Kí Lo Kà sí Pàtàkì Jù?
1 Báwo lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè yẹn? Kò síyè méjì pé gbogbo wa la máa fẹ́ jẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run gbawájú nígbèésí ayé wa. (Mát. 6:33) Ṣùgbọ́n a lè bi ara wa pé, ‘Ṣé ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú nígbèésí ayé mi?’ Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:5) Báwo la ṣe lè mọ̀ dájú pé ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run la fi ṣíwájú nínú ayé wa?
2 Bá A Ṣe Ń Lo Àkókò Wa: A lè bẹ̀rẹ̀ látorí ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó máa ń wù wá láti fi àkókò wa ṣe. (Éfé. 5:15, 16) Báwo ni àkókò tá a fi ń lọ kí àwọn èèyàn, tá à ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n, nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí nídìí àwọn eré ọwọ́dilẹ̀ ṣe máa ń pọ̀ tó? Bá a bá kọ iye àkókò tá à ń lò nídìí àwọn nǹkan wọ̀nyí sílẹ̀ tá a wá fi wé èyí tá a fi ń ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, ó lè yà wá lẹ́nu. Ṣé a máa ń lo àkókò tó pọ̀ níbi iṣẹ́ débi tá a o fi ní í lè lo àkókò tó yẹ ká lò nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́, torí ká lè ráàyè gbá fàájì? Ìgbà mélòó la máa ń pa ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí jẹ torí àtilè rìnrìn-àjò láti najú lọ?
3 Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Ni Kó Gbawájú: Ọ̀pọ̀ wa la ò ní àkókò tó tó láti ṣe gbogbo ohun tó wù wá. Nítorí náà, láti lè fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run síwájú, a ní láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tá a kà sí pàtàkì, ká sì mọ bá a ṣe máa wáyè fún “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Èyí kan kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, bíbójútó ìdílé ẹni àti lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. (Sm. 1:1, 2; Róòmù 10:13, 14; 1 Tím. 5:8; Héb. 10:24, 25) Àwọn ìgbòkègbodò míì bí eré ìmárale tó bójú mu àti eré ìnàjú tó gbámúṣé máa ń ṣàǹfààní. (Máàkù 6:31; 1 Tím. 4:8) Àmọ́, a ó gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì yìí gba àkókò tó yẹ ká lò nídìí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọba Ọlọ́run.
4 Arákùnrin ọ̀dọ́ kan sapá láti jẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run gbawájú nípa bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún dípò tí ì bá fi máa lépa àtiwọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kó bàa lè rọ́wọ́ mú nínú ayé. Ó kọ́ èdè mìíràn, ó sì lọ síbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó ní: “Mò ń gbádùn ara mi gan-an níbi tí mo wà yìí o. Bíi kéèyàn má padà sílé mọ́ ni tó bá ti lọ sóde ẹ̀rí! Ì bá mà wù mí o, ká ní gbogbo ọ̀dọ́ ló lè lọ síbi tí wọ́n ti ń fẹ́ àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, káwọn náà sì rí bí iṣẹ́ náà ṣe lárinrin tó. Kò sóhun tó dà bíi kéèyàn fi gbogbo ohun tó ní sin Jèhófà.” Bó ṣe rí nìyẹn o, jíjẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run gbawájú máa ń mú ìbùkún wá fún wa, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ó máa ń dùn mọ́ Baba wa ọ̀run, Jèhófà nínú.—Héb. 6:10.