MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́
Ṣé o máa ń ka ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Ṣé ó wà lára ohun tó o máa ń ṣe lójoojúmọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Tí o kì í bá ráyè ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé o lè fi kún ohun tó o máa ń ṣe? Àwọn kan máa ń kà á ní ìdájí kí wọ́n lè máa ronú lé e lórí jálẹ̀ ọjọ́ yẹn. (Joṣ 1:8; Sm 119:97) Báwo ló ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní nínú ẹsẹ Bíbélì ọjọ́ kọ̀ọ̀kan? Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú àti èyí tó tẹ̀ lé èyí tí wọ́n tọ́ka sí, kó o lè mọ ibi tí wọ́n ti ń bọ́rọ̀ bọ̀ àti ibi tí wọ́n ń bọ́rọ̀ lọ. Ronú nípa àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì tó ṣàlàyé ìlànà tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì náà. Lẹ́yìn ìyẹn, wo bó o ṣe lè fi ìlànà náà sílò. Ó dájú pé tó o bá ń ronú nípa àwọn ìlànà Bíbélì kó o tó ṣèpinnu, ìgbésí ayé rẹ máa nítumọ̀, á sì ṣe ẹ́ láǹfààní.—Sm 119:105.
Àsìkò oúnjẹ àárọ̀ làwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́. Àtọdún díẹ̀ sẹ́yìn la ti ń gbé àwọn ìjíròrò yìí sórí JW Broadcasting® ìyẹn ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Wàá rí àwọn fídíò yìí ní abala ÀWỌN ÈTÒ ÀTI ÌṢẸ̀LẸ̀ PÀTÀKÌ. Ìgbà wo lo lọ síbẹ̀ kẹ́yìn, bóyá tó o wo ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú wọn? Ó ṣeé ṣe kó o gbọ́ ọ̀rọ̀ tó máa bá ipò rẹ mu. Bí àpẹẹrẹ, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì ṣe lè mú kó o ṣe ìpinnu tó tọ́?
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ MÁ ṢE MÁA NÍFẸ̀Ẹ́ AYÉ (1JO 2:15), KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni mo ṣe lè fi hàn jálẹ̀ ọjọ́ kan pé mo mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?