Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 7
Orin 47
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ, fún oṣù July.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà dídáńgájíá mìíràn jíròrò ìsọfúnni pẹ̀lú àwùjọ.
20 min: “Múra Ìgbékalẹ̀ Tìrẹ fún Ìfilọni Ìwé Ìròyìn.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 7) Béèrè ìbéèrè lórí ìpínrọ̀ 1 sí 4, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kúkúrú méjì tàbí mẹ́ta, láti fi bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni hàn, ní lílo àwọn ìdámọ̀ràn tí ó wà ní ìpínrọ̀ 5 sí 7. Fi àlàyé tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà March 1, 1987, ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 8, 9, kún un.
Orin 222 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 14
Orin 39
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn: (1) Ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ìwé tí o fi síta, àti ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o gbé jáde lákànṣe, (2) ṣètò láti padà wá pẹ̀lú ẹ̀dà tí ó tẹ̀ lé e, kí o sì (3) ya àkókò pàtó kan sọ́tọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ìsìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ láti ṣe àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyí. Fí àsansílẹ̀ owó ọlọ́dún kan lọ̀ ọ́. Bí kò bá gbà á, fi ti olóṣù mẹ́fà lọ̀ ọ́, kí o sì rántí láti ròyìn ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìpadàbẹ̀wò kan.
15 min: “Kíkéde Ìhìn Rere Ohun Dídára Jù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ mánigbàgbé, tí ó ti fara hàn nínú Ilé Ìṣọ́.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà March 1, 1987, ojú ìwé 10.
20 min: “Múra Ìgbékalẹ̀ Tìrẹ fún Ìfilọni Ìwé Ìròyìn.” (Ìpínrọ̀ 8 sí 11) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé lórí àwọn ìdámọ̀ràn mẹ́rin, tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1994, ojú ìwé 24 àti 25, ìpínrọ̀ 18 sí 21, kún un. Ní lílo àwọn ìwé ìròyìn October, fi bí a ṣe lè múra ìfilọni sílẹ̀ hàn: (1) Yan ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ó ṣeé ṣe kí ó fa ọkàn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ mọ́ra, (2) wá kókó tí ń fani lọ́kàn mọ́ra kan láti gbé jáde lákànṣe, (3) ronú ìbéèrè tí o lè lò láti pé àfiyèsí sórí kókó náà, (4) yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ìwọ yóò kà, bí a bá gbà ọ́ láyè, kí o sì (5) múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ àti òun tí ìwọ yóò sọ nípa ìwé ìròyìn náà, kí o baà lè fún onílé níṣìírí láti gbà á. Jẹ́ kí akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Fi èwe kan, tí yóò ṣàṣefihàn ìfilọni ìwé ìròyìn, tí kò nira, kún un.
Orin 82 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 21
Orin 169
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
17 min: “Ṣe Ìpínlẹ̀ Rẹ Kúnnákúnná.” Jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà àti ètò tí ẹ ṣe fún ṣíṣe àwọn agbègbè ìṣòwò. Ké sí àwùjọ láti sọ ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní àwọn ìsọ̀ tí ó wà nínú ìpínlẹ̀ wọn.
18 min: Àwọn àìní àdúgbò. Tàbí ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Di Ìgbọ́kànlé Rẹ Mú Ṣinṣin Títí Dé Òpin,” láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1996, ojú ìwé 21 sí 24.
Orin 12 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 28
Orin 27
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Pẹ̀lú àwọn ọlidé ayé tí ń bọ̀ ní December, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó fún wa ní àyè lẹ́nu iṣẹ́ àti nílé ẹ̀kọ́, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ronú lórí ṣíṣeé ṣe láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà. Rọ gbogbo àwùjọ láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti October sílẹ̀ ní ìparí ọ̀sẹ̀ yìí.
20 min: “Bí A Ṣe Lè Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, December 1, 1989, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 7 sí 11 kún un.
15 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní Oṣù November. A óò fi ìwé Ìmọ̀ lọni, a óò sì ṣe ìsapá àkànṣe láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Àwọn akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta jíròrò ìníyelórí ìwé náà, àti bí a ṣe lè lò ó. Ìsọfúnni tí ń bẹ nínú rẹ̀ kan ìgbésí ayé gbogbo ènìyàn níbi gbogbo. Ó kárí àwọn kókó ẹ̀kọ́ àti ìlànà ìpìlẹ̀ Bíbélì, tí àwọn ẹni tuntun ní láti lóye kí wọ́n tó ṣe batisí. Bí a bá jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa lọ déédéé, akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò tètè tẹ̀ síwájú. Ẹ jíròrò kí ẹ sì ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa lílo ọ̀nà ìgbàyọsíni tààràtà: Ṣàyẹ̀wò àwòrán àti àkọlé àwòrán tí ń bẹ ní ojú ìwé 4 àti 5; ṣàlàyé ọ̀nà tí a gbà ń kẹ́kọ̀ọ́; ní ṣókí, jíròrò àwọn ìpínrọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ ní orí 1; ṣàdéhùn láti padà wá, láti máa bá ìjíròrò náà lọ, ní dídáhùn ìbéèrè náà, Ìyè àìnípẹ̀kun ha jẹ́ àlá kan lásán bí? Tẹnu mọ́ ayọ̀ tí ń bá àǹfààní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé rìn.
Orin 162 àti àdúrà ìparí.