ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/01 ojú ìwé 8
  • Fi Fàájì Mọ sí Àyè Tó Yẹ Kó Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Fàájì Mọ sí Àyè Tó Yẹ Kó Wà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ẹ̀mí Ayé Ha Ń bà Ọ́ Jẹ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú ẹ Jìnnà Sí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 8/01 ojú ìwé 8

Fi Fàájì Mọ sí Àyè Tó Yẹ Kó Wà

1 Ní àwọn ọjọ́ tó le koko wọ̀nyí, gbogbo wa ló nílò ìyíwọ́padà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kò sóhun tó burú nínú ṣíṣe eré ìtura níwọ̀nba. Ṣùgbọ́n, bí èèyàn bá ń lo àkókò púpọ̀ jù nídìí fàájì, nídìí eré ìnàjú, àti nídìí ìgbafẹ́, ó lè mú kí ẹni náà bẹ̀rẹ̀ sí lo àkókó tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan nídìí àwọn nǹkan tẹ̀mí. A gbọ́dọ̀ fi fàájì mọ sí àyè tó yẹ kó wà. (Mát. 5:3) Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn tó wà ní Éfésù 5:15-17 ni.

2 Fi Ààlà Sí I: Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni “máa ṣọ́ra lójú méjèèjì” ní ti bí wọ́n ṣe ń fi ọgbọ́n gbé ìgbé ayé wọn. Ó gba ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìkóra-ẹni-níjàánu láti fi àkókò fàájì mọ sí ìgbà tó bá pọndandan gan-an. Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà tí a ń gbà lo àwọn àkókò tí ọwọ́ wa máa ń dilẹ̀. Ńṣe ló yẹ kí eré ìtura ṣe wá láǹfààní dípò táa fi mú ká ronú pé ńṣe la fi àkókò wa ṣòfò tàbí táa fi mú kí ó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Bó bá jẹ́ pé lẹ́yìn táa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò kan tán, ọkàn wa ń dá wa lẹ́bi lọ́nà kan ṣáá, ìyẹn yóò fi hàn pé ó yẹ kí á ṣe ìyípadà nínú bí a ṣe ń lo àkókò wa.

3 Lo Ọgbọ́n: Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn lórí “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà” láti fi ṣe àwọn nǹkan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì ní ìgbésí ayé, ká má ṣe di “aláìlọ́gbọ́n-nínú.” Àwọn Kristẹni to ya ara wọn sí mímọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí fàájì di ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsinmi àti fàájì lè fún wa lókun nípa ti ara, agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ló ń fún wa lágbára nípa tẹ̀mí. (Aísá. 40:29-31) Ìgbà tí a bá wà lẹ́nu ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run, irú bíi, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àti lílọ sí iṣẹ́ ìsìn pápá la máa ń rí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gbà kì í ṣe ìgbà tí a bá ń ṣe eré ìtura.

4 Gbé Àwọn Ohun Àkọ́múṣe Kalẹ̀: Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” Jésù fi kọ́ni pé Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ kí ó gba ipò iwájú nínú àwọn ìgbòkègbodò wa ní ìgbésí ayé. (Mát. 6:33) Ó ṣe pàtàkì pé kí á kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan tí yóò lè jẹ́ ká pa ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àá lè fi fàájì mọ sí àyè tó yẹ kó wà. Nígbà táa bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò lè gbé wa ró, a ó sì túbọ̀ gbádùn rẹ̀.—Oníw. 5:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́