ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 18-19
“Onídàájọ́ Gbogbo Ayé” Pa Sódómù àti Gòmórà Run
Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà ṣe sáwọn ará ìlú Sódómù àti Gòmórà?
Jèhófà ò ní gbà káwọn ẹni burúkú máa hùwà ìkà títí lọ
Àwọn tó bá ń fetí sí àṣẹ Jèhófà, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ló máa la ìparun tó ń bọ̀ já.—Lk 17:28-30
BI ARA RẸ PÉ: ‘Ṣé ìwà àìnítìjú táwọn èèyàn ayé ń hù máa ń kó mi nírìíra?’ (2Pe 2:7) ‘Ṣé ó hàn nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe pé ìfẹ́ Jèhófà ló gbà mí lọ́kàn?’