Bí A Ó Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!
Àwọn ìjọ jákèjádò ayé yóò kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti ọ̀sẹ̀ May 23, 2005 sí ọ̀sẹ̀ June 20, 2005. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra ìpàdé náà sílẹ̀. Kí àwọn tí yóò darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lo àwọn ìbéèrè náà pẹ̀lú. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń lọ lọ́wọ́, ẹ ka àlàyé tó wà nínú ìwé náà kẹ́ ẹ sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀ bí àkókò bá ṣe wà sí.
Ọ̀sẹ̀ May 23
◼ Ojú ìwé 3 àti 4: Èwo gan-an nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a tò síbí ló ti kàn ọ́ rí? Kí nìdí tó o fi rò pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kì í kàn án ṣe àwọn èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lápá ọ̀dọ́ yín nìkan, tí a kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ nípa wọn, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì?
◼ Ojú ìwé 5: Kí ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa? Kí ló lè fi bí àwa náà ṣe bìkítà tó nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń ṣe hàn?
◼ Ojú ìwé 6 sí 8: Kí ni Mátíù 24:1-8, 14 sọ nípa ohun táwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí túmọ̀ sí? Àkókò wo ni 2 Tímótì 3:1-5 fi hàn pé a wà báyìí? Ọjọ́ ìkẹyìn kí ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí jẹ́? Kí ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́? Kí ni Ìjọba tá à ń wàásù rẹ̀?
◼ Ojú ìwé 9 àti 10: Kí nìdí tó fi yẹ ká fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́ àti àwọn ohun tá a fi ṣáájú nígbèésí ayé? (Róòmù 2:6; Gál. 6:7) Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 10, àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló wá sí ọ lọ́kàn tó yẹ kó máa darí àwọn ohun tó ò ń ṣe?
Ọ̀sẹ̀ May 30
◼ Ojú ìwé 11: Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ronú lórí àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé yìí? (1 Kọ́r. 10:12; Éfé. 6:10-18) Kí ni ohun tó bá jẹ́ ìdáhùn wa sí ìbéèrè yìí máa fi hàn nípa irú ọwọ́ tá a fi ń mú ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù 24:44?
◼ Ojú ìwé 12 sí 14: Kí ni “wákàtí ìdájọ́” tí Ìṣípayá 14:6, 7 mẹ́nu kàn? Kí ló túmọ̀ sí láti ‘bẹ̀rù Ọlọ́run àti láti fi ògo fún un’? Kí ni Bábílónì Ńlá, kí ló sì máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀? Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ ká gbé báyìí nípa Bábílónì Ńlá? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú apá mìíràn nínú wákàtí ìdájọ́ tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀? Àǹfààní wo ló wà nínú mímọ̀ tí a kò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí ìdájọ́ tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ máa dé? (Mát. 25:13)
◼ Ojú ìwé 15: Kí ni ọ̀ràn ipò Ọba Aláṣẹ, báwo sì ni ọ̀ràn yìí ṣe kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
◼ Ojú ìwé 16 sí 19: Kí ni “ọ̀run tuntun” àti “ayé tuntun”? (2 Pét. 3:13) Ta ló ṣèlérí àwọn nǹkan wọ̀nyí? Àwọn ìyípadà wo ni ọ̀run tuntun àti ayé tuntun yóò mú wá? Ǹjẹ́ ire yìí lè kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
Ọ̀sẹ̀ June 6
◼ Ojú ìwé 20 àti 21: Nínú ìkìlọ̀ tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní, ìgbà wo ni Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n sá lọ? (Lúùkù 21:20, 21) Ìgbà wo ló ṣeé ṣe fún wọn láti sá lọ bí Jésù ṣe kìlọ̀ fún wọn? Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ sá lọ kíákíá? (Mát. 24:16-18, 21) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi í ka ìkìlọ̀ kún? Báwo ni kíkọ táwọn èèyàn kọbi ara sí ìkìlọ̀ ṣe ṣe wọ́n láǹfààní ní Ṣáínà àti ní Philippines? Kí nìdí tó fi túbọ̀ jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú pé ká kọbi ara sí ìkìlọ̀ Bíbélì nípa òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí? Bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ kánjúkánjú yìí, kí ni ojúṣe wa? (Òwe 24:11, 12)
◼ Ojú ìwé 22 àti 23: Lọ́dún 1974, nílẹ̀ Ọsirélíà àti lọ́dún 1985, lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí wọ́n fún wọn nípa àjálù tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ká ní pé o wà níbẹ̀ nígbà yẹn, kí lo rò pé ò bá ṣe nígbà tó o gbọ́ ìkìlọ̀ náà, kí sì nìdí tó ò bá fi ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló lè fi hàn bóyá à bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wáyé nígbà ayé Nóà ká ní a wà láyé nígbà náà? Kí nìdí táwọn èèyàn fi fẹ́ láti máa gbé ní Sódómù ayé ọjọ́un àti ní àgbègbè rẹ̀? Báwo ni ríronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sódómù ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
Ọ̀sẹ̀ June 13
◼ Lo àwọn ìbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lójú ìwé 27.
Ọ̀sẹ̀ June 20
◼ Lo àwọn ìbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lójú ìwé 31.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè “máa bá a níṣò ní ṣíṣọ́nà” ká sì fi hàn pé a wà ní ìmúratán. Ǹjẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì kan kéde ti di kánjúkánjú. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.”—Mát. 24:42, 44; Ìṣí. 14:7.