Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́
1 Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ máa ń sapá lójoojúmọ́ káwọn ọmọ wọn lè róúnjẹ gidi jẹ. Fífún wọn lóúnjẹ nípa tẹ̀mí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Mát. 4:4) Ọ̀nà kan tó o lè gbà ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí oúnjẹ aṣaralóore nípa tẹ̀mí lè máa wù wọ́n kí wọ́n sì “dàgbà dé ìgbàlà,” ni pé kó o máa fi àkókó sílẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan láti ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ pa pọ̀. (1 Pét. 2:2) Ìgbà wo ló yẹ kó o fi èyí kún ìṣètò ìdílé rẹ?
2 Nígbà Oúnjẹ: Bó bá jẹ́ pé àárọ̀ lo fi ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ ìdílé rẹ sí, ó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ lè máa ronú nípa Jèhófà jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. (Sm. 16:8) Ohun tí ìyá kan máa ń ṣe ni pé, ìgbà tí ọmọ rẹ̀ bá ń jẹun àárọ̀ ni wọ́n jọ máa ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, wọ́n á sì tún gbàdúrà, ẹ̀yìn ìgbà yẹn lọmọ á tó lọ síléèwé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn máa ń fún un lágbára láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ tọ́ràn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè bá délẹ̀, ó máa ń jẹ́ kó kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́, ò sí tún ń jẹ́ kó lè fi ìgboyà jẹ́rìí fáwọn olùkọ́ àtàwọn tí wọ́n jọ wà nílé ẹ̀kọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó wà nílé ẹ̀kọ́ náà, ìyẹn ò jẹ́ dà á lọ́kàn rú.
3 Bí ò bá rọrùn fún ìdílé rẹ láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ láàárọ̀, ẹ lè máa ṣe é nírọ̀lẹ́, bóyá nígbà tẹ́ ẹ bá ń jẹun alẹ́. Lákòókò yìí, àwọn kan tún máa ń sọ ìrírí tí wọ́n bá rí lóde ẹ̀rí tàbí kókó kan tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n ń ka Bíbélì wọn. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló sọ pé àsìkò yẹn jẹ́ ọ̀kan nínú èyí tó máa ń lárinrin jù lọ lára àkókò tí ìdílé àwọn fi máa ń wà pa pọ̀.
4 Lálẹ́: Àwọn ìdílé kan fẹ́ràn láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ tiwọn nígbà tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n sùn lálẹ́. Àsìkò yìí pàápàá lè jẹ́ àsìkò tó dáa jù láti gbàdúrà pa pọ̀. Báwọn ọmọ rẹ bá ń gbọ́ tó ò ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà lójoojúmọ́ tó o sì ń gbàdúrà sí i, Jèhófà á túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi lójú wọn.
5 A gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún ìsapá tó ò ń ṣe láti lè gbin òtítọ́ sínú àwọn ọmọ rẹ bó o ṣe ń lo Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ láti fi kọ́ wọn.