FEBRUARY 24–MARCH 1
JẸ́NẸ́SÍSÌ 20-21
Orin 108 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ”: (10 min.)
Jẹ 21:1-3—Sérà lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan (wp17.5 14-15)
Jẹ 21:5-7—Jèhófà ṣe ohun tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe
Jẹ 21:10-12, 14—Ábúráhámù àti Sérà nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa Ísákì
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 20:12—Báwo ni Sérà ṣe jẹ́ àbúrò Ábúráhámù? (wp17.3 12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé)
Jẹ 21:33—Báwo ni Ábúráhámù ṣe ké pe “orúkọ Jèhófà”? (w89 7/1 20 ¶9)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 20:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni akéde yẹn ṣe jẹ́ kí onílé rí ìdí tó fi ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà? Báwo ni ìpadàbẹ̀wò tí akéde yẹn ṣe ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa?
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 4)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bhs 35 ¶19-20 (th ẹ̀kọ́ 3)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, lẹ́yìn náà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 16 ¶9-10 àti àfikún Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 119 àti Àdúrà