ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/00 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 1/00 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986, fún ọrẹ ₦40. Àwọn ìjọ tí kò bá ní irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni (kékeré, ₦100; ńlá, ₦195). February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ nítorí àwọn èèyàn tó bá fìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

◼ Kí gbogbo akéde tí ó ti ṣe batisí, tí ó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 10 gba káàdì Advance Medical Directive/Release, kí wọ́n sì gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tí kò sì ní kọjá March 5, àsọyé tuntun tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ fún gbogbo èèyàn yóò jẹ́, “Amágẹ́dọ́nì Gidi—Èé Ṣe? Ìgbà Wo Ni?”

◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Wednesday, April 19, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má ṣeé ṣe ní gbogbo ìgbà. Níbi tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kí gbogbo ìjọ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà, kí àkókò lè wà láti kí àwọn àlejò, kí a sì lè fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ìfẹ́ hàn níṣìírí. Ó yẹ kí a tún ronú nípa ọ̀ràn ọkọ̀ àti ibi tí a óò páàkì wọn sí, títí kan jíjá èrò àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ ní àdúgbò wọn.

◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2000 ni a ó sọ ní ọjọ́ Sunday, April 16. Àkọlé àsọyé náà ni, “Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Ìràpadà.” A ó pèsè ìwé àsọyé. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 16, 2000.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́