, ó kọ̀wé sí More pé: “Ní fífi wọ́n sí ọ̀run, ọ̀run àpáàdì, àti pọ́gátórì, [ìwọ] ń ba ìjiyàn tí Kristi àti Pọ́ọ̀lù fi gbe àjíǹde lẹ́sẹ̀ jẹ́.” Nípa èyí, Tyndale tọ́ka sí Mátíù 22:30-32 àti Kọ́ríńtì Kíní 15:12-19. Òun tọ̀nà láti gbà gbọ́ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun títí di ìgbà àjíǹde ọjọ́ iwájú. (Orin Dáfídì 146:4; Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11, 24, 25) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ètò àdúrà sí Màríà àti “àwọn ẹni mímọ́” kò wúlò nítorí pé wọn kò lè gbọ́, wọn kò sì lè ṣalárinà nínú ipò àìmọ nǹkan kan wọn.
Tyndale Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
Ní ọdún 1530, Tyndale mú ìtumọ̀ Pentateuch, ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jáde. Ó tipa báyìí di ẹni àkọ́kọ́ tí ó tú Bíbélì ní tààràtà láti èdè Hébérù sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Tyndale tún ni olùtúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àkọ́kọ́ tí ó lo orúkọ náà, Jèhófà. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará London náà, David Daniell, kọ̀wé pé: “Ó dájú pé ìyàlẹ́nu ńláǹlà ni yóò jẹ́ fún àwọn òǹkàwé Tyndale pé a ṣí orúkọ Ọlọ́run payá.”
Nínú ìgbìdánwò rẹ̀ láti rí i pé ìkọ̀wé ṣe kedere, Tyndale lo onírúurú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù kan ṣoṣo. Ṣùgbọ́n, ó tẹ̀ lé ọ̀nà ìkọ̀wé Hébérù pẹ́kípẹ́kí. Ìyọrísí rẹ̀ pa agbára gíga lọ́lá tí èdè Hébérù ní mọ́. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ìlò èdè Hébérù bá ti èdè Gẹ̀ẹ́sì mu nígbà ẹgbẹ̀rún ju bí ó ti bá ti èdè Látìn mu lọ. Ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ jọra; tí ó fi jẹ́ pé nígbà ẹgbẹ̀rún, kìkì ohun tí o ní láti ṣe ni láti tú ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.”
Ọ̀nà ìtumọ̀ ṣangiliti yìí fi adùn ọ̀rọ̀ Hébérù sínú ìtumọ̀ Tyndale. Àwọn kan lára wọn lè ṣàjèjì nígbà tí a bá kọ́kọ́ kà á. Síbẹ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín Bíbélì di ohun tí ó wọ́pọ̀ débi pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti wá di apá kan èdè Gẹ̀ẹ́sì báyìí. Àwọn àpẹẹrẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ sí “ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀” (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Sámúẹ́lì Kíní 13:14), “ìrékọjá,” àti “ewúrẹ́ ìdásílẹ̀lọ.” Ní àfikún sí i, àwọn tí ń ka Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tipa báyìí mọ ohun tí ó wà ní èdè Hébérù dunjú, ni fífún wọn ní ìjìnlẹ̀ òye tí ó dára jù nípa Ìwé Mímọ́ tí a mí sí.
A Fòfin De Bíbélì àti Tyndale
Ṣíṣeé ṣe láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè ẹni jẹ́ ohun amúnilóríyá. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dáhùn pa dà nípa ríra gbogbo ẹ̀dà tí a lè gba ọ̀nà ẹ̀bùrú kó wọ orílẹ̀-èdè náà, tí a dì gẹ́gẹ́ bí ìgàn aṣọ tàbí àwọn ẹrù míràn láti fi ṣawúrúju. Láàárín àkókò náà, àwọn àlùfáà ronú nípa ipò tí àwọn yóò pàdánù bí a bá ka Bíbélì sí ọlá àṣẹ gíga jù lọ. Nítorí náà, ọ̀ràn náà wá túbọ̀ di èyí tí ó mú ikú lọ́wọ́ fún olùtúmọ̀ náà àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀.
Nítorí tí Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba ń lé e káàkiri, Tyndale ń bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó níbi tí ó fara pa mọ́ sí ní Antwerp, Belgium. Síbẹ̀, ó ya ọjọ́ méjì sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ fún ohun tí ó pè ní àkókò ìgbafẹ́—ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn olùwábi-ìsádi yòó kù tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn òtòṣì, àti àwọn aláìsàn. Orí èyí ni ó ná èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú owó rẹ̀ sí. Kí ó tó lè túmọ̀ apá tí ó gbẹ̀yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí ó fojú jọ̀rẹ́, da Tyndale nítorí owó. Nígbà tí a pa Tyndale ní Vilvoorde, Belgium, ní ọdún 1536, ọ̀rọ̀ tí ó fi ìgbónára sọ fún un ni pé, “Olúwa! jẹ́ kí ojú inú Ọba England là.”
Fún ète ti ara rẹ̀, nígbà tí yóò fi di ọdún 1538, Ọba Henry Kẹjọ ti pàṣẹ pé kí Bíbélì wà ní gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì tí ń bẹ ní England. Bí a kò tilẹ̀ gbógo rẹ̀ fún Tyndale, ìtumọ̀ tìrẹ ni a yàn. Lọ́nà yí, ìwé Tyndale di èyí tí a mọ̀ bí ẹní mowó tí a sì nífẹ̀ẹ́ sí débi pé ó “pinnu ànímọ́ pàtàkì ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìtumọ̀ tí ó jẹyọ lẹ́yìn rẹ̀” lédè Gẹ̀ẹ́sì. (The Cambridge History of the Bible) Nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ìtumọ̀ Tyndale ni a gbé wọnú ìtumọ̀ King James Version ti ọdún 1611 ní tààràtà.
Níní Bíbélì lárọ̀ọ́wọ́tó jẹ́ ìyípadà ńláǹlà fún England. Àwọn ìjíròrò tí a ṣe nípa àwọn Bíbélì tí a mú kí ó wà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gbóná janjan débi pé, nígbà míràn, wọ́n máa ń forí gbárí pẹ̀lú ààtò ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì! “Àwọn arúgbó kọ́ láti mọ̀wéé kà, kí wọn baà lè lọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tààràtà, àwọn ọmọdé sì dara pọ̀ mọ́ àwọn àgbà láti tẹ́tí sílẹ̀.” (A Concise History of the English Bible) Sáà yí tún rí ìbísí mímúni jí gìrì nínú ìpínkiri Bíbélì ní àwọn ilẹ̀ míràn ní Europe àti ní àwọn èdè míràn. Ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Bíbélì ní England ní láti ní ipa jákèjádò ayé. Báwo ni èyí ṣe wáyé? Báwo sì ni àwọn àwárí àti ìwádìí síwájú sí i ṣe nípa lórí àwọn Bíbélì tí a ń lò lónìí? A óò mú ìròyìn wa wá sópin pẹ̀lú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀ lé e nínú ọ̀wọ́ yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Májẹ̀mú Tuntun” ti Tyndale ní 1526—odindi ẹ̀dà kan ṣoṣo tí a mọ̀ pé a kò dáná sun
[Credit Line]
© The British Library Board
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn Ọjọ́ Pàtàkì Nínú Ìtàtaré Bíbélì
Sànmánì tiwa
A bẹ̀rẹ̀ Bíbélì Wycliffe (ṣáájú 1384)
1400
A pa Hus ní 1415
Gutenberg—Bíbélì tí ó kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní nǹkan bí 1455
1500
Àwọn Tí A Kọ́kọ́ Tẹ̀ Jáde Ní Èdè Ìbílẹ̀
Ìtumọ̀ Erasmus lédè Gíríìkì ní 1516
“Májẹ̀mú Tuntun” ti Tyndale ní 1526
A pa Tyndale ní 1536
Henry Kẹjọ pàṣẹ pé kí Bíbélì wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì ní 1538
1600
Bíbélì King James Version ní 1611
[Àwọn àwòrán]
Wycliffe
Hus
Tyndale
Henry kẹjọ