ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/05 ojú ìwé 1
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Fàájì Mọ sí Àyè Tó Yẹ Kó Wà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Bí A Ṣe Lè Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Lo Kà sí Pàtàkì Jù?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 9/05 ojú ìwé 1

Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ

1 Nítorí pé ó wù wá ká máa ṣe ohun tó dùn mọ́ Jèhófà la ṣe ń ka nǹkan tẹ̀mí sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Ó tọ́ wa sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa ‘wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’ ká sì “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Mát. 6:33; Fílí. 1:10) Báwo la ṣe lè máa ra àkókò padà ká bàa lè máa bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa fàwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí ipò kejì?—Éfé. 5:15-17.

2 Fi Ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run sí Ipò Kìíní: Ṣètò àkókò rẹ kó o má bàa fi ṣòfò lé àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lórí. Ohun táwọn kan máa ń ṣe níbẹ̀rẹ̀ oṣù ni pé wọ́n á sàmì sáwọn àkókò tí wọ́n á lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lórí kàlẹ́ńdà wọn. Wọ́n á sì ṣọ́ra káwọn nǹkan míì má bàa ba ètò tí wọ́n ṣe jẹ́. Àwa náà lè ṣe irú ètò yìí ká bàa lè ra àkókò padà fún àwọn ìpàdé, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àpéjọ. Ọ̀pọ̀ tiẹ̀ ṣètò pé káwọn kọ́kọ́ máa ka Bíbélì báwọn bá jí láàárọ̀ tàbí lálaalẹ́ káwọn tó sùn. Ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ fáwọn nǹkan pàtàkì pàtàkì tó o bá ní láti ṣe, má sì ṣe jẹ́ káwọn nǹkan míì pa ohun tó o fẹ́ ṣe lára bí kò bá nídìí.—Oníw. 3:1; 1 Kọ́r. 14:40.

3 Má Ṣe Lo Ayé dé Ẹ̀kún Rẹ́rẹ́: Láwọn ilẹ̀ kan, kò ṣòro láti rí eré ìdárayá, eré ìnàjú, eré ìtura, eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì téèyàn lè fi pawọ́ dà. Àṣejù tiẹ̀ wọ àkókò táwọn kan fi ń wo tẹlifíṣọ̀n tàbí èyí tí wọ́n ń lò nídìí kọ̀ǹpútà. Èyí ó wù kó jẹ́, béèyàn bá ń pẹ́ jù nídìí fàájì, àtàwọn ohun èlò ìgbàlódé tó wà lóde, ìjákulẹ̀ náà ni gbogbo ẹ̀ máa pàpà já sí. (1 Jòh. 2:15-17) Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi rọ̀ wá pé ká má ṣe lo ayé dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́. (1 Kọ́r. 7:31) Bó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yẹn, o lè fi han Jèhófà pé ìjọsìn rẹ̀ ló gba ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ.—Mát. 6:19-21.

4 Àkókò tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí á dópin ti kù rébété. Àwọn tó bá ń fàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní á láyọ̀, wọ́n á sì jèrè ojú rere Ọlọ́run. (Òwe 8:32-35; Ják. 1:25) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti fọgbọ́n lo ohun ìní ṣíṣeyebíye yìí, ìyẹn ni àkókò wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́