Máa Ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Jèhófà Lójoojúmọ́!
1 Ojoojúmọ́ ni ìpèníjà tuntun máa ń dìde sí ìgbàgbọ́ rẹ. Ó lè jẹ́ pé ojúlùmọ̀ rẹ kan tó jẹ́ ẹni ayé ń rọ̀ ọ́ ṣáá láti bá òun ròde. Olùkọ́ rẹ lè fẹ́ kí o lépa àtikàwé débi tó lámì, kí o wá jókòó ti iṣẹ́ ayé, agbanisíṣẹ́ rẹ sì lè fẹ́ kí o máa ṣiṣẹ́ fún wákàtí púpọ̀ sí i. Ara lè má ṣe ṣámúṣámú mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ìṣòro wọ̀nyí lè dé bá ọ nígbàkigbà, o ní aláfẹ̀yìntì. Jèhófà ṣe tán láti fún ọ ní ọgbọ́n tí o nílò láti kápá wọn. Ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì àti àlàyé inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ jẹ́ ọ̀nà kan tí o lè fi máa gba Ọ̀rọ̀ Jèhófà sínú déédéé. Ǹjẹ́ o máa ń lo àǹfààní ìpèsè yìí dáadáa?
2 Ìrànwọ́ Ń Bẹ Lárọ̀ọ́wọ́tó: Aísáyà 30:20 ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá,’ ẹni tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè máa wo ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ó máa ń pèsè ohun tí o nílò gẹ́lẹ́ láti kojú àwọn ìpèníjà tó bá dìde sí ìgbàgbọ́ rẹ. Báwo ló ṣe ń ṣe ìyẹn? Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.’” Lónìí, Jèhófà ń fi “ọ̀rọ̀” rẹ̀ ránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́” náà. (Mát. 24:45) Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń bẹ nínú àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tó ti kọjá pàápàá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo apá ìgbésí ayé Kristẹni ni wọ́n sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kó ìmọ̀ jọ, èyí sì wúlò gidigidi fún kíkojú onírúurú àdánwò.—Aísá. 48:17.
3 Ṣètò Àkókò fún Un: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ máa ń dí láàárọ̀, ìyá kan sọ ọ́ dàṣà láti máa ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àlàyé rẹ̀ kí ó sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀ nígbà tí ọmọ náà bá ń jẹ oúnjẹ àárọ̀. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn àti àdúrà ni ọmọ náà máa ń gbọ́ kẹ́yìn láràárọ̀ kó tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń fún un lágbára láti sọ pé rárá o nígbà tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ takọtabo lọ̀ ọ́, ó ń ràn án lọ́wọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni rárá, kí ó sì fi ìgboyà jẹ́rìí fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àti olùkọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, kò fìgbà kan ronú pé òun dá wà.
4 Máa wo ọ̀dọ̀ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ìdarí àti ìtọ́sọ́nà. Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò jẹ́ ẹni gidi lójú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tí o finú tán. Máa tọ̀ ọ́ lọ lójoojúmọ́! Bí o ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹlòmíràn kárí ayé tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí ojú rẹ di “ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá.”