Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Láti Wéwèé Kí Wọ́n sì Lo Àkókò Ìsinmi Wọn Lọ́nà Ọgbọ́n
1 Ṣé kì í ṣe òótọ́ ni pé yóò ṣeé ṣe fún wa láti lé àwọn ohun yíyẹ táa ní lọ́kàn bá tí a bá wéwèé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lo àkókò táa ní? Àkókò ìsinmi máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn èwe wa tó ń lọ ilé ẹ̀kọ́ ní ìsinmi tó ń gbádùn mọ́ni tó mú wọn ṣíwọ́ kúrò lẹ́nu ìgbòkègbodò ilé ẹ̀kọ́ wọn. Ṣùgbọ́n, ó tún lè ṣẹlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọ ni àwọn òbí kò ní bójú tó ní àkókò yẹn tí àwọn ọmọ ọ̀hún sì lè tipa báyìí ṣi àkókò wọn lò. (Òwe 29:15) Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ èwe lè lo púpọ̀ nínú àkókò ìsinmi wọn láti fi wo tẹlifíṣọ̀n tàbí fídíò lónírúurú tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó ń gba àkókò tàbí tí kò gbéni ró. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ọ̀ràn rí bẹ́ẹ̀.
2 Ẹ̀yin òbí, ńṣe ni àkókò ìsinmi ń fún yín láǹfààní láti wéwèé àwọn ìgbòkègbodò yíyẹ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ọ̀pọ̀ òbí lo ti rí i pé ó wúlò láti wéwèé ìsinmi wọn ọdọọdún kúrò lẹ́nu iṣẹ́ sígbà àkókò ìsinmi àwọn ọmọ wọn kí ìdílé wọn lè ní àkókò ìsinmi pa pọ̀ kí wọ́n sì jọ rìnrìn àjò kí ìyípadà díẹ̀ lè wà nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe nǹkan lójoojúmọ́. Ó tún lè jẹ́ kí ìdílé ní àǹfààní láti kópa nínú mímú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. (Òwe 21:5) Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe?
3 Ẹ ò ṣe wéwèé bí ìdílé kan láti mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá yín pọ̀ sí i ní àkókò ìsinmi? Àkókò ìsinmi ilé ìwé máa ń jẹ́ kí àwọn èwe láǹfààní láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí àwọn òbí bá wéwèé dáadáa, àwọn pẹ̀lú lè ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ní oṣù August yìí, bí ọdún iṣẹ́ ìsìn yìí ti ń lọ sópin, kí gbogbo wa jùmọ̀ sapá láti túbọ̀ lọ sí òde ẹ̀rí bí a bá ti lè lọ tó. Bí àwọn ìdílé bá jọ wéwèé pa pọ̀ láti túbọ̀ lọ sóde ẹ̀rí, nígbà náà, gbogbo wọn ni yóò sapá láti mú kí ó ṣeé ṣe.—Òwe 15:22.
4 Ǹjẹ́ ẹ lè wéwèé láti ṣèrànwọ́ fún ìjọ tó wà nítòsí yín tí wọ́n ń fẹ́ ìrànwọ́ láti ṣe ìpínlẹ̀ wọn? Ẹ lè ṣètò bí ìdílé kan láti lọ wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í sábàá ṣe tàbí tí a kò yàn fúnni.—Mát. 24:14.
5 Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí ẹ̀yin àti ìdílé yín yóò bá rìnrìn àjò lọ síbòmíràn, ẹ wéwèé láti lọ sí àwọn ìpàdé kí ẹ sì lọ sí òde ẹ̀rí pẹ̀lú ìjọ tó wà níbẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìbátan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lẹ fẹ́ lọ bẹ̀ wò, ẹ múra àwọn ọ̀nà tí ẹ lè gbà fi òtítọ́ kọ́ wọn sílẹ̀ ṣáájú.—Ẹ wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1990, ojú ìwé 25 sí 27.
6 Kí lẹ ń wéwèé fún ní àkókò ìsinmi tó ń bọ̀? Ó dájú pé ẹ fẹ́ kára tu ìdílé yín. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe gbójú fo àwọn àǹfààní tó túbọ̀ ṣe pàtàkì tí ẹ ní láti ru ìdílé yín sókè nípa tẹ̀mí nípa bíbá a nìṣó láti fi àwọn ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé yín.—Mát. 6:33; Éfé. 5:15, 16.