Ṣe Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé Tá Á Ṣeé Tẹ̀ Lé
1 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Ọ̀nà tó dára jù tó o lè gbà ṣètò ìgbòkègbodò ìdílé rẹ táwọn nǹkan tẹ̀mí á fi lè wà láàyè tó yẹ ni pé kó o ṣàkọsílẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn. Wá ìṣẹ́jú díẹ̀ láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé tìrẹ nípa lílo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a kò kọ nǹkan sí tó wà lójú ìwé 6 nínú àkìbọnú yìí. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, àwọn kan lè gé àwọn ìgbòkègbodò tá a kọ sí ìsàlẹ̀ àpótí náà kí wọ́n sì lẹ̀ ẹ́ sínú àyè tó wà lábẹ́ ọjọ́ àti àsìkò tó bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ tiwọn mu. Àwọn míì lè fẹ́ láti fọwọ́ kọ ìgbòkègbodò wọn sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
2 Ìṣètò tá a dámọ̀ràn sísàlẹ̀ yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣètò tí ìdílé rẹ á máa tẹ̀ lé. Ṣàkíyèsí pé kò ju ìgbòkègbodò pàtàkì mẹrin péré lọ: (1) pípésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé, (2) iṣẹ́ ìsìn pápá ìdílé, (3) ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti (4) kíka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́. Bó o bá fi àwọn tá a mẹ́nu bà yìí kún ìṣètò tó o ṣe, wàá lè túbọ̀ “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Tún wo àwọn àbá míì nípa àwọn kókó mẹrin yìí lójú ìwé 4 sí 5.
Kò burú bí ohun tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé rẹ bá ju ìgbòkègbodò mẹrin yẹn lọ o. Tí ìdílé rẹ bá máa ń múra àwọn ìpàdé kan sílẹ̀ láfikún sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, kọ ìyẹn náà sínú ìṣètò ìdílé rẹ. Tẹ́ ẹ bá máa ń ka ẹsẹ Bíbélì mélòó kan lẹ́yìn ẹ̀kọ́ òjoojúmọ́ yín tàbí lásìkò míì tó yàtọ̀, fìyẹn náà sí i. Bó bá sì jẹ́ pé ṣe lẹ máa ń ṣe eré ìnàjú kan lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín, nígbà tẹ́ ẹ bá dé látòde ẹ̀rí tàbí láwọn ìgbà mìíràn, o lè kọ ìyẹn náà síbẹ̀.
Rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé náà bá ipò ìdílé rẹ mu. Kó o sì máa ṣàkíyèsí lóòrèkóòrè bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe wúlò tó kó o lè mọ̀ bó bá yẹ kẹ́ ẹ yí i padà.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 3]
Àpẹẹrẹ Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé
Àárọ̀ Ọ̀sán Ìrọ̀lẹ́
Sun. Ẹ̀kọ́ Ojoojúm
Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn
àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́
Mon. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
Tues. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ
Wed. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́
Thurs. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba
Ọlọ́run àti
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Fri. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́
Sat. Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́
Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Ìdílé
(Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn)
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé
Àárọ̀ Ọ̀sán Ìrọ̀lẹ́
Sun.
Mon.
Tues.
Wed.
Thurs.
Fri.
Sat.
..................................................................
Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́
Ojoo- Ojoo- Ojoo- Ojoo- Ojoo- Ojoo- Ojoo-
júmọ́ọ́ júmọ́ọ́ júmọ́ọ́ júmọ́ọ́ júmọ́ọ́ júmọ́ọ́ júmọ́ọ́
Àsọyé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́
fún Ìjọba Ìwé Ìjọ Ìdílé Ìsìn Bíbélì Eré Ìnàjú
Gbogbo Ọlọ́run Pápá Kíkà Ìdílé
Ènìyàn àti Ìdílé Ìdílé
àti Ìpàdé
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́
Ilé Ìṣọ́ Ìsìn